ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI January 27, 2019. Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ (ÌPÍN KEJÌ)  IGBASOKE

By | January 27, 2019

 

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI January 27, 2019. Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ (ÌPÍN KEJÌ)  IGBASOKE



ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
ÈTÒ AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN FUN ENIYAN

January 27, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ (ÌPÍN KEJÌ)
IGBASOKE

II.   ERONGBA ÀTI ÀWỌN ÀBÙDÁ/AMUYẸ (I Kor. 15:21-23,51-28; I Tesa. 4:14-17).
Erongba ni idi fún ohun kan, nígbà ti amuyẹ jẹ àbùdá tí ẹnikan nilo láti yẹ fún ohun kan tàbí ohun tí o nilo láti wa ni ipo kan. Kin ni idi fun bibọ Jesu Olúwa, ki sì ni àwọn ohun tí yoo mú kí ènìyàn yẹ fún fifo lọ pẹlu Rẹ?

A.   ERONGBA FÚN IGBASOKE (I Kor. 15:21-23,51-58; I Tesa. 4:14-17).
Nigba naa ni a o si gba awa tí o wa láàyè tí o sì ku lẹ́yìn soke pẹlu wọn sínú àwọsánmà, láti pàdé Olúwa ni ojú ọrùn; bẹẹni awa o si maa wa titi lae lọdọ Olúwa (I Tesa. 4:17).
i.   Lati gba àwọn ènìyàn mimọ sọ́dọ̀ ara Rẹ bi O ti ṣèlérí (Jhn. 14:1-3; Efe. 5:27; I Tesa. 4:17).
ii.  Lati jí àwọn òkú ninu Kristi dìde kuro láàrin àwọn àwọn òkú búburú (I Kor. 15:21-23,51-58; Filip. 3:11; I Tesa. 4:14-17).
iii. Láti ko àwọn ayanfẹ lọ sí àwọsánmọ láti gba èrè wọn (Jhn. 14:1-3; 2 Kor. 5:10; 1 Tesa. 3:13) láti kopa ninu àṣe ìgbéyàwó ọdọ Àgùntàn (Ifih. 19:19).
iv. Láti pá ara àwọn ènìyàn mimọ da kúrò ní kíkú sì aiku (I Kor. 15:21-23, 51-56; 2 Kor. 5:1-8; Filip. 3:20-21). Lati sọ àwọn ènìyàn mimọ di mimọ niti ẹ̀mí, ọkàn àti ara (Fil. 3:21; I Tesa. 4:16-17; 5:23).
v.  Láti ko àwọn ènìyàn mimọ wa síwájú Ọlọ́run (Jhn. 14:1-3; I Tesa. 3:13; Juda 24).
vi. Láti gba èso ọjọ akọrọ àti àrọkuro (Jhn. 14:1-3; Jak. 5:7).
vii. Láti mú àdinílọ́wọ́, ohun ìjìnlẹ̀ àìlófin kuro (2 Tesa. 2:1-8)
viii.Lati ko àwọn ènìyàn mimọ yọ kuro ninu ìpọ́njú tí o ń bọ̀ lórí ilẹ̀ ayé (Lk. 21:34-36; Ifih. 3:10).
xi. Lati faaye gba ìfarahàn aṣòdì-sí-Kristi 2 Tesa. 2:1-8). Nígbà tí a ba ti gba àwọn ènìyàn mimọ sókè tán, asodi sì Kristi yoo farahàn láti mu àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ ṣẹ.
x. Ti a ba wo idi ti Jesu Olúwa wa yoo fi pada wa, igbasoke tó láti dúró de àti láti ṣiṣẹ́ fun un.

B.  ÀWỌN ÀBÙDÁ TÀBÍ AMUYẸ ẸNI IGBASOKE (I Tesa. 4:16).
… Àwọn òkú nínú Kristi ni yoo si kọ jinde (I Tesa. 4:16).
i.  Wa ninu Kristi (2 Kor. 5:17-18; I Tesa. 4:16).
ii. Jẹ ẹni mimọ kí aya rẹ si funfun (Jhn. 3:1-3) laini àbáwọn (Efe. 5:27).
iii.Maa sọ́nà ki o si maa gbàdúrà nígbà gbogbo (Lk. 21:34-35).
iv. Máa rin nínú imọlẹ (I Jhn. 1:17; Kol. 2:6-7).
v. Maa rin nínú Ẹ̀mí (Gal. 5:16,25-26). Máa fi eso Rẹ hàn ní ojoojumọ (ẹsẹ 22).
vi. Wa loju ọna, òtítọ́ àti iye naa (Jhn. 14:1-6)
vii. Kan ẹran ara àti Ifẹkufẹ rẹ mọ àgbélébù (Gal. 2:20).
viii.Wa ninu ijọ tabi ara Kristi (I Kor. 12:13; Efe. 5:27; 1:22,23; Kol. 1:18,24).
ix. Duro ninu idalare nipa igbagbọ àti ìgbàlà nípa oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ki o si gbọ́ràn sì òtítọ́.
x. Maa ṣe rere (Jhn. 5:28-29).
xi.Awọn amuyẹ wọ̀nyii pe fún diduroore ni iha tí Kristẹni naa. Ọjọ́ (àkókò) ti lọ. A gbọ́dọ̀ gbé ìgbé-ayé wa ni ibamu pẹ̀lú òṣùwọ̀n mímọ Olúwa wa, Jésù Kristi, òṣùwọ̀n yii si wa ninu Bíbélì. A gbọdọ maa sasaro nínú rẹ, gbé nípa rẹ, wàásù rẹ ni igba ti o wọ àti ìgbà tí ko wọ.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.  Ọlọ́run iba ma tí gba igbasoke láàyè lainidii. Fun anfaani wa ni. Mase fi ṣeré.
2. Iye àwọn tí wọn ba kun ojú osunwọn Kristi nìkan, ní wọ́n yoo jẹ anfaani igbasoke.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1.   Kín ni ìtumọ̀ igbasoke?
2.  Bawo ni igbasoke yoo ṣe ri?
3.  Kin ni erongba igbasoke?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ:
i.  Lọ wo ipin I, abala A.
ii. Ani, kari ayé, igbasoke yoo jẹ ohun ìdùnnú tí ènìyàn yoo kun fun ayọ̀ tí ko si ni rántí ohunkóhun mọ.
iii.Lati inu ìwòye àwọn Kristẹni, niti òye kíákíá, o jẹ iriri tí o tayọ nínú èyí tí ènìyàn gbagbọ tí yoo gbe lọ si ipele ayé tí ẹmi.
iv. Èyí naa tun bá ipadàbọ̀ Jesu Kristi lẹẹkeji mu, nígbà tí a n retí pe ki àwọn onigbagbọ tòótọ́ o jinde kí wọn sì fo lọ pàdé Rẹ ni àwọsánmọ.
v. Igbasoke jẹ iriri tí o ga nínú eyi ti a ti fi ẹjẹ Jésù wẹ àwọn tí wọn gba Kristi ni Oluwa ti wọn si n gbe fún-Un nínú ìwà-mímọ àti ododo Rẹ, ní a o palarada niti ẹ̀mí, tí wọn yoo goke lọ pàdé Rẹ ni ofurufu, lẹyin tí O ba ti kọkọ farahàn ni àwọsánmọ.
vi. Iriri tí o ga julọ yii ni yoo fun gbogbo Kristẹni tí yoo kopa ninu rẹ àti alààyè àti òkú ní iriri ayọ̀ tòótọ́, pàápàá, títí láé, àti pípé.
vii. I Kor. 15:51-57, I Tesa. 4:13 síwájú àti àwọn ẹsẹ Ìwé mímọ́ miran jẹri sì èyí.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJÌ
i.  Ọ̀nà àgbàṣe ni ọna ti a gba ṣe nnkan, tàbí ọna ti o gba ṣẹlẹ̀.
ii. Bi igbasoke yoo ṣe ṣẹlẹ̀, a n sọ nípa bí igbasoke yoo ṣe waye.
iii.Jhn.14:1-3; I Kor. 15:51-26; Filp. 3:11,20-21; I Tesa. 4:13-18 ni iwe mímọ tí wọn tí ṣàlàyé èyí.
iv. Lọ wo ipin I, abala Bẹkọ yii, fun àwọn alaye síwájú sii.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KẸTA
i.  Lọ wo ipin II, abala A.

ÀMÚLÒ FÚN IGBE AYÉ ẸNI :
Nínú Májẹ̀mú Láéláé, a ri àwọn itọkasi bi igbasoke yoo ti rí àti bi yoo ṣe ṣẹlẹ̀. Héb. 11:5 tọkasi iṣẹlẹ inú Gen. 5:24. Nipa igbagbọ ni a si Enoku nipo pada kí o mase rí ikú, “a ko si ri i; nítorí Ọlọ́run si ni i nipo pada” Bẹẹ naa ni ìyípadà agbára wolii ńlá ni, Elija tí ajá gbé lọ sí ọ̀run (2 A Ọba 2:11).

Orisun kan tí a ko mọ sọ àwọn ọrọ wọ̀nyii: A nilati ma a ṣíṣe bi a ti ń retí igbasoke. Asọgba fún ọgbà ńlá ni ariwa Itali n mú àlejò yi ilẹ̀ àti ọgbà daradara yii ka. Bi àlejò naa ti n jẹun pẹlu olùsọgba àti ìyàwó rẹ, o yin wọn fun bi wọn tí ń tọju ọgbà naa. O béèrè wi pe ìgbà wo ni onile naa wa sihin gbẹyin? Ọlọ́gba naa dahun pe ọdún mẹwaa. Alejo naa béèrè pé “Kínní idi ti o ṣe wa n tọju ọgbà naa ni ọna daradara bayii?” Ọlọ́gba naa dahun “Nítorí mo n reti rẹ láti padà wa.” Ṣe ọ̀sẹ̀ tí o n bọ ni o maa wa ni? Ọlọ́gba naa dáhùn, “N ko mọ ìgbà tí o n bọ, ṣùgbọ́n mo n reti rẹ lonii.”

Òtítọ́ ni eti. A ko mọ ìgbà tí Jesu yoo wa. Idi ni èyí tí a fi gbọdọ maa retí Rẹ kódà, nisinsin yii. Igbasoke yoo dabi ìgbà tí olúkúlùkù tẹpẹlẹ mọ iṣẹ oojọ rẹ, ní ìṣẹ́jú kan, lojiji, a o gba àwọn ènìyàn soke ọrun lati pàdé Olúwa, ti a o si re aisan ọjọ ogbó àti ikú kọjá! Iṣẹlẹ tí yoo kede wiwa Jesu ni eyi (Mat. 24:37-41). Bíbélì sọ pé nígbà wiwa Rẹ gbogbo onigbagbọ ní a o gbà sókè ọrùn gẹ́gẹ́ bí Enoku àti Elija! N jẹ o ti mura tan?

IGUNLẸ:
A ti sọ̀rọ̀ pupọ lori iṣẹlẹ tí a n reti kí o ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé. A ti sọ̀rọ̀ nipa ìtumọ̀ àti ọna ti iṣẹlẹ tí a n reti yoo gba/rí. A tun ti sọ̀rọ̀ nípa erongba àti amuyẹ fun igbasoke naa. Ohun kan ní pe ko yẹ ki ẹnikẹ́ni o pàdánù rẹ. Nítorí naa ó wa pe fun igbe ayé iwa mimọ àti ifaraji fun àwọn ohun tí ṣe tí Ọlọ́run nínú Kristi Jésù. A gbàdúrà pe a ko ni wá wa ti nigba bibọ Rẹ. Amin.

Ka eko ojo isinmi ti o ti koja lo nibi yii

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ IKEJI
Mon.  21:   Maa Sọ́nà, Ki o Si Maa Gbàdúrà Nígbà Gbogbo (Lk. 21:34-36)
Tue.   22:   Máa Rin Ninu Imolẹ (Kol. 2:6-7)
Wed.  23:   Ọmọ Ilu Ìbílẹ̀ Ọ̀run Ni Awa I Se (Filip. 3:20-21)
Thur. 24:   Awa Ni Ile Ti Kristi Pese Silẹ Ní Ọ̀run (Jhn. 14:1-3)
Fri.    25:   Ohun Ti O Yẹ Ni Ìgbéyàwó Ọdọ Àgùntàn (Ifih. 19:1-9)
Sat.   26:   Iri Igbasoke (I Kor. 15:51-56).

Leave a Reply