ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ni Àgbáyé  Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN Ọjọ November 3, 2019.  Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.  ÌSỌRI KEJI: A MÚ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.

By | November 2, 2019

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ni Àgbáyé  Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN Ọjọ November 3, 2019.  Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.  ÌSỌRI KEJI: A MÚ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.

EKA AWON EKO TI ATEYINWA NIBI YI

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ni Àgbáyé

Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI

Ki Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.

ÌSỌRI KEJI: A MÚ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.

Ọjọ November 3, 2019.

II.    NÍPA ÀWỌN ORÍLẸ̀ ÈDÈ MÌÍRÀN (Dáníẹ́lì 2:28-40; 7:4-8, 23-26:19-27; Luku 21:24).

Ala àti ìran méjì nínú ìwé Dáníẹ́lì 2,7,ati 8 n sọ ọrọ Pataki kan náà. Gbogbo rẹ, ni o n ṣàpèjúwe ijọba alágbára ńlá ti ayé mẹ́rin laarin ṣeńtúrì kẹfà ṣáájú ibi Kristi àti ìpẹ̀kun ìtàn ayé nígbà tí Jésù Kristi ba de tí a sì ṣe àgbékalẹ ìjọba ayérayé Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run ni ẹ̀dùn ọkàn pupọ fún gbogbo orílẹ̀ èdè, O fẹ ki wọn tẹríbá fún jíjẹ Olúwa Òun àti títóbi àti gíga ọrọ Rẹ ti ko lópin.

A.   ÀWỌN KÈFÈRÍ NÍNÚ ÀSỌTẸ́LẸ̀ MÁJẸ̀MÚ LÁÉLÁÉ (Dan. 2:28-40; 7:4-8, 23-26; 8:19-27)

Ìwọ Ọba n wo, sì kíyèsí ère ńlá kan! Ère gíga yìí tí dídán rẹ pọ̀ gidigidi, o dúró níwájú rẹ, ìrì rẹ si ba ni lẹru gidigidi (2:31)

i.    Ni Dan. 2, Nebukadinésárì ri ère ọkùnrin ńlá kan tí a fi orisirisi irin ṣe. A fi agbára fún Dáníẹ́lì latọrunwa láti le ṣàlàyé pé àlá náà dálórí ọjọ iwájú, àti ti ìkẹyìn ọjọ (2:28)

ii.  2:36-40: Ori wúrà náà dúró fún ìjọba Bábílónì (Kìnnìún tí o ní ìyẹ idi; 7:4) ti ẹlòmíràn yóò rọ́pò, tí àyà fàdákà dúró fún èyí tí yóò jẹ Mẹdo Pasiani (béárì tí o gbé ara rẹ sókè ní apakan; 7:5).

iii. Ijọba yóò padà gorí èyí (ìtàn irin) àwọn Gíríìkì tó wa lábẹ́ Alẹkisáńderu Ńlá (wo 8:1-8, 20-21) àmọ̀tẹ́kùn tí o ni ìyẹ bi ẹyẹ (7:6).

iv. Ẹsẹ irin ni o dúró fún ìjọba kẹrin (ẹranko tí o buruju, tí o lẹru, tí o sì lágbára gidigidi, o si ni èyí irin ńlá; 7:7), ṣùgbọ́n a ko fihan ni pàtó. Síbẹ̀, a mọ nínú ìmúṣẹ náà pé ìjọba Romu èyí tó padà pín sí méjì lẹyin-ó-rẹyìn, àwọn ìjọba ila oorun ati ìwọ oòrùn.

v. 7:24: Ìjọba tí ẹsẹ irin tí o dapọ mọ àmọ́ dúró fún ní a ti fihan ni àwọn ala àti ìran Dáníẹ́lì tí o kọjá tí o ń tọkasi gẹ́gẹ́ bi àpapọ̀ orílẹ̀ ede mẹwa tó tuka ti yoo dìde ni ilẹ̀ (agbegbe) ijọba Romu (ìjọba irin) (ẹsẹ 7-8).

vi. Eyi ni yóò jẹ ipilẹ fún irujade agbára tí Kèfèrí ńlá tí o kẹ́yìn, Aṣòdì si Kristi náà (7:8, 23-26; 8:19-27), èyí tí wiwa Kristi yóò parun pátápátá.

vii. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí wa ni àgbékalẹ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti safihan àwọn ìjọba náà ni ìwòye tí ènìyàn (ala Nebukadinésárì) gẹ́gẹ́ bí ohun tí o dara tí o si lógo, láti inú ìwòye tí Ọlọ́run (ìran Dáníẹ́lì) gẹ́gẹ́ bi gbigba ijọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko búburú alailaanu ni.

B.   ÀWỌN ÌGBÀ (ÀKÓKÒ) ÀWỌN KÈFÈRÍ (Luk. 21:24)

Wọn o sì ti ojú idà ṣubú, a o si di wọn ní ìgbèkùn lọ si orílẹ̀ èdè gbogbo. Jerúsálẹ́mù yóò sì di ìtẹ́mọ́lẹ̀ ni ẹsẹ àwọn Kèfèrí, títí àkókò àwọn Kèfèrí yóò fi kún (ẹsẹ 24).

i Luku 21: Safihan nínú Ọrọ Jésù wí pe awon keferi yóò tẹ (jẹgàba lórí) Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀ títí o fi mú àkókò àwọn keferi ṣẹ. Luku 21:24 (wo Mat. 24:15, 16; Mk. 13:14), safihan àwòrán igbogunti àti ìparun Romu lórí Jerúsálẹ́mù ni 70 lẹ́yìn ikú Kristi (70AD).

ii.  70 lẹ́yìn ikú Kristi (70AD) ṣe ìmúṣẹ òtítọ́ náà pe Jerúsálẹ́mù yóò ṣubú, a o si ko wọn ní ìgbèkùn. Nínú iṣẹlẹ tí o báni nínú jẹ́ náà lábẹ́ Títù ọba Romu, ikú àti ìkoni ńìgbèkùn wọ́pọ̀ èyí to mú kí àwọn Júù o fọnkáàkiri gbogbo ayé.

iii. Láti ìgbà náà títí di isinyii, ní ìlú náà si ti wa lábẹ́ ìṣàkóso keferi. Njẹ ìyẹn túmọ̀ sí ìgbà àwọn Kèfèrí tí yóò wa si ìmúṣẹ?

iv. Bí Israẹli tí ṣẹgun Jerúsálẹ́mù nínú ogún ọdun 1967, ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí gba pe ìgbà àwọn kèfèrí tí kọjá. Ṣùgbọ́n sì ìyàlẹ́nu wọn tí o ga julọ, ijọba Israẹli nípa tara (láyé) da ìṣàkóso òkè tẹmpili padà sí ọdọ àwọn Musulumi!

v.  Nígbà wo ni akoko àwọn keferi yóò wa si opin? (Ifi. 11:1-2) fún wa ní ìdáhùn náà. Yóò di ìgbà tí Jésù bá padà wá sí ayé, pa Aṣòdì sì Kristi rún, tí O sì fi idi ìjọba Rẹ múlẹ̀.

vi. Bákan náà, nípa tẹmi julọ, ìgbà àwọn keferi tún túmọ̀ sí pé ìgbà kan n bọ nínú ètò ìràpadà Ọlọ́run, nígbà tí àwọn keferi yóò jẹgàba, ìṣubú Jerúsálẹ́mù ní yóò sì tọkasi èyí daradara. Ihinrere tí de ọdọ àwọn keferi tí pẹ, wọn si n jẹgàba (pọ ju nínú) lórí ìjọ loni. Orílẹ̀ èdè mélòó ni àwọn Kristẹni tòótọ́ n dari loni (“kii se àwọn Kristẹni aforúkọ jẹ).

vii. Pe àwọn kèfèrí n jọba (ṣàkóso) báyìí, túmọ̀ si pe ìgbà kan wa ti Israẹli yóò tún ko ipa pàtàkì nínú ètò ìràpadà Ọlọ́run (wo Rom. 9-11).

viii.Titi di àkókò yìí, Jerúsálẹ́mù ní ibi tí ìjà (rogbodiyan) tí pọ julọ ninu ayé lónìí. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pe orílẹ̀ èdè Israẹli tí gba ominira rẹ báyìí. Àwọn asoju orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan lagbaye tí n ṣètò àdéhùn àlàáfíà tí yóò ṣàtúnṣe ìdarí (ìṣàkóso) òkè Tẹmpili náà. Gbogbo èyí ni o ń safihan òtítọ́ náà pe ìgbà àwọn kèfèrí tí fẹrẹ kọjá tán, dìde Olúwa wa lẹẹkeji ti n sunmọ ẹtilè!

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1.    Ọlọ́run ni àwọn kèfèrí nínú ètò ìràpadà ayérayé Rẹ, kódà bí O ti bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ pẹlu awọn ọmọ Israẹli. Òun ni Ọba gbogbo ayé, ki ìṣe Israẹli nìkan.

2.  Ìgbà àwọn kèfèrí fẹrẹ parí. Njẹ ó ṣetán láti pàdé Jésù Olúwa wa bí O bá dé?

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1.   Kin ni ìdí tí o fi ro pe o yẹ ki Ọlọ́run tún kó àwọn ọmọ Israẹli jọ kí o sì tún mú wọn bọsipo, bíó-tilẹ̀, jẹ pe wọn ṣàìgbọràn, wọn si jẹ́ ọlọrun lile? Ǹjẹ́ a yàtọ̀ lónìí?

2.  Báwo ni Ọlọ́run ṣe n ṣe (ni ibasepọ) pẹ̀lú ayé ni akoko àwọn kèfèrí yìí, nígbà wo ni akoko náà yóò wà sì òpin?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ:

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ

Ọlọ́run yóò tún àwọn ọmọ Israẹli ko/ṣa jọ, yóò sì tún mú wọn bọsipo bíó-tilẹ̀-jẹ pe wọn n ṣàìgbọràn, wọn si jẹ alaisootọ, nítorí májẹ̀mú Rẹ ti ko nii kùnà láéláé.

Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ pé a o mú Israẹli bọsipo sì ilẹ rẹ. Èyí gbọ́dọ̀ wá si ìmúṣẹ. Ko le tako ọrọ Rẹ.

Imubọsipo náà yóò jẹ tara àti tẹmi.

Imubọsipo náà kò dalori isododo, ìwà-mímọ tàbí títóbi Israẹli bikose lórí ìpinnu, iwa àti ìlérí Ọlọ́run.

A ko yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn aláìṣòdodo wọnyii lónìí, ṣùgbọ́n òdodo àti àánú Ọlọ́run n sọ̀rọ̀ fún wa lonii, O si n da wa ni de kúrò ní ibí tí ẹṣẹ, ayé àti Sátánì tí fi wa pamọ sì, àti ni ayérayé a o kórajọpọ sì ọdọ Rẹ. Síbẹ̀. Ìrònúpìwàdà wa jẹ koseemani /dandan.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJI

Òtítọ́ pé Ọlọ́run n ṣàkóso àwọn orílẹ̀ èdè ko ṣe e sẹ.

Ko tii takete ni igba kankan tàbí ní ìjọba kankan rí, lòdì sí ìwòye àwọn ènìyàn kan.

Jésù kan náà lànà, lónìí àti títí ayé. Ki I ṣe ojúsàájú. Ọlọ́run sì jẹ ọkan náà síbẹ̀ pẹ̀lú ayé isinsin yìí tí o jẹ ti àwọn kèfèrí.

Májẹ̀mú àti àwọn ìlérí Rẹ kii yípadà.

Àwọn ọrọ ọmọ Rẹ máa n ṣe Ìdájọ́ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ de òpin.

O ti rán ọmọ Rẹ kii ṣe láti dá ayé lẹbi bikose láti gba a là. Èyí n safihan ìfẹ́ pípé Rẹ.

Gbogbo ohun tí wa ninu Ọrọ Rẹ fún ayé yóò wà sì ìmúṣẹ. O faaye gbà àkókò àwọn kèfèrí, bóyá àwọn orílẹ̀ èdè àti ìjọba kan yóò padà wá sínú imọ Rẹ.

Laipẹ àkókò àwọn kèfèrí yóò kọjá lọ yóò sì faaye gbà ìjọba ayérayé Kristi. Njẹ ìwọ yóò jẹ ọkan lára ìjọba náà bi?

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :

Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ́ pé kò sí ohunkóhun tí o le da ibi, inúnibíni, kan mọ àgbélébùú, ikú àjíǹde àti ìgòkè re Ọrùn Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi dúró, ko si ọkànkan nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí o wa ninu Iwe Mimọ tí yóò ní idaduro tàbí ìdènà láti wa si ìmúṣẹ. Rántí pé ìmúṣẹ náà pé fún imurasilẹ, fún ipadabọ Jésù Kristi Olúwa wa lẹẹkeji.

IGUNLẸ:

Ipa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, a ti parí ẹ̀kọ́ kẹjọ tí ọwọ ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ ìsinmi ṣáá yìí. Olùkọ́ni àgbà náà, Ẹmi Mímọ́ tí rán wa lọ́wọ́ láti rí díẹ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ikẹhin tí o ti wa si ìmúṣẹ. Igbagbọ wa ni wi pe a ko si ninu òkùnkùn mọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a n ni ìrírí wọn ní àyíká wa. Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan wọnyii jẹ ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà ikẹhin kan. Ohun ti o ṣe pàtàkì ni imurasilẹ rẹ sì àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyii, ìyẹn ni, ipadabọ Jésù Kristi lẹẹkeji àti òpin ayé. O ko nii pàdánù (yọ sọnù) ni orúkọ Jésù, àmín.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ IKEJI

Mon.    Oct.  28:   Ìgbéraga Àwọn Tí O Ku (Isa. 28:2-4)

Tue.              29:   Agbára Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run (Isa. 28. 5-6)

Wed.             30:   Ààbò fún Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run (Isa. 29:5-8)

Thur.             31:  Àwọn Ènìyàn Náà Ko Nii Bẹru Mọ (Isa. 29:20,22)

Fri.     Nov.    1:   Oluwosan Àwọn Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run (Isa. 29:17-19)

Sat.               2:    Olúwa Yóò Mú Kí Àwọn Ènìyàn Rẹ O ṣàṣeyọrí/Ṣe Rere (Isa. 29:21,23-24).

Leave a Reply