ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun October 20, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ Ọjọ́ 

By | October 20, 2019

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun October 20, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ Ọjọ́ 

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI
Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.
ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ
Ọjọ́ October 20, 2019.

II. ÀṢE E LOGO NÍGBÀ ÌGÒKÈ RE ỌRUN (Ìṣe. 1:2-11; I Jhn. 2:1-2)

‘Jesu Kristi gòkè re Ọrùn láti gba ogo tí o tọ si I gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o ṣẹgun ẹṣẹ àti ikú (Fil. 2:8-11), láti jẹ Olùlaja àti Alagbawi wa lọdọ Baba (Heb. 9:24); láti ran Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bi O ti ṣèlérí nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa (Jhn. 16:7), àti láti pese ibi kan fún wa gẹ́gẹ́ bí O ti ṣèlérí (Jhn. 14:2). Ìgòkè re Ọrùn náà n sọ̀rọ̀ nípa ìṣelóge Rẹ ni ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́.

A. O LỌ SÍNÚ ÀWỌN ỌRUN (Ìṣe. 1:2-11)

Nígbà tí o sì ti wi nnkan wọ̀nyii, bi wọn tí n wò, a gbe E sókè, àwọsánmà sì gba A kúrò ní ojú wọn (Ìṣe 1:9).

i. Nípa imọ rẹ ni ìránṣẹ́ mi olódodo yóò da ọ̀pọ̀lọpọ̀ lare,… yoo si ba awọn alágbára pin ìkógun, nítorí yoo ru aisedese wọn wọnnì (Isa. 53:11,12), yoO ni lati goke re ọrun lọ sí iwájú Olúwa ni ọrun, ni ọwọ ọtun Ọlọ́run (wo Orin Daf. 16:10,11).

ii. Ati kọ́kọ́ ri ìgòkè re ọrun Kristi ni Orin Dáfídì (68:18; 110:1), Kristi ni o si sọ àsọtẹ́lẹ̀ yii (Jhn. 6:62; 16:7; 20:17). Eyi safihan pé àjíǹde Jesu rekọjá sísọji (titaji) fún igba díẹ̀.

iii. Ìṣe 1:4-8: Jesu tí mẹ́nuba a tẹlẹ pe fún anfaani wa ni Oun ṣe n padà lọ si ọrùn (Jhn. 18:7). Nítorí náà, bi O ti gbaradi láti padà lọ láti mú ileri náà ṣẹ, O tún ṣatẹnumọ rẹ fun wọn.

iv. Ẹsẹ 9-11: Lẹyin ìfarahàn àti ìrírí Rẹ ogójì ọjọ lẹyin àjíǹde Rẹ, O gòkè re Ọ̀run, ti O joko ni ọwọ ọtun ìtẹ̀, ọlọ́lá julọ ninu awọn ọrun (Heb. 8:1).

v. Ẹfẹ 4:8-10: Jesu tí o jinde naa ni Ẹnikan ṣoṣo tí o goke sì ibi giga, (Orin Daf. 68:18), ju àwọn ọrun lọ, ìwọ di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ. Oun ni ẹni tí a ti gbe ga ju gbogbo àṣẹ lọ (Efe. 1:21-23; Fil. 2:9-11). Láti di ẹni ìgbàlà, a gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ ara wa fun àṣẹ Rẹ ki a si jẹwọ títóbi Rẹ.

vi. Gígòkè rẹ ọrun n tọ́kasi iṣẹlẹ dìde adé igbega Rẹ, o si n dúró gẹ́gẹ́ bi ìbẹ̀rẹ̀ pàtàkì fún ìṣẹ́ Rẹ ti o n tẹsiwaju nípasẹ̀ Ẹ̀mí àti Ìjọ.

vii. Kristi gòkè re Ọ̀run nítorí tiwa àti fún yíyẹ Ẹniti O jẹ, ko tọ pe ki O dúró si ayé lẹyin àjíǹde Rẹ bikose pe ki O gòkè lọ sínú àwọn ọrun Rẹ.

B. O WA PẸ̀LÚ BABA NÁÀ GẸ́GẸ́ BI ALAGBAWI WA (I Jhn. 2:1-2)

Ẹyin ọmọ mi, ìwé nnkan wọ̀nyii ni mo kọ si yin, ki ẹ ma ba dẹ́ṣẹ̀. Bi ẹnikan ba si dẹ́ṣẹ̀, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olódodo (ẹsẹ 1).

i. Alagbawi jẹ ẹnìkan tí n ran àwọn ẹlòmíràn lọwọ tàbí to n ṣipẹ fún wọn níwájú Ìdájọ́. Alagbawi máa n dìde iranwọ, àtilẹ́yìn, gbani niyanju àti ṣipẹ bákan náà nígbà tí o ba yẹ.

ii. Ẹsẹ 1: Jesu ni alagbawi fún àwọn tí o fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Rẹ. Jesu tún pe Ẹ̀mí-Mímọ́ ni alagbawi wa, (Jhn. 14:16,26; 15:26; 16:7). Èyí tí o wuni lórí jọjọ ni pe, Jesu àti Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú Baba náà jẹ ọkan (Jhn. 16:13-15).

iii. Ọrọ Gẹ̀ẹ́sì náà alagbawi ni a túmọ̀ láti inú ede Gíríìkì, parakleton, èyí tí o túmọ̀ si “Oluranlọ́wọ́, Olugbani-niyanju.” Ni eto idajọ tí ènìyàn, alagbawi máa ń sọ̀rọ̀ fún ẹtọ onibara rẹ. A máa ń pe wọn ní àgbẹjọro nítorí wọn tí kọ ẹ̀kọ́ nípa alude àti apade òfin, wọn si le ṣàkóso àwọn òfin tó dabi ẹni pé wọn le pẹlu ìpinnu (Ìgboyà).

iv. Àwòrán tí a ni ni yii nígbà tí a tọ́kasi Jesu gẹ́gẹ́ bi alagbawi wa ti O wa pẹ̀lú Baba náà. Òfin Ọlọ́run ti o jẹ òdodo sọ wa di ẹni ìdálẹ́bi ni gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n Jésù dúró gẹ́gẹ́ bi alagbawi laarin ọkàn wa ti o ti ronupiwada àti òfin.

v. Ẹsẹ 2: Bí a bá ti samulo ẹjẹ Rẹ nínú ayé wa nípasẹ̀ igbagbọ àti jijẹwọ Rẹ gẹ́gẹ́ bi Olúwa (Rom. 10:9-10; 2 Kor. 5:21), O n ṣe alagbawi fún wa lọdọ Onidajọ òdodo naa (Rom. 8:1; Kol. 2:14).

vi. Alagbawi wa àtọ̀runwá mọ ọkàn wa, O si n gba ẹjọ́ wa ro lórí ohun tó wa nibẹ (Mk. 2:8; Luk. 5:22). Ọlọ́run tẹ́wọ́gba ẹ̀bẹ̀ (isipẹ) ọmọ Rẹ lori wa gẹ́gẹ́ bi ọkàn lára àdéhùn àtọ̀runwá wọn, ti o ti wà ṣáájú ìbẹ̀rẹ̀, ayé (I Pet. 1:20; Jhn. 17:24; Ifi. 13:8; Rom. 4:25; 8:3; I Kor. 1:30).

vii. Síbẹ̀, bíó-tilẹ̀-jẹ-pe ko si ìdálẹ́bi fún àwọn tí wọn wa nínú Kristi, a nilo ìdáríjì Ọlọ́run síwájú sii láti gba wa níyànjú láti máa rìn nínú iwa mimọ. Bi a ti n ronupiwada, Jesu n ṣe alagbawi fún wa láti mú idapọ wa pẹ̀lú Ọlọ́run bọsipo.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1. Àjíǹde Kristi ti o mú Iwe mimọ ṣẹ nigbẹyin-gbẹyin ni ipilẹ ìgbàgbọ́ Kristẹni wa. Njẹ ìwọ gbagbọ?

2. Ko yẹ kí ohunkóhun o ba wa lẹru nítorí Jésù wa titi ayé, O n mú Iwe mimọ ṣẹ láti sipẹ (bẹbẹ) fún wa lọdọ Baba ti n bẹ ní ọ̀run.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1. Dárúkọ àwọn ẹri Bíbélì mẹta ni ti àjíǹde Jésù?

2. Kínní ìṣẹ́ Jésù ni Ọrun báyìí?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈR :
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ :

Jésù safihan Rẹ pe Oun wa láàyè pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹri ti ko le kùnà (Ìṣe. 1:3), pẹ̀lú :

i. Òkúta tí a yí kúrò àti ibojì tí o ṣòfò (Mat. 28:6a; Mk. 16:4; Luk. 24:2-3).

ii. Ìfarahàn Rẹ fún Màríà Magidalénì àti àwọn obìnrin mìíràn (Mat. 28:9-10)

iii. Jòhánù Aposteli fidi ìfarahàn Rẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ múlẹ̀ àti bi O ti rán wọn nisẹ, Tọ́másì ko si nibẹ nígbà náà (Jhn. 20:19-23)

iv. O tún farahàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹẹkan sii, pẹlu Tọ́másì nibẹ (Jhn. 20:24-29). O fi àwọn apa tí o wa ni ọwọ Rẹ hàn Tọ́másì pé nítòótọ́ Òun ni o farahàn fún wọn lẹ́yìn àjíǹde Rẹ (Jhn. 20:27)

v. Pọ́ọ̀lù tún sàkọsílẹ̀ onírúurú ìfarahàn fún àwọn ènìyàn àti òun fúnrarẹ pẹ̀lú, ni ojú ọ̀nà Damásíkù (I Kor. 15:5-8).

vi. Ìwàláàyè àti Ìṣẹ́ Rẹ ti o tẹsiwaju nínú ayé àwọn onigbagbọ lónìí, nipasẹ Ẹ̀mí Rẹ jẹ ẹri ti o tọ ni ti àjíǹde Rẹ, ní àfihàn Rẹ, ní àfikún pẹ̀lú àwọn ẹri Bíbélì tí ko ni àbáwọn.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJI

i. Ṣíṣe alagbawi fún àwọn onigbagbọ níwájú Baba Rẹ (I Jhn. 2:1-3)

ii. Pípèsè ilé silẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ bi O ti n múra láti padà wa fún gbogbo ẹni tó ba gbagbọ nínú Rẹ (Jhn. 14:1 síwájú).

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :

Ọkùnrin kan wà ní ìgbà kan, tí o fọn-nù pé òun yóò kú, òun o sì tún jinde, nitori naa o pàṣẹ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ pé kí wọn kóra wọn jọ sí ibi ibojì òun nítorí òun yóò jinde. O gbìyànjú rẹ nípasẹ̀ agbára òkùnkùn, ṣùgbọ́n o jakulẹ níkẹyìn. Orúkọ rẹ ni De-Lawrence, láti India’. Ìtàn kún fún àwọn itan àjíǹde rẹ tí o jakulẹ. Ṣùgbọ́n Jésù kú, a sin In ni ibamu pẹ̀lú àṣà Júù. O jinde ni ọjọ kẹta nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run. O rin káàkiri ayé yìí fún ogójì ọjọ mìíràn kí O tó padà gòkè re Ọrun nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run kan náà, níbi tí o wa báyìí, tí o n sipẹ fún àwọn ènìyàn tiRẹ Ìjọ. Bí o bá gba Jésù Kristi lónìí gẹ́gẹ́ bí Olúwa àti Olùgbàlà rẹ, ìwọ yóò máa tẹsiwaju nínú jíjẹgbadun àwọn ìbùkún àti anfaani ìgòkè re Ọ̀run Rẹ. Njẹ o ti ṣetán bi? Tabi o ti gba A bí? Nítorí náà, dúró tì I titi ayérayé.

IGUNLẸ :

A ti rí bí a ti mú Iwe Mimọ ṣẹ nípa àjíǹde àti ìgòkè re Ọrùn Jésù Kristi. Èyí ni ipilẹ ìgbàgbọ́ wa gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ nínú Jésù Kristi Olúwa. O n pe wa nija láti máa wo Kristi fún gbogbo ìfẹ́ ọkàn wa, bi o ti jẹ pe O n sipẹ fún wa, O si n ṣe alagbawi wa níwájú Ọlọ́run. O tún n fún wa ní ìdánilójú ibùgbé (ààyè) kan ni “Ilé Baba Rẹ”, ní ìkẹyìn ọjọ́, níwọ̀n bi a ba ti dúró nínú Rẹ.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ ÌKEJÌ

Mon. 14: Kristi Ti O Gòkè Re Ọrun, Joko Pẹ̀lú Baba Náà (Kol. 3:1)

Tue. 15: Kristi Ti O Gòkè Re Ọ̀run Dide Dúró Láti Tẹ́wọ́ Gba Sítéfánù (Ìṣe. 7:56)

Wed. 16: Kristi Ti O Gòkè Re Ọ̀run Farahàn Sọọlu Ara Tarsu (Ìṣe. 9:5)

Thur. 17: Kristi Ti O Gòkè Re Ọ̀run Sipẹ Fún Àwọn Ènìyàn Rẹ (Héb. 7:25)

Fri. 18: Kristi Ti O Gòkè Re Ọ̀run N Ran Àwọn Tí A Danwo Lọwọ (Héb. 2:18)

Sat. 19: Kristi Ti O Gòkè Rẹ Ọrun N Kaanu Pẹlu Àwọn Onigbagbọ (Héb. 4:15).

Leave a Reply