OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO ÌJỌ APOSTOLI KRISTI ỌJỌ́ AJÉ, OSU KINI 20, 2020 ÀKÒRÍ: Ó Ń PADÀBỌ̀

By | January 19, 2020

OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO ÌJỌ APOSTOLI KRISTI ỌJỌ́ AJÉ, OSU KINI 20, 2020 ÀKÒRÍ: Ó Ń PADÀBỌ̀

OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO
ÌJỌ APOSTOLI KRISTI
ỌJỌ́ AJÉ, OSU KINI 20, 2020
ÀKÒRÍ: Ó Ń PADÀBỌ̀
KA: MÁÀKÙ 13:35-36

ÀKÓSÓRÍ:
Nítorí náà, ẹ máa sónà, nítorí ẹyin kò mọ ìgbà tí baálé ilé ń bọ̀ wá, bí ní alẹ ni, tàbí ní ọ̀gànjọ́, tàbí ní àkùkọ, tàbí ní òwúrò: pé nígbà tí ó bá dé ní òjijì, kí ó mase bá yín ní ojú oorun (Máàkù 13:35-36)

ÌTÚPALẸ̀
Ẹni ńlá ni, Dwight L. Moody máa ń sọ pé “Èmi kì í wàásù kan láìní lọ́kàn pé Jésù lè dé kí n tó tún wá òmíràn. Omowe G. Campbell Morgan,_gbajugbaja ìránsẹ́ Ọlọ́run ní ilè gẹ̀ẹ́sì sọ pé _”Èmi kì í bẹ̀rẹ̀ isẹ mi laaro laironu pé bóyá ó lè yí isẹ mi padà, kí ó sì bẹ̀rẹ̀ tiRẹ̀. Èmi kò wona fún ikú sugbọn mo ń wona fún Òun” bí ó se yẹ kí Kristẹni ó máa gbé ìgbé ayé rẹ ni èyí ní rireti bíbọ̀/wíwá Jésù Kristi ní gbogbo ìgbà!
Bí a bá lè máa gbé lojoojumo bí i pé ó lè jẹ́ gbígbé inú ayé fún ìgbà kẹ́yìn ni èyí kí idajo ìkẹyìn ó tó dé, ìyàtọ̀ ńlá ni yóò jẹ lórí ilẹ̀ ayé nihin! Sugbọn a kìí fẹ́ ronú bẹ́ẹ̀ yẹn. A kì í fẹ́ máa ronú pé àwọn ètò wa tí a ti se dáradára àti isẹ́ tí a là kalẹ ní ọjọ́ tí ó pé ni, fèrè Ọlọ́run lè yí padà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò sọ pé “òpin ayé kò kúkú tíì dé báyìí; nítorí náà kilo dé tí a fi ń ronú nípa rẹ̀? Ó sì lè tó ẹgbẹ̀rún ọdún síi”
Jésù ń padàbọ̀, sugbọn kò sí ẹniti ó lè sọ àkókò náà (Mk. 13:35). Nígbà tí Ó ń gòkè re ọrun, Ó sèlérí pé Òun yóò padà wá fún àwọn tí wọn jẹ́ t’oun, àwọn ènìyàn mímọ, ìjọ, àwọn ìyàwó Rẹ. Ó ti sèlérí pé Òun yóò padà wá láti wá kó wa lọ ilé wa tí a ti pèsè sílè fún wa ní ìjọba ayérayé Rẹ (Jhn. 14:1swj). Máse dúró kí ọjọ́ ó lọ tán kí o tó máa múra, irú èyí léwu, nítorí ìwọ kò mọ ìgbà tí àkókò ìkẹyìn náà yóò jẹ́. Kilo dé tí o kò gba Jésù ní Olúwa àti Olùgbàlà rẹ nísinsìnyí, kí o ba á lè ní ìrètí ọrun, kí o sì setan láti kéde ìhìn rere ìjọba náà?

ÀWỌN KÓKÓ ÀDÚRÀ
1. Olúwa mo béèrè fún oore ọ̀fẹ́ tí yóò mú mi laaja títí dé òpin ní orúkọ Jésù.
2. Ẹ̀mí mímọ́ ran gbogbo wa lọ́wọ́, àwọn olórí, àti ọmọ ẹ̀yìn, kí dídé ọrun ó lè ká wa lára ju kíkó ọrọ̀ ayé jọ, kí a má bàá sọ ẹ̀mí wa nù.
3. Olúwa, jẹ́ kí àwọn àga ìwàásù kún fún ìwàásù ipadabo Kristi léèkejì leekan síi ní orúkọ Jésù.

ÀFIKÚN IBI KÍKÀ FÚN ÒNÍ: Genesisi 41-42 àti Mátíù 20

Leave a Reply