ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ní Àgbáyé. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun December 1, 2019. Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KẸTA: A O MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ 

By | November 30, 2019

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ní Àgbáyé. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Fun December 1, 2019. Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ. ÌSỌRI KẸTA: A O MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ 

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ní Àgbáyé.

Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.

Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.

ÌSỌRI KẸTA: A O MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ

Ọjọ: December 1, 2019.

II. OLÚWA ONIFẸ YÓÒ GBÀ A LA (Sek. 12:2,3,9,14:1-4,16).

Láti gba ènìyàn la jẹ láti safihan ìfẹ́ nípa aifaaye gba ẹni bẹẹ láti parun. Ọlọ́run fẹ́ràn Israẹli. Nítorí náà, ohunkóhun tí O ba faaye gba láti ṣẹlẹ̀ si wọn jẹ nítorí ìfẹ́ Rẹ̀. Ọlọ́run yóò mú ẹṣẹ jinna si wọn. Laiwo tí ipo wọn isinsin yii, àwọn kan yóò ṣẹku.

A. A FI AGBÁRA ATỌRUNWA DABOBO O KÚRÒ LỌWỌ ÀKỌLU (12:1-9)

Ni ọjọ naa ni Èmi o sọ Jerúsálẹ́mù di ẹrù òkúta fún gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn tí o ba si fi dẹru pa ara wọn ní a o ke si wẹ́wẹ́, bí gbogbo àwọn orílẹ̀-ede ayé tilẹ ko ara wọn jọ sii (ẹsẹ 3).

i. Ẹsẹ 1: Ọlọ́run Olumọ ohun gbogbo tí a ko le bí ní ìbéèrè ni o n sọ (ṣàgbéyẹ̀wò) niti ọjọ́ iwájú yìí, ní ti ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn Rẹ aláìgbọràn, ko si ẹnikankan nínú wa ti ó pamọ kúrò lójú Rẹ (Orin Daf. 139:7).

ii. Ẹsẹ 3,4: Àwọn ọrọ ẹsẹ wọ̀nyí, gbogbo àwọn tí o ba yìí ka… bi gbogbo orílẹ̀-ede ayé tilẹ̀ ko ara wọn jọ sii, túmọ̀ sí pé a o fi ààyè gba àwọn orílẹ̀-ede láti ọrun wa lati kórajọpọ lodi sì Jerúsálẹ́mù.

iii. Ẹsẹ 2: ago imọtiyo… A fi àwòrán Jerúsálẹ́mù hàn gẹ́gẹ́ bi adágún omi (agbada nla) nínú èyí tí gbogbo orílẹ̀-ede yóò mú nínú rẹ pẹlu ìyára, wọn yóò si wa rii pé wọn tí mọti yo, wọn ko mọ ohun tí wọn n ṣe mọ, nítorí náà, wọn yóò di ìjẹ tí o rọrùn fún Ìdájọ́ atọrunwa ni ìkẹyìn, nígbà tí àwọn orílẹ̀-ede ba kórajọpọ láti kọlu Jerúsálẹ́mù (wo ẹsẹ 9; Esik. 38:1-6,14-16; Dan. 11:40-44; Ifih. 9:13-16; 14:20; 16:12-16).

iv. Ọlọ́run Alágbára yóò pa Jerúsálẹ́mù mọ. Àwọn orílẹ̀-ede keferi tí o ba n ṣe lodi sì Jerúsálẹ́mù yóò wa máa ba Ọlọ́run ja. Àwọn orílẹ̀-ede keferi yóò bẹru Jerúsálẹ́mù nítorí wọn yóò wa lati ko Ọlọ́run lójúkoju, wọn yóò sì bẹru Ọlọ́run Jerúsálẹ́mù.

v. Ẹsẹ 3: Gẹ́gẹ́ bii gbigbe ẹrú tí o wúwo, Jerúsálẹ́mù yóò ṣe ìpalára (lerefee) àwọn ènìyàn yowu tí wọn ba n gbìyànjú láti ṣẹgun rẹ, A o ge/ke wọn sì wẹ́ẹ́wẹ́ẹ́.

vi. Ẹsẹ 4-9: Èyí jẹ bẹẹ nítorí idàsì atọrunwa wa. Ọlọ́run ṣèlérí pe: Èmi Ó wa lati pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí o wa kojuja sì Jerúsálẹ́mù, ohun tí yóò sì ṣe ni yìí. Awọn ọmọ ogun keferi, tí o ba koju ija sì àwọn ènìyàn Ọlọ́run àti Jerúsálẹ́mù ní pàtó, tí wọn n kórajọpọ láti pa a run, ní Ọlọ́run yoO pa run. Yóò hàn pé gbogbo ayé n ṣe lòdì (Kọju ìjà) si wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Ọlọ́run ni yóò ṣẹgun. Ọlọ́run máa n gba ija wọn ja tako ẹni tí o ba n dojú ìjà kọ wọn.

vii. Jésù yóò ja ogun wọn, yóò sì ṣẹgun aṣòdìsi Kristi ọta Ọlọ́run àti àwọn Júù (Esik. 38:22; Ifi. 19:17). Wọn yóò sọkún, wọn yóò sì sọfọ nínú ìrònúpìwàdà, ní kété tí wọn ba ti mọ pe ẹni tí a kàn mọ àgbélébùú ni Mèsáyà wọn, ẹni tí wọn tí n dúró de (Sek. 10:9-14).

B. A GBÀ A LA NÍPA IDÀSÌ MÈSÁYÀ RẸ (14:1-21)

Nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ, yóò sì ba àwọn orílẹ̀-ede wọnnì ja, gẹgẹ bi I tí ja ni ọjọ ogun (ẹsẹ 3).

i. Ẹsẹ 1: Ọjọ́ Olúwa jẹ akanlo ede fún ìbínú Ọlọ́run ti yoo wa sórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ. O n sọ̀rọ̀ nípa Ọjọ ti ìbínú Rẹ yóò wáyé, tí yóò wá yọrí sí igbekalẹ ìjọba ẹgbẹrun ọdún Olúwa ni ayé (wo Isa. 2:12). Àwọn iwa búburú tí a mẹ́nuba (tọkasi) níbi yìí ni àwọn ohun to fa ìbínú Ọlọ́run sórí ayé ni Ọjọ Olúwa.

ii. Ẹsẹ 2: Ọlọ́run fúnraRẹ yóò ko àwọn orílẹ̀-ede jọ, yóò lo wọn láti ṣe afọmọ, ṣàtúnṣe àti ṣèdájọ́ (wo Ifih. 16:13-14,16). Ìwàláàyè (ìfarahàn) wọn yọrísí àkókò ìyọnu (wàhálà) orílẹ̀-ede tí ko ṣẹlẹ̀ri. Èyí ni akoko wàhálà fún Jákọ́bù (Jer. 30:5-7).

iii. Ẹsẹ 3,4: Láti dènà imukuro àwọn yoku tó jẹ́ tiRẹ, Olúwa yóò fúnraRẹ dasi i láti dojú ìjà kọ àwọn orílẹ̀-ede tí wọn kórajọ. Gẹ́gẹ́ bí O ti ja fún àwọn ènìyàn Rẹ ni ìgbàanì, bẹẹni Yo Ó ṣe ní ọjọ iwájú, gẹgẹ bi Ọba-Ajagun ayérayé. Jésù yóò padà wá si Òkè Olifi tí o wa ni ìhà ila oòrùn ti o wa ni pẹtẹ́lẹ̀ Kídírónì (wo Ìṣe 1:11).

iv. Ni Ọjọ́ Kẹfà, Oṣù Kejila ọdun 2017, Donald Trump tí o jẹ Ààrẹ orílẹ̀-ede Amerika (U.S.A) ṣe idamọ Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí Olú ìlú Israẹli gẹ́gẹ́ bí o ti yẹ kí ó ri, o si sọ pe ilé-ìṣẹ́ tí n yẹ ìwé irinna lọ si òkèèrè wo tí orílẹ̀-ede Amerika yóò di gbígbé kúrò ní Tel. Avivi lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ìwọ ko ha rí èyí gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Mèsáyà náà bi?

v. Ẹsẹ 5-15: Mèsáyà náà yóò padawa pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ Rẹ láti fọ orí esu, de e, àti láti jọba pẹ̀lú àwọn mimọ fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn alaiwa-bi-Ọlọ́run yóò kábámọ.

vi. Ẹsẹ 16-21: Igbẹyin tí o lere yóò wa ninu awọn idajọ Ọlọ́run nítorí nípasẹ̀ wọn ní àwọn orílẹ̀-ede yóò kọ isododo níkẹyìn, eso rẹ yóò sì jẹ “ìjọsìn gbogbo agbaye fún Olùṣàkóso gbogbo Àgbáyé náà”, Jèhófà àwọn ọmọ Ogun, àti nípa ẹni to jẹ Mèsáyà náà lábẹ́ akoso ẹni tí gbogbo orílẹ̀ èdè yóò di ẹni ìbùkún.

vii. Lẹ́yìn-ó-rẹyìn, Ọlọ́run yóò mú eto Rẹ láti mú Israẹli àti àwọn ayanfẹ padà sínú ijọba Rẹ ṣẹ (Jhn. 6:45; Rom. 11:25). Àwọn tí a pe ni Israẹli gan-an ko ni jẹ àwọn tí Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bi ènìyàn pàtàkì mọ. Dípò bẹẹ, ẹnikẹ́ni tí o ba wa si ọdọ Jésù Kristi ni yóò gbà ipo pàtàkì náà (Rom. 9:6-8; 10:13; Filp. 3:3).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1. Ko si ẹni ti o le dojú ìjà kọ ayanfẹ Ọlọ́run ti máa n wa pẹ̀lú wọn bí alágbára.

2. Jésù n padà bọ gẹ́gẹ́ bi Kìnnìún Júdà, láti ṣèdájọ́ ayé (àwọn Júù àti Kèfèrí). Njẹ o ṣetán láti koju Rẹ? Ronupiwada ki ó sì tẹwọgbà A, báyìí.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1. Kin ni ìdí tí a fi gbogunti Jerúsálẹ́mù, kín sì ni àbájáde igbogunti náà?

2. Ṣàlàyé idàsì Mèsáyà náà sì ipò Israẹli ni ikẹyin.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ

Jerúsálẹ́mù ni Olú ìlú (ìlú-ńlá) tí o wa ni Israẹli àkókò yìí (ìgbàlódé) ti ọpọ si gba pe ọkàn lára àwọn ibi mimọ julọ lagbaye ni i ṣe.

A o gbógun ti i. ìyẹn ni pe, àwọn ọmọ ogun ọta yóò korajọpọ yìí ka láti ṣe àkọlu si i.

Ni ibamu pẹ̀lú ìwé Mímọ́, àwọn ọmọ ogún ńlá náà yóò korajọpọ tako orílẹ̀ èdè Israẹli láti pa a run.

Igbogunti/ido-ti yìí yóò mú wọn gbọ́n, yóò sì mú wọn gba Mèsáyà tí wọn tí fìgbà kan kọsilẹ.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJI

Ọrọ Israẹli ko sú Ọlọ́run. Ìfẹ́ àti àánú Rẹ wa títí lórí àwọn ènìyàn Rẹ. O jẹ onisuuru àti ónípamọ́ra, Òun kò nii kọ wọn silẹ tàbí pa wọn tí si ọwọ àwọn ọ̀tá wọn

Fún àwọn ìdí yìí, lẹ́yìn tí a ba ti gba àwọn ẹni mimọ sókè, Mèsáyà náà yóò wa lati Ọ̀run, láti ja fún Israẹli láti gba itusilẹ.

A o ko àwọn ọmọ Israẹli jọ, a o si mú wọn bọsipo padà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè.

Àwọn orílẹ̀ èdè ọ̀tá yóò gbà idajọ á àwọn iwa búburú wọn lòdì sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI:

Ọlọ́run kò tii dẹkùn láti máa ṣe àwọn ohun tuntun lojoojumọ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Rẹ nípa Israẹli. Àwọn ohun tuntun wa ninu ìròyìn agbaye nípa orílẹ̀ èdè Israẹli. Laipẹ yìí, Iroyin gbe e ijọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà (US) ti tọ́ka Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bi Olú-ìlú Israẹli. Ilé ìṣẹ́ to n ṣètò ìwé irinna ni a ti gbé lọ sí Jerúsálẹ́mù. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro ni Israẹli yóò dojúkọ ni ọjọ iwájú láti mú kí o ṣe idamọ kí o si tẹwọgbà jíjẹ Olúwa Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bi Mèsáyà náà nígbà tí O ba farahàn (wa) nígbà kejì. Nítorí náà, Ọlọ́run n mú wọn la àwọn ìnira wọ̀nyii kọjá fún ìmúṣẹ Ìwé mímọ́. A gbọ́dọ̀ rí gbogbo èyí kì a sì gbọn, nítorí òpin tí sunmọ etile tán.

IGUNLẸ:

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìparí ẹ̀kọ́ kẹwàá. Ko si orílẹ̀ èdè ayé kankan lónìí si gba a lọ́wọ́ ìpalára ìpọ́njú rẹ. Ìwé Mímọ́ gbọ́dọ̀ wa si ìmúṣẹ. Orílẹ̀ èdè Israẹli wa ninu eto Ọlọ́run fún ìgbà ìkẹyìn. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ gbọn, kí a sì múra silẹ, kí ìgbà-ìkẹyìn ma ba de ba wa lójijì.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KEJI

Mon. Nov. 25: Àdéhùn Aṣòdìsi Kristi Náà Pẹ̀lú Israẹli (Dan. 9:27).

Tue. Nov. 26: Àwọn Tí O Mọ Ọlọ́run Yóò Moribọ (Dan. 11:29-34)

Wed. Nov. 27: Aṣòdìsi Kristi Náà Yóò Ṣe Inúnibíni Si Israẹli (Dan. 12:1)

Thur. Nov. 28: A O Gbogunti Israẹli (Esik. 38:1-17)

Fri. Nov. 29: Israẹli Yóò Mọ Mèsáyà Rẹ Níkẹyìn (Sek 12:10)

Sat. Nov. 30: Israẹli Yóò Dì Atunbi, A O Si Mú Un Bọsipo (Rom. 11:26).

Leave a Reply