OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO ÌJỌ APOSTOLI KRISTI ỌJỌ́ ISEGUN, OSU KINI 21, 2020 ÀKÒRÍ: OHUN RERE KAN

By | January 20, 2020

OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO ÌJỌ APOSTOLI KRISTI ỌJỌ́ ISEGUN, OSU KINI 21, 2020 ÀKÒRÍ: OHUN RERE KAN

OMI ÌYÈ NÁÀ,OJOJUMO

ÌJỌ APOSTOLI KRISTI

ỌJỌ́ ISEGUN, OSU KINI 21, 2020

ÀKÒRÍ: OHUN RERE KAN

KA: HÉBÉRÙ 13:8-10

ÀKÓSÓRÍ:

Ẹ mase jẹ́ kí a fi onírúurú àti ẹ̀kọ́ àjèjì gbá yín kiri. Nítorí ó dára kí a mú yín ní ọkàn le nípa oore ọ̀fẹ́, kì í se nípa oúnjẹ, nínú eyiti àwọn tí ó ti ń rìn nínú wọn kò ní èrè (Hébérù 13:9)

ÌTÚPALẸ̀

Áńgẹ́lì Olúwa sọ fún Àpọ́sítélì Jòhánù olufe pé, níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jésù mọ (ifih. 14:12). Gbogbo wa ni a ń ronú nípa “sùúrù” gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní agbára. Agbára láti mase kanra tàbí máa tu bí ejò nígbà tí nǹkan kò bá rọgbọ fún wa. Sùgbọ́n nihin ni a ti rí bí wọn ti sàlàyé sùúrù ni ìwòye igbese àti ìsòtítọ́. A sọ àmì sùúrù tí a yàsímímọ́ fún wa pé on ni pípa ẹni, ìrora, inúnibíni tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì. Ó jẹ́ igbese titesiwaju àti ifara-eniji nígbà tí àwọn ipenija bá bò wá mọ́lẹ̀. Sùúrù yìí kìí se èyí tí a ń ronú pé bóyá kí a ní tàbí tí a ń pongbe fún. Sùúrù yìí kì í se dídúró lásán. Ó ń sise bákan náà. Ǹjẹ́ òtítọ́ yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìrírí rẹ gẹ́gẹ́ bí i Kristẹni?

Ọkan lára àwọn irinse tí èsù ń lò lòdì sí wa ni ìrẹ̀wẹ̀sì. Tí ó bá lè sọ wá di ọ̀lẹ àti alailagbara nípa rírán àwọn ìdánwò sì wa, nígbà náà, ni ó ti pa àwọn ẹri Kristẹni wa mọ wa lẹ́nu pátápátá. Ọ̀nà àbáyọ kan soso fún Kristẹni tí ó ń la ìdojúkọ tàbí ibanuje tàbí àìní ìdánilójú kọjá ni kí o máa tesiwaju nínú ìrìn Kristẹni, kí o máa pa òfin Olúwa mọ kí ó sì máa farada nínú ìgbàgbọ́ Jésù.

Gbogbo wa ni a ní ìwà kí a pa ẹnu mọ tàbí kí a fàsẹyín, nígbà tí àwọn ìsòro bá wá sí ọ̀nà wa. Sugbọn ọ̀nà sùúrù ni kí a farada ìsòro náà pẹ̀lú ìgbàgbọ́, kí a máa tesiwaju nínú ìsìn wa sí Jésù Kristi. Èyí ni ìfarahàn ifesemule nípa àti nínú oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Èyí ni yóò jẹ́ ẹ̀rí wa. Àmín.

ÀWỌN KÓKÓ ÀDÚRÀ

1. Olúwa gba ẹ̀mí mi ọkàn àti ara mi kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí aileni sùúrù.

2. Ọlọ́run mi kún mi pẹ̀lú Ẹ̀mí Rẹ tí yóò ràn mí lọ́wọ́ láti dojú kọ gbogbo ipenija tí ń bẹ nínú ìrìn Kristẹni pẹ̀lú sùúrù gbogbo.

3. Gbàdúrà fún àwọn ọdọ tí wọ́n jẹ́ iranse Ọlọ́run tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ ń bọ̀ fún oore ọ̀fẹ́ láti fi sùúrù dúró de àsìkò Ọlọ́run, dípò kí wọn ó máa wá ọ̀nà tí wọn yóò fi bú jáde nínú isẹ ìránsẹ́.


ÀFIKÚN IBI KÍKÀ FÚN ÒNÍ: Genesisi 43-44 àti Mátíù 21

Leave a Reply