ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI LAGBAYE. OMIYE NÁÀ Ọjọ Iṣẹgun March 17, 2020 :- ṢIṢẸ́ IFẸ ỌLỌ́RUN BI WỌN TÍ Ń ṢE NÍ Ọ̀RUN

By | March 17, 2020

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI LAGBAYE. OMIYE NÁÀ Ọjọ Iṣẹgun March 17, 2020 :- ṢIṢẸ́ IFẸ ỌLỌ́RUN BI WỌN TÍ Ń ṢE NÍ Ọ̀RUN

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI LAGBAYE.
OMIYE NÁÀ
Ọjọ Iṣẹgun (Tuesday), March 17, 2020.

ÀKÒRÍ: ṢIṢẸ́ IFẸ ỌLỌ́RUN BI WỌN TÍ Ń ṢE NÍ Ọ̀RUN

Ka Mátíù 6:9,10

AKỌSORI
Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa, ẹyin áńgẹ́lì Rẹ, tí o pọ ni ipa tí ń ṣe òfin Rẹ, tí ń fi etí si ohun ọrọ Rẹ (Orin Dáfídì 103:20)

ITUPALẸ
Ni ọpọlọpọ ìgbà ni a máa ń gba “Àdúrà Olúwa” lai kíyèsí pé ó ṣe e ṣe kí a jẹ alágàbàgebè tàbí kí a jẹ ẹni tí o mọ tí ara rẹ nìkan! O da bí ẹni pé a ko mọ ohun tí a ń béèrè, bí ko ba ṣe bẹ́ẹ̀, kí lo de tí a ko ti máa ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ gẹgẹ bí wọn ti n ṣe ni ọrun? A kò mọ ìfẹ́ Rẹ̀, bí o tilẹ jẹ pé a kọ ọ sínú ọrọ Rẹ ru a sì ń gbọ́ ọ láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ Rẹ. Àwọn áńgẹ́lì ko lọ́ra láti dáhùn sì ìpè Ọlọ́run — Wọn máa ń yàrá, wọn kii si wi awawi tàbí kí wọn fi falẹ, bí ó ṣe wu ki ìṣẹ́ náà jẹ, yàtọ̀ sí bí àwa ṣe ń ṣe níhìn-ín. Ẹ jẹ ki a wo bi Áńgẹ́lì Gabriẹli ṣe ba Balogun Persia wọ ìjàkadì fún ọjọ́ mọ́kànlélógún (Dan. 10:13; wo Eks. 23:23; Isa 37:36). Bóyá a ṣi n sọ pe a ko mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, nígbà náà:
✔ Rin nínú Rẹ. Èyí ni nípa nini ibasepọ pẹ̀lú Rẹ. Jíjẹ Kristẹni jẹ nini ibasepọ.
✔ Jọ̀wọ́ ìfẹ́ tìrẹ fún Ọlọ́run. Ní ọpọ ìgbà, a máa ń fẹ́ láti fi etí sí ero ọkàn wa ki a si ṣe ohun tí Ó fẹ́. A gbọ́dọ̀ fi ara jí láti gbọ́ràn sì ohun yòówù tí àṣẹ Rẹ bájẹ.
✔ Gbọ́ràn sì àwọn ohun yòówù tí o ba ti mọ tẹ́lẹ̀ pé wọn jẹ ìfẹ́ Ọlọ́run. Èyí wa ninu ọrọ Rẹ ti O fi fún wa.
✔ Mọ ìṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ. Ṣé àwárí eredi tí a fi da ọ sí àyè kí o sì gbìyànjú láti mú un ṣẹ (I Pet. 4:10).
✔ Fi etí sí ẹmi Ọlọ́run, fi ara balẹ láti gbọ bí Ọlọ́run ti ń ba ọ sọ̀rọ̀ (Jn. 10:27).
✔ Fi etí sí ọkàn rẹ, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ to ń lọ lọ́wọ́ (O. D. 37:4,5; Ìṣe 16:6-10). Ṣé àkíyèsí àwọn ilẹkun tí o si tàbí èyí tí o ti gẹgẹ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gba ba ọ sọ̀rọ̀.
O jẹ òun ti o ṣeni láàárín pé onigbagbọ nínú Kristi lóde ooni fẹ́ràn láti máa ṣe ohun tí àwọn ọga wọn, ọkọ wọn, ọrẹ wọn abbl., kí wọn le ri ère goboi gba. Ìfẹ́ Ọlọ́run ń bere fún igbesẹ kíákíá wa, ìgbọràn ni pípé, iwa mimọ láti inú wa wá àti ara wa. Àwọn áńgẹ́lì fẹ́ràn láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀run, gẹgẹ bẹẹ ni àwọn gbọ́dọ̀ ṣe. O ko ni gbé ìgbé ayé tí o kere sì ìrètí Rẹ lórúkọ Jésù Àmín.

ÀWỌN KÓKÓ ÀDÚRÀ
1. Oluwa, rán mi lọ́wọ́ kí n le ni ibasepọ tí o dán mọran pẹ̀lú Rẹ, ki ayé mi ma bàa parí si ìparun.
2. Oluwa, rán ìjọ lọ́wọ́ láti máa gbé ìgbé ayé tí o ba ìjẹwọ rẹ mu.
3. Baba, dárí àwọn olórí wa si ọna ti o tọ, ki O si fún wọn ní etí igbọ, kí wọn mọ baa sì àwọn àgùntàn lọ́nà.

ÀFIKÚN IBI KÍKÀ FÚN ONI: Númérì 36, Deuteronomi 1 àti Jòhánù 10

Leave a Reply