ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.  Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Fun  March 31st, 2019. Ẹ̀KỌ́ KẸFÀ – ÌKÓRÈ AYÉ

By | March 31, 2019

 

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.  Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan Fun  March 31st, 2019. Ẹ̀KỌ́ KẸFÀ – ÌKÓRÈ AYÉ

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Eto Ayeraye Olorun Fun Eniyan.
March 31st, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KẸFÀ
ÌKÓRÈ AYÉ

Kristi n bọ kankan lati kore ayé. Maṣe ba èṣù dọ́gba, ki o ma baa kábámọ.

AKỌSÓRÍ
Ẹ jẹ ki awọn méjèèjì ki o dàgbà pọ titi di ìgbà ìkórè: ni akoko ìkórè èmi o si wi fún àwọn olùkórè pe, Ẹ tete kọ kò èpò jọ ki ẹ di wọn ni ìtì láti fi iná sun wọn, ṣùgbọ́n ẹ kó àlìkámà sínú aba mi (Mateu 13:30).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Jesu pa òwe àlìkámà àti èpò láti fi ṣe ikadi ọrọ Rẹ nipa ijọba Ọlọ́run. O ti kọkọ safiwe ijọba ọrun gẹgẹ bi afúnrúgbìn ti o gbin ohun ọ̀gbìn daradara sinu oko rẹ, ohun ti o si gbọ lẹyin rẹ ní pe àwọn epo ti n hu pẹ̀lú àlìkámà ti o gbin. O wi pe ọta ni o ṣe èyí! Gẹgẹ bi ọrọ Jesu, agbẹ naa gba pe ki awọn ohun ọ̀gbìn méjéèjì (rere ati búburú) maa dagba pọ titi di ọjọ ìkórè. O gbagbọ pe oko riro ṣáájú ìkórè le ni ipa búburú lórí awọn ohun ọ̀gbìn ti o dara, nítorí a le pa awọn naa lara. Ìyẹn túmọ̀ si ìjàkadì àti ìṣẹ́gun alágbára.

A tun gbagbọ bákan naa pe iyasọtọ ni akoko ikore ni yoo fi àlìkámà ati awọn epo si ibi ti onikaluku tọ si. Bẹẹni, awọn ti ko dara ni a o kọ́kọ́ kójọ, wọn kò dara fún ohunkóhun, bikose fún ina. Àlìkámà ni ohun ọ̀gbìn ti a yan ti a kore ti a o si kojọ sinu aba.

Laipẹ jọjọ, ohun ti aye yoo ni iriri rẹ ni yii, awọn eniyan ti o dara (awọn ọmọ ijọba ọrun) ni a o kojọpọ sinu párádísè Ọlọ́run nigba ti awọn eniyan búburú, awọn ọmọ egbe yoo ni ipin tiwọn ninu iná, eyi tii ṣe ikú keji. Eyi ni yoo wa jẹ ìdáhùn fun awọn ti o gbagbọ pe Ọlọ́run ko ni agbara tí o to láti mu iwa ibi ati iwa búburú kuro, ko si si ohun ti O le sọ ju pe ki o jẹ ki wọn máa tẹsiwaju. Ọlọ́run jẹ alágbára, O si ni agbara lati mu ohunkóhun ti o ba fẹ kuro, síbẹ̀, O ti ṣe alakalẹ ọjọ ìkórè, nígbà tí yoo mu iyapa ba rere ati búburú. Èyí ni ìkórè aye.

ÀṢÀRÒ LATI INU BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ
Mon.    25:   Ìkórè Ijiya Israeli (Isa. 5:1-7)
Tue.     26:   A Ó Kore Ọmọbìnrin Bábílónì (Jer. 51:33)
Wed.    27:   Ọlọ́run Yoo Kore Àwọn Orílẹ̀-Ede (Joeli 3:12-16)
Thur.    28:   Ayé: Ti Pọn Fun Ìkórè (Ifi. 14:14-15)
Fri.       29:   Tẹ Doje Rẹ Bọ ọ Fun Ìkórè (Ifi. 14-15)
Sat.      30:    Ẹ Jẹ Ki Wọn Dagba Pọ Titi Di Ìgbà Ìkórè (Mat. 13:24-30.

ÀṢÀRÒ FUN ÌFỌKÀNSÌN
1.   Bi o ti wu ki a pẹ to laye yii, a ó pẹ ju bẹẹ lọ ni ọrùn pẹ̀lú Jesu.
2.   Àlejò (àtìpó) lásán ni a jẹ nibi yii, wiwa ni aye wa ni akoko. Ọrun ni ilu ìbílẹ̀ wa. Nítorí naa, máṣe ba ayérayé rẹ jẹ pẹlu ogo aye ti o n kọja lọ yii.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FUN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : Matiu 25:1-46

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Lati jẹ ki awọn onkawe o mọ pe Ọlọ́run yoo mu kí ìpínyà o waye láàrín rere ati búburú laipẹ.

ÀWỌN ERONGBA: Ni ipari ẹ̀kọ́ yii, awọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀:
i.   le safihan ìmò wọn niti iwa papọ rere ati búburú pe ko ni wa titi lae, ìpínyà yoo waye lati ọdọ Ọlọ́run laipẹ ju bi a ti lero lọ;
ii.  le tọkasi esu gẹgẹ bi olùsọkunfa ti o n fun ibi ati irúgbìn ẹsẹ sinu ayé.
iii. le jiroro lori òtítọ́ naa pe ìpínyà ni ìkẹyìn ni ohun ti Bíbélì n tọkasi gẹgẹ bi ikore aye;
iv. maa safihan awọn àmì ti o n pese wọn silẹ fun ìkórè nla yii ki orúkọ wọn ba le wa ninu iwe iye Ọlọ́run.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: MATIU 13:24-43.
A ko le sai mọriri oore Ọlọ́run fun ọna ti O n gba ba wa lọ nínú ọwọ Ẹ̀kọ Ilé-Ẹkọ Ọjọ́ Isinmi yii, eyi ti ìṣe àkókò nínú ọdun ologo 2019 ti a wa yii. Laipẹ jọjọ yìí, O jáde siwa lakọtun lori awọn ofin ati ilana oníwà-bí-Ọlọ́run to ṣe iyebíye ti o si n ṣe akoso iwa ati ìṣe ninu ijọba Kristi ni aye yii ati ni ayérayé. Wọnyi ni o si bi ohun ti a pe ni AWỌN IWA Ẹ̀KỌ́ RERE TI AYÉRAYÉ ti a gbe yẹwo ninu Mateu ori 5 si 7. Ki Ọlọ́run jẹ ki ireti Rẹ jẹ ayọ̀ ati igbe aye wa, ní orúkọ Jesu. Amin.

Ẹkọ kẹfà jẹ ìpinnu Ọlọ́run fun wa lati ṣe awari òtítọ́ lọtun pe Jesu n bọ wa lati kore ayé, ati bi yoo ti ṣe sẹlẹ. A nilo imọ yii bi ati n lọ wẹrẹwẹrẹ sinu ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ọrọ Ọlọ́run yii. Yala eniyan mọ tabi ko ti lẹ mọ, gbogbo ènìyàn lo n gbaradi fun ìkórè, nítorí igbakuugba tí a ba ti fúnrúgbìn, o pọndandan lati ri ìkórè; bẹẹ naa ni eyi ri ninu ere ije Kristẹni.

Ọlọ́run ti ṣèlérí pe ni igbẹyin ayé yii, ìkórè nla ti àgbà-ńlá ayé yoo sẹlẹ. Ìkórè yii kii ṣe ti àgbàdo, àlìkámà tabi ọkà, bikose awọn ọkan. Oluwa ṣe ikilọ pe nígbà ìkórè opin ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yoo wa ninu àfonífojì airo tẹ́lẹ̀ nítorí aini igbagbọ, aisotitọ, igbọjẹgẹ ati akatakiti ẹsin. Yoo jẹ àkókò ti awọn onigbagbọ òdodo àti onigbagbọ ayédèrú awọn ti iwa àti ìṣẹ́ ẹsin wọn le nira pupọ lati damọ yàtọ̀ lori eto ti o tọ loju ara wọn yoo han kedere.

Bíbélì tọka o si ṣàpèjúwe orisii ìkórè meji, ìkórè rere ati ìkórè ìbínú nla (Mat. 13:24-30; Ifih. 14:14-16). Bíbélì wi pe, “Ọmọ ènìyàn yoo ran awọn áńgẹ́lì rẹ, wọn o si ko gbogbo ohun tí ó mu-ni-kọsẹ ni ijọba rẹ kuro, ati àwọn tí ó n dẹ́ṣẹ̀. Yóò sì sọ wọn sinu ina ìléru: nibẹ ni ẹkùn oun ìparun keke yoo gbe wa. Nígbà naa ni àwọn olódodo yoo maa ran bi oorun ni ijọba Baba wọn. Ẹni ti o ba ni etí ki o gbọ” (Mat. 13:41-43).

Ninu ẹ̀kọ́ yii a ó wo àwọn ọrọ to ṣe pàtàkì tí a fàyọ láti inu owe Oluwa ti i ṣe Àlìkámà àti Epo ninu Ihinrere ti Mateu ori 13, eyi ti yoo jẹ iranwọ fun wa lati mura silẹ pẹlu igbona ọkàn fun ìkórè ayé tí ó n bọ wa lọwọ, ni orúkọ Jesu. Àmín.

ONKỌ̀WÉ ATI IPILẸ ÌWÉ MATEU
Lọ si ẹ̀kọ́ kejì, Abala *5A

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN :
A pín ẹ̀kọ́ yii si ipa meji, I ati II. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìpín yii ni a ṣe atunpin si A ati B.

ÌPÍN KÍNNÍ: OYE ÒWE NAA
Ipin yii n jíròrò lori awọn ọrọ méjì tí ó lágbára nípa ìkórè ayé. AWỌN ÈRÒJÀ ÌKÓRÈ NAA jẹ ọkan lára ìpín A, nígbà tí ÀWÒRÁN Ọ̀TÁ NAA jẹ ìpín kejì B. Ọmọ Ènìyàn ni afúnrúgbìn rere, irugbin rere naa fúnraRẹ, epo naa ati satani, afúnrúgbìn búburú, gbogbo wọn ni a tọ́kasi lábẹ́ àwọn eroja ìkórè naa. Ẹni ti ọta naa jẹ, gan-an, ani satani, ni a tun safihan ni ìpín B.

ÌPÍN KEJÌ: ÒPIN YÓÒ DÉ
Ohun ti yoo ṣẹlẹ̀ ni igba ìkẹyìn ni o jẹ ipilẹ (orisun) ipin yii. Ọrọ kan wa ti awọn eniyan maa n sọ wí pé igbẹyin ni alayoo ta. Òpin yoo de yoo si ni ise. Bawo? Ìpínyà (ìyàtọ̀) pátápátá yoo de; a o ṣàwárí awọn ti ko dara, a o si ya wọn sọtọ kuro lara awọn ti o dara. Ìṣe (iwa) Ọlọ́run ni yii. Ohun ti ipin yii fẹ́ satẹnumọ ni yẹn.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I.    OYE ÒWE NÁÀ
A.    ÀWỌN ÈRÒJÀ ÌKÓRÈ NÁÀ
B.    ÀWÒRÁN Ọ̀TÁ NÁÀ

II.   ÒPIN YÓÒ DÉ
A.    DÍDÀGBÀ PAPỌ ÌSINSÌNYÍ
B.    ÌKÓRÈ NÁÀ NÍ ÌKẸYÌN

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
Mar. 31, 2019.
I.    OYÈ ÒWE NÁÀ (Matteu 13:36-39)
Owe ni Jesu maa n lo lati fi kọ́ni lọpọ ìgbà, kín-ni-ìdí? Lati jẹ ki ọrọ Rẹ o ye awọn olugbọ Rẹ, ni ti sisalaye koko ìkọ́ni Rẹ ati ṣíṣapẹẹrẹ fun ìkọ́ni tí o yanranti. O tun jẹ àbùdá Rẹ láti ṣàlàyé awọn òwe naa fún àwọn ọmọ-lẹyin Rẹ lẹ́yìn-ó-rẹyìn. Ki wa ni owe? O jẹ itan kúkúrú tí o rọrùn tí a sọ láti fi ẹ̀kọ́ ìwà-rere tàbí tí ẹsin han. Nínú òwe, Jesu ṣe ìkọ́ni ìkórè ayé. Kíkọ́ni pẹ̀lú òwe ko wáyé láti mu adinku ba òye wa, bikose láti mu u gbòòrò sii.

A.    AWỌN ÈRÒJÀ ÌKÓRÈ NÁÀ (Mat. 13:36-39)
Oko ni ayé; irúgbìn rere ni àwọn ọmọ ijọba; epo si ni awọn ọmọ ẹni búburú ni; (ẹsẹ 38).
i.   Afúnrúgbìn irúgbìn rere naa ni Ọmọ Ènìyàn (Jesu Kristi) ẹni tí o tun jẹ Oluwa oko náà àti ìkórè. Awọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jẹ ohun-elo ni ọwọ Kristi láti fúnrúgbìn rere náà (àlìkámà) nínú ayé.
ii.   Oko naa jẹ ayé tí ẹda eniyan wa, ọkọ-ńlá tí o le so èso rere ati búburú lábẹ́ ojú-ọjọ ati àyíká kan naa.
iii.  Irúgbìn Rere Náà (Àlìkámà) ni awọn ọmọ ijọba:awọn ẹni mimọ (ẹnì ìràpadà) kii ṣe nínú ìṣẹ́ nìkan ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ pẹ̀lú. Wọn jẹ irúgbìn rere tí wọn si ṣe iyebíye ni ọwọ Oluwa láti fun (gbìn) wọn fun ibisi (wo Orin Daf. 126:6). Njẹ ìwọ jẹ irúgbìn rere ti ijọba Ọlọ́run bí?
iv.   Èpò Náà (koríko) ni àwọn ọmọ ọta ika ni. Wọn kii ṣe rere. Wọn jẹ koriko nínú ọgbà. Bi-o tilẹ jẹ pe ojo kan náà lo n rọ si wọn, oòrùn kan náà lo n rán sí wọn tí wọn sì wa lori ilẹ kan naa,wọn ko wulo fun ohunkóhun. Awọn ni “Kristẹni” ti wọn maa n dibọn gẹ́gẹ́ bi ẹni tí o tọ̀nà niti ẹsin ti o si kunju osunwọn àti ẹni àpẹẹrẹ ṣùgbọ́n dájúdájú, aini-lóhùn lọ ní wọ́n (2 Tim. 3:5). O tilẹ̀ maa n nira pupọ láti dá wọn mọ kí a sì yà wọn sọtọ titi di ìgbà tí èso yoo bẹ̀rẹ̀ si ni yọ síta (Mateu. 13:26-28). Mo lero wí pé ìwọ kii ṣe èpò?
v.    Ọ̀tá Náà ni Èṣù ti o fún irúgbìn epo naa. Pẹ̀lú ìwà arekereke, nígbà tí àwọn ẹlòmíràn ko mọ, o n sọ gbogbo anfaani lati le di mimọ, pe oun n sisẹ to burú jai ni ikọkọ nínú ọkàn ọmọ eniyan.
vi.   Awọn irúgbìn rere wa, bákan naa ni awọn irugbin búburú wa. Ipa tí wọn ni: awọn ti o dara gbọdọ maa kiyesara nítorí tí idibajẹ tí o wa lara awọn ti ko dara nítorí láìsí ainiaini, koríko (èpò) maa n fa ìpalára fun irugbin to dára nitori naa, awọn ọmọ ijọba ọrùn gbọdọ máa kiyesara nitori awọn isẹ Sátánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ (Jak. 4:7; I Pet. 5:8).

ÀWÒRÁN Ọ̀TÁ NAA (Mat. 13:39)
Ọ̀tá tí o fun wọn ni Èṣù (ẹsẹ 39a)
i.    Oseni laanu, pupọ ninu àwọn to n wàásù lodi si Òtítọ́ tí kọ́kọ́ jẹ oníwà-bí-Ọlọ́run, atunbi tòótọ́, àwọn ènìyàn to fẹ́ Ọlọ́run ni ìbẹ̀rẹ̀. Nígbà miran, wọn n kọ́ni ni ìṣìnà, pẹ̀lú òtítọ́, ṣùgbọ́n nígbà to ṣe ni wọn lamilaaka nínú ìṣìnà (ẹ̀kọ́ eke) ni ìlọ́po ìdiwọ̀n òtítọ́ wọn ṣáájú. Wọn jẹ ọga apawọda; o ṣòro pupọ láti da wọn mọ yàtọ̀ (Jer. 6:13; Mat. 24:1-4; Ifi. 2:14).
ii.   Díẹ̀díẹ̀ ni òtítọ́ ńlá àárín gbùngbùn igbagbọ bẹ̀rẹ̀ si ni di ẹ̀kọ́ àríyànjiyàn tó le koko nípasẹ̀ ọna arekereke tí èṣù maa n yọ kẹlẹ wọlé sínú ọgbà àti sínú agbo àwọn aṣáájú Kristẹni àti àwọn ọmọlẹ́yìn bí ti wọn (Kol. 2:8; I Tim. 1:3,4).
iii.   Laideena pẹnu, òtítọ́ n dàgbà díẹ̀díẹ̀ o di ohun tí o han gbangba pe awọn ẹkọ odi naa bẹ̀rẹ̀ si ni mu awọn eniyan ṣáko lọ, nígbà tí òtítọ́ si fẹsẹ múlẹ̀ sibẹsibẹ nibẹ. Wẹrẹwẹrẹ, èpò tí bẹ̀rẹ̀ si ni jẹyọ tí yoo si farahàn láti dabi òtítọ́ (2 Tim. 4:1-4) ti wọn yoo si maa tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ.
iv.   Awọn eniyan Ọlọ́run gbọdọ gbé imolẹ Kristi láti pa ọ̀tá ọkàn wa lẹ́nu mọ nínú àwọn igbesẹ ibi (búburú) rẹ lórí ilẹ̀ ayé níbi.
v.    Ogun tí bẹ̀rẹ̀ laarin ímọ́lẹ̀ àti òkùnkùn naa, rere àti búburú. Sátánì àti ogún rẹ ń gbógun ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. Ewu ńlá n rọ dẹdẹ (bọ) lórí àwọn ọmọ ijọba ọrùn, láìsí iranlọwọ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọlọ́run ba wa ni ìhà tí wọn; kò sì ẹru, ìṣẹ́gun dájú.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1.   A n gbe laarin awọn eniyan búburú bayii, nítorí naa, a gbọdọ mú ìdúró wá niti didi ímọ́lẹ̀ iwa mimọ Ọlọ́run mú.
2.  Èṣù n ja fitafita láti gba gbogbo Kristẹni dànù. O n gbìn awọn asoju rẹ yi wa ká. A nílò iranlọwọ Kristi.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE
Ki ní àwọn ohun to n ṣẹlẹ̀ sí àlìkámà àti èpò tí wọn ń dàgbà pọ kí o to di ìgbà ìkórè fun ìjọ àti ayé?

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
Àbájáde àlìkámà àti èpò tó ń dàgbà pọ.
i.    Wọn nilati dàgbà pọ, ki àlìkámà ma ba a ni ìpalára nigva ti a ba n tu epo kuro ṣáájú ìkórè.
ii.   Owe yii n ṣàlàyé idi ti Ọlọ́run fi gba ibi láàyè lati maa ṣẹlẹ̀ nínú ayé, lodi si awọn igbagbọ kan ni awọn ibi kan, pe Ọlọ́run ko le ṣẹ́gun agbára ibi, idi ni yii ti o fi gba a láàyè.
iii.   Bi Ọlọ́run ko ba gba awọn mejeeji yii laaye láti maa dàgbà pọ ni, a ko bá ti ni ìkórè aye bi a ti n kẹ́kọ̀ọ́ nipa rẹ lonii.
iv.   Ipa miiran ni pe Ọlọ́run, ninu Oore-ọ̀fẹ́ ati àánú ailopin Rẹ fi ìyọ́nú àti anfaani Rẹ han fun ìrònúpìwàdà fun ẹlẹ́sẹ àti ènìyàn to ti ṣubú, ki ẹnikẹ́ni ma baa ni awawi (awijare) kankan.
v.   Bákan naa, ìrí irúgbìn naa gan-an yoo farahàn nígbà tí a ba gbe awọn irúgbìn naa sẹgbẹ ara wọn gẹgẹ bi ipenija/àdánwò tí maa n fi iru ẹni ti a jẹ gan-an han, ti òkùnkùn si maa n fi iri ímọ́lẹ̀ hàn.
vi.   Ìjọ gbọdọ mọ pe dídàgbà nínú ayé búburú yii ko le rọrùn. O gbọ́dọ̀ ṣetán láti dojúkọ inúnibíni, iya, ibajẹ àti àwọn yòókù. Nínú gbogbo èyí, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run yoo wa lati mú ki ìjọ o la a ja de ayérayé, bi o ba fi ìpinnu tẹle Ọlọ́run de òpin.

KA AWON EKO TI ATEYIN WA NI BI

vii.  Dídàgbà pẹ̀lú àwọn èpò naa n pese ìjọ silẹ fún Ọlọ́run, o si n fi idi jijẹ ojúlówó rẹ múlẹ̀. Ìjọ nílò láti farada ìnira, láti ọwọ Sátánì, àti gbogbo awọn ọmọ rẹ búburú gẹgẹ bi ọmọ ogún tòótọ́, láti le dúró níwájú Ọlọ́run laini àbáwọn àti àbùkù.

Leave a Reply