ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun Ojo  October 27, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ 

By | October 26, 2019

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun Ojo  October 27, 2019. Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KEJI: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ 

Ẹ̀KỌ́ KẸJỌ:

ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ ÌGBÀ IKẸHIN TI WỌN TÍ WA SI ÌMÚṢẸ


Israẹli gba ominira ni ọdún 1948. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpẹẹrẹ ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ tí o ni ise pẹ̀lú Israẹli. Èyí jẹ ẹri pe àwọn itọkàsi Iwe mimọ tí o niise pẹlu Israẹli àti àwọn orílẹ̀-ede miiran yóò wa si ìmúṣẹ ni akoko ti Ọlọ́run.

AKỌSORI

Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Iran yii ki yóò rekọja títí gbogbo nnkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ

(Matiu 24:34).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ

Ọlọ́run jẹ́ olotitọ, O si dájú síbẹ̀. Ohunkóhun tí O ba sọ tàbí ṣe jẹ́ òtítọ́. Gbogbo ohun tí o ba jáde láti ẹnu Rẹ yóò wa si ìmúṣẹ dandan. Ko tii kùnà ri, ko si le kùnà. Ko dabi ènìyàn tí ko ṣe e gbẹkẹle tàbí tí o n ṣe ségesège. Agbeyẹwo tí o dájú nípa ayé wa isinsin yii àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àyíká n safihan ìfarahàn ìgbà ikẹhin. Pupọ nínú àwọn àpẹẹrẹ rẹ wa pẹ̀lú wa lai fara pamọ. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a ti sọ nípa àwọn ohun ti yoo sẹlẹ ni ọjọ iwájú, èyí tó n fún gbogbo ọmọ Ọlọ́run ni àmì láti múrasilẹ kí wọn si ṣetán fún ìṣẹ̀lẹ̀ ikẹhin náà (igbasoke).

Ko si ọkànkan nínú àwọn ohun tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ àti àwọn ohun tí a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ nínú ìwé mímọ́ nípasẹ̀ àwọn wolii àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù ti yoo lọ láìṣe. Ohun tí o ṣe pàtàkì julọ ni pé kí o ṣetán (múrasilẹ) fún ìgbà ikẹhin.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ

Mon. 21: Tẹmpili Naa: Ibi Ìjọsìn gbogbogboo Ti A n fojúsọ́nà Fún (Mik. 4:1)

Tue. 22: Àwọn Orílẹ̀-èdè Yoo Kọ Ọrọ Ọlọ́run (Mik. 4:6-7)

Wed. 23: A O Fi Agbára Fún Àwọn Tí O Wa Ni Ìgbèkùn (Mik. 4:6-7)

Thur. 24: A O Mu Àwọn Ọmọ Israẹli Bọsipo (Mik. 4:8,10b)

Fri. 25: A O Pa Àwọn Ọ̀tá Israẹli Run (Mik. 4:11-13)

Sat. 26: A O Tun Àwọn Ìlú Wọn Kọ (Mik. 7:11).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN

1. Nínú ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ jíjẹ Olumọ ohun gbogbo, àwọn nǹkan (ìṣẹ̀lẹ̀) ki i deede ṣẹlẹ̀; wọn máa n ṣẹlẹ̀ ni akoko pipe tiRẹ.

2. Ìmúṣẹ àwọn kan nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí o ní ìṣe pẹ̀lú ìgbà ikẹhin n pe àwọn ẹlẹ́ṣẹ si ìrònúpìwàdà, nígbà tí àwọn onigbagbọ gbọdọ máa tẹsiwaju láti máa dúróṣinṣin, nítorí ọrọ Ọlọ́run dúró (wa) titi láé.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: Mátíù 2:1-6; Esra 1:1 síwájú

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA

ILEPA: Láti kọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pe ohunkóhun tí o ba jáde láti ẹnu Ọlọ́run ko yipada bẹẹni ko le ni idaduro, èyí n tọkasi ìmúṣẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ikẹhin kan.

ÀWỌN ERONGBA: Ní ìparí ẹ̀kọ́ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò ti:

i. mọ pe a ti n ní ìrírí (rí) ìmúṣẹ díẹ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ikẹhin nínú ayé.

ii. maa múrasilẹ fún bibọ Jésù Kristi Olúwa wa nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ìkẹyìn n tọkasi dìde Rẹ.

iii. maa mú gbígbẹkẹle Ọlọ́run dàgbà nínú ọkàn wọn, níwọ̀n bi o ti jẹ pe lotitọ Ọlọ́run nìkan ni O le fun wa ni ìrètí ọjọ ọ̀la.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́
: Isaiah 2:2-4; 44:24, 27,28; 45:1; Dáníẹ́lì 2:28-40; 7:4:8, 23-26; 8:19-27; Luku 21:24.

A dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run fún ẹ̀kọ́ tí o kọjá èyí tí o jẹ bi isiloju sì ìmúṣẹ Ìwé mímọ́ nípa àjíǹde àti ìgòkè re ọrùn Kristi. O n safihan pe àjíǹde Jésù jẹ igbesẹ Ọlọ́run ti o ṣètò fúnra Rẹ ni ìmúṣẹ ohun tí O sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn nínú ìwé mímọ́, bóyá àwọn ènìyàn gbagbọ tàbí wọn ko gbagbọ. Abájọ tí igbiyanju ènìyàn láti tẹ ori rẹ ba kùnà pátápátá. Ọrọ Ọlọ́run jẹ Bẹẹni àti Àmín, gẹgẹ bí o ti jẹ pe ìmúṣẹ àjíǹde Rẹ ni o fún ìgbàgbọ́ wa ni ìgbẹ́kẹ̀lé ayérayé (àtọ̀runwá), bákan náà ni o jẹ ẹri ibujade Ẹ̀mí-Mímọ́ àti ìrètí ipadabọ Rẹ lẹẹkeji, gẹgẹ bí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ ṣáájú nínú Ìwé Mímọ́.

Ẹkọ kẹjọ niyii tí o jẹ èyí tí o kẹ́yìn nínú ìsọri kejì láti fún wa ní ìdánilójú sii pe gbogbo ọrọ ti o ba jáde láti ẹnu Ọlọ́run GBỌ́DỌ̀ wa si ìmúṣẹ dandan.

Ẹkọ náà yóò tún kọju àfojúsùn wa si àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà ikẹhin tí o níìṣe pẹlu Israẹli àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Ọrọ Ọlọ́run kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí O ti fojúsọ́nà fún pe yoo sẹlẹ si àti ní orílẹ̀ èdè Israẹli àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn. O han gbangba pe O n ṣe àwọn ohun ìyanu, isododo Rẹ si n mú àwọn ohun tí O sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ wáyé.

Ṣáájú nínú ọwọ yìí, a ti wo díẹ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà ìkẹyìn yìí nínú ìwé Mímọ́. Akoko lati wo ìmúṣẹ rẹ ni yìí isododo Ọlọ́run gbà pé ohunkóhun tí O bá sọ gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí o ma ń ruwa sókè nínú ẹ̀kọ́ tí a fẹ jíròrò nípa rẹ, ní ọ̀sẹ̀ méjì tó wà níiwájú wa yìí. A gbàdúrà pé a o di ẹni ìbùkún bi a ti n kẹ́kọ̀ọ́ ní ẹsẹ Olúwa ni Orúkọ Jésù. Àmín.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN:

A pín ẹ̀kọ́ yìí sí ìpín méjì I àti II, a sì ṣe atunpin ìpín kọ̀ọ̀kan sì A àti B lọ́kàn-ó-jọkan.

ÌPÍN KÍNNÍ: NÍPA ISRAẸLI

Ipin yìí n safihan ìmúṣẹ májẹ̀mú Ọlọ́run lórí bí O ti tún ṣe àkójọpọ àwọn ènìyàn Rẹ, Israẹli. Ọlọ́run nínú agbára ńlá Rẹ, mú gbogbo àwọn olóòótọ́ yoku wálé láti ibi gbogbo tí wọ́n fọn kaakiri si, ìyẹn ni orígun mẹrẹẹrin ayé. Àwọn Júù tí wa n padà lọ si ilu wọn gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run. Ọlọ́run ti kede Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bi ìlú ayérayé fún ati àwọn Júù àti àwọn tí kii ṣe Júù. Èyí n wa si ìmúṣẹ báyìí, ní bí a ti tọ́ka sí Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí Olu-Ilu-Israẹli.

ÌPÍN KEJI: NÍPA ÀWỌN ORÍLẸ̀ ÈDÈ MÌÍRÀN

Ìpín yìí n safihan bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà-ìkẹyìn kan ṣe wa si ìmúṣẹ lórí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn. Ìmúṣẹ ìran Nebukadinésárì, èyí tí a fi ìtumọ̀ rẹ hàn Dáníẹ́lì nípa ìjọba Bábílónì àti àwọn ìjọba mìíràn, àti aṣòdì-sì-Kristi jẹ òtítọ́; a si n ni iriri rẹ lónìí.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I. NÍPA ISRAẸLI
A. MÁJẸ̀MÚ ỌLỌ́RUN TÚN KO ISRAẸLI JỌ PADÀ
B. IBI ÌPÉJỌPỌ ỌLỌ́RUN FÚN GBOGBO ORÍLẸ̀-EDE

II. NÍPA ÀWỌN ORÍLẸ̀ ÈDÈ MÍRÀN
A. ÀWỌN KÈFÈRÍ NÍNÚ ÀSỌTẸ́LẸ̀ MÁJẸ̀MÚ LÁÉLÁÉ
B. ÀWỌN ÌGBÀ (ÀKÓKÒ) ÀWỌN KÈFÈRÍ

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́

I. NÍPA ISRAẸLI (Isaiah 2:2-4; 44:24,27,28; 45:1)

Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí a ti sọ, o wa si ìmúṣẹ pe Kírúsì mú Bábílónì mọ àwọn Ìlú tí o ṣegun ni Osu kẹwàá, 539 ṣáájú ibi Kristi (October 12,539 BC) Àṣẹ méjì ni o tètè tẹle e tí o n pàṣẹ fún àwọn Júù tí o wa ni ìgbèkùn láti padà kí wọn si ṣe atunkọ tẹmpili wọn ní Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run ni Israẹli nínú àfojúsùn Rẹ idi si ni yìí tí O fi ní Ìwé Mímọ́ tí o gbọdọ wa si ìmúṣẹ nípa wọn.

A. MAJẸMU ỌLỌ́RUN TÚN KO ISRAẸLI JỌ PADÀ (44:24,27,28; 45:1)

Ti O wi ni ti Kírúsì pe, Olùṣọ́ àgùntàn Mi ni, yóò sì mú gbogbo ìfẹ́ mi ṣẹ, ti O wi ni ti Jerúsálẹ́mù pé, A o kọ ọ, àti ní ti tẹmpili pé, a o fi ipilẹ rẹ sọlẹ (44:28)

i. YAHWE kan náà tí o n sọ òpin láti ibere nítorí tí o jẹ Olumọ ohun gbogbo (Isa. 46:10), tí ṣèlérí láti mú àwọn tí o ku (yókù) nitòótọ́ padà wa, àwọn díẹ̀ tí wọn sì jẹ olóòótọ́ (wo 10:20), láti di “irú ọmọ” náà fún ìjọba tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ di mímọ́ tí o bọ náà (Isa. 6:11-13; 11:11,12).

ii. Bí Ọlọ́run ti ṣèlérí láti ko wọn jọ láti origun mẹrẹẹrin ayé, àwọn Júù tí o wa ni gbogbo orílẹ̀ èdè ayé n padà si ilu (ilé) wọn (Jer. 16:14-16).

iii. 44:24,27, 28: Ni nnkan bi ìgbà ọdún ṣáájú ibi Kírúsì, Ọlọ́run ti dárúkọ rẹ ni pàtó gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò ṣegun tí yóò sì tú àwọn ènìyàn Ọlọ́run silẹ kúrò nínú ìgbèkùn.

iv. Ní ìmúṣẹ, Herodorus òpìtàn Gíríìkì ni, sọ pé àwọn ọmọ ogún Kírúsì yí ojú odò Ufrete (Euphrates) padà, èyí to n san gba ìlú Bábílónì, èyí sì fi àyè gba àwọn ẹgbẹ́ ogún rẹ láti gba ìlú náà, kí wọn sì tu àwọn ẹni ìgbèkùn Júù ni Bábílónì silẹ, o faaye gba wọn láti padà àti láti tun Jerúsálẹ́mù kọ (wo Isa. 45:1).

v. Ọlọ́run mú eyi wáyé ní 539 ṣáájú ìbi Kristi. Nígbà tí a ṣẹ́gun Bábílónì pátápátá (wo Isa. 13:19) tí o sì di ilẹ omi ira (wo Isa. 14:23), àwọn Júù si mori bọ nínú ìjọba Bábílónì láti padà sí ilé (wo Jer. 32:36-37).

vi. Pipọ sii ni iye àwọn ọmọ Júù láti ọ̀kẹ mẹẹdọ́gbọ́n (500,00) ni ọdun 1948, ni akoko ti wọn gba ominira si milionu mẹjọ o le lónìí, jẹ ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Rẹ (wo Mat. 24:31). Ìwé Mímọ́ sàsọtẹ́lẹ̀ pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù yóò padà wá sí ilẹ wọn (Deut. 30:3; Isa. 43:6; Esik. 34:11-13; 36:24; 37:1-14; 39:28). O tún jẹ́ mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láti sọ wọn di imọlẹ fún ayé ni ṣíṣẹ-ńtẹle (Isa. 42:6).

vii. Nibo ni ìwọ yóò wa nígbà tí àwọn onigbagbọ tí wọn jẹ olotitọ bá parapọ̀ sì ọdọ Kristi ni àwọsánmà?

B. IBI ÌPÉJỌPỌ ỌLỌ́RUN FÚN GBOGBO ORÍLẸ̀-EDE (2:24)

Yóò sì ṣe ní ọjọ́ ìkẹyìn, a o fi òkè ilé Olúwa kalẹ lórí àwọn òkè ńlá, a o si gbe e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ, gbogbo orílẹ̀ èdè ni yóò sì wọ̀ sí inú rẹ (Isa. 2:2).

i. Ẹsẹ 2… Yóò sì ṣe… túmọ̀ sí pé “yóò ṣẹlẹ̀” A ṣàpèjúwe Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bi òkè ilé Olúwa, níbi tí Ọlọ́run yóò ti fi tìtobi ìwàláàyè Rẹ hàn fún àwọn ènìyàn Rẹ, nítorí náà, o jẹ ibi tí o ṣe pàtàkì julọ láyé (wo Mik. 4:1-4; Sek. 8:3).

ii. Ẹsẹ 3,4: Àwọn ènìyàn láti gbogbo orílẹ̀ èdè yóò wà sì ibẹ láti gba isejọba pípé Ọlọ́run, àti fún ìtọ́ni. ‘Wọn n wọ’ lọ sí Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí odo ńlá, kí Ọlọ́run ba le kọ wọn ní ọ̀nà Rẹ’

iii. Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bi Olu-ilu tí ìta fún àwọn ará Júù àti fún àwọn tí kii ṣe Júù bákan náà. Ilé àdúrà fún gbogbo ènìyàn, ìbi ìpéjọpọ àti gẹ́gẹ́ bí Olú-ìlú Israẹli (Sek. 12:2; 14:6). Ọpọ tí rí wíwà Donald Trump, aare orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lọ́wọ́lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà. A rí èyí nínú bí àwọn ìlànà òfin rẹ tí n ṣe anfaani fún Jerúsálẹ́mù, jù bí a ti lérò lọ. Fún àpẹẹrẹ, o ti gbé olú ìlú. Israẹli lọ sí Jerúsálẹ́mù, Ó sì lọ ṣe ibẹwo sì odi ìgbàlódé ni laipẹ. Èyí n tọ́kasi bibọ Jésù Kristi Olúwa wa.

iv. Bákan náà, irin ajo ìgbà gbogbo lọ sí Jerúsálẹ́mù ní gbogbo agbaye jẹ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà (Sek. 14:16). Ọgọọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn lo n lọ síbẹ̀ láti sin Ọlọ́run —- gbígbàdúrà ni ibi odi ìpohùnréré ẹkùn náà àti àwọn ojuko ìtàn tí Jésù ti ṣíṣẹ ni ayé yìí.

v. Ibo tí o waye ni orílẹ̀ èdè UN (United Nation) ni ti Jerúsálẹ́mù laipẹ yìí jẹ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà (Sek. 12:2), O n fi àmì ìgbà ikẹhin hàn.

vi. Gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò parapọ̀ sì ibi kan ni ọjọ kan (Jerúsálẹ́mù) níwájú Olúwa, báwo ni o ṣe n múrasilẹ tó?

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1. Bíó-tilẹ̀-jẹ pe àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀ tí Ó sì fìyà jẹ wọn, àwọn ìlérí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Rẹ wa si ìmúṣẹ, pàápàá julọ bí wọn tí jẹmọ́ àwọn ìgbà ikẹhin.

2. Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ènìyàn Rẹ kii yẹ. Isododo Rẹ n fún wa ní ìrètí fún ọjọ́ iwájú. Nínú igbagbọ (ìgbẹ́kẹ̀lé) nínú Rẹ nìkan ni kọ́kọ́rọ́ náà.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan tó n ṣẹlẹ̀ ni ayé loni sì àwọn Júù àti àwọn orílẹ̀ èdè ayé mìíràn tí di sísọtẹ́lẹ̀ nínú ìwé mímọ́. Ṣàlàyé.

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE

Àkọsílẹ̀ (ìtọ́kasi) diẹ nípa àwọn ohun to n ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé, èyí tí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn tẹlẹ: Iyán, ogún àti ìró ogún, èké Kristi, àwọn wòlíì àti olùkọ́ni, orílẹ̀-èdè n dìde sí orílẹ̀ èdè, ẹ̀tan, àìsàn àti ajakalẹ àrùn: kogboogun (HIV), jẹjẹrẹ abbl.

Gbigbogunti àwọn Kristẹni, idide ijọba alágbára ayé (agbaye), dìdi pupọ sii ni imọ, Ìfẹ́ n di tútù sii, abbl. Gbogbo èyí ni a ṣètò fún nínú Ìwé Mímọ́.

Bẹẹni, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ohun wọ̀nyí ni a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ nínú Ìwé Mímọ́ síbẹ̀, èyí n tọ́kasi àwọn ohun wọ̀nyí.

Ayé yìí jẹ ti Ọlọrun; O da ayé àti ohun gbogbo tí o wa ninu rẹ.

Ọlọ́run ni alakoso (Olusakoso) lórí gbogbo orílẹ̀-èdè (Orin Daf. 22:28).

Ko si ohun to le ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ọlọ́run àti láìsí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Rẹ.

Ìwé mímọ́ jẹ́ Ọrọ Ọlọ́run, èyí tí o wúlò tí o sì jẹ òtítọ́ titi láé.

Gbogbo ohun tí ìwé mímọ́ tí sọ ní yóò wà sì ìmúṣẹ, àwọn kan ti wa si ìmúṣẹ, àwọn ti ko si tii wá sí ìmúṣẹ yóò wa si ìmúṣẹ laipẹ.

Nípasẹ̀ ìwé mímọ́ ni a da ayé, àti nípasẹ̀ rẹ, ayé àti ohun gbogbo tí o wa ninu rẹ yóò dópin (2 Pet. 3:1-10).

Ọlọ́run ni onidajọ ayé (agbaye) tí kii ṣe ojúsàájú (2 Pet. 3:9,10).

Leave a Reply