OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO ÌJỌ APOSTOLI KRISTI ỌJỌ́BỌ̀ , OSU KINI 23, 2020 ÀKÒRÍ: AYỌ̀ ÌDÁRÍJÌ

By | January 23, 2020

OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO ÌJỌ APOSTOLI KRISTI ỌJỌ́BỌ̀ , OSU KINI 23, 2020 ÀKÒRÍ: AYỌ̀ ÌDÁRÍJÌ

OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO
ÌJỌ APOSTOLI KRISTI

ỌJỌ́BỌ̀ , OSU KINI 23, 2020

ÀKÒRÍ: AYỌ̀ ÌDÁRÍJÌ

KA: ORIN DÁFÍDÌ 32:1-11

ÀKÓSÓRÍ:
Ìbùkún ni fún àwọn tí a dárí aisedeede wọn jì tí a bo ẹsẹ wọn mọ́lẹ̀ (Orin Dáfídì 32:1)

ÌTÚPALẸ̀
Ọba Dáfídì náà dẹ́sẹ̀ bíi ẹnikẹ́ni nínú wa. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí “elekee/opuro” “apànìyàn” àti “panságà” ni ó farahàn lára àwọn ẹsẹ tí ó dá. Ó mọ bí àwọn ohun aidara yìí ti yọ ibasepo òun àti Bàbá ọrun lénu tó. Kò bó lọ́wọ́ àáké ìdájọ́, àwọn àbájáde àwọn ẹsẹ rẹ. Ó rí idakeji Ọlọ́run (wo òwe 16:5).
Sugbon nínú rẹ̀ a rí ìfẹ́ láti ronupiwada àti jewo àwọn ẹsẹ rẹ, pẹ̀lú ìpinnu/ìlérí pé òun kò ní padà sínú wọn mọ́. Ohun ìyanu há a ni pé Dáfídì kó ọrọ̀ àkọ́kọ́ Orin Dáfídì 51 bí? Ǹjẹ́ a há a lè dáa lebi fún tí tọ́ka sí ẹniti a dárí jì (niti èyí, ara rẹ) gẹ́gẹ́ bí “ẹni ìbùkún” tàbí “ẹni ayọ̀?” Bíbélì “Amplified” sàlàyé ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí alábùkún fún gẹ́gẹ́ bí AYỌ̀, órí ire ẹni tí a lè jowú. Ó dà bíi pé àkọsílẹ̀ àwọn ẹsẹ ti lọ sí òkun ìgbàgbé, títí láé tí a kò sì tún ní sí ìwé kàn án mọ́.
Finuro ìmọ̀lára ẹsẹ tí a dárí jini. Ǹjẹ́ ó lè ní ìmọ̀lára òmìnira àti ìdùnnú tí ó mú wá? Abala tí ó dára jù lọ nínú òtítọ́ yìí ni àbájáde ìyípadà tí yóò ní láàrín elese àti Olùgbàlà, ibarasoro ọtun, ìrírí oore ọ̀fẹ́ ọtun, àti àánú láti rọ́pò ẹbi àti ìtìjú. Abájọ tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn náà sọ pé, Ẹniti o bo ẹsẹ rẹ mọ́lẹ̀ kì yóò se rere, ẹniti o jewo rẹ tí ó sì kọ̀ ọ́ sílè yóò rí àánú gbà (Òwe 28:13). Òye èyí yé Dáfídì dáradára (O. D. 32:3,5) bẹẹni Olúwa wa sọ fún wa nípasẹ̀ Jòhánù olufe láti jewo ẹsẹ wa, kí a sì máa gbádùn ayọ̀ àti ẹwà ìdáríjì (1Jhn 1:8-10)
Olufe ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a jewo ẹsẹ wa kí a sì ronupiwada. Tí a bá sì ti fi òtítọ́ inú àti òdodo se èyí, a gbọ́dọ̀ gbà pé wọn ti lọ pátápátá, Bàbá ti dárí jì. Nígbà náà ni a ó wà nínú ayọ̀ ìfẹ́ Rẹ̀ tí a ó sì yọ àyọ̀ didí ẹni iwenumo àti ẹni mímọ́.

ÀWỌN KÓKÓ ÀDÚRÀ
1. Lọ síwájú Ọlọ́run kí o sì sọ fún Un nípa àwọn ẹsẹ tí o ti ń ní ìdálẹ́bi nípa rẹ̀ pé kí Ó sì tú ọ sílè kúrò nínú ẹ̀bi.
2. Bàbá mi ọ̀run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ fún ìdáríjì àwọn ẹsẹ mi.
3. Gbàdúrà fún àwọn orílẹ̀ èdè àti àwùjọ tí wọn ti fún ní ìdáríjì ní gbogbo àgbáyé, pé wọn kò ní tún si anfaani yìí lo.

ÀFIKÚN IBI KÍKÀ FÚN ÒNÍ: Genesisi 47-48 àti Mátíù 23

Leave a Reply