ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Ọlọ́run Nínú Ìṣàkóso Ènìyàn. ÌSỌRI KÍNNÍ: NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ/Ẹ̀KỌ́ KÍN-IN-NI.  January 26, 2020.

By | January 22, 2020

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI Ọlọ́run Nínú Ìṣàkóso Ènìyàn. ÌSỌRI KÍNNÍ: NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ/Ẹ̀KỌ́ KÍN-IN-NI.  January 26, 2020.

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ

Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI

Ọlọ́run Nínú Ìṣàkóso Ènìyàn.

ÌSỌRI KÍNNÍ: NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ/Ẹ̀KỌ́ KÍN-IN-NI.

January 26, 2020.

ỌLỌ́RUN, ONINKAN ÀTI ALÁKÓSO

II. SÁTÁNÌ, OLE ÀTI AFIPA GBA NNKAN/ALỌNILỌWỌGBA (Genesis 3:15-20; Orin Dáfídì 8:4-6; Ìfihàn 12:1-10).


Sátánì ni èṣù, ọta Ọlọ́run, olúwa ohun búburú àti oludanwo ènìyàn, òun ni Lusiferi, olórí àwọn áńgẹ́lì tí wọn ṣubú. Gbogbo ìgbà ni o n tako Ọlọ́run, àwọn ènìyàn Rẹ àti nnkan Rẹ. O fi arekereke wa lati jale àti láti gba fún ara rẹ ojúṣe ìdarí tí Ọlọ́run fi oore ọ̀fẹ́ fi fún ènìyàn. Báwo, kín sì ni ọna àbáyọ?

A. ỌLỌ́RUN FÚN ÈNÌYÀN NÍ OJÚṢE ÌDARÍ/ÌṢÀKÓSO (Gen. 6:1-14; 12:1swj; O.D.8:4-6)

Kín ni ènìyàn, tí ìwọ fi n ṣe ìrántí rẹ? Àti ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi n bẹ ẹ wò (O.D. 8:4)

i. Sátánì tí pàdánù ipò tí o ṣe pàtàkì níwájú Ọlọ́run, kí a ti da ènìyàn, èyí ni o fà òwú àti ìlara èyí tí ènìyàn ko kíyèsí.

ii. A dá ènìyàn ni onirẹlẹ ju àwọn áńgẹ́lì lọ, síbẹ̀ Ọlọ́run ti yàn láti gbé e leke àwọn áńgẹ́lì (Tani ènìyàn àti kín ni ènìyàn?) Heb. 2:5-8.

iii. Ohunkóhun tí ènìyàn bá ti ṣe tí ó fi ògo fún Ọlọ́run ti ó sì jẹ ìbùkún fún ènìyàn ni Ọlọ́run fi ààyè gba (ọpẹ ni fún Ọlọ́run lórí ẹ̀kọ́, ọgbọ́n atinuda, ikiyesara, isẹra-ẹni ènìyàn abbl). Ọlọ́run wa ni ipilẹ gbogbo ìdáwọ́lé ìṣẹ́ aláṣẹyọrí pátápátá. Ko fún ènìyàn ni ìṣàkóso lórí ohun tí o dàgbà ju u lọ.

iv. O fún Nóà ni iṣẹ́ tí kò wọ́pọ̀ (Gen. 6:7-14),

O fún Ábúráhámù ní ogún ayérayé (Gen. 12:1-4, 17:1-8),

O jẹ ki Jákọ́bù o rọwọ mú (Gen. 25:19-27; 27:18-23),

O fún Sólómọ́nì ní ìtẹ ìjọba (II Sam. 12:24,25). Ọmọ Batseba? Mat. 1:6.

O fún Jèróbóámù ni àǹfààní (IA. Ọba 11:26-39). Njẹ o wa lati ìdílé ọba bi? Ẹsẹ 26

O fún Gídíónì ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ (Onid. 6:11-40)

O fún àwọn òbí ni ọmọ: Mósè, Sámúẹ́lì, Jòhánù Onitẹbọmi abbl.

Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn, o fi ọ sí ẹnu ìṣàkóso àwọn ọkàn (ènìyàn), èyí ni agbo àgùntàn Rẹ.

v. Kín ni ohun tí o ní ti ki ìṣe pé a fún ọ ni (Jak. 1:17, I Kor. 4:7)?

iv. Ènìyàn kò yẹ fún ohunkóhun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa. Òun ni a da kẹ́yìn ohun gbogbo, síbẹ̀ a fún un ní ìjọba lórí ohun gbogbo. Abájọ tí Onisaamu fi sọ nínú O.D. 8:3 nípa irú anfaani tí ko wọ́pọ̀ yìí. Máa rántí nígbà gbogbo: Ohunkóhun tí o jẹ tàbí tí o ní lónìí, kí ìṣe nípa AKITIYAN rẹ sugbọn nípa ÀÁNÚ. Máṣe gberaga!

B. SÁTÁNÌ JA OJÚṢE ÌDARÍ / ÌṢÀKÓSO GBA (Gen. 3:1-24; Jhn. 8:44; Ifih. 12:9)

A si lé dírágónì ńlá náà jáde, ejo láéláé ni, tí a n pe ni Èṣù, àti Sátánì, tí n tán gbogbo ayé jẹ, a sì le e ju si ilẹ̀ ayé, a si le àwọn áńgẹ́lì rẹ jáde pẹ̀lú pẹ̀lú rẹ (Ìfihàn 12:9).

i. Èṣù ni ọpọlọpọ orúkọ tí o n fi irú ẹni tí o jẹ hàn (Jhn. 8:44), nihin Jésù pe e ni, èṣù, apànìyàn, èké, alailootọ, àti baba èké.

ii. Ifih. 12:9 fi i hàn gẹ́gẹ́ bí èṣù, dírágónì ńlá, ejò láéláé, Sátánì, ẹlẹtan àti olufisun àwọn ará wa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan orúkọ wọ̀nyí ni ẹri níbi tí o ti hùwà bẹẹ. Máṣe fojú rena èṣù.

iii. O ṣe àyídáyidà fún Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì ológo,, ṣùgbọ́n Ọlọ́run Ẹlẹda, Oninkan àti Baálẹ gbogbo orílẹ̀ èdè sọkalẹ wa, O fi ara àwọn ènìyàn Rẹ balẹ, bẹẹ ni O si pa èṣù lẹ́nu mọ (Gen. 3:20-24).

iv. Gẹ́gẹ́ bí ole àti alọnilọwọgba, o tọ Jesu wa, o sọ pe oun ni o ni ayé àti ogo rẹ, O sì wi pe ki Jésù Kristi o foribalẹ fún oun. Tani o fa a le èṣù lọwọ? (bóyá Ádámù àti Éfà) kí ìṣe àwọn ni oninkan. Jésù tọ ọ sọ́nà (Lk. 4:5-8; wo Mat. 4:8-10).

v. Ikuna rẹ lórí Jésù Kristi ko tẹ ẹ lọrun, gẹ́gẹ́ bi alọnilọwọgba àti bí ole, o tún padà wa lati ipasẹ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti o sunmọ Ọn tipẹtipẹ èyí ni Pétérù (Mat. 16:23). Finuro iwuwo àti oorin ede Jésù Kristi sì èṣù nínú Mat. 4:10 àti 16:23.

vi. Máṣe gba èṣù láàyè (Efe. 4:27). Kọju ìjà si i (Jak. 4:7), òun ni ọ̀tá ènìyàn tí o ga julọ àti ọta láéláé (I Pet. 5:8,19), bi o tilẹ jẹ pé a ti ṣẹgun rẹ, síbẹ̀ ó sì n gbe iwa ibi/búburú rẹ kiri, níbikíbi tí wọn ba ti faaye gba a, bíó-tilẹ̀-jẹ pé Ìdájọ́ n bẹ lọrun rẹ, nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde Jésù Kristi Olúwa wa.

vii. Aitẹle ìtọ́ni ní o yọrísí àìgbọràn nínú ọgbà Édẹ́nì èyí tí o mú kí ènìyàn o wọnú ìrírí tí kò fararọ. Ṣùgbọ́n, lojukan náà, láàrin Ìdájọ́, ìwé mímọ́ tẹle e (Gen. 3:15).

viii. Ọlọ́run gbé igbesẹ ni kankan láti dásọ bo ènìyàn, èyí tí o nílò “títa ẹ̀jẹ̀ silẹ” àpẹẹrẹ ohun tí a o ṣe lapapọ fún ìran ènìyàn (Gen. 3:21). Ipa ẹjẹ nihin ni a ko le fojú rena rẹ.

ix. Ènìyàn le sọnù tàbí yapa kúrò lọdọ Ọlọ́run títí ayé. Jésù nínú ìwé mímọ́, ní a tọ́kasi bi i Ọdọ Àgùntàn, tí a ti pa ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé (Ifih. 13:8). Jòhánù Baptisi fìdí èyí múlẹ̀ bí o ti safihan Olùgbàlà Aráyé (Jhn. 1:29). Nípa ẹ̀jẹ̀ Rẹ, ní a gbà wa la tí a sì mú wa sunmọ Ọlọ́run (Efe. 2:11-13, Kol. 1:19).

x. Imubọsipo ìkẹyìn ni a ti fihan nínú Ìwé Mímọ́. Báyìí, a ti jókòó pẹ̀lú Jésù Kristi ni ọrùn. Nígboṣe a o wa pẹ̀lú Rẹ títí ayérayé gẹ́gẹ́ bí ìwé Mímọ́ tí sọ. Njẹ ó ti múra tán?

xi. Láti fi ipá gba ni lati gba nnkan láìní ẹtọ tàbí láti lo o lai ni ẹtọ láti ṣe bẹ́ẹ̀. O jẹ láti gba nnkan lọ́nà àìtọ. Sátánì fi arekereke gba ojúṣe ìdarí tí a fi fún ènìyàn fún ara rẹ, ṣùgbọ́n ọpẹ ni fún Ọlọ́run, Jésù wa lati gba èyí padà fún ènìyàn. Gbogbo ẹni tí o bá sá pamọ sínú Kristi ni èṣù tí wa ni abẹ atẹlẹ́sẹ wọn (Rom. 16:20). Irú ìṣẹ́gun ńlá tí wo ni èyí (I Kor. 15:57)!

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1. Ọlọ́run ni Olufunni ni ohun gbogbo ni ayé. Kín ni idi? Òun ni Oninkan tí o n fi nnkan leni lọ́wọ́, tí O n fi ìṣẹ́ lè ni lọ́wọ́, tí O sì n fi ààyè gba ènìyàn láti ṣíṣẹ fún Òun. Abájọ tí O fi n fúnni tí O sì ń gba padà. Nítorí náà ènìyàn yóò jíhìn ohun gbogbo tí O fi le e lọ́wọ́ fún Un.

2. Ole, apànìyàn, èké àti bàbà èké ni Sátánì. O ti wa bẹẹ, ìpín/ayanmọ rẹ tí ko ni àtúnṣe mọ ni a ti parí rẹ. Síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ kọju ìjà si i níbikíbi/nigbakugba tí a ba ti kẹfin iwa arekereke rẹ. Àbájáde: Yóò sa ni orúkọ Jésù.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1. Ti Ọlọ́run ba jẹ Ẹniti ó ní ayé òun Ọrun, báwo ni àwọn ènìyàn ṣe wa n ro pe àwọn le ṣàṣeyọrí ni sisako kí wọn o sì wa láìsí Rẹ (Dan. 4:28-33)?

2. Bí Sátánì ba burú tó báyìí láti atetekọṣe, kín ni idi ti Ọlọ́run fi da a si? Ǹjẹ́ a le borí rẹ rara?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ

i. Lọ wo abala *1. Alaye kúkúrú

ii. Ko si àríyànjiyàn lórí pé Ọlọ́run ní oninkan ni ayé àti ọ̀run (O.D.24:1swj). O tún jẹ́ Òtítọ́, àwọn ènìyàn máa n ronú pé àwọn lè ṣàṣeyọrí, ṣe ìjọba, kí wọn o si wa láìsí Rẹ.

iii. Iwa were/omugọ ni fún ẹnikẹ́ni láti ro pe oun le di nnkan tàbí ṣe àṣeyọrí ohunkóhun láìsí tàbí ní òde Ẹlẹ́dàá rẹ, Ọlọ́run. Ki i háà ṣe nípa Ọlọ́run kan náà yìí, Ẹniti ó ṣe pé Òun nìkan ṣoṣo ni O n fi fúnni tí O si n da igbega/igbeleke dúró la n sọ̀rọ̀ ni O n fi fúnni tí O si n da igbega/igbeleke dúró la n sọ̀rọ̀ nípa Rẹ bi (O.D. 15:4swj)?

iv. Iwa were Nebukadinésárì (Dan. 4:28-33) wá si ọkàn nihin.

v. Àwọn ènìyàn máa n hùwà wéré yìí nítorí àìmọkan. Tí ènìyàn kò ba mọ iyì nnkan tàbí ènìyàn, tí ko si ni òye bí o ti tọ, ènìyàn yóò sì i lo tàbí ṣe aibọwọ fún ẹni náà tàbí ohun náà. Èyí le ṣẹlẹ̀ nínú ibasepọ ènìyàn pẹ̀lú Ọlọ́run. A le dariji ènìyàn lórí èyí de ààyè kan (wo Ìṣe 17:30). A gbàdúrà kí àwọn tí wọn n bẹ ní ipò/ipele yìí o ri Imọ́lẹ̀ ihinrere Ọlọ́run láti ipàṣẹ Olúwa wa Jésù Kristi kí a sì jẹ irinṣẹ sì iṣẹlẹ yìí.

vi. Ìdí míràn fún èyí ni ìgbéraga, èyí ni mimọ-ọ-mọ pa Ọlọ́run ti àti fífi ojú rena Rẹ (O.S. 14:1 swj, 53:1 swj). Ìṣòro Nebukadinésárì ni ìgbéraga. O fi ògo Ọlọ́run fún ara rẹ. O dara láti máa ronú nípa ìrírí rẹ ju láti ni irufẹ rẹ lọ.

vii. Èyí tí o ṣe pàtàkì julọ ni pé nígbà tí ènìyàn kò bá ti i ni ìrírí ìgbàlà àti ìyásí mímọ tí Jésù mú wa fún ènìyàn, ko le safihan iwa ti o tọ si ohun ti ṣe ti Ọlọ́run. ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJI

i. Ti o ba ṣe pé Sátánì burú tó bayii láti atetekọṣe, kín ni ìdí tí Ọlọ́run fi da a si?

ii. Ibéèrè tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí n béèrè ní eyi. O ti fa awuyewuye pupọ laarin awọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, fún àpẹẹrẹ, ni apero/ìjíròrò lórí ìṣòro ibi/búburú

iii. Kín ni ìdí tí Ọlọ́run fi dá irú ẹda bayi si? Ẹniti o jẹ pé láti ìpìlẹ̀ ni o ti ni ìgboyà láti ditẹ si I (Isa. 14:12 swj; Èṣek. 28:1 swj; Ifih. 12:11 swj)?

iv. O n bẹ ní ọ̀run o n ṣe ohun tí o wu U, ni ibamu pẹlu erongba ìràpadà Rẹ (O.D. 115:3).

v. Òun I ba ti fi ààyè gba èyí, tí o ba jẹ pe yoo ba wúlò fún / jẹ àǹfààní fún ìràpadà àti ìgbàlà ènìyàn nisinsin yìí àti ní ikẹhin (wo Rom. 8:28). Ma gbàgbé pé Sátánì pápá wa jẹ irinṣẹ ni ti ipa ni gigisẹ Mèsáyà tí O ṣe pàtàkì tí yóò parí ìṣẹ́ ìràpadà ènìyàn.

vi. Ohunkóhun tí Sátánì ba ro pe oun n ṣe, tí máa ń dabi pé, ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, Ọlọ́run n lo o láti mú erongba tiRẹ fún àwọn ènìyàn Rẹ ṣẹ ni. Ko wa mú ọgbọ́n lọ́wọ́ nígbà náà láti sọ pé, Sátánì gan-an jẹ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀nà kan?

Ǹjẹ́ a le borí rẹ rara?

i. Bẹ́ẹ̀ ni, a le borí rẹ!

ii. Nípa igbe ayé ètùtù àti ikú Kristi (I Kor. 15:57)

iii. Jésù ti fi èṣù sì abẹ atẹlẹ́sẹ wa ti a ba rọ mọ Ọn (Rom. 16:20).

iv. Ọ̀ta tí a ti ṣẹgun ni Sátánì tí a ko gbọ́dọ̀ bẹru nítorí ohunkóhun (wo Kol. 2:14 swj). Àwọn tí wọn ko tẹle Kristi nìkan ni o le ma a ba ja.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI:

Wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọdọ kan tí wọn fẹ jáde lọ sí àsè ìfẹ́. “Àwọn ìyá wọn sọ fún wọn pé kí wọn lọ pẹ̀lú Jésù sì àsè ìfẹ́ yìí” Ọkàn nínú wọn dáhùn pé ko si ààyè fún Jésù nínú ọkọ àyọkẹlẹ yìí, àyàfi ibi iko ẹrú si. Wọn gbéra, ṣùgbọ́n kí wọn tó dé gbọ̀ngàn àsè yìí, wọn ní ijanba ọkọ. Si ibanujẹ, ọkọ náà parẹ pátápátá, ṣùgbọ́n si ìyàlẹ́nu, ààyè ibi iko ẹrú sì nìkan ni ko bajẹ pẹ̀lú àwọn ẹru tí wọn ko sibẹ àti ologinni kan. O han jẹ ohun ti ko mọgbọn lọwọ láti sọ pé ologinni náà ko farapa nítorí àwọn tí wọn tí wọ́n wa ninu ọkọ náà tí yẹpẹrẹ Jésù sì ààyè iko ẹrú sì nínú ọkọ náà? Èyí jẹ ọkan lára àwọn àǹfààní mimọ-Ọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa. Wọn kò gbọn bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti n bẹ nínú ọkọ ojú omi nígbà tí efufu dìde lójú ibú. Iwa rẹ si títóbi Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi ni yóò sọ/ìpinnu bí ayé rẹ yóò ti dára/jẹ ti ológo si nisinsin yìí àti ní ayérayé.

IGUNLẸ :Ẹkọ àkọ́kọ́ ni èyí ni ọwọ yìí. O ti fún wa ní ifaara sì ohun tí Ọlọ́run ní fún wa ní ọwọ yìí. O ti fi Ọlọ́run hàn wa bí Oninkan àti Olúwa ayé. Àwọn tí wọn gba A, yóò jẹ àǹfààní pé èṣù, ẹṣẹ àti àwọn ikọ rẹ ko ni jọba lé wọn lórí. Bi a ti n tẹsiwaju nínú ọwọ yìí, ẹ jẹ ki a ni i lọ́kàn pé, Baalẹ gbogbo orílẹ̀ èdè ni a gbọ́dọ̀ náà sìn títí ayé ni ọna ti o tọ. A gbàdúrà pé a ko ni kùnà nínú èyí! Àmín.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KEJI

Mon. 20: Sátánì Ole Náà (Lk. 4:6; Jhn. 10:10)

Tue. 21: Apànìyàn Ni Sátánì (Jhn. 8:44)

Wed. 22: Sátánì; Olupilẹsẹ Ohun Búburú / Ibi (Mat. 9:33)

Thur. 23: Sátánì Olufurugbin Ohun Búburú (Mat. 13:39)

Fri. 24: Ègbé Ayérayé Ní Ti Sátánì (Ifih. 20:7-10)

Sat. 25: A Gbọ́dọ̀ Kọju Ija Si Sátánì (Efe. 4:7; Jak. 4:27).

Leave a Reply