ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ní Àgbáyé. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI fUN Dec.15, 2019 ÌSỌRI KẸTA: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ :- Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ OHUN GBOGBO NI YÓÒ DI ỌTUN

By | December 13, 2019

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ní Àgbáyé. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI fUN Dec.15, 2019 ÌSỌRI KẸTA: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ :- Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ OHUN GBOGBO NI YÓÒ DI ỌTUN

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Ní Àgbáyé.
Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Kí Ìwé Mímọ́ Kí O Le Ṣẹ.
ÌSỌRI KẸTA: A MU ÀWỌN ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ
Ọjọ: December 15, 2019.

Ẹ̀KỌ́ KEJÌLÁ
OHUN GBOGBO NI YÓÒ DI ỌTUN

Ìrètí ọrun tuntun gbọ́dọ̀ ru wa soke láti máṣe gbọjẹgẹ igbe ayé iwa mimọ ni fifoju sọ́nà fún bibọ/wíwà Olúwa.

AKỌSORI


Ṣá wo o, èmi o da ọrun tuntun àti ayé, a ki yóò sì rántí àwọn tí ìṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wa si aya

Isaiah 65:17

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ


Fún àwọn tí wọn n ṣiyèméjì lórí ìṣẹ̀dá àti dídá ayé láti ọwọ Ọlọ́run ti o ga julọ, ọrọ isegbe tàbí àtilẹ́yìn mìíràn ni yìí fún dídá ayé (wo Gen. 1:1; O.D. 24:1,102:25). Akọsori wa ti òní jẹ ìṣẹ́/ọrọ Ọlọ́run sì àwọn ènìyàn Rẹ láti ẹnu wolii Isaiah. Èyí ni àkókò ìjìyà Israẹli ni ọwọ àwọn orílẹ̀-ede keferi àti àwọn ọba wọn.

Ìlérí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Rẹ jẹ ipa méjì: Ekinni, pe àwọn ara Júdà yóò tún padà sí ìlú wọn Jerúsálẹ́mù; bí àwọn wọn yóò ti padà wa lati ìgbèkùn. Èyí jẹ itọkasi ìjọ ajagun. Èkejì àti èyí tó gbẹyin, ní ìjọ aṣẹgun tí yóò fìdí kalẹ sì ayé aláyọ̀ àti àlàáfíà níbi tí ohun àtijọ́ yóò ti kọjá lọ (2 Kor. 5:17). Ìdánilójú Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Rẹ ni pe, irú ìyá yowu kí wọn jẹ ní ọwọ sátánì àti àwọn ikọ rẹ, nítorí ẹsẹ wọn kì yóò lọ títí. Àti ọrun níbi tí satani n gbe tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ninu ògo àti ní ayé níbi tí ó ti n ṣàkóso àwọn ẹni tí rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni a o ṣe atunda rẹ, a o sọ ọ di ọtun, a o si mú kí o tutù yọyọ.

Abala àkọ́kọ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ náà tí ṣẹ nípa pé àwọn ọmọ Israẹli tí padà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn ìgbèkùn. Nítorí náà, a n dúró de isọdọtun ohun gbogbo ni igbẹyin: nínú èyí tí a da ọrun àti ayé. Àwọn onigbagbọ gbọ́dọ̀ pá ìrètí wọn mọ láàyè bí a ti n retí/dúró de ìrírí ọtun yìí nínú Ọlọ́run àti pẹlu Ọlọ́run.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ

Mon. 9: Ọlọ́run Yóò Sọ Ohun Gbogbo Di Ọtun (Isa. 66:22)

Tue. 10: Ọlọ́run Yóò Ṣẹgun Sátánì Ni Amágẹ́dọ́nì (Ifi. 16:16; 19:11-21)

Wed. 11: Ọlọ́run Yóò De Sátánì Ni Ogun Magog (Ifi. 20:7-15)

Thur. 12: Jerúsálẹ́mù Tuntun Yóò Jẹ Ológo (Ifi. 21:9-21)

Fri. 13: Ọlọ́run Ní Tẹmpili Tí N Bẹ Nínú Rẹ (Ifi. 21:22-27)

Sat. 14: Itẹ Ọlọ́run Yóò Máa Sun Odo Omi Iye (Ifi. 22:1-5).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN


1. Ọlọ́run ti ṣèlérí láti sọ ohun gbogbo di ọtun. Ọtun náà yóò dé lai pẹ. Ẹnikẹ́ni tí o ba pàdánù rẹ yóò máa sọkun títí láé. Kiyesara!

2. Ohunkóhun tí a le maa ni ìrírí rẹ nihin àti nísinsìn yìí, nínú ayé tí o ti burú yìí, yóò faaye silẹ fún ayé aláyọ̀ tí òdodo, èyí tí o wa fún olódodo nìkan. Tí àwọn ènìyàn kan kò ba ni sì nibẹ, ko yẹ kí ó jẹ ìwọ.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : Matiu 24:29-51

ILEPA ÀTI ERONGBA


ILEPA: Láti rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọ láti inú Bíbélì pé ọrun àti ayé ni a o sọ di tuntun, nítorí náà ki wọn kì ó múrasilẹ láti ni iwa àwọn olùgbé tuntun ibẹ.

ÀWỌN ERONGBA: A nírètí pe ni ipari ẹ̀kọ́ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́:

i. le sọ nípa ohun tí ọrun àti ayé tuntun jẹ,

ii. le ṣàlàyé bí ọrun àti ayé tuntun ti lẹwa to,

iii.le sọ àwọn amuyẹ tí yóò mú ènìyàn lè kopa ninu ohun tuntun tí a n retí náà,

iv. lè túbọ̀ faraji láti máa fi sùúrù dúró de ìfarahàn ológo Jésù Kristi.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: ÌFIHÀN 21:1-27.


Gbogbo ogo ni fun Ọlọ́run ti O ti fi oore ọ̀fẹ́ mú wa la saa ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi yìí kọjá. Ẹ̀kọ́ dídára mọkanlaa tí n yí igbe ayé padà ní a ti gbé yẹ̀wò, nípa oore-ọ̀fẹ́ Rẹ. Gbogbo rẹ ni o dúró lórí ohun tí ìwé Mímọ́ jẹ, láti inú ìwòye Ọlọ́run, iye àwọn tí o ti wa si ìmúṣẹ nínú rẹ, àti àwọn tí a o maa retí ìmúṣẹ wọn laipẹ.

Ẹkọ kọkànlá, ÌFARAHÀN KÌNNÌÚN Ẹ̀YÀ JÚDÀ, jẹ ọna ti Ọlọrun gba láti fìdí òtítọ́ pe Jésù n padabọ lẹẹkeji múlẹ̀, lẹ́yìn wíwà Rẹ àkọ́kọ́ nígbà tí o wa bí olùṣọ́-àgùntàn tí n wa àgùntàn tí o nù kiri, tí o si n tọ ọ (Mat. 2:6). Yóò padà wa bíi Kìnnìún Júdà pẹ̀lú ìbínú láti pa èṣù, ìṣẹ́ rẹ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ run (Ifi. 19:11-16). A rii pé igbasoke ni ohun àkọ́kọ́ tí yóò kọ sẹlẹ. A gbàdúrà pé a ko ni kabamọ nígbà tí Kìnnìún ẹ̀yà Júdà ba pada wa. Àmín.

Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ tí o kọjá, ẹ̀kọ́ kejila ni ọwọ yìí jẹ ti ọlọsẹ kan. Oun ni o pari ọwọ yìí. Lẹyin ọrọ sísọ gbogbo nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá wọ̀nyí tí a ń dúró de ìmúṣẹ rẹ nígbà ikẹyin yìí, Ọlọ́run yóò sọ ohun gbogbo di ọtun. Ayọ̀ tuntun tí ènìyàn tí pàdánù nínú ọgbà Édẹ́nì ni a ó dà padà sí ìtìjú èṣù. Èyí jẹ ilepa Ọlọ́run ti ó ga julọ.

Ẹkọ tí a n ṣe agbeyẹwo rẹ ni OHUN GBOGBO NI YÓÒ DI ỌTUN. ‘Yóò’ nihin n sọ nípa ìdánilójú. O da wa lójú láti inú Ìwé Mímọ́. Ọlọ́run ni o sọ ọ, ko si lee sọ pé ko ri bẹẹ mọ. Nítorí èyí yẹ kí ó pe fún níní òye pé a ko gbọdọ lé ohun ayé ju bí ó ti yẹ lọ, ṣùgbọ́n ki A fojú wa si awọn ohun ti ọrun láti ibi tí Kristi yóò ti farahàn láti sọ ohun gbogbo di ọtun.

Ìfihàn 21 yóò rán wa lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ ayérayé yìí. A gbàdúrà pé kí òye wa ki o ṣi nítòótọ́ láti mọ ohun gbogbo tí Kristi ni fún wa ní orúkọ Jésù. Àmín. MARANATA!

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN :

Ẹkọ yìí jẹ ti ọlọsẹ kan, a sì pín sí abala A àti B.

ÌPÍN KÍNNÍ :

Ẹkọ yìí ni o kẹ́yìn sì ṣáá yìí bẹẹni ó sì jẹ ọkan lára àwọn ẹ̀kọ́ méjì ọlọsẹ kan. O n safihan pé dandan ni a o fi òpin sí aya isinsin yìí àti ọrun àti aisedaduro ifirọpo pẹ̀lú ògo Ọlọ́run, ọrun aláyọ̀ àti ayé aláyọ̀, níbi tí ohun gbogbo yóò ti di ọtun. Àmọ́ sa ki i ṣe gbogbo ènìyàn ní yóò le de ibẹ. Iye àwọn ènìyàn tí wọn bá bá ìrètí Kristi mú ní wọ̀n yóò wa ninu ìjọba tuntun Ọlọ́run, wọnyìí ni itọkasi amuyẹ fún gbigba wọlé sínú ijọba náà.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I. OHUN GBOGBO YI YÓÒ DI ỌTUN
A. ẸWÀ ỌTUN NÁÀ
B. AMUYẸ FÚN ÌGBÀWỌLÉ

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
I. OHUN GBOGBO NI YÓÒ DI ỌTUN (Ifihan 21:1-27)

“Ohun gbogbo” nsafihan/dúró fún ohun tí n bẹ gbogbo, bóyá o ṣe pàtàkì tàbí ko ṣe Pàtàkì, àti ènìyàn, àyíká, ilé tí Ó kọ, ijọba, ipò, gbogbo ìrora àti òtútù, abbl ni yóò gbà ọna àti iri miran. Àwọn ohun àtijọ́ gbọdọ ṣí ààyè silẹ fún ohun tí o dara àti àwọn ohun ológo. Ayé tí o ti dibajẹ yóò yọ dànù fún ìlú ńlá tuntun.

A. ẸWÀ ỌTUN NÁÀ (Ẹsẹ 1,2,9-27).

Mo si ri ìlú mimọ ni, Jerúsálẹ́mù tuntun n tí ọrun sọkalẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa ti a múra silẹ bi ìyàwó tí a ṣe lọsọọ fún ọkọ rẹ (ẹsẹ 2).

i. Ẹsẹ 1a: ‘Tuntun’ n sọ̀rọ̀ nípa ti tútù yọyọ, ni ìmúṣẹ Isa. 65:17; 66:22; 2 Pet. 3:13). A n dúró de àkókò tàbí ìgbà tí o yatọ, ologo, tí o dara, tí o ji pépé ti o si ga ju ti ọrun àti ayé isinsin yìí lọ.

ii. Ẹsẹ 1b: Ọ̀run àti ayé isinsin yìí ni o ti gbọ́dọ̀ kọjá lọ nígbà tí ọrun tuntun àti ayé tuntun yóò sọkalẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa. Kin ni ìdí?

iii. Tuntun n tọkasi fifi irufẹ ohun kan tí o ti wa tẹ́lẹ̀ paarọ pẹ̀lú èyí ti o tun dára julọ. Ọrun àti ayé isinsin yìí tí dibajẹ. Lòtítọ́ sátánì dẹ́ṣẹ̀ ni ọrun (Isa. 14:12 swj), ìdí ni èyí tí a fi gbọ́dọ̀ paarọ rẹ kì o le wa ni ibamu pẹ̀lú ìwà mímọ ayérayé Ọlọ́run.

iv. Bawo? (wo 20:11-15). A o jo wọn run nínú ìtẹ́ Ìdájọ́ funfun nla. Nítorí náà, máṣe bá ayé dọrẹẹ (I Jhn. 2:15,16) kí o ma baa ṣègbé pẹ̀lú ayé (Jak. 4:4-6).

v. Ẹsẹ 2: Ọtun yìí yóò sọkalẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, nítorí gbogbo ẹ̀bùn réré àti pípé, ọdọ Rẹ (Ọlọ́run) ni o ti n wa. Kin ni o ro pe yóò jẹ òpin ẹniti o ba kọ láti ṣe tí Ọlọ́run nígbà tí òpin ayé bá dé? (Heb. 2:3)

vi. Ẹsẹ 9-27: Ogo tuntun ayérayé tí a ńfojúsọ́nà fún yìí kọjá ohun tí a lérò. Ṣé àlàyé ògo yìí láti inú àwọn ẹsẹ yìí.

vii. Ògo Ọlọ́run ni yóò tàn Imọ́lẹ̀ sì ìlú ńlá tuntun yìí, níbi tí Jésù yóò ti jẹ tẹmpili, Imọ́lẹ̀ àti ààbò. Mọ dájú pé kò sí ohun tí o jẹ alaimọ tí yóò wọnú rẹ. Nítorí náà, gba ara rẹ là kúrò lọ́wọ́ ìran àyídáyidà/búburú yìí (Ìṣe 2:40).

B. ÀWỌN AMUYẸ FÚN ÌGBÀWỌLÉ (Ẹsẹ 3-8)

Ẹni tí o bá ṣẹgun ni yóò jogún nnkan wọ̀nyí, Emi yóò sì máa jẹ Ọlọ́run rẹ, òun o sì máa jẹ ọmọ Mi (ẹsẹ 7).

i. Gbogbo ilé ẹ̀kọ́ ni o ni amuyẹ fún ìgbàwọlé àwọn ọmọ ile ẹ̀kọ́. Ẹnikẹ́ni tí ko ba kún ojú osunwọn ko le e jẹ ọmọ ile ẹ̀kọ́ náà. Bẹẹni yóò rí pẹ̀lú ọrun tuntun àti ayé tuntun.

ii. Ẹsẹ 3: Jésù wa lati gbe pẹ̀lú wa nihin ni ọdún díẹ̀ sẹ́yìn (Jhn. 1:14). Esek. 37:27,28 sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run yóò wa lati ba wa gbé ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀.

iii. Ọrun tuntun yóò sọ agọ mimọ Ọlọ́run kalẹ sáàárín àwọn ènìyàn. Ọlọ́run yóò máa gbé láàárín wa, èyí yóò sì fi òpin sí onírúurú ibanujẹ (ẹsẹ 4), nítorí yóò sọ ohun gbogbo di ọtun pátápátá (ẹsẹ 5,6).

iv. Ẹsẹ 7a: Irú àwọn ènìyàn mimọ wo ni Ọlọ́run yóò máa gbé láàárín wọn títí ayérayé? (wo ẹsẹ 3). Dájúdájú àwọn tí a ti yà sí mímọ́ tí wọn sì ti mimọ (Heb. 12:14; 1 Pet. 1:15-21). Àwọn tí wọn tí fọwọ́sowọpọ láti ṣẹgun sátánì, ẹṣẹ, ẹran-ara àti ayé. Wọn yóò jogún ohun gbogbo (wo 2:7,11,17,26-28; 3:5,12,21).

v. Ẹsẹ 7b: Wọn yóò ní anfani ayérayé láti jẹ ọmọ Ọlọ́run (àwọn ènìyàn tí wọn ní anfani láti jẹ arole Ọlọ́run ti o tọ́/yẹ) titi láéláé.

vi. Ẹsẹ 8: Nítorí pe Ilu naa jẹ mimọ, ohun aimọ kan kí yóò wọ ibẹ. Wọn yóò ní ipa àti ìpín wọn nínú adágún iná tí n jo pẹ̀lú imi ọjọ. A gbàdúrà pé a ko ni jẹ alábàápín nínú iná gbígbóná yìí. Àmín. Ìwà Mímọ́ tí a ko gbọjẹgẹ rẹ ni ọna àbáyọ.

vii. Gbogbo ìwé mimọ ni a gbọ́dọ̀ múṣẹ. Ní ọjọ́ díẹ̀ sì ibẹwo Ọlọ́run sì Sódómù, a ti pa a run. Bi ohun gbogbo ṣe ri nisinsin yìí nihin ni a o yipada. Gẹgẹ bi àwọn áńgẹ́lì ṣe sọ fún Lọti àti ìdílé rẹ kì wọn yàra kankan kúrò ní Sódómù ọ̀rọ̀ Rẹ n rọ̀ ọ́ láti jáde kúrò nínú ohun tí ayé gbogbo. Yàrá kankan (Gen. 19:16; Gal. 5:18-21).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ


1. Irú ìrètí ológo wo ni èyí! Ọlọ́run yóò sọ ohun gbogbo di ọtun ni ibamu pẹlu erongba ayérayé Rẹ.

2. Iye àwọn tí wọn ba faramọ òṣùwọ̀n ìwà mímọ Rẹ ni wọn yóò kopa ninu ogo tuntun yìí.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1. Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti ṣèlérí láti sọ ohun gbogbo di ọtun pàtápàtá, kín ni a gbọ́dọ̀ máa retí?

2. Báwo ni ìfojúsọ́nà fún ọrùn tuntun àti ayé tuntun ṣe n ru ìrètí sókè nínú wa?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ

i. Kí Ìwé Mímọ́ ki o le ṣẹ. Ọlọ́run kì ìṣe onirọ; Yóò mú ọrọ Rẹ ṣẹ (Num. 23:19; I Sam. 15:29; O.D. 69:35).

ii. O yẹ ki a mọ pe ko yẹ kí a to ìṣúra pupọ jọ sí ayé yìí, niwọn ìgbà tí a o fi ina sun ún (Mat. 6:20-21). Ki a túbọ̀ máa na owo lórí àwọn iṣẹ́ àkànṣe ti ọrun.

iii. Àwọn onigbagbọ ni lati maa to ìṣúra wọn jọ sí ọ̀run níbi tí kòkòrò ko le e pa a run.

iv. Niwọn ìgbà tí dìde Olúwa tí sunmọ etile, O n fẹ́ ìyípadà sì rere nínú àwọn iwa wa (Isa. 1:18; Ifih. 7:14).

v. Èyí n pe wa pe ki a fọ àwọn akisa ẹlẹ́gbin wa kí o mọ bí òjò didi.

vi. A gbọ́dọ̀ máa retí fún isọdọtun yìí, bí o ti wu ki o pẹ to (2 Pet. 3:9).

vii.A gbọ́dọ̀ farada gbogbo ìjìyà kí a sì duro fún Kristi nígbà gbogbo, tí a ko ba ṣe èyí á ko ni le wọ ìjọba Rẹ (I. A. Ọba 15:20; I Pet. 4:3-4).

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJI

i. Ti ìrètí wa ba mọ ni ayé yìí nìkan, awa ni àbòsí julọ (1 Kor. 15:19)!

ii. Ohun pupọ ni a o pohùn réré ẹkún fún, tí a o si jìyà fún nihin, bio-tiwu ki a jẹ ẹni ìbùkún to.

iii. Ibanujẹ, ẹbi, àìní abbl wa ti n mú ayọ̀ àwọn ènìyàn lọ/kúrò nígbà kan tàbí òmíràn. Nihin yìí satani n ni wa lara, ara ati ẹran n ní wa lara.

iv. Ní ọ̀run àti ayé tuntun, Oluwa yoo nù omijé gbogbo nù kúrò (Ifih. 21:4). A o sọ èṣù di alailagbara titi ayérayé.

v. Gẹ́gẹ́ bí ayọ̀ níní ilé tuntun, ọkọ ayọ̀kẹlẹ tuntun abbl, tí n kún inú ọkàn wa, ayọ̀ wa yóò pọ ni ojo naa, a o ni ile tuntun.

vi. Gbogbo làálàá wa ni a ó fi silẹ nihin tí a ba ti kú. A o gbé nibẹ pẹ̀lú èrè wa titi ayérayé (2 Kor. 3:8; 2 Kor. 5:10).

vii. A o ri Jésù ni ọjọ kan bi Oun ti ri (I Jhn. 3:2).

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI:

Irufẹ ìrírí ìdùnnú/ayọ̀ ologo wo ni èyí fún ènìyàn tí ó n yá ilé alapa gbe pẹ̀lú ẹbi rẹ tí o dojú kọ alominira àti ìnilára láti ọ̀dọ̀ onílé láti kéde rẹ pe o jẹ ẹ̀bùn (ṣe orí re) ilé kan nínú àwọn ìlú ńlá tí o fẹ. Ìdílé rẹ yóò bọ lọ́wọ́ ẹ̀gbin àti òórùn tí o n tí àyíká wa. Ìròyìn pé wọn n fi ibi ahamọ yìí silẹ lọ, si àyíká tuntun tí to gẹ́gẹ́ bí wọn tí n retí èyí laipẹ, “ipo wa yóò yipada,” Bẹẹ naa ni títóbi Ọlọ́run ni sísọ ohun gbogbo di ọtun fún àwọn onigbagbọ nínú Kristi. Laipẹ, abala ìwé mimọ tí o sọ nípa wiwọ ibi ayérayé wa lọ yóò ṣẹ. Ilé tuntun túmọ̀si wiwọ aṣọ tuntun, ìwo ojú tuntun, àti iwa tuntun tí o ba àyíká náà mu. Àwọn onigbagbọ gbọ́dọ̀ gbé iwa ọrun àti ayé tuntun wọ láti le wọnú rẹ. Oun rere mélòó ni ìwọ gbádùn nihin yìí? Sa gbogbo ipá rẹ láti de Jerúsálẹ́mù tuntun tí o n bọ láti ọrun. A ko ni ja wa silẹ ni ọjọ naa ni orúkọ Jésù. Àmín.

IGUNLẸ

A ti wa si ìparí sáà (ọwọ) yìí nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ tí o kẹ́yìn ni èyí ṣùgbọ́n ohun kọ ní òkèèrè julọ. O sọ fún wa àwọn ohun tí o yẹ ki a maa retí ni ọrun tuntun àti ayé tuntun, níbi tí àwọn onigbagbọ yóò máa gbé pẹ̀lú Ọlọ́run Ọlọ́run ni ayérayé nínú ayọ̀. A gbàdúrà ki Ẹ̀mí Mímọ́ ki o sọ ara kíkú wa di ààyè, ki o si mú wa yẹ, kí a si ṣetán láti wọ ilé ayérayé wa. Àmín.

Leave a Reply