NBC ILE-EKO OJO ISINMI FUN APRIL 25, 2021 : AKORI – EBE FUN IMUPADABO SIPO

By | April 24, 2021

NBC ILE-EKO OJO ISINMI FUN APRIL 25, 2021 : AKORI – EBE FUN IMUPADABO SIPO

NBC ILE-EKO OJO ISINMI

APRIL 25, 2021

EBE FUN IMUPADABO SIPO

Bibeli Kika fun Ibere Eko: Ekun Jeremiah 3:22-23

Bibeli Kika fun Ipalemo Eko: Ekun Jeremiah 5

Bibeli Kika fun Eko: Ekun Jeremiah 5:1-22

ESE LATI RANTI

Oluwa, yi wa pada sodo re, awa o si yipada, so ojo wad i otun gege bi ti igbaani. – Ekun Jeremiah 5:21

Awon Ete Eko: Ni opin eko yii, o ye ki awon omo kilaasi le:

√ Mo awon idi ti o mu ki awon eniyan Jerusalemu la iponju koja ti won si sofo gidigidi

√ Jiroro lori awon atubotan ese ti o lewu

√ Tun ipinnu won se lati gbadura si Oloruin fun imupadabo sipo.


ORO ISAJU

Orisirisii ni awon idojuko ti a n ba pade ni orisii agbegbe ti a n gb e, eyi ti o maa n yori si iponju ati iya ni opo igba. Awon die n wa lati odo enikookan, awon miiran si n wa lati odo agbarijopo awon eniyan. Enikan so nigba kan pe, “oniruuru isele ibanuje ni o maa n sele, afowo-fa lowo olodanni kookan, o si le je ti agbarijo ti ko se e salaye. O kadi oro re nile pe niogbati o bar i bee, ohun ti eniyan le koko se mi ki o bere sii kabamo, ki eniyan maa sokun tabi ki o maa se mejeeji papo. Bayii ni oro awon ara juda se ri, isubu Jerusalemu tayo pipadanu olu ilu won ti o dara nitori pe ilu yii ni ilu Olorun. Nigbati won dana sun ilu yii ti won sib a tempili Olorun re je, opo ninu won ni won ko leru lo si babiloni. Won mo daju pe Olorun ti fi won le awon ota won lowo. Nigbati won wan i igbekun, Jeremiah joko, o sokuin kikoro lati fi ibanuje re han, kii se nitori wi pe awon eniyan re n sesin ti won si n fiya je won bikose nitori pe Olorun ti ko awon eniyan Re ti O ba da majemu latari ese won.

Awon eniyan yii gbagbo pe ko si ogun kankan ti o le ja Jerusalemu (Ekun Jeremiah 4:12,20). Won ko ni oye pe Olorun ti pinnu lati fi iya jewon ati pe ko si ohun kan ti o le pin In lowo lati se bee. Kedere ni ibi kika yi se afihan isubu, ipadanu ominira, ile ati owo, o tun safihan ailaanu, ifini sise tipatipa, ifi-ebi-pani, ifipa-bani-lopo ati ise-kupani nitori iwa ese awon eniyan naa. Sugbon Jeremiah gbadura si Olorun funn imupada-bo-sipo ni oruko awon eniyan Re. Afojusun eko wa ti oni n ran wa leti pe Olorun je alaanu, o si fe lati mu awon eniyan Re bo sipo nigbati a ba wa A ninu adura.

ALAYE LORI EKO

A. IGBE FUN AANU – EKUN JEREMIAH 5:1-16

Nigbati won ko awon Isreli lo si igbekun ti won si pa Jerusalemu run, Jeremiah joko, o se agbekale orin ikabamo ati adura si Olorun fun aanu nitori Jerusalemu (ese 1). Lati ese 2 titi de 16,o sapejuwe itiju ati ipo abamo ti won wa nigbati ti o so pe:

• Ile ti Olorun fifun won ati ile won ni a ti fi fun awon alejo.

• Won ti di omo orukan awon iya si di opo.

• Won ti pon on ni dandan fun won lati san owo omi ti won n mu ati igi ti won n fi I dana ninu ilu won.

• Awon ara Asiria n gba owo ori lori gbogbo nnkan lowo won.

• Won so won di eniyan lasan (eru) ti awo won si gbo tan nitori ko si isinmi fun won.

• Won di alagbe lati Egipiti titi de Asiria.

• Awon eru lo joba le won lori ko si si eni ti o le fun won ni ominira.

• Won te awon obirin won ni ogo ni Sioni ati awon wundia ni ilu Juda. Koda ko si owo fun awon agbagba won.

• A ko gbo orin lati enu awon omode mo, ayo okan won ti da, ijo ti di ofo.

• Bori bori gbogbo re, ade ti o fi ogo won han ati owo ti o yi ilu Jerusalemu ka poora patapata, latari eyi, o wipe “Egbe ni fun wa, nitori ti awon ti se!”(ese16b).

Awon eniyan naa ta ara won lopo. Ninu ekun Jeremiah, won so nipa ipo ti o buru ti won wa pelu igbagbo wipe Olorun yoo gba won. O ye ki a mo pe awon eniyan yii mo pe iponju ti won la koja kii se nitori ese won ti won jewo ni ese 7 sugbon nitori ese awon baba nla won (Jeremiah 31:29-30). Won mo, won si gba wipe wahala ti o doju ko awon gege bi Orile-ede je ebi awon baba-nla won, eyi ti o lodo si ohun ti won ti koko so tele wi pe Olorun ni o mo on mo fi iya to nipon yii je awon. Yato fun iponju ti o kolu won lapapo, ipin kookan naa jiya; won n ba awon agba obirin ati omobirin won ni ibalopo tipatipa, won si n se won sibasibo. Ko si owo kankan fun awon agbaagba, beeni ko si awon ologbon agbalagba kankan mo ni enu ibode. O ye ki awa onigbagbo mo nigba gbogbo pe awon atubotan ti o lagbara wa ese gege bi iriri awon omo isreli ti won la iponju nla koja. Bakan naa, a tun gbodo ranti pe alaanu ni Olorun, ife Re ti kii ye si n tesiwaju. Lori awon abuda wonyi, Jeremiah sii so nipa iponju won nipa gbi-gbadura, beeni o si n bere lowo Olorun pe ki o gba won ninu itiju won (ese 1).

AKOKO IJIRORO

1. Jiroro lori ohun ti o fa ijiya awon omo Isreli ki o si se afiwe re pelu ijiya won gege bi orile-ede tabi olodanni kookan lode oni.

2. Jiroro lori awon ijora ati awon iyato ti o wa ni akoko igba-aye Jeremiah ati aye ode oni.

B. ADURA ISRELI FUN IMUPADA-BO-SIPO –  EKUN JEREMIAH 5:17-22

Jeremiah ti we idi ti ajalu ti o de ba won mo ese awon baba nla won (ese7).  Nitori eyi o jewo wi pe:

• Okan won rewesi, o si ku.

• Oju won n wo baibai nitori ekun kikoro won.

• Oke sioni ti dahoro, o si ti di iho kolokolo ati awon eranko miran.

Sugbon saa, Jeremiah pari ori Bibeli yii pelu fifi oju sun abuda ayeraye Olorun ti ko yipada. O so ni ese 19 pe, “Iwo Oluwa ni o wa laelae, ite re lati iran de iran.” Eyi ni pe, bi o tile je pe won ti pa tempili ti won feran gan an run (ese18), o ni igbekele ninu otiito pe Olorun n joba, o si n se akoso lori gbogbo aye tit lae. Sibesibe, Ibeere re ni ese 20 dabi pe Olorun ti gbagbe won fun igba pipe, o si n ro o boya yoo sir anti won. Nitori naa, o gbadura kikankikan si Olorun pe ki O jowo da won pada si odo Re ko si da ogo won atijo pada(ese21). O gbagbo wi pe ibinu Olorun ko wa fun igba pipe, nitori eyi ko ni gbagbe awon omo Re laelae. Okan lara awon abuda Olorun ni aanu. Nigba ku igba ti a ba se ti a si ironupiwada tooto han pelu igbagbo ati igboran, imupada-bo-sipo yoo wa.

AKOKO IJIRORO

1. Se agbeyewo awon eda itan kan ninu Bibeli ti won ronupiwada ese won lotito ti won si gba idarijin.

2. Kin ni awon igbese ti o ye ki a gbe ki o to dipe imupada-bo-si po waye?

Mimu Ibakegbepo ati Ise-Iranse Dagba.

• Pin kilaasi si ipin meji. Je kii pin A se akosile orisii awon agbon ti awon omo Isreli ti ri iponju gege bi o ti wa lakosile ninu ibi kika naa, kii pin B si ko eko ti won ti ri mko ninu re sile. Won ni lati ko gbogbo awon ipinnu won po ki won si ka a jade.

Awon Eko Ti A Ri Dimu

~ Olorun ki gbagbe awon omo Re titi laelae.

~ Alaanu ni Olorun.

~ Bi a ba yipada si odo Olorun ninu ironupiwada, yoo gba wa.

~ O ye ki a gbekele Olorun sii, koda ni akoko ti o le.

~ Awon atubotan a maa wa fun aigboran.

~ O ye ki awa onigbagbo ni igbagbo ninu Olorun ki a si ni ireti fun ojo ola ti o dara.

Atunyewo: A dupe lowo Olorun fun mimu wa la osu kerin ninu odun koja. Mo ni idaniloju pe Olorun ti ba o soro ni orisii ona lati ipase ise-iranse awon wolii to n muni-pada-bo-sipo. Lori eko merin yii:

√ So die ninu awon eko ti o ko nipa ipinu Nehemiah lati se aseyori ninu iseakanse mimo odi naa ………………………………………….

√ Agbon wo ni o ru o lokan soke julo nipa ipenija to n dojuko awon adari Kristiani lati dari awon ti o wan i abe won ki won o le gboran si ase Olorun ati ki won le maa ni ibasepo to gunmo pelu Re nigba gbogbo gege bi Esra ti se?………………………………………………………………

√ Kin ni awon ijagbudu re nipa nini imo lori Ojiya-Iranse eyi ti o mu igbala wa fun iran eniyan?……………………………………………………………….

√ Nje o ba awon nnkan ti o le ran o lowo lati dagba sii ninu emi pade bi?……………………………………………………………………………………….

Gbadura pe ki Olorun fun o ni oore-ofe lati le wulo sii ninu ise-iranse.

Gege bii Eko ti o ko ninu Osu yii, se Ifarajin kan ni pato fun Ijo Re…………………………………………………………………………………

Leave a Reply