ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN SEPTEMBER 15, 2019 Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.  Ẹ̀KỌ́ KÀRÚN UN : AKORI – MÈSÁYÀ NÁÀ WA NIGBẸYIN-GBẸYIN

By | September 15, 2019
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN SEPTEMBER 15, 2019 Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.  Ẹ̀KỌ́ KÀRÚN UN : AKORI – MÈSÁYÀ NÁÀ WA NIGBẸYIN-GBẸYIN
 
 
 
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.
ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.
September 15, 2019.
Ẹ̀KỌ́ KÀRÚN UN
MÈSÁYÀ NÁÀ WA NIGBẸYIN-GBẸYIN
Ni akoko ti a da Ọlọ́run ran ọmọ Rẹ Jesu Kristi láti mú Iwe Mimọ ṣẹ tí o sọ nípa irẹlẹ Mèsáyà náà, ibi Rẹ ti ko jẹ irufẹ èyí tí a fẹ.
AKỌSORI.
O tọ àwọn tìRẹ wa, àwọn tiRẹ ko si gba A, ṣùgbọ́n iye àwọn tí o gba A, àwọn ni o fi agbára fún lati di ọmọ Ọlọ́run, àní àwọn náà tí o gba orúkọ Rẹ gbọ́
(Johanu 1:11-12)

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
I lo àkọ́kọ́ tí ara Rẹ ní ó n tọkasi ayé ènìyàn lapapọ, nígbà tí tí ẹlẹẹkeji n tọkasi orílẹ̀-ede àwọn Juu. Gẹgẹ bi Ẹlẹdaa; aye jẹ ti Oluwa gẹgẹ bí ẹ̀bùn ini Rẹ, ṣùgbọ́n ayé ko da A mọ nítorí ifọju tí ẹmi. Aye tí ko gbagbọ tí ya bára kúrò nínú ọrọ Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá. Aráyé ko mọ Ẹlẹ́dàá wọn.
Nínú Jòhánù 1:11; Jòhánù lo ọrọ náà àwọn tìRẹ láti tọkasi àwọn ènìyàn Jésù ti Í ṣe àwọn Juu. Wọn ni Iwe Mimọ tí o jẹri sii pe o jẹ ènìyàn àti wíwà Rẹ. Síbẹ̀, wọn ko gba A. Jesu tọ àwọn Juu wa ti wọn n bẹ nínú Májẹ̀mú ibaṣepọ pẹ̀lú Ọlọ́run, bẹẹni a si ti fún wọn ní òfin Májẹ̀mú Láéláé. Nígbà tí Jesu de, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù ni wọn ti da onírúurú ẹsin silẹ gẹ́gẹ́ bí atọwọda ara wọn. Nítorí Jesu ko ba ero àwọn Juu mu niti irú ẹniti ó yẹ ki Mèsáyà o jẹ ko faramọ ẹsin atọwọdọwọ wọn. Nítorí náà ni ọpọ àwọn Juu ṣe kọ Ọ.
Síbẹ̀, a ko gbọ́dọ̀ ro pe gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ní o kọ Jesu. Nínú Jòhánù 1:12, O fihan pe iye àwọn tí o gba A ní a fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ́run. Àwọn tí wọn jẹ ọmọ Ábúráhámù nípa ìgbàgbọ́ gba A gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà àti Olùgbàlà aráyé. Láti gba A, ẹni tí ìṣe ọrọ Ọlọ́run túmọ̀ sí láti mọ Ọn? ni ìgbàgbọ́ nínú Rẹ ki o si fi òtítọ́ rọ mọ Ọn.
Ọrọ ti a fi fúnni n ṣe atẹnumọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti n bẹ nínú ìgbàlà (Efe. 2:8-10). Àwọn tí wọn gba A ti wọn si gbagbọ nínú orúkọ Rẹ ni a fún ní anfaani lati di ọmọ Ọlọ́run. Gbigba A àti gbigba gbọ́ nínú Rẹ jẹ àwọn ìlànà tú ènìyàn n múṣẹ ni ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run n fẹ́, láti di ọmọ Rẹ.
ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ
Mon. 9: O Wa Ninu Ara (Ron. 8:3)
Tue. 10: O Wa Bi Ètùtù Fún Ìràpadà (Rom. 8:4)
Wed. 11: O Wa Lati Da Wa Lare (2 Cor. 5:21)
Thur. 12: O Wa Lati Gba Wa La (Lk. 19:10)
Fri. 13: O Wa Láti Gba Wa kúrò Lọ́wọ́ Òfin (Heb. 7:25-27)
Sat. 14: O Wa Lati Ra Wa Padà (I Pet. 1:18,19)
ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1. Iwe Mimọ di mímúsẹ nígbà tí Ọlọ́run rán ọmọ bibi Rẹ kan ṣoṣo wá sí ayé láti gba wa kúrò lọwọ ẹṣẹ àti ikú.
2. Wiwa ọmọ Ọlọ́run sínú ayé wa lábẹ́ àkókò tí Ọlọ́run ti fúnrara Rẹ yasọ̀tọ̀. Wíwà Rẹ wa ni ibamu pẹ̀lú ọrọ ti Ọlọ́run ti sọ nínú Iwe Mimọ, bẹ́ẹ̀ sì ni wíwà Rẹ yóò wà ní ìbámu pẹlu ìwé mimọ ni gbogbo ọ̀nà.
ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: Isaiah 9::5-7; 11:1-5
ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Láti fi idi rẹ múlẹ̀ pé Ọlọ́run rán olùgbàlà aráyé kan ṣoṣo wá ní àkókò tí a yan/da ni mímú ìwé mimọ ṣẹ.
ÀWỌN ERONGBA: Lẹyin ẹ̀kọ́ ọlọ́sẹ méjì yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ le è:
i. safihan òye didara àti ìfẹ́ fún Jesu, Mèsáyà/Olùgbàlà wa
ii. mọ ibí Jésù mọ ìrètí/Ìwé Mímọ́ pe a o tọpàṣẹ ìtàn Mèsáyà títí kan Ábúráhámù.
iii. sọ òtítọ́ pe ọmọ Ọlọ́run wa ni akoko ti Ọlọ́run yan/da àti láti:
iv. fi idi ibasepọ ibi irẹlẹ Jésù pẹ̀lú ìrètí pé a o bí I bí irú ọmọ Ábúráhámù múlẹ̀.
IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: MÁTÍÙ 1:1-17; 2:1-5; LUKU 1:1-4, 26-38; GÁLÁTÍÀ 4:1-4.
Ẹ̀kọ́ tí o kọja, ìkẹrin ni ọwọ yii ti àkòrí rẹ jẹ NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ ÌGBÀ IKẸHIN, jẹ ìbùkún fún wa. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Ẹmi Mímọ́ tí fún wa ní àwọn ìṣiniye ìyanu nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ikẹhin, gẹ́gẹ́ bí a ti to o sínú Ìwé Mímọ́ nínú Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun.
Ẹ̀kọ́ tí a n kọ lọ́wọ́ yìí jẹ ti ọlọsẹ meji bí ìṣe wa, a o si da lori ìmúṣẹ Iwe Mimọ tí o ṣèlérí pípadà wa Mèsáyà. Nítorí náà ni ọsẹ meji yii, a o wo bi Iwe Mimọ ṣe ṣẹ lórí pípadà wa Mèsáyà tí a ṣèlérí.
Ìtàn ìran niti ẹ̀mí fihan pe Jésù Kristi ni Arole tí o tọ̀nà sì orí ìtẹ́ Dáfídì. Eto ìran náà n satẹnumọ agbára Ọlọ́run láti pa ìlérí Rẹ mọ. O fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bi Arole àtọ̀runwá tí o tọ̀nà tí a bí nínú obìnrin. A ko kan fi fúnni láti tán inaga ènìyàn nípa gbongbo Jésù, tàbí láti fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ ni anfaani lati gberaga. Àwọn Iwe Mimọ pàápàá julọ Mátíù ṣe ayẹwo gbogbo Jésù Kristi láti fihan pe Oun ni Mèsáyà náà tí a ṣèlérí.
Mèsáyà náà ni lati jẹ́ ọmọ Ábúráhámù àti ti Dáfídì. Ọlọ́run ṣe ìlérí pe Ábúráhámù àti irú ọmọ rẹ yóò jẹ ìbùkún fún gbogbo agbaye àti Dáfídì àti irú ọmọ rẹ, ìlérí ìjọba ayérayé. Nítorí náà, ihinrere ṣe atẹnumọ pé obìnrin ni o bi Jésù Kristi, Òun ni ọmọ Ábúráhámù àti Dáfídì ti a ṣèlérí. Àwọn onigbagbọ yóò pín nínú ìbùkún Ábúráhámù àti nínú ìjọba ayérayé tí a ṣèlérí fún Dáfídì.
Bí a ti n jókòó láti kọ ẹ̀kọ́ yii, ẹ jẹ ki a maa retí àwọn ohun rere àti títóbi tí Ọlọ́run ti pinnu láti ṣe pẹ̀lú, nínú wa àti fún wa ninu rẹ. A gbàdúrà pé a ko ni pàdánù ìkankan nínú rẹ. Àmín
IFAARA ṢÍ ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN :
Ẹ̀kọ́ yìí ni ìpín méjì I àti II. Ìpín kọ̀ọ̀kan ni a tún pín si A àti B.
IPIN KÍNNÍ: A BÍ I GẸ́GẸ́ BÍ JÚÙ
Abala ẹ̀kọ́ yìí jẹ ki a mọ pe Jésù Kristi, ọmọ Ọlọ́run, jẹ́ arole tòótọ́ sì orí ìtẹ́ Dáfídì. Bákan náà, o fihan fún wa pé ìtàn ìran Kristi n safihan pe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kì ìṣe ohun tí a n jogún, ṣùgbọ́n Ọlọ́run n fi fúnni bí o ti wu U. O ń satẹnumọ agbára Ọlọ́run láti pa ìlérí Rẹ mọ. Ẹ̀kọ́ yìí fún wa ní òye pé aráyé nílò olùgbàlà àti Olùdáǹdè, ní àkókò tí O da. Ọlọ́run ran ọmọ bibi Rẹ kansoso sínú ayé. Ìfarahàn Jésù Kristi fi òpin sí ìsìnrú ènìyàn lábẹ́ òfin ẹṣẹ àti ikú. Ní èdè mìíràn, ènìyàn gba ominira pátápátá kúrò lábẹ́ òfin àti ẹṣẹ nípa wíwà Kristi.
IPIN KEJI: A BÍ I LÁTI INÚ OBÌNRIN
Ìpín kejì fi ọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì ibi Olùgbàlà, ìyẹn, Jésù Kristi, ọmọ Ọlọ́run. O jẹ ọmọ Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí O yàn láti wa sínú ayé nípasẹ̀ wúńdíá láìsí ibalopọ ọkùnrin àti obìnrin. Èyí sì wa ni ibamu pẹ̀lú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Wolii Isaiah. Obìnrin náà lóyún nípa ọrọ Ọlọ́run lọ́nà ìyanu. Ẹ̀kọ́ yìí tún fihan fún wa irẹlẹ Jésù Kristi ti a bí nínú obìnrin sínú ìdílé òtòṣì/aláìní, tí a bi ni ibi tí o banilẹru, ibi oorun tí a sì tẹ si ibùjẹ ẹran.
KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I. A BI I GẸ́GẸ́ BÍ JÚÙ
A. A TAN IBI RẸ DE ỌDỌ ÁBÚRÁHÁMÙ
B. ÌṢEDEEDE ÀKÓKÒ IBI RẸ
II. A. A BI I LÁTI INÚ OBÌNRIN
A. IRÚ ỌMỌ OBÌNRIN NÁÀ
B. IBI IRẸLẸ RẸ
I. A BI I GẸ́GẸ́ BI JÚÙ (Mátíù 1:1-17; Gálátíà 4:1-4)
A mu ìwé mimọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ, ọmọ ènìyàn, Olùgbàlà aráyé, jẹ Arole tòótọ́ tí Baba àti ìran Ábúráhámù àti Dáfídì, O wa si ayé ni akoko ti o tọ̀nà tí Ọlọ́run ti da láti mú erongba Rẹ ti O ti pinnu ṣẹ.
A. A TÁN IBI RẸ DE ỌDỌ ÁBÚRÁHÁMÙ (Mátíù 1:1-17)
Ìwé ìran Jésù Kristi, ọmọ Dáfídì ọmọ Ábúráhámù (ẹsẹ 1)
i. Àwọn Ìwé Mímọ́ kan wa ti wọn sọ̀rọ̀ nípa ibi Jésù Ọmọ Ọlọ́run niwọn ko ṣeé fọwọ́rọ sẹ́yìn (Isa. 7:14; 9:1-9). Àwọn Ìwé Mímọ́ wọnyi àti ìtàn ìran Jésù fihan gẹ́gẹ́bí Arole Baba ti ó tọ̀nà àní Mèsáyà tí a ṣèlérí Rẹ.
ii. Mat. 1:1-16: Ìwé Mímọ́ jẹ ki o ye wa pe Mèsáyà náà yóò jẹ ọmọ Ábúráhámù (Gen. 12:1-3; 22:18) àti ti Dáfídì (2 Sam. 7:12). Èyí ni pé yóò jẹ ìran àwọn méjèèjì.
iii. Ẹsẹ 1: Àwọn Júù gba àwọn ìlérí Ọlọ́run yìí gbọ, bẹẹni wọn sì fi sùúrù dúró de ìmúṣẹ rẹ, Ihinrere Mátíù fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ábúráhámù àti Dáfídì ti a ṣèlérí Rẹ.
iv. Ẹsẹ 17: Láti Ábúráhámù wa de Dáfídì jẹ́ ìran Mẹrinla: láti Dáfídì títí dé ìgbèkùn Bábílónì jẹ́ Mẹ́rinla láti ìgbèkùn títí dé àkókò Kristi jẹ Mẹ́rinla. Ìtàn ìran Kristi fihan pe a jogún oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n o n fi fúnni bí o ba ti fẹ́. O satẹnumọ agbára Ọlọ́run láti pa ìlérí Rẹ mọ (ẹsẹ 11-16).
v. Ọlọ́run fún Ábúráhámù àti irú ọmọ Rẹ ni ìlérí ìbùkún fún gbogbo aráyé. O fi fún Dáfídì àti irú ọmọ rẹ, ìlérí ijọba ayérayé. Jésù wa, a sì tọpa Rẹ kan Ábúráhámù àti Dáfídì. Irufẹ Ọlọ́run isedeede wo ni èyí!
B. ÌṢEDEEDE ÀKÓKÒ IBI RẸ (Gal. 4:1-4)
Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ Rẹ jáde wa, ẹniti a bí nínú obìnrin, tí a bí lábẹ́ ofin (Gal. 4:4)
i. Ẹsẹ 1-3: Láti ìgbà ìṣubú ènìyàn, ní nǹkan ti burú jọjọ, awa wa ni onde lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá (ẹsẹ 3), ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣèlérí láti da sii ni akoko ti ó tọ (wo Gen. 3:15).
ii. Ẹsẹ 4a: Wíwà Kristi sínú ayé ko ṣèèṣì. O wa lábẹ́ àkókò tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ tàbí yàn. O wa ni akoko ti Ọlọ́run ti pinnu rẹ.
iii. Ẹsẹ 4b: Ọmọ Ọlọ́run ti a bí nínú obìnrin, tí a bí lábẹ́ òfin, láti ṣe asepe òdodo òfin fún ènìyàn (Rom. 10:3 síwájú), Òfin kún fún àìlera débi pé kò lè fúnni ní iye. Jésù ni lati gbọ́ràn sì òfin lẹ́nu ni gbogbo ọ̀nà, kí o sì dúró níwájú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin pípé àti Ẹni tí o yẹ.
iv. Aráyé nílò olutusilẹ/Olùgbàlà. Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ sínú ayé, kí ìṣe áńgẹ́lì tàbí ẹ̀dá miran. Ọlọ́run n tọju bẹẹni ó sì fẹ́ràn ènìyàn, tóbẹ́ẹ̀ gẹ tí o fi rán ọmọ Rẹ láti gba ènìyàn silẹ kúrò lábẹ́ ìdálẹ́bi búburú òfin.
v. Ọlọ́run mú kí wíwà Jésù o fi òpin sí àkókò òfin, kí àkókò oore-ọ̀fẹ́ o le bẹ̀rẹ̀, kí àwọn ènìyàn o le tipàṣẹ Rẹ kúrò lábẹ́ jíjẹ ẹrú sì òfin sì òfin ẹṣẹ àti ikú (Rom. 6:14; 8:12).
vi. Nítorí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sì ènìyàn, Ó rán ọmọ Rẹ láti gbala àti láti fún ènìyàn ni òmìnira pátápátá kúrò lábẹ́ ìdálẹ́bi ẹrú jẹjẹ tí òfin. Ní àkókò tí O da.
ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1. Eto ati erongba Ọlọ́run kọjá òye ènìyàn bẹẹni ó sì n bojuto eto ayérayé Rẹ fún ènìyàn. Èyí sì farahàn sínú ayé Ábúráhámù àti Dáfídì ti ó sì wa si ìmúṣẹ nínú Jésù Kristi.
2. Ohunkóhun tí Ọlọ́run ba ti pinnu láti ṣe ni yóò ṣe ni àkókò tí O yàn.
ÌṢẸ̀ ṢÍṢE
Ọlọ́run ko lọra láti safihan Jésù, ọmọ Rẹ fún aráyé ni àkókò tí o tọ. Ẹ jíròrò.
 
ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
i. Ọlọ́run n tọju ènìyàn bẹẹni Ó si fẹ́ràn rẹ. O rán ọmọ Rẹ láti gba ènìyàn kúrò lábẹ́ ìdálẹ́bi òfin tí o ní ẹrù.
ii. Wíwà ọmọ ènìyàn pa òfin lẹ́nu mọ, Ó sì fún ènìyàn ni oore ọ̀fẹ́.
iii. Ọlọ́run fìdí ètò Rẹ múlẹ̀ ni akoko ti O da
iv. Wíwà ọmọ Ọlọ́run ni o ṣe àkóso eto ayérayé Rẹ fún Ènìyàn.
v. Ọlọ́run fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn fún aráyé nípa fífún wá ní ọmọ Rẹ kansoso, nítorí pé aráyé nílò olùdáǹdè kan.
vi. A bí ọmọ Ọlọ́run láti inú obinrin lábẹ́ òfin, o gbé lábẹ́ òfin láti gba òdodo pípé òfin fún ènìyàn.
vii. Ọlọ́run lè ma jẹ ki ọmọ Rẹ ki o wa lati kú gẹ́gẹ́ bí ètùtù fún ìràpadà ènìyàn ṣùgbọ́n O yàn láti yọnda Rẹ ni akoko ti O da (Wo Rom. 8:32).
viii.Ọlọ́run ko ṣiyèméjì láti fi Jésù fún aráyé ni àkókò tí O da nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ fún ènìyàn. Ẹ̀bùn Jésù fún aráyé ṣe iyebíye (ọ̀wọ́n) sì Ọlọ́run, bíó-tilẹ̀-jẹ́ ọ̀fẹ́ fún wa.
x. Ẹ̀bùn yí ni a ko gbọ́dọ̀ sì lo, nítorí àwọn tí wọn n sì ẹ̀bùn yìí lo yóò kábámọ ni isinsin yìí àti ní ígbẹhin.

Leave a Reply