MÁNNÀ OJOOJÚMỌ́ ỌJỌ́ ÀBÁMẸ́TA FUN 28, OṢÙ KẸ́TA, ỌDÚN 2020 : AKORI – ÌBẸ̀RÙ ALÁÌNÍDǏ

By | March 28, 2020

MÁNNÀ OJOOJÚMỌ́ ỌJỌ́ ÀBÁMẸ́TA FUN 28, OṢÙ KẸ́TA, ỌDÚN 2020 : AKORI – ÌBẸ̀RÙ ALÁÌNÍDǏ

MÁNNÀ OJOOJÚMỌ́

ỌJỌ́ ÀBÁMẸ́TA 28, OṢÙ KẸ́TA, ỌDÚN 2020

ÌBẸ̀RÙ ALÁÌNÍDǏ

IBI KÍKÀ: GẸ́NẸ́SÍSÌ 12:10-20

ẸSẸ̀ WÚRA: ” Nitorina yio si ṣe, nigbati awọn ara Egipti yio ri ọ, nwọn o wipe, aya rẹ̀ li eyi: nwọn o si pa mi, ṣugbọn nwọn o dá ọ si ” (GẸ́NẸ́SÍSÌ 12:12).

Abrahamu, ẹni ti o fi ile baba rẹ silẹ nipasẹ igbagbọ ni o ṣe aniyan nitori ìyàn. Dípò ti o fi yẹ ki o tọ Ọlọrun lọ ninu adura lait le mọ igbesẹ ti o yẹ ki o gbe tabi ibi ti o yẹ ki o lọ, o mu irin-lọ si Ilẹ egyipti. Nigba ti o wọ ilu Egyìti, o bẹrẹ si ni bẹru, o si gberu ọgban kan lati daabo bo ara rẹ.

Eredi ibẹru rẹ ni wipe o ṣeenṣe ki awọn ara Egyipti gbe oun pa nitori iyawo rẹ. Nitorinaa, o pinnu lati fa iyawo rẹ le wọn lọwọ lati gba ẹmi rẹ la. Ibẹru rẹ jẹ alaini’di. O parọ lati ri oju-rere gba dipo iyawo rẹ. Ọlọrun ni lati gbe igbesẹ nipa mimu idajọ de ba Farao ati idile rẹ. household.

Ọmọ eniyan a ma fi aye gba awọn ibẹri lainidi, eyi ti ma n yọri si irora. Ibru a ma sọ igabgbọ wa di akurẹtẹ, igba miran a si ma mu awọn iṣoro ti n dari si wahala ti o ga ju agbara wa lọ. Ibẹru ọjọ-ọla jẹ eyi ti o ṣe olubori ninu awọn ohun ti nfa idayafo ati àníyàn ninu aye ọmọ-eniyan. O yani lẹnu wipe, ọpọlọpọ awọn ibru ti a n fi aye gba ninu ọkan wa ko ni eredi kan-tabi omiran. A si ti fi idi rẹ mulẹ wipe ibẹru ti awọn eniyan gbe lọkan jẹ awọn ohun ti ko lee wa si imuṣẹ.

Bi o ba ṣe aniyan nipa ohun kan, fi le Oluwa lọwọ pẹlu igbagbọ, ki o si fi silẹ sibẹ. Abrahame gbagbe ipe Ọlọrun ninu aye rẹ, o si lọ si ilẹ Egyipti lai wa oju Ọlọrun fun aiye ati idari. Bakan naa ni o gbagbe wipe Ọlọrun le e pese fun gbogbo awọn aini rẹ lakoko ìyàn nibi-kibi ti o ba fi ṣe ibugbe.

Màa fi igba-gbogbo ranti wipe o jẹ iyebiye lọwọ Ọlọrun, ki o si gbẹkẹ rẹ lee lakoko aini, lakoko ti oko owo o ṣe deede, lakoko aniyan, lakoko aisan ati iṣoro. Nigba ti awọn ipenija aye ba n dojukọ ọ, mu ọkan le, nitori wipe Ọlọrun yoo gba ọ la. (Ìsàíàh 35:4).

ÀṢÀRÒ FÚN GBOGBO ỌJỌ́ ÒNÍ: Mu ọkan le, ma ṣe bẹru, Ọlọrun yoo Gba ọ La

Kíka Bíbélì TÁN LỌ́DÚN KAN
: DEUTERÓNÓMÌ 28 – 30

Leave a Reply