ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI LAGBAYE.    OMIYE NÁÀ.    Ọjọ Iṣẹgun (Tuesday), February 18, 2020.    ÀKÒRÍ: ÌRÈTÍ FÚN ÀPẸHINDA

By | February 18, 2020

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI LAGBAYE.    OMIYE NÁÀ.    Ọjọ Iṣẹgun (Tuesday), February 18, 2020.    ÀKÒRÍ: ÌRÈTÍ FÚN ÀPẸHINDA

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI LAGBAYE.

OMIYE NÁÀ.

Ọjọ Iṣẹgun (Tuesday), February 18, 2020.

ÀKÒRÍ: ÌRÈTÍ FÚN ÀPẸHINDA

Ka Jeremáyà 3:12-14

AKỌSORI

Yipada ẹyin ọmọ àpẹhinda, èmi o si wo ipẹhinda yín san (Jeremáyà 3:22a).

ITUPALẸ

Iwa àánú Ọlọ́run sì àwọn ọmọ Rẹ ti wọn ti pẹhinda ni a ṣe ìfihàn rẹ kedere nínú Jeremáyà 3:14: “padà, ẹyin àpẹhinda ọmọ ni Olúwa wi, èmi ni Olúwa yín, Èmi yóò mú yín padà sí ilẹ Israẹli ọkàn nínú ìlú kan àti méjì nínú ìdílé kan láti ibi gbogbo tí ẹ tuka lọ”.

Ẹṣẹ n ba ibasepọ wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fi àánú gba àwọn tí o ba padà sí ọdọ Rẹ pẹ̀lú irẹlẹ gbogbo àti ìrònúpìwàdà tòótọ́. O n wọna láti gba wa padà, ifẹ Rẹ láti dariji àwọn ọmọ Rẹ ko si lopin. Ibikíbi yòówù kí a wa, tàbí ohun tí a ti ṣe, a lee ni ìgboyà nípa pé Ọlọ́run yóò dárí jì wa, tí a ba kọ ẹṣẹ wa ti a si yipada sì Kristi nìkan fún ìdáríjì. Èyí ni gíga julọ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ. Èyí ni ìròyìn ayọ̀ fún apadasẹhin!

Ìfẹ́ Ọlọ́run ti ó ni ìmọ̀lára fún apadasẹhin dúró, o si dájú, sún mọ́ Ọn. Òun yóò sì sunmọ ọ (Jak. 4:8). Rántí, owe ọmọ oninakuna, bi bàbà rẹ tí gba a padà, nígbà tí o mọ àṣìṣe rẹ tí o sì pinnu láti padà sí ile lọdọ baba rẹ, lai wo ti ohun tí yóò ní ìrírí lọ́wọ́ bàbà náà, fún ìjìyà omugọ rẹ (Lk. 15:11 síwájú sii).

Ma ṣe jẹ́ ki ohunkóhun fa ọ padà kúrò lọdọ Ọlọ́run àti ìdáríjì pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ Rẹ. Máṣe jẹ ki fàájì ẹṣẹ tán ọ jẹ. Bákan náà máṣe jẹ ki iyèméjì tàbí ẹbi da ọ dúró fún àwọn ìlérí Rẹ. “Bí àwa ba jẹwọ ẹṣẹ wa, olóòótọ́ àti olódodo ni Òun láti darí ẹṣẹ wa ji wa, àti láti wẹ wa nu kúrò nínú ẹṣẹ wa.


ÀWỌN KÓKÓ ÀDÚRÀ

1.   Dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìfẹ́ Rẹ̀ fún àwọn àpẹhinda àti ìdáríjì pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ Rẹ.

2.   Ọlọ́run o, jọwọ da aya funfun sì inú mi, kí O sì sọ ọkàn dídúró ṣinṣin di ọtun ni inu mi.

3.   Gbàdúrà fún gbogbo àwọn àpẹhinda ni inu igbagbọ, pé ki Ọlọ́run fún wọn ní oore-ọ̀fẹ́ láti padà sí ọdọ Rẹ pẹ̀lú ìrònúpìwàdà tòótọ́.

ÀFIKÚN IBI KÍKÀ FÚN ÒNÍ: Léfítíkù 13 ati Luku 6.

Leave a Reply