ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN September 29, 2019. ÌSỌRI KEJI: A MÚ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ. Ẹ̀KỌ́ KẸFÀ:

By | September 29, 2019

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI. Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN September 29, 2019. ÌSỌRI KEJI: A MÚ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ. Ẹ̀KỌ́ KẸFÀ:

E ka awon eko ti ateyin wa ni ibi yi

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI.
Ẹ̀KỌ́ ILẸ̀ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI. FUN

September 29, 2019.

ÌSỌRI KEJI: A MÚ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.
Ẹ̀KỌ́ KẸFÀ:

ÌGBÉ AYÉ KRISTI ÀTI IKÚ RẸ MU ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ.

Igbe ayé (iye) àti ikú Jésù Kristi mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ to ṣe Pàtàkì ni ọna ti ìbẹ̀rẹ̀ ónirẹlẹ ìgbé-ayé ìjìyà, ikú tí o fi ṣe ètùtù, abbl ṣẹ. Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ gba A gbọ kí a si gba A ni Olúwa àti Olùgbàlà wa. Njẹ ìwọ ti ṣe èyí bí?

AKỌSORI
Ni ojoojúmọ́ ni èmi wa pẹ̀lú yín ni tẹmpili ti èmi n kọ yín, ẹyin kò sì mu mi: Ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ ko le ṣe aláṣẹ.

(Maku 14:49).

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ
Ọnkọ̀wé Olorin kan kọ, “Lojoojumọ bí mo ṣe wa, bí mo ṣe n mí nigba gbogbo, jẹ ki gbogbo igbe ayé mi jẹ ìsọrọ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ”. Jésù mú àwọn Iwe Mimọ ṣẹ, niti igbe ayé àti ikú ikú. O sì n jẹ àpẹẹrẹ pípé tí igbe ayé imuwee-mimọ ṣẹ sibẹsibẹ. Gbogbo àwọn iṣẹ́ Rẹ, ọrọ Rẹ ati awọn ẹkọ Rẹ jẹ ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mimọ. O sọ nínú Mátíù 5:17 – 18 wí pé Òun ko wa lati pa òfin run / rẹ bikose láti ri ìdánilójú ìmúṣẹ rẹ.

Igbesẹ àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó fa ikú Rẹ gan-an, gbogbo wọn wa fún ìmúṣẹ àwọn Ìwé Mímọ́. Akọsori wa fún wa ní àpẹẹrẹ irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹẹ. Bí àwọn ológun tí de láti mú Jésù, Ó pe wọn nija pe kin ni idi ti wọn ko fi mú Òun bi Òun ti n wọlé àti jáde laarin wọn láti ìgbà pipẹ bọ. Gbólóhùn yìí láàyè ara rẹ loyun pẹ̀lú òtítọ́ wi pe, wọn ko le ṣe ohunkóhun fún Un ṣáájú ìgbà náà tí wọn papa wá mú Un, nítorí pé ìgbà kò ti ìtó (wo Lk. 4:28 swj). Ni ìmúṣẹ àwọn Ìwé Mímọ́, ìgbà tí a ti yàn wa fún Un láti fẹmi Rẹ lélẹ̀ (ku), gẹgẹ bi ìgbà ibi Rẹ gẹlẹ (wo Gal. 4:4).

Awa Kristẹni (awa ọmọlẹ́yìn ìyè àti àwọn ẹ̀kọ́ Kristi nitootọ), a gbọ́dọ̀ máa ṣàfẹ́rí láti gbé ìgbé ayé wa ni ibamu pẹ̀lú ìfẹ́ àti eto Ọlọ́run. Rántí wí pe Ọlọ́run ni igba fún wa ninu ohun gbogbo, ko si sí ohunkóhun tí O ṣètò fún wa ti yoo waye (ṣẹlẹ̀) ṣáájú tàbí lẹ́yìn ju ìgbà tí O ti yàn lọ, niwọn ìgbà tí a sì wa pẹ̀lú àti nínú Rẹ. Nípa ṣíṣe bẹẹ, Ọlọ́run yóò di ayinlogo nínú wa. Ṣé ìwọ n gbé ìgbé ayé rẹ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Ọlọ́run bí?

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ
Mon. 23: A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Kristi (Isa. 9:6-7)
Tue. 24: A Ṣe Àlàyé Ibi Kristi Ní Kíkún Fún Màríà (Lk. 1:31)
Wed. 25: A Bi Kristi Gẹ́gẹ́ bi A Ti Sàsọtẹ́lẹ̀ (Lk. 2:7).
Thur. 26: A Kọ Jésù Ní Ila, A Si Sọ Ọ Lórúkọ (Lk. 2:21,23; wo Gen. 17:12).
Fri. 27: A Ya Kristi Ṣí Mímọ́ Nínú Tẹmpili (Lk. 2:22,23; wo Eks. 13:2).
Sat. 28: A Baptisi Kristi Láti Mú Gbogbo Òdodo Ṣẹ (Mat. 3:13-17).

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN
1. Ìgbé-ayé (iye) àti ikú Jésù ni o mú Iwe-Mimọ ṣẹ papọ. Tìrẹ gbọ́dọ̀ wa ni ìbámu pẹ̀lú Ọrọ Rẹ, láti le jẹ “ẹni tí o ni Ìmúṣẹ láyé.
2. Abala wo ninu ayé rẹ ni ko fogo fún Ọlọ́run? O gbọ́dọ̀ ṣe àtúnṣe kíákíá, ki gbogbo iwa láàyè rẹ le fogo fun Un. Ọrọ Ọlọrun, ìlérí Rẹ ati májẹ̀mú Rẹ pẹlu ènìyàn jẹ òtítọ́. Ṣùgbọ́n ìhùwàsí ènìyàn, isesi àti igbe ayé nii ṣe pupọ nínú mímú àwọn ìlérí náà ṣẹ, tàbí wọn ko nii wa si ìmúṣẹ.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : Fílípì 2:5-7; Mat. 5:17-18

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA
ILEPA: Láti fihan àwọn ènìyàn Ọlọ́run bí gbogbo ìgbésí ayé àti ikú Jésù Kristi ṣe jẹ́ ìmúṣẹ àwọn ìwé mimọ.

ÀWỌN ERONGBA: Ni opin ẹ̀kọ́ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀
i. maa safihan àwọn ẹri didi òtítọ́ náà mú ṣinṣin wí pé Jésù gbé ayé O si kú láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ iwe mimọ ṣẹ
ii. setan láti máa fi tinútinú gbé ayé wọn ní ọ̀nà tí Ọlọ́run yóò fi di ayinlogo ni ibamu pẹ̀lú àwọn ìwé mimọ,
iii. le dúró fún, pé Ọrọ Ọlọ́run àti àwọn ìlérí àti àwọn májẹ̀mú Rẹ jẹ bẹẹ ni ati Àmín, àti wí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mimọ tí wọn ko ti i ṣẹ yóò ṣẹ ìdánilójú tasiko wọn ba to ; àti
iv. faraji pupọ fún gbígbé igbe ayé ìgbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run pátápátá, àní titi dojú ikú.

IFAARA
ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: MÁTÍÙ 2;3;26;27; LUKU 1; 2;4;5:9; JÒHÁNÙ 2:19; FÍLÍPÌ 2:5-7
A fi gbogbo ogo, ọlá àti ìyìn fún Ọlọ́run nìkanṣoṣo, fún oore-ọ̀fẹ́ àti ànfàní láti di alábùkún fún lọsọọ̀sẹ̀ àti lojoojumọ, nipasẹ ILÉ -Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi. Àdúrà wa ni pe a o gba èrè laalaa (ìṣẹ́) wa lásìkò rẹ, a o si jẹ ikọ tí a ka yẹ titi Kristi yóò fi de ni Orúkọ Jésù.

Nínú ẹ̀kọ́ tí o kọjá, a ṣe àgbeyẹwo àkòrí náà. MÈSÁYÀ NÁÀ WA NIGBẸYIN-GBẸYIN WA. A rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣe di òtítọ́, tí o túmọ̀ sí pé, Mèsáyà náà, ẹni tí a ti sọtẹ́lẹ̀/ṣèlérí Rẹ nigbẹyin-gbẹyin wa. Ẹ̀kọ́ wa ṣàlàyé dáadáa nípa ibi Rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ to yi I (ibi Rẹ) ka gẹ́gẹ́ bi òtítọ́ sì àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ tí sọtẹ́lẹ̀ nibẹrẹ pẹpẹ. Kí Ọlọ́run jẹ ki awọn erongba rere Rẹ ṣẹ lórí wa ni Orúkọ Jésù.

Ẹkọ tí isinsin yìí, tí o jẹ ẹ̀kọ́ kẹfà nínú ọwọ yìí, tí a pe àkòrí rẹ ni ÌGBÉ AYÉ KRISTI ÀTI IKÚ RẸ MU ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ: A o ṣe àgbeyẹwo èyí ni ipa méjì: bi Igbe ayé Rẹ ti jẹ láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ, láti ìgbà ewe Rẹ to fi di àgbàlagbà, ipa kejì n safihan bí, paapaa ìjìyà àti ikú Rẹ ṣe jẹ́ láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ nìkan. Irú igbe ayé tí o mú erongba atokewa ṣẹ wo ni èyí!

Kí Ọlọ́run fún wa ní ojú inú to jinlẹ si Ọrọ Rẹ ki O si mú kí Ọrọ náà máa di ṣíṣe julọ, ki O si di mímú ṣẹ nínú ayé àwa náà, ní orúkọ Jésù. Àmín.

IFAARA SI IPIN KỌỌKAN :
Ẹkọ yìí pín sí ìpín méjì, I àti II. Ìpín kọ̀ọ̀kan ni a tún ṣe arunpin sì A àti B.

IPIN KÍNNÍ: O GBÉ ÌGBÉ AYÉ LÁTI MU ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ
Ìpín yìí n ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ alaye pẹ̀lú bí Jésù ṣe gbé gbogbo igbesẹ ayé Rẹ fún mímú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mimọ ṣẹ, lábẹ́ èyí tí a tún pín sí méjì. Ipa A n ṣàlàyé bí ìgbà ewe Rẹ ṣe mú awọn iwe mimọ ṣẹ, èyí tí a mú jáde láti inú Matiu 2:13-15; Luku 1:80; 2:41-52; Filip. 2:5-7. Ipa B n safihan àgbàlagbà Rẹ gẹ́gẹ́ bí ọna sì ìmúṣẹ àwọn ìwé mimọ. A mu un jáde láti inú Matiu 3:16-17; 4:13-15; 5:17-18; Luku 4:17-21; 9:27-36; Jòhánù 2:16-17. A pè wa nija láti gbé ayé wa gẹ́gẹ́ bi tiRẹ

IPIN KEJI: O KU LÁTI MU ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ
Ìpín yìí n ṣàlàyé bí Jésù ṣe papa kú, bákan náà gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ àwọn iwe mimọ. A pín in sì ipa meji. Ipa A, Ó jìyà gẹ́gẹ́ bi ìwé mimọ tí sọ, a mu un jáde láti inú Mat. 26:14-75; 27:3-35, àti Ipa B, O ku A Si Sin In, a mu un jáde láti inú Mátíù 27:35-50; Jòhánù 19:30-42. Àwọn ìpín méjéèjì yìí n fún wa ní òye inú tó jinlẹ sì ìgbà ewe, àgbàlagbà, ìjìyà, àti ikú Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí gbogbo wọn ṣe mu Un lọ si ìmúṣẹ àwọn Ìwé Mímọ́.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́
I. O GBÉ ÌGBÉ AYÉ LÁTI MÚ ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ
A. IGBA EWE RẸ
B. IGBA TI O DAGBALAGBA
II. O KU LÁTI MU ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ
A. O JIYA GẸ́GẸ́ BI IWE MIMỌ TI SỌ
B. O KU A SI SIN IN

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́
I. O GBE ÌGBÉ AYÉ LÁTI MU ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́ ṢẸ (Matiu 2:13-15; 3:16-17; Luku 1:80; 2:41-50; 4:13-21; 5:17,18; 9:27-36; Jòhánù 2:16-17; Filipi. 2:5-7)
Gbogbo igbesi ayé Jésù Kristi ni o da lori ìmúṣẹ àwọn ìwé mimọ. O n gbe ìgbé ayé lojoojumọ láti ìgbà èwe Rẹ titi di àgbàlagbà, gbogbo wọn lo n ṣe ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a ti sọ nípa Rẹ (Olùgbàlà náà), ni ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn.

A. ÌGBÀ EWE RẸ (Mat. 2:13-15; Lk. 1:80; 2:41-50; Filip. 2:5-7).
Ṣùgbọ́n O bọ ogo Rẹ silẹ, O si mú àwọ ìránṣẹ́, a si ṣe E ni àwòrán ènìyàn (Filip. 2:7).
i. Filip. 2:5-7: Jésù I bá ti pinnu láti farahàn lojiji nínú ayé gẹ́gẹ́ bí alágbára/akọni ẹ̀dá, ṣùgbọ́n dipo bẹẹ, O yan láti gbé iri/àwòrán ọmọdé, paapaa onde ìránṣẹ́, ni ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ (Isa. 7:14; 9:6).
ii. Mat. 2:13-15: Àṣẹ tí a pa latokewa láti gbe E salọ si Egipti n fún wa ni ìtumọ̀ kíkún sì àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ (Hos. 11:1) nínú eyi ti Ọlọ́run ti pé Orílẹ̀-ede Israẹli ọmọ Rẹ jáde. Jésù ni ojúlówó ọmọ Ọlọ́run, Olùgbàlà (Mèsáyà) Israẹli (àti gbogbo ayé)
iii. Ẹsẹ 16-18: Ìpakúpa tí Hẹ́rọ́dù pa àwọn ọmọ aláìlẹ́ṣẹ lọrun (àwọn ọmọkùnrin) ni eredi láti pa ọmọdékùnrin náà Jésù, jẹ àwòrán miran ni ti ọ̀fọ̀ (ẹkùn) Rakeli fún ípàdánù àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bi a ti rii nínú Jer. 31:15 tí o n tọ́ka si ìgbèkùn ara Bábílónì àwọn ẹni ìkà ni 586 ṣáájú Ibi Kristi.
iv. Ẹsẹ 19-23: Ipadabọ Rẹ si Násárétì ni Gálílì mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ (ẹsẹ 23)
v. Lk. 1:80: Òtítọ́, wi pe ọmọdékùnrin náà Jésù dàgbà O si di alágbára (wo 2:40,52) mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ pe Oun (Mèsáyà náà) yóò dàgbà níwájú Rẹ (Yahweh) bi ọjẹlẹ ohun ọ̀gbìn (Isa. 53:2a).
vi. Ìhùwàsí Jésù nínú Lk. 2:41-50 si ìjọsìn tẹmpili ko ha mu O.D. 69:9).
viii.Eyi gan-an ni idi ti o (ìwọ) fi ní láti dẹ́kun gbigba (ìyẹn bí o bá ti gba wọn gbọ tẹlẹ) àwọn ìtàn asán, àwọn ìtàn tó kun fún ẹ̀tàn àti àwọn ọrọ ti wọn ni ìṣẹ̀dá idán pípa nínú ìgbà ewe Rẹ gbọ, tí a máa n rí nínú àwọn ìwé bíbélì alafikun kan àti àwọn ìwé mimọ mìíràn. Ìgbà ewe Jésù mú àwọn ìwé mimọ ṣẹ ní àwọn ọ̀nà to f’ogo fún Ọlọ́run nítòótọ́.

B. ÌGBÀ TÍ O DAGBALAGBA (Mat. 3:16-17; 4:13-15; 5:17,18; Lk. 4:17-21; 9:27-36; Jhn. 2:16-17)
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ sì ránti pe, a ti kọ ọ pé “ìtara ilé Rẹ jẹ mi run” (Jhn. 2:17)
i. Mat. 3:16-17: A ṣe ìrìbọmi fún Jésù, Ẹmi Mimọ sì ba le E ni ojú ayé ni àwòrán àdàbà, ohun náà tí o sì wa lati ọrùn jẹ láti fẹsẹ Jésù múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlérí náà (wo Isa. 9:6a).
ii. 4:13-15: Jésù bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ ni Gálílì ni ìmúṣẹ Isaiah 9::6-7.
iii. 5:17,18: Jésù Kristi sọ ọ kedere wi pe, Oun wa lati mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí sì jẹyọ lọpọlọpọ nínú àwọn iwa Rẹ, ìṣòro Rẹ ati ìṣe Rẹ.
iv. Lk. 4:17-21: Wọn fún Jésù ni Ìwé Wolii Isaiah O sì ka a sókè nínú Sínágọ́gù, lẹhin èyí, O fi ye àwọn ènìyàn náà pé ohun tí o ṣẹlẹ̀ náà jẹ ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ (Isa. 61:1-3).
v. 9:27-36: Ìrírí Jésù nihin yìí níwájú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ pàtàkì, n fi I hàn gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ tòótọ́ tí àwọn akọni ẹ̀mí ńlá dúró fún nínú isafihan eto Ọlọ́run —- Mósè (Òfin) àti Èlíjà (Wòlíì).
vi. Jhn. 2:16-17: Nígbà tí Jésù le àwọn tó n ta to n ra kúrò nínú tẹmpili, O n mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ ní (wo O.D 69:9; 122:1), O si n safihan ìtara fún ilé Baba Rẹ kan náà.
vii. Àpẹẹrẹ pàtàkì julọ niti igbe ayé àgbà (àgbàlagbà) Jésù to n fogo fún Ọlọ́run ti o si n mú àwọn ìwé mimọ ṣẹ ní a rí nínú Mátíù 4:1-10 níbi tí Sátánì tí dán Jésù wo. Gbogbo àwọn ìdáhùn Rẹ jẹ ìmúṣẹ àwọn ìwé mimọ, nítorí náà, 4:4 jẹ ìmúṣẹ Deut. 8:3; 4:7 ni ìmúṣẹ tí Deut. 6:16; nígbà tí 4:10 jẹ ìmúṣẹ Deut. 6:13.
viii.Gẹ́gẹ́ bi àwọn ìtàn asán àti àwọn ọrọ alálùpàyídà nípa ìgbà ewe Kristi máṣe faaye gba irú àwọn àkọsílẹ̀ to n bu Jésù lọla kù bẹẹ eyiti yóò sì máa ṣàkóso fún ìgbàgbọ́ rẹ díẹ̀díẹ̀. Kiyesara.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ
1. Igbe ayé Jésù Kristi láti ọmọdé titi O fi di àgbàlagbà, gbogbo rẹ da lori ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́.
2. Òtítọ́ náà pe, ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ti di Mímúṣẹ gbọ́dọ̀ máa fún ọ lókun kí o sì máa rú ọ sókè nítòótọ́. Ọrọ Ọlọ́run ko ni lọ láiṣẹ láéláé àti fún ìwọ paapaa.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Májẹ̀mú Láéláé n tọ́ka si Jésù Kristi, O wa lati mú wọn ṣẹ ní ọ̀nà afojuri. Ẹ jíròrò.

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN IṢẸ́ ṢÍṢE
i. Jésù Kristi ni ọdọ-àgùntàn Ọlọ́run pípé, tí a tọ́kasi nínú Májẹ̀mú Láéláé, àti ẹni tí o farahàn bi ènìyàn nínú Májẹ̀mú Tuntun.
ii. Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù 1:14 ṣe sọ, Ọrọ náà di ara… Jésù ni Ọrọ náà tó wa pẹ̀lú Ọlọ́run láti atetekọṣe (Jòhánù 1:1), nipasẹ ẹni tí a da ọrùn òun ayé (Gen. 1siwj), àti wí pe a da ohun gbogbo nípasẹ̀ Rẹ (Jhn. 1:3).
iii. Jésù ni Ọrọ náà tí O wa ninu ara nínú Májẹ̀mú tuntun. A rí I, a fọwọ́ kan án, a ba A sọ̀rọ̀, a gbọ́ Ọ, a di I mú abbl. Gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni mìíràn tí o gbé láyé, kí I kan ìṣe gẹgẹ bí ẹ̀mí àìrí (I Jhn. 1:1-3).
iv. Jésù wá nínú Májẹ̀mú Tuntun láti mú àwọn ìlérí àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run nínú Májẹ̀mú Láéláé ṣẹ.
v. Jésù ni Ọdọ-Àgùntàn Ìrékọjá tí a tọ́kasi nínú Májẹ̀mú Láéláé (Eks. 12:46; Num. 9:12; Jhn. 19:12; Jhn. 19:32-36). O wá nínú ara ati nínú ìṣe láti mú àwọn ìwé mimọ tí wọn ní ìṣe pẹ̀lú èyí ṣẹ. A bi I sínú ayé, o gbé ní àyè, O ku ninu ayé (nípa ti ara), O jíǹde nínú ara, O si gòkè re ọrùn nisoju ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí. Àwọn ẹri pọ pupọ láti fìdí gbogbo àwọn wọ̀nyí múlẹ̀.
vi. Nínú gbogbo wọn, Májẹ̀mú Láéláé n tọ́kasi Kristi nígbà tí Májẹ̀mú Tuntun n ṣe ìmúṣẹ tí Kristi. Gbogbo Ìwé Mímọ́ pátápátá lo dá lórí Kristi Jésù àwọn ìrètí nípa Rẹ ati ìmúṣẹ àwọn ìrètí wọnnì.
vii. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ gba A gbọ lai kù síbi kankan, ki eniyan ma bàa padanu ojurere pẹ̀lú (lọdọ) Olufunni ni iwe Mimọ náà Ọlọ́run to n bọ laipẹ láti ṣèdájọ́ ayé lórí ìwà onikaluku sì Olumu Ìwé Mímọ́ ṣẹ pátápátá (ni ayérayé) (Jésù).

Leave a Reply