ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN OCTOBER 6, 2019  Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ

By | October 5, 2019

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN OCTOBER 6, 2019  Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ
ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ

II. O KÚ LÁTI MÚ ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ (Mat. 26:14-27; 3-50; Jhn. 19:30-42)

Oct. 6, 2019.

Àwọn ìjìyà àti ikú Jésù níkẹyìn gbogbo da lori ìmúṣẹ àwọn Ìwé Mímọ́. Gbogbo igbesẹ ayé Rẹ fogo fún Ọlọ́run, kódà lójú ikú. O ni lati kú kí Isaiah 53:5 swj. àti àwọn Ìwé Mímọ́ pàtàkì mìíràn lè di mímúṣẹ.

A. O JÌYÀ GẸ́GẸ́ BÍ ÌWÉ MÍMỌ́ TÍ SỌ (Mat. 26:14-75; 27:3-35).

Ṣùgbọ́n Ìwé-Mímọ́ yóò há tí ṣe tí yóò fi ṣẹ, pé bẹẹ ni yóò ri? (26-54).

i. Mat. 26:14-16: Ọgbọ́n owo fàdákà tí Júdásì torí rẹ fi Jésù hàn, jẹ iye owó (ìdíyelé) ẹrú (wo Eks. 21:32). Bákan náà, o ń ṣe ìmúṣẹ àwọn igbesẹ àsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Sekaráyà (Sek. 11:7-13). Ṣe afiwe iye owó aláìníláárí tí Júdásì ọdalẹ yìí pẹ̀lú ìfọkànsìn obìnrin náà tí o ṣe iyebíye nínú 7:13. Irú ipò irẹsílẹ̀ tó banilẹru jọjọ wo ni Jésù fi ara Rẹ si yìí, nítorí tí wa nìkan!

ii. Ẹsẹ 31: Jésù rí ikọsilẹ tí o wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ ati ituka wọn (ẹsẹ 56) gẹ́gẹ́ bi ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ (wo Sek. 13:7).

iii. Ẹsẹ 47:50: Isafihan Jésù ti o wá sáyé, nipasẹ Júdásì mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ (wo O.D. 41:9).

iv. Ẹsẹ 50-54: Jésù ba Pétérù wí fún gbigbiyanju láti ja fun Un. O sọ wí pé Òun gbọ́dọ̀ jìyà gẹ́gẹ́ bi Baba ti ṣètò rẹ. “Ago náà” (Jhn. 28:11) n tọ́ka sí ìjìyà, dídáwa àti ikú tí Baba ti fi fún Un láti la kọjá.

v. Ẹsẹ 51-56: Jésù ri ifagbara mú Rẹ gẹ́gẹ́ bi ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́, tí ó ṣe Pàtàkì fún ìràpadà ẹ̀dá ènìyàn tí a ti da lẹbi (Maku 14:48,49).

vi. Ẹsẹ 69-75: Pétérù sẹ Jésù gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọtẹ́lẹ̀ (wo ẹsẹ 33:35). Maa kọ láti mọ ọkàn Ọlọ́run nígbà gbogbo láti le mọ ohun tí O ni fún ọ, kí ìwọ ma ba si ẹsẹ gbe (sise) lọ́nàkọnà.

vii. 27:3-10: Ikú Júdásì àti irọpo/ìpàrọ rẹ pẹlu Matia láàrin àwọn Aposteli (Ìṣe 1:15 swj), ní a ri gẹ́gẹ́ bi ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ (wo O.D.69:25; 109:8).

viii. Ẹsẹ 11:14: Jésù ni ìmúṣẹ òtítọ́ náà niti Àgùntàn tí o fi idakẹ jẹjẹ yadi níwájú olùrẹ́run Rẹ (wo Isa. 53:7).

ix. Ẹsẹ 27-35: A fi Jésù ṣẹlẹ̀ya lọpọlọpọ (Jhn. 18:22) gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí sọ (wo O.D. 22:18).

x. Gbogbo àwọn iṣẹlẹ búburú wọ̀nyí ni Jésù la kọjá ní ọwọ èṣù àti àwọn akọ/aṣojú rẹ, lójú ọna Rẹ si ori àgbélébùú, gbogbo wọn pàtápàtá lo n mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ wi pé ejo láéláé ni yóò pa Mèsáyà náà ni gigisẹ (irú ọmọ obìnrin náà) fún ìràpadà wa (wo Gen. 3:15).

ix. O jìyà, a na An, fiya jẹ Ẹ, a si pọn Ọn lójú, gbogbo rẹ fún ìmúṣẹ Isaiah 53:7 ni. Ikú Rẹ ki i ṣe láti safihan agbára idán pípa Rẹ gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ nipa ẹlẹgbẹ ìmulẹ kan ni odun díẹ̀ sẹ́yìn tí o funnu láti kú àti láti jinde lọ́jọ́ kẹta láti fi hàn wí pé ohun tí Jésù ṣe kí ṣe babara; o fi idan pípa dibọn ikú, tí o si n gbìyànjú láti jinde, ṣùgbọ́n agbára tí o dabi ará Jésù alágbára julọ san pa a pátápátá. Ìwọ yóò ni “èyí báni-nínú-jẹ pupọ. Jésù ko gbìyànjú láti tọ́kasi ohunkóhun. A ran An láti mú àwọn ìwé mímọ́ ṣẹ nípa ti ìràpadà wa. Máṣe faaye gba ẹbọ onirora Rẹ láti lọ lásán lórí ayé rẹ.

B. O KÚ A SÌ SIN IN (Mat. 27:35-50; Jhn. 19:30-42).

” Níwọ̀n wákàtí Kẹ̀sán-an ni Jésù kígbe ni ohun rara wí pé, Eli, Eli lama Sabaktani? Èyí ni ni Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ mi silẹ?” (Mat. 27:46).

i. Mat. 27:35-50: Yàtọ̀ sí àwọn ìrírí tí a mẹ́nuba nibẹrẹ pẹpẹ nípa ti aṣọ Rẹ ti àwọn ológun wọnnì pín láàrin wọn, Jésù la akaimoye àwọn ìrírí kọjá lórí igi àgbélébùú (wo Jhn. 19:30swj). Ibùwọ̀n ìjẹnìníya/irẹsílẹ tí O la kọja lórí Igi Àgbélébùú ṣe ìmúṣẹ pípé Isaiah 53:8,9.

ii. Ẹsẹ 45,46: Kìkìgbé sókè Jésù ni ede Aramaiki tí ṣe ede ibi Rẹ nígbà tí O n la ibanujẹ tí kíkorò rẹ kọjá sísọ nínú ọkàn Rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn kọjá, nítorí irẹsílẹ atokewa jẹ ọrọ/àlàyé tí Orin Dáfídì 22:1 sọ àti ìṣẹ́gun tí Sáàmù náà n ṣàpèjúwe.

iii. Jhn. 19:32-36: Ko si ọkan kan (èyíkéyìí) nínú egungun Jésù ti o sẹ/kan/run, bi o tilẹ jẹ pé egungun àwọn ìyókù ni lati ṣẹ/kan. Èyí mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ (wo Eks. 12:46; Num. 9:12; O.D. 34:20). Òun ni ìrékọjá Ọdọ-Àgùntàn Ọlọ́run ti o ga julọ, ẹbọ pípé náà (wo I Kor. 5:7).

iv. Ẹsẹ 37: A gbe Jésù kọ sórí igi láti mú Iwe Mimọ ṣẹ “… wọn o si maa wo mi ẹni tí wọn tí gun ni ọkọ (Sek. 12:10).

v. Ẹsẹ 42: Ni akotan, a tẹ ara Rẹ sínú ibojì, gbogbo rẹ fún ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ àti eto Ọlọ́run latokewa ni (wo Isa. 53:9).

vi. O gbọ́ràn si Ọlọ́run nípa rirẹ ara Rẹ silẹ, kódàa titi de ojú ikú (tí ko tọ si I) gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn lórí àgbélébùú (Filip. 2:8). Láti faaye gba ìmúṣẹ eto Ọlọ́run tó ga julọ fún aráyé — Igbala (wo Deut. 21:23; Gal. 3:13).

vii. O mú àwọn Ìwé Mímọ́ ṣẹ kódà dojú ikú. Irú ayé wo ni èyí! Àpẹẹrẹ fún gbogbo Kristẹni láti máa ṣe awokọse. Ikú Rẹ ni pípé kan ṣoṣo tí o yẹ láti máa lo gẹ́gẹ́ bí awokọse àpẹẹrẹ láti gbàdúrà. Num. 23:10.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RI KỌ

1. Àwọn ìjìyà Jésù jẹ àmọ́tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run fún eto ìràpadà ayérayé. Àwọn nǹkan kan wa ti a ti yàn fún ọ láti la kọjá láti de ibi ìmúṣẹ ayànmọ rẹ. Maa gbàdúrà fún oore-ọ̀fẹ́ láti la wọn kọjá pẹ̀lú àṣeyọrí.

2. Kódà ni ojú ikú, Jésù Kristi si n mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ. Njẹ o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀mí rẹ tí o si n gbe igbe ayé to lapẹẹrẹ láti jẹ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ bi?

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1. Jésù mọ àwọn ohun tí a ti kọ fun Un láti la kọjá nínú igbe ayé (iye) àti ikú, síbẹ̀, O doju kọ wọ́n tààrà. Njẹ èyí ni ìtumọ̀ kankan si awọn Kristẹni lóde òní bi?

2. Gbogbo igbesẹ ayé Jésù láti ìgbà ọmọdé títí dé ikú Rẹ gbogbo jẹ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ. Kin ni èyí túmọ̀ si si ọ gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ:

i. Jésù ti mọ lẹkun-un-rẹrẹ nipa gbogbo àwọn ohun tí yóò la kọja láyé, èyí tó burú julọ, nitori àwọn tí ko tọ sí, tí a pe ni àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, a gbé àwòrán gbogbo rẹ wa fun Un ní Gethsemane. Èyí tí o yànlẹ́nu julọ ni pé O yàn láti ru gbogbo ẹrù wọnyi pẹ̀lú gbogbo àwọn ìrora to rọ̀ mọ wọn.

ii. O mọ wí pé gbogbo rẹ ni yóò yọrí si èbúté ogo, nítorí náà, kO wo iya naa bikose àbájáde rẹ. O mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí a ti kọ nípa Rẹ niti ẹrú iṣẹ ńlá tí O ti wá láti ṣe parí ko si ṣetán láti jẹ ki ohunkóhun gba Òun kúrò lójú ìlà náà.

iii. Oju Jésù ti tẹ mọ́ orí àgbélébùú láti ọjọ ti O ti wọnú ayé titi di ọjọ ti a papa wa kan an mọ igi àgbélébùú. Òun kò ní faaye gba ohunkóhun miran (kirakita owo ṣíṣe ẹsin àti òṣèlú ayé, iwa omugọ àti iwa ẹ̀gbin àwọn ọmọlẹ́yìn àti àwọn ará ile, idunkooko mọni àti àtakò àwọn ọ̀tá Rẹ, ayọ̀/ìdùnnú àwọn iṣẹ́ ìyanu yọ tọwọ Rẹ ṣẹlẹ̀ abbl) ko gbá àfojúsùn Rẹ dànù.

iv. Kristẹni bákan náà gbọdọ mú ìdúró àfojúsùn wọn nípa títẹ́jú wọn àti ọkàn wọn mọ ogo tó wa níwájú, kii sì ìṣe láti tẹjúmọ àwọn àdánwò àdìnílọ́wọ́ (wo Rom. 8:18).

v. Jésù pinnu láti gbọ́ràn sì baba Rẹ lẹ́nu ni gbigba ayé la kúrò nínú ẹṣẹ àti ikú, nítorí náà, ohun tí yóò dojúkọ láti mu èyí ṣẹ ko ṣe pàtàkì si I gẹ́gẹ́ bi ìṣẹ́ tí a ran An.

vi. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ pinnu láti tẹle Kristi, nínú iye àti ikú, kii ṣe ki a wa jọ̀wọ́ ara wa fún àwọn àdánwò, ìdojúkọ àti inúnibíni ayé (wo I Kor. 11:1).

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJI:

i. Eyi túmọ̀ si wí pé Jésù raraRẹ ji lẹkun-un-rẹrẹ àti pátápátá fun ìṣẹ́ Rẹ.

ii. Èyí túmọ̀ sí pé Jésù gbé gbogbo igbesẹ ayé Rẹ nínú rinrin àti ṣíṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

iii. Jésù tikalara Rẹ ni Ọrọ náà tí o wa ni ìwò ènìyàn, láti fi ara Rẹ hàn nínú ara nínú ẹ̀dá ènìyàn.

iv. GGẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Rẹ, a gbọ́dọ̀ máa rántí nigba gbogbo pé, yálà a mọ̀ tàbí a ko mọ, a n mú àwọn ìwé mímọ́ ṣẹ pẹ̀lú igbe ayé wa.

v. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ kiyesara, kí a mase máa mú àwọn ìwé mimọ ṣẹ lọ́nà odi. Júdásì ni àpẹẹrẹ búburú niti ọ̀ràn yìí.

vi. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣáṣáro nínú Bíbélì nígbà gbogbo kí a sì máa gbàdúrà daradara kí a ma ba wa ninu òkùnkùn sì àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ tí a ko ti i múṣẹ.

vii. A gbọdọ jijade pẹ̀lú iranlọwọ Ẹ̀mí Mímọ́, láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rere tí ìwé mimọ tí O n retí wa lati múṣẹ. Ìgbà náà nìkan ni a to le laya láti pàdé Rẹ pẹlu ayọ̀ ńlá àti ìgboyà nínú Rẹ, ní ọjọ́ ìkẹyìn. A ko ni kùnà (pàdánù)

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI:

Jésù Kristi gbé gbogbo igbesẹ ayé Rẹ láti mú àwọn ìwé mimọ ṣẹ. Koda, O ti sọ fún wọn gbangba, ni ọpọlọpọ ìgbà wí pé Òun yóò kú láti mú iṣẹ ìràpadà ènìyàn ṣẹ. O gbé ìgbé ayé Rẹ gẹ́gẹ́ bí imuwasoju ìṣe (àfihàn) àwọn ohun tí àwọn ìwé mimọ sọ nípa Rẹ nínú Májẹ̀mú Láéláé àti àwọn wọnnì tó ti sọ ṣáájú nípa ara Rẹ bí O ti n gbaradi láti safihan Májẹ̀mú Tuntun. Àpẹẹrẹ ni èyí fún gbogbo Kristẹni láti wokọ̀ṣe fún igbe ayé wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ìwé mímọ́ le ma wa sí ìmúṣẹ nínú ayé ènìyàn bi ẹni náà (ọkùnrin/obìnrin) ko ba wa ni ìbámú sí àpẹẹrẹ igbe ayé tí yóò ṣe rẹ́gí julọ fún àwọn ìwé mimọ láti di mimusẹ. O gbọ́dọ̀ gbé ayé rẹ ni ọ̀nà to jẹ pé yóò fi ògo fún Ọlọ́run ti yóò sì ti ìmúṣẹ àwọn ìlérí àti májẹ̀mú Ọlọ́run láti ṣiṣẹ́ fún ayé rẹ. Bákan náà o tún ní láti gba Ọlọ́run gbọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run to n pa májẹ̀mú mọ Ẹni tí ki ikuna tàbí jánikulẹ. O máa n dúró lórí ohun tí O ba sọ, O si maa n sọ ohun tí O ba pinnu láti ṣe.

IGUNLẸ :

Ọrọ Ọlọ́run ko le re bọ lulẹ láéláé; yóò ṣe àṣeparí erongba fún èyí tí a rán an dandan. Àwọn Ìwé Mímọ́ tí wá sí ìmúṣẹ, wọn si n ṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, àti àwọn ọpọ mìíràn yóò sì wa sí ìmúṣẹ. Àwọn ìwé mímọ́ yìí ni ìfihàn fúnra-ara-ẹni, àwọn àsọtẹ́lẹ̀, àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìran láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá fún ènìyàn. Igbe ayé àti ikú Jésù Kristi jẹ itọkà /àpẹẹrẹ èyí kedere. O wá gbé láyé, jìyà, O si ku ni ìmúṣẹ àwọn Ìwé Mímọ́. Nítorí náà, ènìyàn gbọdọ gbé ìgbé ayé rẹ kì o sì ṣètò ayé rẹ lọ́nà tí yóò fi le faaye gba àwọn ìwé mímọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run láti di mimusẹ nínú ayé rẹ pẹlu irọrun. Jésù Kristi ni àpẹẹrẹ pípé wá gẹ́gẹ́ bí gbogbo igbesẹ ìgbésí-ayé Rẹ (láti ibi titi de ikú) ṣe jẹ́ isafihan ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́. Ki Ọlọ́run rán wa lọ́wọ́ láti tẹle E bí o ti to. Àmín.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ ÌKEJÌ

Mon. Sept. 30: Kristi Wa lati Mú Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ Ṣẹ (Mat. 5:17).

Tue. Oct. 1: A Gbọ́dọ̀ Mú Gbogbo Àwọn Ìwé Mímọ́ Ṣẹ (Mat. 5:18)

Wed. Oct. 2: Jésù Kígbe Lóhùn Rara Lórí igi Àgbélébùú (Mat. 27:46).

Thur. Oct. 3: Nigbẹyin Jésù Jọ̀wọ́ Ẹ̀mí Rẹ (Mat. 27:50).

Fri. Oct. 4: Àwọn Iṣẹlẹ To Wáyé lásìkò Ikú Jésù (Mat. 27:51-54).

Sat. Oct. 5: A Sin Ara Jésù (Mat. 27:57-61).

Leave a Reply