ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN ỌJỌ́ October 13, 2019. Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.

By | October 12, 2019

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN ỌJỌ́ October 13, 2019. Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.

Ẹ̀KỌ́ KEJE:
ÀJÍǸDE ÀTI ÌGÒKÈ RE ỌRUN KRISTI MÚ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ

Àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì àti ìtàn àwọn to n ṣe ìwádìí nípa ohun àtijọ́ náà pe Jésù jíǹde O sì gòkè re Ọrùn múlẹ̀ lojuna láti mú àwọn ìpín tó sọ bẹẹ nínú ìwé mímọ́ ṣẹ.

AKỌSORI

Nítorí náà Ọlọ́run pẹ̀lú sì ti gbe E ga gidigidi, O si ti fi orúkọ kan fún Un tí o bori gbogbo Orúkọ

(Filipi 2:9).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ

Ọrọ náà, “nítorí náà” tí o bẹ̀rẹ̀ akọsori náà túmọ̀si pe ọrọ jẹ ọrọ ti o ti parí tàbí àbájáde ohun tí a sọ ni àwọn ẹsẹ ìṣáájú. Jésù di àpẹẹrẹ ìránṣẹ́ ónirẹlẹ tí o ga julọ nípasẹ̀ wiwa Rẹ, si ayé ni irẹlẹ, gbígbé nínú igbọ́ran àti kíkú lórí àgbélébùú fún àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ. Ẹ ma jẹ ki a gbàgbé pe O ku fún wa nígbà tí a ko safihan ìfẹ́ kankan si I. O ti fidi agbára Rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ àjíǹde Rẹ ati nípasẹ̀ agbára Rẹ láti yí ọkàn àwọn ènìyàn padà. Jésù ti safihan wí pé Òun ni ifẹ tí o ga julọ tí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run ni ọkàn nítorí O finufindọ kúrò ní ipò tí O wa ni ọrun, O si gba ipo ìránṣẹ́ ki O le gba wa la àti láti ra wa pada. Nítorí èyí, “Ọlọ́run náà tí gbé E ga gidigidi O sì ti fún Un ní orúkọ tí o ju gbogbo orúkọ lọ. Ko si orúkọ mìíràn tí a le fi safiwe pẹ̀lú tiRẹ. O da dúró. Òun ni Olurapada kanṣoṣo àti Olùgbàlà. Òun nìkan ṣoṣo ni Kristi náà, Ẹni àmì òróró Ọlọ́run. Òun nìkan ṣoṣo ni ọmọ Ọlọ́run. Ipo, àwọn orúkọ àti iyi Rẹ ga ju ti gbogbo àwọn ẹlòmíràn lọ. Fún ìpọ́njú àti ìjìyà Rẹ, igbega àti orúkọ tí o ga julọ ni ere tí o dara julọ tí Ọlọ́run le fún Ọmọ Rẹ kanṣoṣo.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ

Mon. 7: Jesu, Ko Si Ninu Iboji Mọ (Mat. 28:1-6)

Tue. 8: Jesu Ti Jinde Kúrò Nínú Òkú (Mk. 16:1-6)

Wed. 9: Àwọn Ẹlẹ́rìí Fidi Àjíǹde Múlẹ̀ (Jhn. 20:9)

Thur. 10: Jesu Ti O Jinde Farahàn Àwọn Obìnrin (Matt. 26:6-10)

Fri. 11: Jesu Tí O Jinde Farahàn Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Rẹ̀ (Mk. 16:9-13)

Sat. 12: Jesu Ti O Jinde Fi Ìwàláàyè Rẹ Daniloju (Mat. 25:16-20).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN

1. Àjíǹde àti ìgòkè re ọrun Kristi ti o lógo ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Bíbélì tí sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ Ogo fún Ọlọ́run ti O sedede.

2. Nípa àjíǹde Jesu kúrò, ni a jogún tí a wọnú ijọba Ọlọ́run pátápátá. A gbọ́dọ̀ mọ kí a sì gbagbọ pe ìgòkè re ọrun Kristi jẹ abala ti o ṣe pàtàkì tí o sì pọndandan nínú ètò Ọlọ́run fún ìjọ àti fún ayé. Gbogbo rẹ ṣẹlẹ̀ ni ìbámu pẹlu ìwé mimọ.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: 1 Kọ́ríńtì 15:4-8

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA

ILEPA: Láti rán wa lọwọ láti ni òye bí àjíǹde àti ìgòkè re ọrun Jésù Kristi ti mú àwọn ìwé mímọ́ ṣẹ.

ÀWỌN ERONGBA: Ni ipari ẹ̀kọ́ yii, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ ti:

i. ni òye kíkún kí wọn sì ti le ṣàlàyé àjíǹde àti ìgòkè re ọrùn Jésù Kristi ni ibamu pẹlu ìwé-mímọ́;

ii. le ṣàlàyé ohun ti o túmọ̀si pe a ṣe Jésù lógo ní àjíǹde àti ní ìgòkè re ọrun;

iii. ni ìgboyà sii láti dúró fún igbagbọ Kristẹni, nígbàkúùgbà àti níbikíbi; àti

iv. maa retí igbasoke àwọn onigbagbọ, èyí tii ṣe ìgòkè re ọrun tiwa.

IFAARA

ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: JÒHÁNÙ 20:24-31; ÌṢE ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ 1:2-11; 2:25-28; I JÒHÁNÙ 2:1-2.

Ogo àti ìyìn fún Ọlọ́run Alágbára fún ẹ̀kọ́ tí o kọjá ÌGBÉ AYÉ KRISTI ÀTI IKÚ RẸ MU ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ. Ọlọ́run ran wa lọ́wọ́ láti rí ìgbé ayé tí Jésù gbé ní ìbámu pẹlu ibi Rẹ ṣe mú àwọn ẹsẹ Bíbélì wa si ìmúṣẹ ni pípé ni àwọn ọ̀nà ti ko ṣe e sẹ (fojurena). A tun tí ran wa leti bi O ti kú láti mú Iwe Mimọ ṣẹ. A o ti ni oye daradara nípa igbe ayé àti ikú Oluwa wa Jésù Kristi ti o mú Bíbélì ṣẹ. A tún gbagbọ wí pé gbogbo wa ni o ti ni irulọ́kànsoke láti lépa ìmúṣẹ ni gbogbo ọ̀nà ayé wa.

Ẹkọ yii farajọ èyí tí o kọjá. Bi Kristi ba wa si ayé tí O si kú, O jẹ ohun ti o mọgbọn wá láti ronú àti láti sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde Rẹ, àti ìgòkè rẹ ọrùn Rẹ. Nítorí náà, ẹ̀kọ́ tí a bẹ̀rẹ̀ lọsẹ yìí dálórí ríran wá lọwọ láti ri àti láti ni òye kíkún lórí bi àjíǹde àti ìgòkè rẹ ọrùn Jésù ti mú Iwe Mimọ ṣẹ.

A ti jíròrò ṣáájú nínú ọwọ yìí, àwọn Ìwé Mímọ́ kan tí o tọ́ka ni pàtó sì àjíǹde àti ìgòkè re ọrùn Jésù ti ó lógo tí yóò wáyé. Nítorí náà, a o maa ṣàgbéyẹ̀wò bí a ti ṣe Jésù lógo niti àjíǹde àti ìgòkè Rẹ ọrun, a ko kọ O silẹ nínú ibojì, dípò bẹẹ, a ji I dìde kúrò nínú òkú pẹ̀lú àwọn ẹri; bi O ti gòkè re àwọn ọrun, tí O si joko pẹ̀lú Baba Rẹ.

A gbàdúrà pe Ọlọ́run yóò rán wa lọ́wọ́ láti de ìsàlẹ̀ ọkàn Rẹ fún wa ninu ẹ̀kọ́ yìí, ki O si gba wa níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni orúkọ Jésù. Àmín.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN :

Gẹ́gẹ́ bi ìṣe wa, a pin ẹ̀kọ́ yii si ìpín méjì gbòógì I àti II, pẹ̀lú ìpín sísọri sì ìpín A àti B.

ÌPÍN KÍNNÍ: A ṢE E LOGO NÍGBÀ ÀJÍǸDE

Ìpín yii n ṣi ojú wa si awọn ífìdímúlẹ̀ Bíbélì pe Jésù Kristi jinde kúrò nínú òkú nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run, ẹni tí o tún pa ara Rẹ mọ kúrò nínú idibajẹ. Ìyẹn ni ipilẹ ìgbàgbọ́ wa gẹ́gẹ́ bi Kristẹni: pe Kristi jinde kúrò nínú òkú! O pari pẹ̀lú pe ipenija àti ìgbani-níyànjú tí o n ru ìrètí sókè pe Ọlọ́run ko le kọ wa silẹ (pa wa ti) láéláé, laiwo tí ipokipo tí a ba wa, niwọn bi a ba ti wa ni inu ìfẹ́ Rẹ̀.

IPIN KEJI: A ṢE E LOGO NÍGBÀ ÌGÒKÈ RẸ ỌRUN

NÍ òpin yii, a ri bi a ti gba Jésù Kristi sókè Ọ̀run, lẹ́yìn àjíǹde Rẹ ti o logo, ni ọna ti o logo julọ tí o yẹ ọmọ bibi kanṣoṣo tí Ọlọ́run. Ìgòkè re ọrun ti o logo yìí sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ igbega Rẹ, o si n dúró gẹ́gẹ́ bi ìbẹ̀rẹ̀ pàtàkì fún ìṣẹ́ Rẹ ti o n tesiwaju nípasẹ̀ Ẹ̀mí àti ìjọ. O pari pẹ̀lú ìdánilójú pe Jesu tí wa ni Ọrun na, O n bẹbẹ nítorí (fún) wa, nítorí Òun nikan ni alagbawi kanṣoṣo tí Ọlọ́run fọwọ́si.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́

I. A ṢE É LÓGO NÍGBÀ ÀJÍǸDE

A. A KO KỌ Ọ SILẸ NÍNÚ IBOJI

B. A JI I DÌDE PẸ̀LÚ ÀWỌN ẸRI

II. A ṢE E LÓGO NÍGBÀ ÌGÒKÈ RẸ ỌRUN

A. O LỌ SÍNÚ ÀWỌN ỌRUN

B. O WA PẸ̀LÚ BABA NÁÀ GẸ́GẸ́ BI ALAGBAWI WA.

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́

I. A ṢE E LÓGO NÍGBÀ ÀJÍǸDE (Luku 24:4-8, 44-46; Jòhánù 20:1-31; Ìṣe Àwọn Aposteli 2:24-36)

A ṣe Kristi logo nínú àjíǹde Rẹ. Nínú àjíǹde Rẹ, Kristi yi ipo Rẹ pada: O jẹ ènìyàn ẹlẹ́ran ara, ṣùgbọ́n báyìí Òun ni Èmi ti n fún ní ní iye (I Kor. 15:45). A sọ gbogbo ara Rẹ di ẹ̀mí, a yi i padà sí Ẹ̀mí, Òun ni Ẹmi Jésù ti a ṣe logo ni báyìí, Ẹmi òtítọ́, àti Ẹ̀mí to n fún ní ní Iye. Irú ìyanu wo ni èyí!

A. A KO KỌ Ọ SILẸ NÍNÚ IBOJÌ (Luku 24:4-8, 44-46; Ìṣe. 2:24-36)

Ẹni tí Ọlọ́run gbé dìde, nígbà tí O ti tú ìrora ikú, nítorí tí ko ṣe ṣe fun Un láti di I mu (Ìṣe 2:24).

i. Luk. 24:44-46: Jésù ṣàlàyé pe àjíǹde Òun mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii ṣẹ (wo Orin Dáfídì 16:9-11). Èyí le jẹ òtítọ́ bí ẹnikan ba jinde kúrò nínú òkú (Ìṣe 13:34-38); ẹnìkan náà sì ni Jésù ẹni tí o jinde kúrò nínú òkú.

ii. Ẹsẹ 4-8; Isa. 53:7-12 ti sàsọtẹ́lẹ̀ pe Mèsáyà náà yóò ku, yóò ri iru ọmọ Rẹ, yóò mú ọjọ́ Rẹ gùn (ẹsẹ 10). Báwo ni èyí ṣe le wáyé? Nípa àjíǹde nìkan ṣoṣo. Jésù ni ẹni tí o jinde náà! (Luk. 24:5,6; Ìṣe 2:23-31; 17:2,3; I Kor. 15:1-4).

iii. Ronú nípa bi Jésù ti ń sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ tí o lágbára bẹẹ ni Matt. 16:21 àti Jhn. 2:18-22. Bi ó ba jẹ pe ayédèrú ni, kété leyin iku Rẹ ni gbogbo ènìyàn yóò ti mọ. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn àti dípò kí o pàdánù àwọn ọmọlẹ́yìn, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọn jẹri pe àwọn fún ra wọn ri I pe O tun wa láàyè lẹ́yìn ikú Rẹ (wo Mat. 17:9,23; 20:19; 26:32; 27:63; Mk. 8:31; 9:9, 10:31; 10:34; 14:28; Lk. 18:33; 24:4-7; Ìṣe 10:40-43).

iv. Ìṣe 2:24-36: Pétérù fi ìgboyà fi idi òtítọ́ náà múlẹ̀ pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí àjíǹde Jésù (ẹsẹ 24), ni bí o ti ṣe ojú rẹ. O wa tẹsiwaju láti fi ìwé mímọ́ jẹri rẹ pé àjíǹde Jésù mú Orin Dáfídì 16:8-11 wa si ìmúṣẹ, ní ayérayé (ẹsẹ 25-36).Pọ́ọ̀lù tún gbà wọn níyànjú ni ọna yìí ni ìṣe. 13:33-39.

v. Irú ìgbàgbọ́ yìí nínú ikú àti àjíǹde Kristi jẹ ohun ti o ṣe pàtàkì julọ si ìgbàgbọ́ Kristẹni lónìí (I Kor. 15:14,17-19).

vi. Àjíǹde Kristi ni o rọ́pò ẹ̀gàn ikú Rẹ, O mọ pé Ọlọ́run ko ni fi Òun silẹ sínú ibojì. Àwọn onigbagbọ náà ni lati mọ pé Ọlọ́run ko nii fi wa silẹ pẹ̀lú àwọn ìjàkadì wa. Didakẹ Rẹ kii ṣe aisi nibẹ Rẹ; àṣìṣẹ Rẹ kii ṣe aibikita.

B. A JI I DIDE PẸ̀LÚ ÀWỌN ẸRI (Jhn. 20:1-31)

Nígbà náà ni O wí fún Tọ́másì pé, “mú ìkà rẹ wà nihin, kí o sì wo ọwọ Mi, sì mú ọwọ rẹ wà nihin, kí o sì fi ìhà Mi, kí ìwọ kì o ma ṣe alaigbagbọ mọ, ṣùgbọ́n jẹ onigbagbọ” (ẹsẹ 27).

i. Jhn. 20:1-10: Bi o ba jẹ pé Jésù kú lai jinde, Sátánì ibà tí jẹ àṣẹgun, gbogbo wa yóò sì wa yóò sì wà nínú ẹṣẹ wa báyìí (Rom. 1:4; I Kor. 15:16,17). Lojuna àti ṣẹgun Sátánì kí O sì dawalare, Jesu ni láti jinde kúrò nínú òkú (Mat. 28:1-10).

ii. Ẹsẹ 1-8: Luku jẹri lábẹ́ imisi pé Jésù fi ara Rẹ hàn láàyè lẹyin ìjìyà Rẹ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹri ti o dájú (Ìṣe. 1:3). Òkúta náà tí a yí kúrò àti ibojì tí o ṣòfò náà (wo. Mat. 28:6a; Mk. 16:4; Luk. 24:2,3) tún wà lára àwọn ẹri wọ̀nyii.

iii. Ẹsẹ 11-18: O farahàn fún Màríà Magdalene àti àwọn obìnrin kan (wo Matt. 28:9,10).

iv. Ẹsẹ 19-23: Jòhánù, bi o ti jẹ ajẹri tún fìdí rẹ múlẹ̀ pé O farahàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀, O si rán wọn nisẹ, ṣùgbọ́n Tọ́másì ko si nibẹ.

v. Ẹsẹ 24:29: Ó tún padà fi ara hàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ pẹ̀lú Tọ́másì nibẹ ni akoko náà. Àwọn ọgbẹ tí o wa lara Rẹ jẹ ẹri ti o dájú (Jhn. 20:27).

vi. Pọ́ọ̀lù sàkọsílẹ̀ àwọn ìfarahàn Jésù, pẹlu ìfarahàn Rẹ si Pọ́ọ̀lù ni ọna Damásíkù, èyí tí o jẹ ẹri àjíǹde Jésù (I Kor. 15:5-8).

vii. Ẹsẹ 27-31: Kínní ìwọ yóò ṣe pẹ̀lú àwọn ẹri ti ko ṣe yípadà (dájú) nípa àjíǹde Jésù yìí? Mase jẹ Tọ́másì, gba Jésù gbọ lai ri I (Rom. 10:9,10; 2 Kor. 5:7). Nítorí náà, lọ kí o si wàásù Kristi ti o jinde náà nìkan (Matt. 28:18 síwájú)!

viii. Ṣíṣe ìtànkalẹ ihinrere àjíǹde Jésù àti ipadabọ Rẹ lẹẹkeji ni ọna kanṣoṣo tí a lè gbà ṣe ìtànkalẹ ẹsin Kristẹni tí yóò sì tẹsiwaju láti ni ipa ńlá kankiri gbogbo ayé. Ní pàtàkì julọ, a n mú Iwe mimọ ṣẹ ní ọ̀nà dídára (Mat. 28:18 síwájú; Mak. 16:15 síwájú) bí a ti n ṣe èyí (bẹẹ).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1. Bí Ọlọ́run ko ba kọ Jésù silẹ nínú ibojì, Ó dájú pé kò nii kọ ọ silẹ nínú ipokipo, niwọn bí o ba ti wa lábẹ́ òjìji Rẹ.

2. Bíbélì kún fún àwọn ẹri àjíǹde Jésù.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE

Ọlọ́run pa ara Olúwa wa mọ kúrò lọ́wọ́ idibajẹ nígbà tí O wa ninu ibojì, O tún gbà ẹ̀mí Rẹ padà, gẹ́gẹ́ bi O ti ṣèlérí, ní òwúrọ̀ ọjọ àjíǹde. Jiroro.

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE

i. Agbára àtọ̀runwá náà pa ara Kristi mọ kúrò nínú idibajẹ, gẹgẹ bí o ti ji I dìde kúrò nínú òkú. Eyi mú Iwe mimọ ṣẹ pé àwọn egungun Rẹ ki yóò ṣẹ (Orin Daf. 34:20).

ii. Ọlọ́run ko faaye gba ara Kristi láti rí idibajẹ ni ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ (Orin Daf. 16:10).

iii. Ní ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ láti inú Májẹ̀mú Láéláé àti ẹnu Jésù Olúwa wa gan-an, O jinde kúrò nínú ipò òkú pẹ̀lú ẹyẹ. Ọlọ́run ko le seke (purọ) láéláé.

iv. Jésù Olúwa jinde kúrò nínú òkú, O si jáde kúrò nínú ibojì nípasẹ̀ agbára àtọ̀runwá tí ko ṣe e daduro. Èyí jẹ ẹri ti o dájú pé a ní láti gbé ènìyàn dìde nípasẹ̀ agbára àtọ̀runwá, kii ṣe kúrò nínú ibojì wọn nìkan bikose kuro ninu irú ipokipo tí o bá dára tó ti wọn ba wa.

v. Nínú Kristi ti o jinde náà, ààbò ayérayé wa; Iye ni o wa kí ìṣe ikú; aidibajẹ ni o wa níwájú wa, o si dájú pe a le ri wọn gba nígbàkúùgbà, “ni ìṣẹ́jú aaya”, ni ipadàbọ̀ Kristi.

Leave a Reply