ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN January 20, 2019.  Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ: IGBASOKE

By | January 20, 2019

 

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN January 20, 2019.  Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ: IGBASOKEÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.
January 20, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KÍNNÍ: IGBASOKE

Laipẹ Jesu Oluwa wa yoo farahàn ni àwọsánmọ fun àwọn ènìyàn mímọ. Ṣe a o gba o soke?

AKỌSÓRÍ:
Nigba naa ni a o gba awa tí o wa láàyè tí o si ku lẹyin soke pẹlu wọn sinu àwọsánmọ, lati pade Oluwa ni ojú ọrùn: bẹẹni awa o si maa wa titi lai lọdọ Oluwa (I Tesa. 4:17)

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Ìkorò ọkàn ba àwọn ara Tẹsalóníkà nípa arákùnrin wọn tí wọn pàdánù (ẹsẹ 13). Pọ́ọ̀lù ni lati tú wọn nínú kí wọn mase banujẹ nítorí rẹ, bí ó ti lẹ jẹ pé ikú arákùnrin naa báni nínú jẹ. Pọ́ọ̀lù gbe ọrọ yii lórí ìdánilójú pé, niwọn ìgbà tí Kristi ti jíǹde kúrò nínú òkú, Oun yoo ji àwọn tí wọn kú nínú Rẹ dide (ẹsẹ 14). O fi da wọn lójú nínú Olúwa pé àwọn òkú nínú Olúwa ni anfaani ńlá nitori pé a o fun wọn ní anfaani lati jínde láti lọ pàdé Olúwa ni igbasoke, saaju àwọn onigbagbọ tí wọn wa láàyè ní àkókò igbasoke (ẹsẹ 15-16). Akọsórí wa tun fun àwọn tí wọn n bẹ láàyè níìrètí nígbà bibọ Olúwa. A o gba àwọn wọ̀nyii soke (eyi ni igbasoke) ni àwọsánmọ láti lọ pàdé Olúwa (ẹsẹ 17). Iye àwọn tí wọn ba ni ẹmi Rẹ ti wọn si n gbe igbe ayé ìwà mímọ Rẹ ni yoo ṣetán fún iṣẹlẹ jákèjádò gbogbo agbaye yii. Pọ́ọ̀lù tẹsiwaju láti sọ pé àwọn alààyè àti òkú nínú Kristi ni asiko igbasoke ti ẹnikẹ́ni tí n bẹ lori ilẹ ayé àti lọrun ko mọ, yàtọ̀ sí mẹ́talọ́kan funrara Rẹ, yoo so wa papọ láti wa pẹlu Olúwa nigba gbogbo. Ìtumọ̀ rẹ ni pé, a gbọ́dọ̀ múrasilẹ láti máṣe pàdánù iṣẹlẹ ńlá tí igbẹyin ayé yii, èyí ni o si yẹ kí o jẹ ìtùnú wa ti a ba pàdánù àwọn tí a fẹ́ràn (ẹsẹ 18)

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ
Mon.   14:   Àwọn Àmì Bibọ Rẹ (2 Tim. 3:1-5)
Tue.    15:   Àwọn Àmí Opin Ayé (Mat. 24:1-18)
Wed.    16:   Àwọn Àmì Fún Àwọn Ènìyàn Mímọ́ (Mat. 24:9-14)
Thu.     17:   Owe Àwọn Wundia Mẹwa (Mat. 25:1-13)
Fri.       18:   Ijẹri Juda (Juda 14-15)
Sat.      19:   Ijẹrisi Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì (Ìṣe 1:11)

ÀṢÀRÒ FUN ÌFỌKÀNSÌN
1.   Ohun kan tí o yanilẹnu fẹrẹ sẹlẹ nínú ìtàn eniyan nípa igbasoke àwọn ènìyàn mímọ. Ẹ múra silẹ!
2.  Igbasoke jẹ ohun ti ko wọpọ, yàtọ̀, o si kọjá iṣẹlẹ lásán tí a ń retí ni opin ayé. O jẹ ohun ti ko wọ́pọ̀, tayọ, ó sì kọjá iṣẹlẹ lásán tí a ń retí ni opin ayé. O jẹ bibọ/wiwa Jesu Olúwa wa lati mú àwọn tiRẸ lọ sí ilé (ìjọ: ìyàwó Rẹ) kuro ninu ìrora, ibanujẹ, ati ipo ìnira tí satani, ẹsẹ àti aye n fa.
3.   Ẹnikẹ́ni tí o ba pàdánù iṣẹlẹ ńlá yii yoo da ara rẹ lẹbi titi ayérayé. Gbigba Kristi ni Olúwa rẹ nikan ni ọna àbáyọ.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FUN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : Matiu 24:29-51

ILEPA ATI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Láti safihan bi igbasoke ṣe ṣe pàtàkì to si àti idi ti a fi gbọ́dọ̀ múrasilẹ gidigidi

ÀWỌN ERONGBA: Ni opin ẹ̀kọ́ yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ:
i.   le salaye ìtumọ̀ igbasoke àti ohun tí o jẹ fun àwọn Kristẹni àti gbogbo agbaye
ii.  le ṣàlàyé bí igbasoke yoo ṣe ṣẹlẹ̀ ni ibamu pẹlu ohun tí ìwé mímọ sọ fún wa
iii. le ṣàlàyé erongba igbasoke
iv. le ṣàlàyé àwọn amuyẹ tí Kristi fẹ́ kí a ní láti le yẹ fún ati pade Rẹ pẹlu ayọ̀ ni ọjọ ti O ba de.

IFÀÀRÁ
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: JOHANU 14:1-3; I KỌ́RÍŃTÌ 15:21-23; FILIPI 3:11,20-21; I TESA. 4:13-18.
Adupẹ lọwọ Ọlọ́run ti O mu wa la akoko ìyanu kọjá níwájú Rẹ ní ọdún tí o kọjá. O jẹ iriri tí ko se e gbàgbé gẹgẹ bi a ti ni anfaani lati túbọ̀ ni òye ọkàn Ọlọ́run lori àkòrí gbòòrò naa IFẸ NINU ÌṢE. Ni apa kinni (January si June 2018), a ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe safihan ìfẹ́ sì ìran ènìyàn. A rii pẹlu alaye yekeyeke pé kí ìṣe pé Ọlọ́run kan saa fi ìfẹ́ hàn sakala sì wa, ṣùgbọ́n o n tẹsiwaju láti fihan sì wa ohun tí o jẹ láti ayérayé de ayérayé. Apa kejì (July si December 2018) dalori igbesẹ ènìyàn si ìfẹ́ nla Ọlọ́run ti ko se e ṣàpèjúwe yii. A gbàdúrà pe awon ipenija tí a ti gba láti fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn tọkàntọkàn ni ibamu pẹ̀lú rí Kristi, yoo ti wà láti ṣe gẹgẹ bi ìfẹ́ ayérayé Rẹ. Àmín.

Ogo ni fún Ọlọ́run Olódùmarè fún oore ọfẹ tí O fun wa lati tí ọdún tuntun tí ìyanu 2019. Anfaani àtọ̀runwá ni kí ìṣe ẹtọ. Bẹẹni o sì fún wa ní anfaani lati jíròrò lórí àkòrí gbòòrò, ETO AYÉRAYÉ ỌLỌ́RUN FUN ENIYAN ni saa kinni yii (January si June 2019) bẹẹni O sì ti ṣetán láti maa ṣíṣe pẹlu wa lori àkòrí yii, IGBASOKE

Ede Latinni fun ọrọ-isẹ Giriki ni ‘rapturo’ ninu eyi ti wọn ti fà ede Gẹ̀ẹ́sì ‘rapture’ yọ (igbasoke). A gbagbọ pe a o gbà ìjọ soke láti pade Olúwa ni ofurufu (Jhn. 14:1-3; I Kor. 15:23,51-58; I Tesa. 4:13-17). Igbasoke jẹ bibọ Jesu Olúwa láti ofurufu fún àwọn ènìyàn mímọ. Eyi ni iṣẹlẹ tí yoo fi òpin si akoko oore ọ̀fẹ́ ti yoo si mú àwọn iṣẹlẹ ìgbà ikẹyin gbogbo wọlé wa.

Nínú ẹ̀kọ́ ọlọsẹ mejii yii, a o maa wo ohun tí igbasoke jẹ láti inú Bíbélì àti ìrètí Ọlọ́run fún olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí o fẹ ki a gbà òun sókè. A gbàdúrà pe a ko ni pàdánù ohunkóhun tí Ọlọ́run ní fun wa ninu ẹ̀kọ́ yii ni orúkọ Jésù. Amin.

IFÀÀRÁ SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN
A pín ẹ̀kọ́ yii si ìpín meji, I ati II. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni a tun pin si A ati B.

ÌPÍN KÍNNÍ: IGBASOKE: OHUN TÍ Ó JẸ
Ipin kinni yii jẹ ọrọ Jòhánù 14:1-3; I Kor. 15:51-57; Filipi 3:11, 20-21; I Tesa. 4:13-18. A pín wọn si abala A (Igbasoke ìjọ) ati B (Bi Igbasoke naa yo ṣe ri). Abala kinni ṣàlàyé ohun tí Igbasoke jẹ nígbà tí abala kejì sọ pé Kin ni/bawo láti inú ìwòye ìwé Mímọ, bi Igbasoke yoo ti ri? Eyi ni pe bi yoo ti ṣẹlẹ̀. Igbasoke yoo jẹ iṣẹlẹ kariaye nígbà tí Olúwa yóò farahàn ni àwosanmọ láti mú àwọn tiRẹ wọnú ogo. Báwo ni èyí yoo ṣe sẹlẹ? Ohun tí ìpín yii ṣíṣẹ le lori ni èyí.

ÌPÍN KEJÌ: ERONGBA ÀTI ÀWỌN ÀBÙDÁ/AMUYẸ
Ipin kejì ni in lọ́kàn láti fọkàn àwọn onkawe sì erongba igbasoke ati awọn amuyẹ fun igbasoke. A nilo eyi ni igba ìkẹyìn yii nígbà tí nnkan ti le pupọ nípa ọrọ ẹsẹ ti ọkan ọpọlọpọ ènìyàn sì ti kúrò ní ipadabọ ati awọn amuyẹ àwọn tí yoo gba sínú ogo pẹ̀lú ara Rẹ.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.    IGBASOKE: OHUN TI O JẸ
A.  IGBASOKE ÌJỌ
B.  BÍ IGBASOKE YOO ṢE RI
II.   ERONGBA ATI ÀWỌN ABUDA/AMUYẸ
A.   ERONGBA FÚN IGBASOKE
B.   ÀWỌN ÀBÙDÁ/AMUYẸ ẸNI IGBASOKE

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
Jan. 20, 2019.
I.   IGBASOKE: OHUN TI O JẸ (Jhn. 14:1-3; I Kor. 15:51-57; Fili. 3:11,20-21; I Tesa. 4:13-18).
Ohun tí ènìyàn ba n ṣe tí ko ba mọ ìtumọ̀ rẹ, o ṣe e ṣe ki o maa ṣe asilo rẹ. Eyi ki i ṣe alájẹ òtítọ́ nípa iṣẹlẹ jalejako, igbasoke ti a n sọ̀rọ̀ rẹ yii. A nilo òye tí o n ṣiṣẹ́ nípa ọrọ yii ki a ma baa siwahu niti eyi. A gbàdúrà kí ojú òye wa kí o si bi o ti yẹ. Amin.

A.   IGBASOKE ÌJỌ (I Kor. 15:51-57).
Lọgan, ni isẹju, nígbà ipe ìkẹyìn; nitori ìpè yoo dun a o si ji àwọn òkú dìde ní aidibajẹ a o si pawalarada (I Kor. 15:52).
i.    O ṣe pàtàkì láti mọ pé wíwà Oluwa yoo pin si ọna meji. Ekinni ni igbasoke, Èkejì ni Bibọ Jésù Kristi lẹẹkeji. Bibọ ẹẹmeji yii ni a o pin pẹlu ọdún meje.
ii.   Nigba igbasoke, Kristi ko ni farahàn lori ilẹ aye gẹgẹ bi O ti ṣe nigba wiwa Rẹ lakọkọ, ṣùgbọ́n ni ofurufu láti gba àwọn oku àti àwọn ènìyàn mímọ tí wọn wa láàyè soke (I Kor. 15:15-57).
iii.  Nigba igbasoke, Kristi yoo pade àwọn ènìyàn mímọ ni ofurufu níbi tí wọn yoo wa ni akoko ti ìpọ́njú yoo wa lori ilẹ ayé (Jhn. 14:3; I Tesa. 3:13).
iv.  Ase alẹ ìgbéyàwó ọdọ Àgùntàn àti ìdájọ́ tàbí ere àwọn ènìyàn mímọ yoo waye ni ofurufu. Ni bibọ Rẹ lẹẹkeji/lẹ́yìn ìpọ́njú, Kristi àti àwọn ènìyàn mimọ yoo kúrò ní ofurufu láti jọ wa si ori ilẹ̀ ayé (Mat. 24:30; Ìṣe. 1:10-11; I Kor. 5:10; Ifih. 1:7; 19:7-9).
v.   Nigba igbasoke Kristi yoo wa fun àwọn ènìyàn mímọ àti nígbà ìfarahàn Jésù Kristi èyí tí ìṣe wiwa Rẹ lẹẹkeji, Kristi yoo wa pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ (Mat. 24:30, 16:27; Mk. 13:26; Ìṣe 1:11; Ifih. 1:7).
vi.  Igbasoke ko ṣe e dunadura. O jẹ ọna wiwa Ọlọ́run nínú Kristi láti ya àgùntàn sọtọ kuro lara ewurẹ, ki a le mú àwọn àgùntàn kuro ninu ibanujẹ ayé yii sínú ayọ̀ ayérayé tí o jẹ ere òtítọ́ wọn sì Kristi, nígbà tí àwọn alaiwa-bi-Ọlọ́run (ewurẹ) yoo ni ọrùn àpáàdì gẹgẹ bi ere ayérayé wọn. Apa/ìhà wo ni ìwọ yoo wa?

B.   BI IGBASOKE YOO ṢE RI (Jhn. 14:1-3; I Kor. 15:51-56; Fili. 3:11,20-21; I Tesa. 4:13-18).
Nitori Oluwa tikalara Rẹ yoo sọkalẹ láti ọrun wa ti Oun ti ariwo, pẹ̀lú ohun olori àwọn áńgẹ́lì, àti pẹ̀lú ipe Ọlọ́run; àwọn òkú nínú Kristi ni yoo si kọ jíǹde (I Tesa. 4:16).
i.   Gbogbo Kristẹni kò ní kú ṣáájú igbasoke, ṣùgbọ́n a o pa wọn lara da (I Kor. 15:51-54; I Tesa. 4:15).
ii.  Yoo jẹ iṣẹlẹ ojiji láàrin ìṣẹ́jú-aaya (I Kor. 15:52).
iii. Olori angeli yoo fọn ipe (Mat. 24:31; I Kor. 15:52, I Tesa. 4:16; Ifih. 11%15).
iv. Gbogbo àwọn olódodo tabi awọn eniyan mimọ tí wọn tí sun ni a o ji dide pẹlu ara aidibajẹ (I Kor. 15:52;-53; Filip. 3:11; I Tesa. 4:14-15).
v.  Lẹ́yìn naa, àwọn tí n bẹ láàyè ní a o pa lara da.
vi. Ati awọn oku àti alààyè nínú Kristi ni wọn yoo gbe ara àìkú wọ. Ṣùgbọ́n àwọn ti n bẹ láàyè ko ni ṣáájú àwọn tí wọn tí sún niti igbasoke (I Kor. 15:53-54; Efe 5:27; Filip. 3:21b).
vii. Jesu yoo farahàn fun àwọn ènìyàn Rẹ ni ofurufu (I Tesa. 4:16).
viii.Ati àwọn alààyè àti òkú ní a o gbà sókè láti pàdé Kristi ni ofurufu láti darapọ mọ Ọn (Jhn. 14:3; Filip. 3:20b; I Tesa. 4:17).
ix. Àwọn ènìyàn mímọ tí a gbasoke yoo farahàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ‘BEMA’ lati gba ọkàn-ó-jọkan ere (Mat. 16:27; I Kor. 5:10) ni ìrí ade (I Tesa. 2:19,20; 2 Tim. 4:6-9; Jak. 1:12; I Pet. 5:2-4; I Kor. 9:24-27).
x.  Aṣòdì si Kristi yoo gba orílẹ̀ ayé.
xi. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ ni wọn ti sọ pe ko si igbasoke. Síbẹ̀ Olúwa yoo wa ni akoko ti o yàn. Gbogbo ojú ni yoo ri ogo Rẹ, iye àwọn tí wọn ba gba A nisinsin yii ni yoo wa lara àwọn tí yoo fo lọ pàdé Olúwa ni àwosanmọ.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RI KỌ
1.   Iṣẹlẹ gbòógì tí a gbọ́dọ̀ maa múra fun ni ìtàn ènìyàn tí ko se e da dúró tì ó sì gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ ni igbasoke àwọn Ayanfẹ Kristi.
2.  Igbasoke naa yóò jẹ ìyàlẹ́nu débi pé ẹnikẹ́ni tí o ba pàdánù rẹ yoo kabamọ gidigidi.

ISẸ ṢÍṢE
Ṣe òtítọ́ ni pé ìgbà kọ̀ọ̀kan (èèkàn-lare) ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ìjọ maa n sọ̀rọ̀ nípa igbasoke lonii? Kin ni àwọn ọ̀nà àbáyọ?

Ka Eko Ile Ojo Iinmi Ti Ateyin Wa Ni Bi Yi

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
i.   Bẹẹni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọ àti àwọn iransẹ Ọlọ́run n sọ̀rọ̀ nipa igbasoke lẹẹkọọkan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ idi ni owa fun èyí.
ii.  O jẹ àmì ìgbà ìkẹyìn, yoo nira fun àwọn ènìyàn láti gba òtítọ́ (2 Tim. 2:3,4). Eyi n mú kí àwọn ìjọ àti àwọn Iransẹ Ọlọ́run maa wàásù ohun tí wọn fẹ gbọ fún wọn.
iii. Ìfarahàn ihinrere miran nínú àwọn ìjọ àti laarin awọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan (Gal. 1,2) àwọn tí wọn ṣe èyí julọ ni àwọn tí wọn n ro pe àwọn n ri nnkan gba nítorí èyí, o n di àwọn ìjọ àti àwọn iransẹ Ọlọ́run lẹ́nu láti wàásù nípa igbasoke àti àwọn ìwàásù tí o jẹ mọ́ ìwà mímọ.
iv. Àsìkò ihinrere ọrọ ti n gba ọkàn ìjọ àti àwọn iransẹ Ọlọ́run ti ihinrere yii ti gba lọ́kàn láti kúrò nínú òtítọ́ ipadabọ Kristi ti ko ṣe é da dúró àti ayọrisi rẹ fún igbe ayé Kristẹni.
v.  Ikopa àwọn iransẹ Ọlọ́run kan nínú àwọn ìwà àìmọ àti wiwonù ẹgbẹ́ òkùnkùn yoo pa ìránṣẹ́ bẹẹ lẹ́nu mọ láti sọ òtítọ́ nípa bibọ Kristi, nítorí pé ọna ti o ngba a gun wọn, tí wọn n ronú lórí bibọ Olúwa láti wa ṣe ìdájọ́ búburú wọn. Wọn ro pé láti maa yẹra fun àwọn ìwàásù bí èyí yoo mu inú wọn dun.
vi.  Idi miran ni ifẹ ìṣáájú àwọn ìjọ kan àti ìránṣẹ́ Ọlọ́run fún ọrọ Ọlọ́run ti n kú lọ (wo Ifih. 2:4)
vii. Ọ̀nà àbáyọ ni lati tún ṣàwárí ìfẹ́ tòótọ́ fún Kristi àti ọ̀rọ̀ Rẹ (Ifih. 2:5). Isọji tòótọ́ ni èyí.
viii.Awọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tún gbọdọ mu un lọkunkundun láti maa wàásù gbogbo ohun tí o wa ninu iwe mímọ, àti igbasoke pẹ̀lú (wo Ìṣe. 20:20,21).

Leave a Reply