ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Fun January 19, 2020. NÍ ÀGBÁYÉ Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. Ọlọ́run Nínú Ìṣàkóso Ènìyàn.

By | January 18, 2020

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Fun January 19, 2020. NÍ ÀGBÁYÉ Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI.

Ọlọ́run Nínú Ìṣàkóso Ènìyàn. ÌSỌRI KÍNNÍ: NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ/Ẹ̀KỌ́ KÍN-IN-NI

ỌLỌ́RUN, ONINKAN ÀTI ALÁKÓSO

Gbogbo ọrùn àti ayé ń bẹ ní ọwọ Ọlọ́run wa gẹ́gẹ́ bí Oninkan àti Alákóso.

AKỌSORI

Bi ọrọ náà sì ti wa ni ẹnu ọba, ohun kan fọ láti ọrùn wa, pé, Nebukadinésárì, ọba, ìwọ ni a sọ fún; pé, a gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Rẹ (Dáníẹ́lì 4:31).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ

Ènìyàn ni ìtẹ̀sí láti gberaga, gẹgẹ bi i èéhù ìṣubú; láti ìyìn ara ẹni sì igapa, lẹ́yìn náà si ìgbéraga. O máa n burú tí ènìyàn ko ba ti i ni ìrírí ìràpadà àti agbára ìgbàlà Olúwa, tí o si n bẹ lábẹ́ ipa agbára ẹṣẹ síbẹ̀. Irufẹ eyi ni igbe ayé ọba Nebukadinésárì. Irú ohun tí ènìyàn tí ara pátápátá le ṣe, o gberaga lórí ohun tí o ro pe oun jẹ pe o kọ babiloni

Onilati tún fẹ/gberaga si i nítorí pé o ṣẹgun tí o si tún kó Júdà alágbára lẹru (gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀ ede keferi yóò ti ṣe wò wọn, nítorí ìwàláàyè Yahweh àti àtilẹhin Rẹ. O fi ìgboyà gberaga pẹ̀lú aibikita (Dan. 4:28-30), si aidunnu ogo Yahweh tí ko ni afiwe ẹni tí ko ni gba àfojúdi/gberaga bii irú èyí (Isa. 42:8).

Àbájáde: ki o to parí iwikuwi wéré rẹ tán ni ete rẹ àti ní ọkàn rẹ (wo Mat. 12:34), ohun kan jáde láti ọrùn wa (ẹsẹ 31a). Ohùn tani? Ohun Yahweh ẹlẹ́ru-niyin (Eks. 20:18-21, O.D. 46:6). Ohun Ìdájọ́ Ọlọ́run sọkalẹ pẹ̀lú agbára sórí ọba onigberaga. Ọlọ́run máa n kọjá ìjà sí agberaga ni gbogbo igba (O.D. 138:6; Òwe. 3:34; Mat. 23:12; Jak. 4:6-10; I Pet. 5:5). A ja Nebukadinésárì walẹ sì ipo ti a ko le ronú rẹ; ẹnikẹ́ni ní a le rẹ silẹ bi ẹranko, ki o pàdánù àwòrán Ọlọ́run ti n bẹ lára rẹ (ẹsẹ 32b-33).

Ìtumọ̀ ohun tí ọba náà ṣe ni pé o fi àbùkù kan títóbi ìwàláàyè Ọlọ́run, èyí sì jẹ ìṣiwèrè (O.D. 14:1-4) tí o pe/fa ìbínú Ọlọ́run (O.D.14:5-7). Ohunkóhun yowu kí o da tàbí jẹ ní ayé, máṣe jẹ ki ó ko si ọ̀ lórí. Gbogbo ìgbà ni ki o maa mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bi Oninkan àti Alakoso, Eniti o n fúnni tí o si le gba a padà, ni ibamu pẹ̀lú eto ayérayé Rẹ (Orin Daf. 24:1 swj; 75:6swj).

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ

Mon. 13: Tí Olúwa Ni Ilẹ̀ (O.D. 24:1)

Tue. 14: Gbogbo Alákóso/Olórí Ní Wọn Nilo Ọlọ́run (Òwe 8:14-16)

Wed. 15: Ọlọ́run N Fi Fúnni Bẹẹni O Si Tún Ń Gba A Padà (Dan. 4:28-37)

Thur. 16: O N Pín Ilẹ̀ Fún Ogun Ìní (Deut. 4:2-19)

Fri. 17: O N Diwọn Iye Ọjọ́ Ayé Ènìyàn (Dan. 5:28-37)

Sat. 18: Nítorí Náà, Jẹ Ọlọgbọn (Jak. 4:13-17).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN

1. Oluwa ti o ga / tobi julọ máa n lo agbára, ògo, ọlá àti títóbi Rẹ lori ohun gbogbo tí o wa, àti ènìyàn, èṣù àti lórí ohun gbogbo tí O da.

2. Agbára, ògo, ọlá àti ọláńlá Rẹ ati awọn àbùdá Rẹ miran, sọ nípa títóbi àti oore Rẹ, ipa méjì tí ẹ̀dá Rẹ jẹ. Dájúdájú o tobi jọjọ. A ri èyí kedere àti ní àìsí àríyànjiyàn tí o fi hàn lórí ohun gbogbo tí O da/ẹ̀dá ọwọ Rẹ èṣù, àwọn ẹ̀mí òkùnkùn, ènìyàn àti ẹ̀dá ohunkóhun.

3. Kín ni o de tí o fi n ba A ja tàbí tí o n gbìyànjú láti máa fà ohun tí o ro pé o jẹ tàbí tí o ní pẹ̀lú ẹniti o ko le ṣẹgun Rẹ ni ọna kọ́nà? So/rọ mọ Ọn nísinsìn yìí ni ipàṣẹ Jésù Kristi Olúwa wa.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: Orin Dáfídì 24:1-10

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA

ILEPA: Láti fi hàn pé Ọlọ́run ní Oninkan, bẹẹni ni o ṣe jẹ́ Oninkan síbẹ̀ àti Alákóso Ọrun on Ayé, láìka ọrọ Sátánì sì pe oun ni oninkan àti àwọn iṣe rẹ.

ÀWỌN ERONGBA: Ní ìparí ẹ̀kọ́ yìí, a n retí pé àwọn onkawe gbọdọ:

i. Le fi Olúwa hàn gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ẹniti o ni ọrùn òun ayé àti ohun gbogbo tí o n bẹ nínú rẹ

ii. Le fi Olúwa hàn gẹ́gẹ́ bí Olúwa gbogbo ayé.

iii. Le fi ẹ̀mí imoore hàn sí Ọlọ́run fún fífi oore ọ̀fẹ́ yàn láti ṣe àjọpín ojúṣe ìṣàkóso Rẹ pẹlu ènìyàn

iv. Le fihan pe gbogbo ìwà búburú Sátánì síbẹ̀, a ko le rọ Ọlọ́run lórí ìtẹ́ bẹẹni O si n tẹsiwaju láti máa ṣàkóso nípasẹ̀ ènìyàn.

IFAARA

ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: GENESISI 3:1-15; ORIN DÁFÍDÌ 8:6-8; 22:28; ISAIAH 45:18; KÓLÓSÈ 1:16,17; ÌFIHÀN 12:1-10.

Ọpẹ ti ko ṣe e da tan jẹ ti Ọlọrun Ẹni tí O mú wa la ẹ̀kọ́ oṣù mẹ́fà tí o kọjá ja nípa Ẹ̀mí Rẹ, bi a ti ṣe agbeyẹwo àkòrí Gbogbo ni: KÍ ÌWÉ MÍMỌ́ KÍ Ó LÈ ṢẸ. Nípa oore ọ̀fẹ́ Rẹ, a rán wa lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ rírí ohun tí ìwé Mimọ jẹ sì Ọlọ́run, Jesu Kristi Olúwa, ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ àti ohun tí o yẹ ki ó jẹ sì wa, àní, Ìjọ Ọlọ́run alààyè ni ìran yìí (II Tim. 3:16,17; II Pet. 1:20,21). Jésù gbé ìgbé ayé ìwé mimọ bẹẹni O si mú Iwe mímọ́ ṣẹ.

A ti ri ìmúṣẹ Ìwé mímọ́ ni ṣíṣẹ-n-tẹle, bẹẹni O sì tún di ipenija láti ṣàwárí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àtijọ́, wa di ìtàn lónìí, èyí tí o n tọkasi òtítọ́ pé ohunkóhun tí a ti kọ tàbí sọ, nípasẹ̀ ìwé mímọ́, ní a o múṣẹ. Báyìí, èyí tí o ṣe pàtàkì julọ ninu iwe mimọ tí yóò wa si ìmúṣẹ (báyìí) ni Wíwa ẹlẹ́ẹkeji Olùgbàlà Olúwa àti Onidajọ ayé tí kò ṣe e dá dúró. Èyí wa jẹ orísun imunilọkanle fún àwọn onigbagbọ (I Tes. 4:17,18). A gbàdúrà pé kí a lè máa rántí eyi, kí a sì ro wa lágbára láti máa ba A rin, kí a sì máa ṣíṣẹ fún Un bí a ti n dúró de abala ìwé mímọ́ yìí.

Báyìí, Ọlọ́run tún n mu wa lọ sínú kókó ọrọ miran nípa Ẹ̀mí Rẹ “Ọlọ́run nínú Ìṣàkóso Ènìyàn” (O.D. 22:28). Àwọn ìbéèrè tí a lè béèrè ní pe. Tani o ṣedá, tí o ní Ọ̀run àti ayé? Kín ni ti àwọn ènìyàn, ìdílé àti orílẹ̀ ede tí wọn kò da A mọ daradara. Njẹ O ni ipa lórí àwọn orílẹ̀-ede wọ̀nyí? Ǹjẹ́ iditẹ, ìfiẹ́honu hàn, aìgbàgbọ́ abbl. ha a lè da A dúró láti gbé igbesẹ bi? Nígbà wo ni yóò gbà akoso pátápátá Abbl?

Nípa oore Rẹ, a ti pín ẹ̀kọ́ yìí sí Ìsọri Kejì: Ìṣàkóso Nípasẹ̀ Àwọn Onidajọ àti Ìsọri Kẹta: Ìṣàkóso Nípasẹ̀ Àwọn Ọba. Ẹ̀kọ́ kin-in-ni, ni Ìsọri kin-in-ni ni a pe ni Ọlọ́run Oninkan àti Alakoso.

Ko si ohunkóhun tí o da wa fúnra rẹ. Kódà ènìyàn gan-an ni a ronú nípa rẹ, tí a lóyún rẹ, tí a si da. Bi ohun tí o ní ẹmi, ẹmi /iye tòótọ́ ba gba orísun rẹ ba jẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, báwo wa ni ti àwọn ohun yoku miran àti àwọn ẹranko. Bíbélì àti àwọn onigbagbọ nínú Ọlọ́run ko mọ ẹlẹda miran ti o pegede tí o le ṣàkóso ohun tí O ti da fún erongba ayérayé tí ko ṣe e yipada. A gbàdúrà pé kí a kún fún ọgbọ́n láti rí láti mọ ko se e ma ni Rẹ, ni orúkọ Jésù.

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN

A pín ẹ̀kọ́ yìí sí abala méjì I àti II. Abala kọ̀ọ̀kan ni a tún pín si A àti B.

ÌPÍN I: ỌLỌ́RUN ẸNITI O NI OHUN GBOGBO

Ìpín yii fi Ọlọ́run hàn gẹ́gẹ́ Oninkan àti Olúwa ayé (ọrùn òun ayé), ni ọna ohun méjì tí o yatọ ṣùgbọ́n tí wọn fi ara kọ ara wọn, A àti B gẹ́gẹ́ bi i atẹyinwa. Isaiah 45:18; Kol. 1:16-17 ni àwọn koko ọrọ ni ìpín yìí. Ọlọ́run ni Ẹlẹda ohun gbogbo ni tòótọ́, ohun tí o sọ O di Oninkan. Ìpín yìí fún wa ní àwọn àpẹẹrẹ nínú Bíbélì láti fìdí Olúwa Ọlọ́run nínú ọrọ ènìyàn múlẹ̀.

ÌPÍN II: SÁTÁNÌ OLE ÀTI AFIPA GBA NNKAN/ALỌNILỌWỌGBA

Gen. 3:15-20; O.D. 8:4-5; Ifih. 12:1-10 ni àwọn ipilẹ fún ẹ̀kọ́ ìpín kejì yìí. Ipa/abala méjèèjì yìí jẹ Ojúṣe Ìdarí Tí Ọlọ́run Fún Ènìyàn tí Sátánì Fi Ipá Gba Ojúṣe Ìdarí Yii. Abala àkọ́kọ́ ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tí o nitumọ láti inú òtítọ́ pé Ọlọ́run ṣe àjọpín ojúṣe ìdarí Rẹ pẹ̀lú ènìyàn nínú oore ọ̀fẹ́. Èyí farahàn nínú ibasepọ Rẹ pẹlu Ádámù, Nóà, Ábúráhámù, Jákọ́bù àti àwọn miran ti a dárúkọ. Abala B safihan bi Sátánì ṣe fi ẹ̀tan gba ojúṣe ìdarí tí a fífún ènìyàn lai kíyèsara. Kí ìṣe pé a o kan sọ ìtàn náà, ṣùgbọ́n a o wo bí Sátánì tí gbìyànjú to, títóbi Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bi Oninkan àti Olúwa ayé ni a kò le sọ di alailagbara.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́

I. ỌLỌ́RUN, ẸNI TÍ Ó NÍ OHUN GBOGBO

A. ÒUN NI O NÍ AYÉ

B. ÒUN NI OLÚWA GBOGBO AYÉ

II. SÁTÁNÌ, OLE ÀTI AFIPA GBA NNKAN/ALỌNILỌWỌGBA

A. ỌLỌ́RUN FÚN ÈNÌYÀN NÍ OJÚṢE ÌDARÍ/ÌṢÀKÓSO

B. SÁTÁNÌ JA OJÚṢE ÌDARÍ/ÌṢÀKÓSO GBA

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
I. ỌLỌ́RUN, ENITI O NÍ OHUN GBOGBO
 (Isaiah 45:18; Orin Daf. 22:28; Kólósè. 1:16,17)

Pé ènìyàn ni o ni nnkan túmọ̀si pé, ènìyàn ni nnkan náà gẹ́gẹ́ bíi ti ara rẹ. Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run nínú ìṣàkóso ènìyàn, O jẹ ohun ti o mú ọgbọ́n lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ pẹlu ipò àti ti tóbi Ọlọ́run ni ìbámú pẹ̀lú ènìyàn tí o n sọ tí ìjọba Rẹ nínú ọrọ ènìyàn. Ohun tí o ba ni, ní o le pinnu lilo rẹ. Ọlọ́run jẹ Olúwa wa, nítorí pé Òun ni o da ohun gbogbo tí o sì ni ohun gbogbo.

A. ÒUN NI O NÍ AYÉ (Isa. 45:18; Col. 1:16,17)

Nítorí bayi ni Olúwa wí, ẹniti ó da àwọn ọrùn; Ọlọ́run tìkáraRẹ tí o mọ ayé, tí o sì ṣe; O ti fi idi rẹ múlẹ̀, kò da a lásán, O mọ ọn ki a le gbe inú rẹ; Emi ni Olúwa; ko si ẹlomiran (Isaiah 45:18).

i. Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá àti Ẹniti o ni Ọrun òun Ayé (Isaiah 45:18)

ii. Ẹlẹ́dàá? Bẹẹni Òun ni o mú kí ohun gbogbo (èyí tí o ṣe e fojuri àti eyi ti ko ṣe e fojuri) wà, bẹ́ẹ̀ ni O si n gbe wọn ro (Jhn. 1:3; Kol. 1:14-17).

iii. Ọlọ́run lè ràn ènìyàn lọ́wọ́, lórí ohun tí o jẹ dandan fún wọn àti ẹ̀kọ́, láti ṣàwárí, dọgbọn, sagbekalẹ ohun tuntun ṣùgbọ́n ko si ẸLẸDA miran. Òun nìkan ni Ẹlẹ́dàá.

iv. Gbogbo àwọn idagbasoke àwárí imọ miran nínú sísìn màlúù, nínú orin kíkọ (Gen. 4:20, 21) nínú ohun ìjà ogún ni wọn jẹ àwárí imọ láti inú àwọn ohun tí Ọlọ́run, Ẹlẹda nìkan ṣoṣo tí DA.

v. Nítorí náà Ọlọ́run nìkanṣoṣo ni Ẹlẹ́dàá àti Ẹni tí o ní ohun gbogbo. Kín ni ìdí? Fún ògo Rẹ, erongba ayérayé Rẹ ati fún ìbùkún ènìyàn (Ifih. 4:11; Kol. 1:16,17).

vi. Nítorí náà, O ni gbogbo ẹtọ láti wa ni igbọnnu ìṣàkóso (boya tààrà tàbí láìṣe tààrà) ohun gbogbo tí n bẹ /ṣẹlẹ̀ nínú ayé àti ní ọ̀run.

vii. Ero pe Oun ni Oninkan yẹ kí o rẹ wa silẹ nínú gbogbo ìṣe wa, kí o máa da wa padà sọ́dọ̀ Rẹ loorekoore. Ko si ẹnikẹ́ni nínú wa ti o ni ara rẹ. Ọlọ́run ni o ni wa. O gbọ́dọ̀ gba ògo pé O da wa, O si ṣe wa ni ohun tí a jẹ àti ohun tí a o jẹ.

B. ÒUN NI OLÚWA GBOGBO AYÉ (Gen. 18:20-23; 19:19-25; O.D. 22:28)

Nítorí ìjọba niti Olúwa; Òun sì ni Baalẹ nínú àwọn orílẹ̀ ede (O.D. 22:28).

i. Láti jẹ Olúwa ni lati ni àṣẹ àti agbára lórí àwọn ẹlòmíràn.

ii. Ọlọ́run ni Olúwa àwọn olúwa (Heb. Adonai) (Eks. 20:2; Deut. 6:4), Jésù ni a pe ni Olúwa (Kariousi ni Griki) (Ìṣe 2:21, 36). A pe ènìyàn náà ní oluwa (pẹ̀lú lẹ́tà kedere ‘o’ donai ni Heb). Jíjẹ oluwa ènìyàn lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá wa jẹ nípa àṣẹ tí a fi fún un. Ènìyàn kí ìṣe Ẹlẹ́dàá tàbí Oninkan.

iii. Oluwa jẹ orúkọ fún ẹniti o ni àṣẹ, ìṣàkóso tàbí agbára lórí gbogbo àwọn tí o kù. Agbára Ọlọ́run ko ni opin. Àsìkò, ibi, àwọn àgbékalẹ òfin ènìyàn ko le dín agbára Rẹ ku.

iv. Wo bi Ọlọ́run ṣe da si ọrọ ènìyàn, àní láìsí ÌWÉ ÌPÈ.

(a) Lẹ́yìn dídá ènìyàn àti àyídáyidà ọwọ ènìyàn ọwọ ènìyàn, O wa lati yii nnkan padà (Gen. 3:20-24).

(b) Nígbà tí ènìyàn n di pupọ tí ko si fi ọwọ /ọ̀la fún OLÚWA RẸ MỌ, O wa, O si fi omi pa ohun tí O ti da rẹ (Gen. 6:6-8,9:1-3,8-15).

(c) Nínú ìdílé Ábúráhámù, O da si i Gbogbo Gen. 16:7-13, Gen. 21:8-21).

(d) Àní ní ilẹ keferi, Sódómù àti Gòmóràh “wọn ní ìrírí” idasi Ọlọ́run, Olúwa, Oninkan (Gen. 18:20-23; 19:19-25). Awuyẹwuyẹ ki Awuyẹwuyẹ, àtakò kí àtakò àti Idina kí Idina? Ni ko ṣe e ṣe, nítorí OLÚWA, Oninkan ń bẹ lẹ́nu ìṣẹ́.

v. Pé Òun ni Olúwa ń pe fún ìjọsìn wa si Òun nígbà gbogbo. A gbọ́dọ̀ gba A ní Olúwa lórí gbogbo ayé wa (kí ìṣe abala kan) TAKUNTAKUN, kii ṣe díẹ̀díẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí o ba fi òtítọ́ ṣe èyí yóò ní ìrírí ohun tí o túmọ̀si fún Un láti saggbatẹru Ọ̀rọ̀ ẹni náà, ní gbogbo ìgbà àti níbi gbogbo.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1. Ọlọ́run nìkan ni Ẹlẹ́dàá. Òun ni orísun. Orísun ohun gbogbo. O n tẹsiwaju nínú ìṣẹ́ Rẹ ni ríran ènìyàn lọ́wọ́ láti ṣàwárí, láti dàgbà àti láti sagbekalẹ àwọn ohun tuntun. Jẹ ki Ọlọ́run lo ọ ní ọ̀nà dídára.

2. Ọlọ́run kì í kan ṣe Ẹlẹda nìkan, O tún jẹ́ Ọ̀gá/Olùkọ́ni tí Ó n safihan ìfẹ́ ayérayé si ìṣàkóso ayé Rẹ ti O da, nítorí Òun ni Olúwa, ko si ibi kankan tí O ti da si ọrọ, ti O ti wọnú ọrọ ènìyàn, ti O gbé igbesẹ, tí wọn kọ jalẹ tàbí gbakoso lọ́wọ́ Rẹ.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE

Ṣàlàyé “nítorí ìjọba niti Olúwa, Òun sì ni Baalẹ nínú àwọn orílẹ̀ èdè” ni ìwòye ìwé Ìfihàn 4:11.

i. Nítorí ìjọba ni ti Oluwa, Òun sì ni Baalẹ nínú àwọn orílẹ̀ èdè wá láti inú O.D. 22:28. Ìjọba wo? Ijọba ọrùn àti ti ayé, nísinsìn yìí àti ní òpin. Òun ni o da ohun gbogbo, àti àwọn ìjọba pẹlu (O.D. 24:1 swj). Ohun gbogbo jẹ tiRé.

ii. Baalẹ jẹ ènìyàn aláṣẹ, gẹgẹ bí olugbani-si-ise tàbí ọga. Idi ni èyí tí Ọlọ́run fi jẹ Baálẹ àwọn orílẹ̀ èdè. O ju pé a gbà A tàbí yàn Án si ipo láti ṣàkóso Ìpínlẹ̀, ègbẹ, tàbí agbegbe kan fún ṣáá kan pàtó. Ìṣàkóso Rẹ lori awọn orílẹ̀ ede ko ni opin àti ìpẹ̀kun.

iii. Gbogbo orílẹ̀ ede n tọkasi gbogbo ìjọba tí n bẹ nihin lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run nìkan ni o n faaye gba ifìjọba àti iyọ̀ kúrò lórí ìtẹ̀ àti akoso àwọn ọba, emirs, sultans, ọba abbl. Jẹ ki a mú/wo ọrọ Nebukadinésárì gẹ́gẹ́ bi àpẹẹrẹ.

iv. Pe Oun ni Baalẹ nínú àwọn orílẹ̀ èdè túmọ̀si pé ko si ohunkóhun tí o n ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Rẹ (wo Àmọ́si 3:6). Òun ni Ọba gíga julọ lórí gbogbo orílẹ̀ èdè, iye àwọn orílẹ̀ èdè tàbí àwọn ènìyàn tí wọn mọ riri èyí, ní wọ́n le jẹgbadun ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún Rẹ. Èyí wa ninu iwe Ìfihàn 4:11 tí o wi pé, “Olúwa ìwọ ni o yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni o da ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú Rẹ ni wọn fi wa ti a si da wọn.”

v. Ọlọ́run ti o jẹ Ẹlẹ́dàá. Oninkan àti Olùgbé ohun gbogbo ro ni o yẹ ki a maa sìn, èyí ni pé, kí a máa fún Un ògo, ọlá àti agbára. O yẹ sì èyí ko si ẹlomiran ti o yẹ.

Leave a Reply