ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ.  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN OJO August 2 àti 9, 2020 : ÀKÒRÍ – ÌṢỌ̀KAN NÍNÚ ÌṢẸ̀DÁ

By | August 9, 2020

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ.  Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN OJO August 2 àti 9, 2020 : ÀKÒRÍ – ÌṢỌ̀KAN NÍNÚ ÌṢẸ̀DÁ

KA EKO ATIYIN WA NI BI

ÀKÒRÍ: ÌṢỌ̀KAN NÍNÚ ÌṢẸ̀DÁ

AKỌSORI

Nípa ìgbàgbọ́ ni a mọ pé a dá ayé nípa ọrọ Ọlọ́run; nítorí náà kì ìṣe ohun tí o hàn ni a fi da ohun tí a n ri

(Hébérù 11:3).

A rí ìṣọ̀kan Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan bi a ti ṣafihan rẹ ni kíkún nínú Ìṣẹ̀dá paapaa julọ, nínú ìṣẹ̀dá ènìyàn.

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ

Oye ẹ̀dá ènìyàn gba pe ìṣẹ̀dá wà àti nítòótọ́ Ẹlẹ́dàá wa bákan náà. Nípa ìfihàn àtọ̀runwá nìkan ni a fi mọ bí ìṣẹ̀dá náà ṣe rí. Èyí ni nípa ìgbàgbọ́ wa nínú Ẹlẹ́dàá nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ (wo Gen. 1:1; O.D. 33:6; Jhn. 1:3; Héb. 1:2). Ìgbàgbọ́ ni ijẹri àwọn ohun tí a ko ri (Héb. 11:1). Nípasẹ̀ imoye tí ẹmi nìkan ni a le fi mọ àwọn òtítọ́ tí ìṣẹ́daa láti ípàsẹ Ọlọ́run, tí ki sì ìṣe nípasẹ̀ ìyípadà tàbí èyíkéyìí ohun tí ayé ń sọ. Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nìkanṣoṣo ni a le ni oye isọkan ti o ṣẹlẹ̀ nínú Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan nínú Ìṣẹ̀dá.

O báni-nínújẹ pé ayé faramọ ọrọ iyirapada láti iri kan sì òmíràn, ẹ̀kọ́ tí o ń bu ìṣẹ̀dá ènìyàn ni ọla ku láti ipere pe a da a tẹru-tẹru àti tiyànu-tiyanu láti òkè wa si ipele pé ènìyàn jẹyọ láti ara ẹranko. Irú iye rírà wo ni èyí!. Ko si òtítọ́ là kankan ju ohun tí Ìwé Mímọ́, Ọrọ Ọlọ́run, tí jẹ ki o ye wa lọ: pe Ọlọ́run gbogbo wà nípasẹ̀ Ọrọ Ọlọ́run àti agbára Rẹ (Jhn. 1:3). Báwo ni o ti ṣe e ṣe? Ọlọ́run sọ ọrọ náà nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ, Ìyẹn ni pé, O rán Ọrọ Rẹ jáde, a si da ohun gbogbo. Àwọn onigbagbọ gbọ́dọ̀ mọ wi pe àwọn ẹlẹgan yóò wa lati fẹ́ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ifẹkúfẹẹ alaiwa-bi-Ọlọ́run wọn, wọn yóò ṣe agbára Ọlọ́run, bi a ko ba si kiyesara wọn yóò gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ kúrò lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wọn (wo 2 Tim. 3:4,5; 2 Pet. 3:3; Júdà 1:18). Ọrọ náà sì jẹ imọlẹ kanṣoṣo síbẹ̀ nípasẹ̀ èyí tí a fi le di òmìnira kúrò lọwọ onírúurú àwọn olùkọ́ èké àti àwọn ẹ̀kọ́ wọn. Máa ka Bíbélì rẹ kì o sì mọ ọn dojú amí!

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ

Mon.   July 27: Ọlọ́run, Ìyanu Ní Ìṣẹ́ Rẹ (O.D. 139:14b)

Tue.    July 28: Ọlọ́run Ṣẹda Ọrun Òun Ayé (Gen. 1:1).

Wed.   July 29: Ọlọ́run, Nípasẹ̀ Ọgbọ́n Ní O Fìdí Ayé Sọlẹ (Òwe. 3:19a)

Thur.   July 30: Ọlọ́run Ṣẹda Wa Tẹru-tẹru Àti Tiyanu-tiyanu (O.D.139:14a)

Fri.      July 31: Ọlọ́run Ṣẹda Ohun Gbogbo Nípasẹ̀ Jésù (Jhn. 1:3)

Sat.     Aug. 1:  Ọlọ́run Ìṣẹ́ Rẹ Ti Pọ Tó (O.D. 104:24).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN

1.  Ọlọ́run wa Mẹ́talọ́kan / Ológo mẹta jẹ ìyanu! Ẹnì tí a ko da, tí O da ohun gbogbo nípasẹ̀ ọgbọ́n àti agbára Rẹ.

2.    Ọlọ́run jẹ́ mẹ́talọ́kan. Kí i ṣe pé àwọn Kristẹni ń sìn oríṣii Ọlọ́run mẹta, bikoṣe Mẹ́talọ́kan nínú isọkan àti isọkan nínú Mẹ́talọ́kan. Lilo ọpọ fún Ọlọ́run ń sọ tí isọkan Ọlọ́run-Mẹ́talọ́kan, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nìkan sì ni òye èyí fi le ye wa.

3.   Ènìyàn tìkálara rẹ jẹ ẹ̀dá ónípa-mẹta: O jẹ ẹ̀mí, o ni ọkàn, o si n gbe nínú agọ ara (I Jhn. 5:8). Èyí jẹ àpẹẹrẹ látàrí pé a da wa ni ìrì tí Ọlọ́run.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : Jhn. 17:20-24; Rom. 12:4,5; Gal. 3:26-28

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA

ILEPA:  Láti fihàn pé ayé àti àwọn ẹkùn inú rẹ gbogbo jẹ ìṣẹ́ ọwọ ìṣẹ̀dá elerongba tí Ọlọ́run fún ogo Rẹ.

ÀWỌN ERONGBA: Ní òpin ẹ̀kọ́ yii, ìrètí wa ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ le:

i.   Sàfihàn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá ayé àti gbogbo ẹkùn ohun inú rẹ gbogbo.

ii.  Sàfihàn pé a ṣẹda ènìyàn lọ́nà ara ọtọ ni iri Ọlọ́run.

iii. Sàfihàn ìdí tí Ọlọ́run fi pinnu láti ṣẹda ohun gbogbo àti ènìyàn pẹ̀lú ni atetekọṣe; àti

iv. Sàfihàn imọrírì Ọlọ́run púpọ̀púpọ̀ fún iṣọwọ-ba-eniyan-lo Rẹ lọ́nà ara ọtọ láàrín àwọn ẹ̀dá yòókù.

IFAARA

ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: GENESISI 1:1-31; 2:7; ORIN DÁFÍDÌ 8:1-9; 19:1-6; 103:5, 19; 104:21,24; 107:9; 139:13-15; 148:1-14; ÒWE 3:19-20.

A fi ẹ̀mí imoore wa hàn sí Ọlọ́run fún atilẹhin Rẹ ti a jẹ̀gbádùn nínú ìṣẹ́ ìránṣẹ́ ọrọ Rẹ. Ẹ̀kọ́ kinni fún saa yii, “July sì December,” ọdún 2020, ÌṢỌ̀KAN MẸ́TALỌ́KAN, ní a parí ni ọsẹ tó kọjá nínú èyí tí a kíyèsí ohun tí Mẹ́talọ́kan dálè lórí, àwọn amuyẹ Ẹni tí Mẹ́talọ́kan ìṣe, àti ibasepọ àti ìṣẹ́ to dámọ̀ràn láàrin mẹ́talọ́kan náà. Bákan náà ni a wo ipa ti wọn ko fún ìràpadà àti ìgbàlà wa. A gbàgbọ́ wí pé a ti di alábùkún fún nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ náà.

Ẹ̀kọ́ kejì yii nínú ọwọ́ yii ni a pe akori rẹ ni ÌṢỌ̀KAN NÍNÚ ÌṢẸ̀DÁ. Nihin yii, a o maa jíròrò lórí ikopa tí Igbimọ Mẹ́talọ́kan nínú ìṣẹ̀dá Ọ̀run àti láyé àti gbogbo ẹkùn inú wọn (Gen. 2:1), fún ìtura ènìyàn àti fún Ògo Ọlọ́run. Bíbélì kọ wa nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn, bí a ti dá ènìyàn àti bí a ti fi oore-ọ̀fẹ́ fi sínú ayé tí Ọlọ́run dá, kí iṣe nípasẹ̀ ìràpadà láti iri kan sì òmíràn tàbí èyíkéyìí igbimọran èké míràn.

Ọlọ́run ti ṣètò ẹ̀kọ́ yii lati fún wa ní isiniye lórí bi Mẹ́talọ́kan tí fi ìmọ̀ sọ́kàn da àwọn ọrùn àti ayé, tí wọn sì da ènìyàn ni àwòrán Ọlọ́run. Bákan náà ni o tún jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ti ko ṣe e da dúró láti rán wa lọ́wọ́ kí a le ni òye tó jinlẹ ni ti erongba Rẹ fún ṣíṣẹda gbogbo ohun tí O da. Kí Ọlọ́run fún wa lágbára láti mọrírì ìfẹ́ Rẹ̀ tó jẹ́ ara ọtọ fún wa nípa yíyọndá ayé wa fún Jésù Kristi pátápátá. Àmín.

IFAARA ṢÍ ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN

A pín ẹ̀kọ́ yii si ìpín méjì, I àti II. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpín wọ̀nyí ni a tún pín sí ipa A àti B.

ÌPÍN I: ÌṢẸ̀DÁ: NÍ ATETEKỌṢE

Ìpín yii ṣagbekalẹ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá ayé. Ipa A ń ṣàlàyé ọ̀nà tí Ọlọ́run gba da ayé láti inú ofo. Bákan náà ni o n fi idi òtítọ́ náà múlẹ̀ pé Ọlọ́run ṣe èyí nípasẹ̀ ọgbọ́n Rẹ, èyí tí o tako ọrọ asán ti ìràpadà láti ìrí kan sì òmíràn tí àwọn ònímọ́ sayẹnsi ń sọ kiri. Ipa B ń sọ tí títóbi ọlanla Rẹ nínú ṣíṣẹda ènìyàn ni àwòrán Rẹ, èyí tí a da tẹru-tẹru, tiyanu-tiyanu àti onipa mẹta.

ÌPÍN II: ÌṢẸ̀DÁ: ERONGBA NÁÀ.

Ìpín yii n ṣàlàyé àwọn erongba Ọlọ́run nínú èyí tí a ti rí ògo Rẹ, ìyìn Rẹ ati Ọla Rẹ, gẹ́gẹ́ bi O ti gbọna ara ọtọ ṣẹda ènìyàn ni “àwòrán wa” tí Ó sì fi ìtọ́jú àti ìpèsè ara ọtọ Rẹ kẹ ẹ láti ṣojú Rẹ ni mímú àwọn erongba Rẹ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé nihin-in. A gbàdúrà pé a o ni ja A kulẹ mọ!

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́

I.   ÌṢẸ̀DÁ: NÍ ATETEKỌṢE

A.  ỌLỌ́RUN ṢẸDA AYÉ

B.  ỌLỌ́RUN DA ÈNÌYÀN NÍ ÀWÒRÁN ‘WA’

II.  ÌṢẸ̀DÁ: ERONGBA NÁÀ

A.  ERONGBA ỌLỌ́RUN NÍNÚ ÌṢẸ̀DÁ

B.  ÌTỌ́JÚ TÍ ỌLỌ́RUN PÈSÈ FÚN ÈNÌYÀN

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́

I.   ÌṢẸ̀DÁ: NO ATETEKỌṢE (Genesisi 1:1-31; 2:7; Orin Dáfídì 148:5; 104:24; 139:13-15; Òwe 3:19-20).

Ìṣẹ̀dá jẹ igbesẹ Ọlọ́run ti ó mu ayé gbogbo ẹda alààyè wà. Wiwo bí Ọlọ́run ti ṣẹda ayé nìkan kọ́ ni a ń ṣe nihin yii. A ní láti kọ àwọn ẹ̀kọ́ nípa bi Ọlọ́run ónìṣọkan tí wọnú pípé ayé láti wa àti dídá ènìyàn ni àwòrán ara Rẹ.

A.  ỌLỌ́RUN ṢẸDA AYÉ (Gen. 1:1-31; O.D. 148:5; 104:24; Òwe 3:19-20).

Jẹ ki wọn kì o máa yin orúkọ Olúwa; nítorí tí Òun pàṣẹ, a sì dá wọn (O.D. 148:5).

i.   Ki a to da ayé ni atetekọṣe, Ọlọ́run ti ń bẹ láti ayérayé de ayérayé. Òun ko ni ìbẹ̀rẹ̀ bẹẹ ni ko ni opin (O.D. 90:2)

ii.  Gen. 1:1: “Ní atetekọṣe, Ọlọ́run da ọrùn òun ayé” Ọrọ Hébérù náà ‘bara’ túmọ̀ si “láti ṣẹda”. Ọlọ́run pàṣẹ, a si da àwọn ọrùn àti ayé, àti gbogbo ẹkùn inú wọn (Gen. 2:1; O.D. 148:5).

iii. 1:3-25; Heb. 11:3: fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé Ọlọ́run ṣẹda ohun gbogbo tí a ń rí lonii yii lati inu “òfo” (exnihilo). Fún ọjọ́ mẹ́fà, O da àwọn èwebẹ àwọn igi eléso, ofurufu àwọn ẹranko, ẹja, ẹyẹ abbl., O si sure fún wọn láti máa bí sii kí wọn sì máa rẹ sii. Bákan náà ni O ṣẹda oòrùn, òṣùpá àti àwọn irawọ, fún àmì, igba/àkókò, ọjọ́ àti ọdún.

iv.  Ṣọ́ra fún àwọn ẹ̀kọ́ èké ni ti “iparada/ìyípadà” tí ko tẹ́wọ́gba gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa Ìṣẹ̀dá. Bi o ba jẹ pé ènìyàn jáde/parada láti ara nnkan kan ni, kilo de tí ko fi tún ti da/parada sì ìrí miran láti ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún tí o ti wà?

v.  Ìṣọ̀kan tí Mẹ́talọ́kan ni a rí nínú ìṣẹ́ ìṣẹ̀dá, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin (Jóòbù 26:13; Jer. 10:12-13; Jhn. 1:13; Kol. 1:16). Ọrọ náà jẹ àṣẹ nípasẹ̀ Ẹniti Ọlọ́run ṣẹda ohun gbogbo.

vi. O.D. 104:24; Òwe 3:19-20: Olúwa fi ọgbọ́n ṣagbekalẹ ayé. Ọlọ́run ṣe agbekalẹ eto àti pàtàkì wíwà láyé ohun gbogbo ni ọnà ara ọtọ débi pé ko si ẹ̀dá ènìyàn tàbí ẹ̀mí kan tí o le ronú rẹ. Ǹjẹ́ ìwọ gbà Á gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí títóbi julọ lórí ayé rẹ bí?

vii. A ko le pe agbára ìṣàkóso gíga julọ Ọlọ́run lórí gbogbo ẹda nija. O n jọba O n ṣàkóso, O n yanni-sipo, O n yọni-nipo bẹẹ ni O si n ṣe àbójútó ohun gbogbo àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú. Máṣe dúró de ìrírí tó burú jáì gẹ́gẹ́ bi tí Nebukadinésárì kí o to gba títóbi julọ Rẹ. (Dan. 4:14-16).

B.  ỌLỌ́RUN DA ÈNÌYÀN NÍ ÀWÒRÁN ‘WA’ (Gen. 1:26-27; 2:7; O.D. 139:13-15)

Èmi o yín Ọ; nítorí tẹru-tẹru àti tiyanu-tiyanu ni a dá mi: ìyanu ní ìṣẹ́ rẹ; eyini, ní ọkàn mi sì mọ dájúdájú (O.D. 139:14)

i.   Gen. 1:26,27: Jẹ ki a da ènìyàn ni àwòrán Wa’. A kò dá wa ni àwòrán àwọn áńgẹ́lì tàbí tí àwọn ogun ọrùn bikoṣe ni ìrí tí Mẹ́talọ́kan… ‘àwòrán Wa’. Fún ìdí èyí, Ìwé Mímọ́ pè wa ni Kristẹni, ọlọ́run kéékèèké (O.D.82:6; Jhn. 10:34-35; I Jhn. 5:8).

ii.   2:7’… ènìyàn sì di alààyè ọkàn’. Kò dabi àwọn ẹ̀dá mìíràn tí O lo ọrọ àṣẹ láti ṣẹda wọn (O.D. 148:5), Ọlọ́run ṣẹda ènìyàn láti inú erupẹ ilẹ̀, O si mi èémí iye sì ihò imú rẹ, ènìyàn si di alaye ọkàn.

iii. A ṣẹda ènìyàn pẹ̀lú imọ tí o ga, àti òye tó gbòòrò, ìwà mimọ, ailẹṣẹ pẹ̀lú iwa pípé, tí o dùn-un wo pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìmọ̀lara. Èyí ni ìrí Ọlọ́run nínú ènìyàn. Laipẹ jọjọ, a o ri I gẹ́gẹ́ bí O ti ri, a o si dabi Rẹ (I Jhn. 3:2).

iv.  O.D. 139:13-15: “… nítorí tẹru-tẹru àti tiyanu-tiyanu ni a da mi”. Ọlọ́run da ènìyàn tẹ́rù-tẹ́rù gẹ́gẹ́ bi olórí àti alákòóso gbogbo àwọn ẹ̀dá mìíràn (Gen. 1:26,28). Nítorí idi eyi Ọlọ́run fi ibẹru àti ìwárìrì ènìyàn sì gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ abiyẹ abbl, lára (Gen. 9:2; O.D. 8:6). Irú àǹfààní tí ìwọ ko gbọ́dọ̀ sílò wo ni èyí!

v.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Ọlọ́run da ènìyàn tiyanu-tiyanu. Ilóyún ko ha yanilẹnu bi? Igbesẹ ìbímọ ńkọ́, idagba, gbígbẹrusi, ìrònú, ìṣòro àti ohun gbogbo tí ènìyàn ń ni ńkọ́? Bí a ṣe ń sún àti bí a ṣe ń ji jẹ ìyanu, nítorí ọwọ ìyanu Ọlọ́run ń ṣàkóso, o si n ṣètò ayé wa.

vi. Nígbà ìṣubú, ènìyàn ba àwòrán tí atokewa yii jẹ de ààyè kan to lapẹẹrẹ púpọ̀, èyí tí o yọrísí ikú ni gbogbo àwọn ọ̀nà rẹ (Rom. 3:23). Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìpèsè Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọnà àbáyọ, gbogbo àwọn onigbagbọ nínú Jésù Kristi ni a ṣe imubọsipo ogo tí o ti sọnù náà fún (Rom. 10:9-10; Ìṣe 4:12).

vii. Ogo Édẹ́nì ni a ti wa mú bọsipo nisinsin yii nínú ọkàn àwọn onigbagbọ níní Kristi ti wọn gba A ní Olúwa àti Olùgbàlà wọn. Ìgbàlà ikẹhin ènìyàn ń bọ̀ wa/ku sì dẹdẹ, nígbà tí a o ri Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Òun ti rí (I Jhn. 3:2).

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1.  Ohun gbogbo yàtọ̀ fún ènìyàn ni a pàṣẹ ìwàláàyè wọn. Pé Òun fi sùúrù, tẹru-tẹru, tiyanu-tiyanu àti ìtara ṣẹda ènìyàn láti wa ni ẹnu ìṣàkóso ohun gbogbo jẹ oore-ọ̀fẹ́ tí a ko gbọ́dọ̀ ṣì lo.

2.  Nípa ìṣubú ọkùnrin àkọ́kọ́, gbogbo ènìyàn wa lábẹ́ ègún ẹṣẹ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí o ba le tẹ́wọ́gba ìṣẹ́ ìràpadà tí Kristi ni a o sọ dòmìnira tí a o si mu un bọsipo sì àwòrán àti ìri Ọlọ́run ki òun kì o le jogún ìjọba Ọlọ́run.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE

Báwo ni a ṣe dapọ mọ/ri bí àwòrán Ọlọ́run? Ṣé nípa ti ara ní tabi nípa ti ẹ̀mi?

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE

i.   Ko si ẹnikan tí o ri Ọlọ́run ni ojúkojú ri (akọyinsi Rẹ nìkan ni Mósè ri). Láìsí àní-àní, Ọlọ́run ń safihan ìwàláàyè Rẹ fún wa nígbà tí O wu U. Nínú Májẹ̀mú Láéláé a n pe e ni ‘ìfarahàn Ọlọ́run fún ènìyàn (Theophany).

ii.  Nítorí náà, a ko le ṣàpèjúwe Ọlọ́run nípa tara. Nítorí Òun ko fún wa ní èyíkéyìí àpèjúwe nípa Rẹ nípa ti ara.

iii. Láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú pé, fún ẹnikẹ́ni láti dapọ mọ/ri bí àwòrán Ọlọ́run, ẹni náà tí gbọ́dọ̀ fi àyè rẹ fún Jésù kí o sì ti gbà A ní Olúwa nitòótọ́. Ìgbà náà nìkan ni ẹni náà tó bẹ̀rẹ̀ ire-ije sì didapọ mọ/rírí bí àwòrán Kristi.

iv.  A gbọ́dọ̀ mọ ki a sì gbà òtítọ́ Bíbélì pé, yiyan wa jẹ láti dabi Kristi (Rom. 8:29). Èyí gbọ́dọ̀ ru wa sókè sí àfojúsùn gíga láti dà-bí-Kristi.

v.  A rí bí àwòrán Rẹ nígbà tí ohun tí Ẹmi ba jẹ wa lógún (Rom. 8:5,6; Kor. 2:14). Ẹ̀mí ní Ọlọ́run (Jhn. 4:24). A mú kí eyi rọrùn nípasẹ̀ ìkọla tí àyà (Deut. 30:6; wo Òwe 4:23).

vi. O túmọ̀ sí níní àwọn àbùdá Ọlọ́run nínú wa, àwọn amuyẹ Rẹ ti máa n ranmi, ìyẹn ni ìrírí bí Jésù nínú igbe ayé àti iwa; gbígbé igbe ayé tí a ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ti Kristi. Pọ́ọ̀lù wí pé, ẹ máa safarawe mi gẹ́gẹ́ bí èmi ti n safarawe Jésù Kristi (I Kor. 11:1; Efe. 5:1).

vii.Bakan náà ni a ní láti dabi Kristi nínú ìjìyà Rẹ, ìrẹlẹ Rẹ, ìgbọràn Rẹ ati Ògo Rẹ (wo Filipi. 1:29).

viii.A ni lati ni iru ẹ̀mí kan pẹ̀lú Kristi (wo Kol. 3:1-swj).

August 9, 2020

II.     ÌṢẸ̀DÁ: ERONGBA NÁÀ (Orin Dáfídì 8:1-9; 19:1-6; 103:5,19; 104:21; 107:9; 148:1-14).

Ọlọ́run ti O ni erongba/àfojúsùn ni a ń sin, Ẹni tí ki i ìdáwọ́lé ohunkóhun láìní erongba kan pàtó. Nitòótọ́, irú èyí ni yóò wa ni ibamu pẹ̀lú erongba ìràpadà ayérayé Rẹ. A gbọ́dọ̀ wa rí ìṣẹ̀dá nínú òye/imọlẹ yii. Dájúdájú, Oun ni O ṣẹda ohun gbogbo, àti ènìyàn pẹ̀lú, fún erongba tí Ó ti ní fún un láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ wa. Èyí ń sọ fún wa ní ti ìpèsè ìtọ́jú tí O ń fún ènìyàn. Irú Ọlọ́run àgbàyanu, tí O ní erongba rere, Ẹni tí ohunkóhun ko le ba laimura silẹ wo ni a ń sin yii!

A.  ERONGBA ỌLỌ́RUN NÍNÚ ÌṢẸ̀DÁ (19:1-6; 148:1-14)

Àwọn ọrùn ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọ́run; àti òfuurufú ń fi ìṣẹ́ ọwọ Rẹ hàn. Ọjọ de ọjọ ń fọhùn, àti òru de òru ń fi imọ han (19:1-2).

i.   Ọlọ́run da ọrùn òun ayé láti safihan ọgbọ́n Rẹ, agbára àti Ọlanla Rẹ fún ayé (O.D. 104:24; Jer. 10:12-13)

ii.  148:1,2: “Ẹ fi ìyìn fún Un gbogbo ẹyin áńgẹ́lì Rẹ”. Ọlọ́run da àwọn áńgẹ́lì kí wọn le maa fi ọlá, ògo àti agbára Rẹ hàn; láti máa yin títóbi agbára Rẹ títí láéláé.

iii. Àwọn ila 3-10: Ọlọ́run da ọrùn àti ayé láti fi títóbi àti àwọn iṣẹ́ ìyanu awamaridii Rẹ hàn fún ènìyàn. Ògo Rẹ farahàn nínú ìṣẹ̀dá. A ṣàlàyé èyí yekeyeke nínú Isa. 55:12. Ọlọ́run gbọ́dọ̀ gba gbogbo ọlá àti Ògo tí o tọ si I, nítorí pé, gbogbo àwọn ẹ̀dá Rẹ, bii oòrùn, òṣùpá, igi, àwọn odo ńlá abbl. gbọ́dọ̀ máa fogo fún Un (O.D. 96:12; 98:7-8).

iv.  Ọlọ́run da ayé níbi tí erongba àti eto Rẹ yóò ti di mímúṣẹ. O da ènìyàn ki o le maa bẹru Rẹ ki o le tẹsiwaju láti máa yin In, láti máa jọsin fún Un, láti máa pá àwọn àṣẹ Rẹ mọ, àti láti máa ṣojú Rẹ lori ilẹ ayé (O.D. 29:2; 96:9). Nítorí náà, O da wa kí a le jẹ ìdùnnú fún Un kí a sì le jẹ ẹni amuyangan sì Sátánì (Jóòbù 1:8; 2:3).

v.  Ọlọ́run dá ọrun gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi ayérayé fún ènìyàn lẹ́yìn ayé ẹṣẹ àti ìpọ́njú yii (Ifi. 14:13).

vi. Ọlọ́run da ayé gẹ́gẹ́ bí ibi ìgbáradì/imura fún ìjọba ayérayé Rẹ (Dan. 2:35-44). Ǹjẹ́ ìwọ jẹ ọmọ ìjọba (ìjọ) Rẹ nisinsin yii bi?

vii.Erongba Ọlọ́run fún ènìyàn mi Ògo Rẹ. Àti pé ohun tí o tuni lára dáadáa nitòótọ́, ní pé ohun tí o ń fi Ògo fún Ọlọ́run ní ohun tí ó dára julọ fún ènìyàn tikalara rẹ. Nítorí náà, ènìyàn gbọ́dọ̀ lakaka/jijadu láti máa ṣe ohun gbogbo tí yóò máa fogo fún Ọlọ́run. Èyí ni ohun tí a yàn wá fún. A ko ni kùnà rẹ. Àmín.

B.  ÌTỌ́JÚ TÍ ỌLỌ́RUN PÈSÈ FÚN ÈNÌYÀN (8:1-9; 103:5, 19; 104:21; 107:9).

Ìwọ mú un ìjọba iṣẹ ọwọ Rẹ; ìwọ sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ Rẹ (8:6).

i.   O.D. 8:5: “Ìwọ sì ti fi ògo àti ọlá de e ni adé”. A fún ènìyàn ni agbara lati jọba lórí ẹ̀dá gbogbo ni atetekọ̀ṣe. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, o pàdánù èyí lapakan nípasẹ̀ ẹṣẹ, òun yóò gbà á padà nígbà tí Jésù Olúwa wa bá padà dé.

ii.  103:19: 104:21; Ọlọ́run ń ṣàkóso ayé yìí fúnra Rẹ, O si n ṣètọ́jú, kódà fún àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ojú ọrùn. Bí Òun ba le maa bọ àwọn ẹ̀dá tí wọn kii ṣe ẹ̀dá ènìyàn, ìwọ ko nílò láti ṣe’yọnu (Mat. 6:26). Òun ni ifẹ ọkàn rẹ ti dára julọ lọ́kàn Rẹ (wo Jer. 29:11).

iii. O n ṣàkóso àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú ìpèsè Rẹ, O n fi ère àti ààbò fún àwọn olódodo, àti ìjìyà fún àwọn ẹni búburú (O.D. 139:14-16; 22:28, 66:7; Isa. 44:28; 45:1-4; Rom. 8:28).

iv.  Ọlọ́run ń ṣètọ́jú ohun gbogbo tó niise pẹ̀lú wa. O ni ìmọ̀lara àwọn àṣeyọrí, àti àwọn ijakulẹ wa paapaa (O.D. 139:14-16; 75:6-7; Jer. 1:5; Mat. 10:30).

v.  103:5; 107:9: Ọlọ́run ń pèsè fún àìní ẹ̀dá gbogbo, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Rẹ, gẹ́gẹ́ bí ọrọ Rẹ nínú ògo. Filip. 4:19 safihan ìgboya yii nínú òtítọ́ náà pé Ọlọ́run yóò pèsè fún gbogbo àìní wa (wo I Tim. 6:17). Si àfikún nihin yii ni òtítọ́ náà pé O n pèsè ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa (Mat. 6:7-9, 33).

vi. Bi Òun ba n ṣe ìwọ̀nyí fún ọ, kín ni ìwọ yóò fún Un?

vii. Ohun tí ìpèsè jẹ niiṣe pẹ̀lú tàbí ohun tí a gbàgbọ́ pé ọgbọ́n, ìtọ́jú, ìtọ́ni tí Ọlọ́run pèsè ni a lè fi ṣe odiwọn rẹ. Ìtọ́ni tí ìṣe ìpèsè Ọlọ́run jẹ ìtọ́ju tí Ọlọ́run Olódùmarè pèsè. O jẹ ara erongba ayérayé Rẹ fún ènìyàn. Biko bá sì ìpèsè Rẹ ni, ayé í bá ti i run tán pátápátá. Ọlọ́run Olufẹ ni yii.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1.  Ọlọ́run dá ọrùn àti ayé kí wọn kì o le maa fi ògo Rẹ, títóbi Rẹ, ọlá àti agbára Rẹ hàn níbi gbogbo. Ṣé ayé rẹ ń fogo fún Un bi?

2.  Bí ayé yìí ti burú to pẹ̀lú ìwà àìgbọràn ènìyàn, Ọlọ́run olufẹẹ ko pa ènìyàn tí, ṣùgbọ́n O n ṣe itọju rẹ síbẹ. Haleluya!

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1.  Kín ni ìyàtọ̀ láàrin ìṣẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ẹ̀dá yòókù?

2.  Kin ni ìdí tí Ọlọ́run fi wọnú ìṣẹ́ ìṣẹ̀dá àgbáyé?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ

i.    Ọlọ́run ṣẹda ohun gbogbo àti ènìyàn pẹ̀lú nípasẹ̀ ọrọ Rẹ (Jhn. 1:3; Kol. 1:16).

ii.   A ṣẹda gbogbo àwọn ẹ̀dá yòókù ṣáájú ènìyàn, èyí ni lati mú kí ènìyàn ni ìtura.

iii.  Ìṣẹ́ ni a pè àwọn ẹ̀dá yòókù jáde, kí o wà (Gen. 1:3,6), ṣùgbọ́n a mọ ènìyàn pẹ̀lú àmọ́ pẹ̀lú ìpéjọpọ Ọlọ́run mẹ́talọ́kan, àwọn mẹ́talọ́kàn náà ti wọn sọkan: Ẹ wa, jẹ ki a…'(Gen. 1:26).

iv.  A da ènìyàn ni àwòrán Ọlọ́run; ni àwòrán Mẹ́talọ́kàn (Gen. 1:27, 28; I Jhn. 5:7,8). Idi ni yi ti a fi da ènìyàn ni onipa mẹta; ara ọkàn àti ẹ̀mí.

v.   Ọlọ́run fún ènìyàn ni àṣẹ lórí àwọn ẹ̀dá yòókù lọ, nítorí náà ni ẹnu ṣe ń ya Onisaamu nínú Orin Dáfídì 8:3 swj.

vi. A fun ènìyàn ni anfaani lati jẹ aṣojú Ọlọ́run (2 Kor. 5:20; 6:1).

vii.Ọkan ènìyàn a padà sí ọdọ Ọlọ́run nígbà tí o ba kú. Àwọn ẹ̀dá yòókù ko ri bẹẹ (Oniw. 12:7).

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJÌ

i.   Bíbélì fi ye wa pé Ọlọ́run ni o da ayé.

ii.  Ọlọ́run da ayé fún Òun tìkálara Rẹ (Òwe. 16:4; Rom. 11:36; Kol. 1:16).

iii. Ọlọ́run da ayé fún Ìyìn Rẹ, Ọlá Rẹ àti Ògo Rẹ (O.D. 19:1; Isa. 43:6b-7)

iv.  O da a fún ìdùnnú ara Rẹ (Efe. 1:5; Ifi. 4:11)

v.   Láti sọ agbára àti ọgbọ́n Rẹ di mímọ (Efe. 3:9,10).

vi. Kí àwa lè mọ Ọn, kí a fẹ́ Ẹ kì a sì safihan Rẹ fún ayé (Rom. 1:20,21).

vii.A da ènìyàn lọ́nà ara ọtọ láti máa jẹgbádùn ẹwà àti ogo Ọlọ́run to ń fani-mọ́ra.

viii.A da ènìyàn làti wa pẹ̀lú Kristi ni ọrun Rẹ. Èyí gan-an ni ojúlówó eto Ọlọ́run fún ènìyàn ṣáájú ìṣubú. Kristi ti wa lati ṣe ilaja wa pẹ̀lú Ọlọ́run.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :

Ohun-èlò oniga mẹta (tiripọdu) jẹ irin ìṣẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹta tí a gbékalẹ tàbí na dúró, tí a máa ń lo gẹ́gẹ́ bí iranlọwọ fún rírú ẹrú ohun kan àti ṣíṣe imuduro àwọn ohun èlò miran. O n pese iduroore sì abilu àtẹ̀gùn láti ìhà gbogbo. A o gbé ẹrọ ayàwòrán/wọnlẹwọnlẹ (kamẹra náà) lọwọ abilu afẹ́fẹ́ àti iji láti igun yowu wa. Mẹ́talọ́kan dabi tiripọdu tí a fi n gbe nnkan dúró. Apa kan èyí tí a ko le yà kúrò lára àwọn yoku ko ma salai yí iri rẹ padà. Ọlọ́run mọ agbára àwọn mẹ́ta náà nígbà tí o ṣẹda ènìyàn àti ayé. Ẹ mase jẹ ki a gbàgbé pé ìgbà ni ayé, gẹgẹ bí àkókò àti ṣáá, tí jẹ ti Ọlọ́run (Oniw. 3:11; Dan. 2:21; Ìṣe 1:7). Àwọn ọmọ Israẹli gbádùn àkókò Ọlọ́run, Baba, àwọn Àpọ́sítélì gbádùn àkókò Ọlọ́run Ọmọ nígbà tí awa ń gbádùn Ẹ̀mí Mímọ́ báyìí lọ́wọ́lọ́wọ́. Èyí kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run mẹta ni a ń sin. Ó ní òye èrò ìṣọkan ni onírúurú ọ̀nà. Àwọn Kristẹni ni ohun èlò (èrò ayàwòrán) náà tí a gbé kà orí ohun èlò oniga mẹta náà. Èyíkéyìí ìdojúkọ láti ọ̀dọ̀ ayé wà ko le mi wa bí a ti ń dúró lórí mẹ́talọ́kan. A o lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ takuntakun ni bi a ti wa ninu ìṣọkan pẹ̀lú Ọlọ́run Mẹ́talọ́kàn. A gbàdúrà pé a o ni mí wa dànù kúrò nínú ìṣọkan Jésù Kristi Olúwa wa. Àmín.

IGUNLẸ :

Ọpẹ ni fún Ọlọ́run fún mímú wa wa si opin ẹ̀kọ́ yii. Laisi àní àní, ọ̀pọ̀ ìfihàn ni a ti sipaya fún wa, bẹ́ẹ̀ ni a ko si le gba láti jókòó tẹtẹrẹ ju pé kí a fi gbogbo ìwọ̀nyí sì ìṣe. Ní ìṣọkan ni a dúró, ní iyapa ni a ṣubú. Èyí gbọ́dọ̀ jẹ idakọro wa bí a ti ń ṣe ìpinnu láti dúró ní ìhà òtítọ́ tí Kristi, nínú aisegbe Rẹ àti ìwà òdodo Rẹ. A gbàdúrà kí a lè máa múra sílẹ̀ dáadáa ju ti àtẹ̀hin-wá lọ. Àmín.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ ÌKEJÌ

Mon.   3:  Gbogbo Ènìyàn Gbọ́dọ̀ Máa Mọrírì Àwọn Iṣẹ́ Ọlọ́run (Ifi. 15:3)

Tue.    4:   Máṣe Gbìyànjú Láti jẹ Asiwere (O.D. 14:1)

Wed.   5:  A Ṣẹda Ohun Gbogbo Láti Inú Ofo “Ex-nihilo” (Heb. 11:3)

Thur.   6:  Gbogbo Onigbagbọ Nínú Kristi Jẹ Ọlọ́run Kéékèèkee (O.D. 82:6)

Fri.      7:  Àwọn Ọ̀run Paapaa Ń Sọ̀rọ̀ Ògo Ọlọ́run (O.D. 19:1)

Sat.     8:  Ìṣe Olúkúlùkù Eniyan Ń Tọ Ọ Lẹ́yìn (Ifi. 14:13).

Leave a Reply