NBC ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN IGBARADI RE FUN September 5, 2021 : AKỌ́LE – MOSE ATI MIRIAMU YIN OLORUN.

By | September 4, 2021

NBC ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN IGBARADI RE FUN September 5, 2021 : AKỌ́LE – MOSE ATI MIRIAMU YIN OLORUN.

Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI FUN IGBARADI RE

NBC ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI

Date: Ojo Aiku, September 5, 2021.

AKỌ́LE: MOSE ATI MIRIAMU YIN OLORUN.

Bibeli Kika fun lbere Eko: Eksodu 14:1-15:1-21.

Bibeli Kika fun Ipalemo Eko: Eksodu 15:11-21.

Bibeli Kika fun Eko: Eksodu 15:11-21.

Ese lati Ranti: Ta ni o dabi lwo OLUWA, ninu awon alagbara? Ta ni o dabi lwo, ologo ni mimo, eleru ni iyin, ti n se ohun iyanu? Eksodu 15:11

AWON ETE EKO: Ni opin eko yii, o ye ki awon omo kilaasi le:
• Tokasi oniruuru ona ti o ye ki Kristiani ko si awon ise-iyanu ti idande Olorun kuro lowo awon ota.
• Gbe awon orin idupe ati ti iyin kale fun Olorun ni oniruuru ede won.
• Gba awon ti won n dokujo isoro niyanju lati duro sinsin ninu Olorun

ORO ISAAJU:

Oniwaasu Jakobu je olusoaguntan Ijo Onitebomi Ologo
Mimo. Yato si eleyi, o tun je eni ti o mo nipa orin daadaa, o feran ki o maa se agbekale orin, orin kiko ati ijo jijo. Lati igba ti o ti gba ise gege bi oluso-aguntan ijo naa ni eko orin ibe ti ni iriri iyipada ti o lagbara. Gbogbo isin Ojo lsinmi ni o maa n kun fun orin iyin ati ijosin ti o lagbara. O je Ojo Isinmi ti o gbeyin odun, gege bi asa ijo naa, won maa n fun gbogbo omo ijo laaye lati korin ope to ba wu won Iati fi moriri isotiito Olorun ni gbogbo odun naa. Mama Ooreofe gege bi awon omo ijo se maan pe e bo sita, on rerin muse pelu bi o se n korin:

Nigba ti mo ro o,
ise-iyanu Re laye mi
Mo ri pe o ga,
mo ri pe o ga,
mo ri pe oga Baba;
Nigba ti mo ro o,
ise-iyanu Re laye mi,
Mo ri pe o ga,
mori pe o ga,
mo ri pe o ga pupo!

Eri re nii se pelu bi Olorun se tu u sile lowo awon ajinigbe ti won mu ni igbekun fun ojo mefa lai fi enu kan ounje tabi omi. Nigbeyin, won tu u sile lai gba kobo. Nigba yoowu ti a ba ni iriri ise-iyanu airotele tabi ti a ba gba ebun ti o niyelori pupo, igbese ojuese to saba maa n tele e ni a ki bere sii korin to rewa si Olorun. Apeere kan ti o dara niti Mose ati Miriamu ti won korin iyin si Olorun Iati sajoyo bi awon omo lsreli se jajabo lowo awon Egipti ni ona iyanu ati isegun ti won ni lori Farao ati awon omo ogun re nigba ti won koja lori Okun Pupa. O je orin isegun lori awon aninilara won. Eko toni je imulokanle fun awa onigbagbo lati tesiwaju lati maa yin Olorun fun awon ise agbara Re, kii se nigba ti inu wa ba dun nikan, sugbon nigba ti a ba wa ninu isoro pelu, ki a si ni idaniloju pe isegun wa daju.

ALAYE LORI EKO..

A. MOSE YIN OLORUN FUN ISEGUN:
[Eksodu 15:11-13]

Nigba ti Olorun pe Mose ni ibi papa to n jo lati gba awon eniyan Re lowo Farao, eni buburu n ni, boya lo tile mo pe Olorun yoo fun oun ni isegun lotiito. Gege bi O ti fi da Mose loju, Olorun safihan agbara nla Re, O mu ki awon omo Isreli la Okun Pupa ja lailewu, O si pa awon ara Egipti run. Nigba ti awon omo Isreli ri agbara nia naa ti Oluwa fi paa Egipti run, eru Oluwa ba won, won si ni igbagbo ninu Oluwa ati Mose, iranse Re (Eksodu 14). Ni idahun si isegun nla yii, Mose yin Olorun ninu orin re. O wi pe, Tani o dabi lwo, OLUWA,
ninu awon alagbara? ta ni o dabi lwo, ologo ni mimo, eleru ni iyin, ti n se ohun iyanu? (ese 11). Eyi ni pe, ko si olorun ti o le se ise-iyanu alagbara yii yato si Olorun alagbara ti o je mimo, eleru niyin ati ologo. O na owo otun Re, O si pa a ota lenu mo. ljewoo Mose ni ese 13 se pataki pupo. O jerisi isotito Olorun si ileri Re. Nitori naa, yoo se amona awon eniyan ti O ti ra pada de lle lleri pelu agbara Re; yoo si to won si iwaju Re.

Orin Mose je eri titobi Olorun ti ko fe orogun rara. O segun gbogbo awon olorun Egipti ati awon to n josin fun won nipa bi O se gba awon omo lsreli kuro lowo iponju olojopipe ni ona iyanu. Awon oro orin naa je eyi to fojusun Olorun ti o tumo si pe ko dari si odo enikeni bikose odo Olorun. O se pataki ki aa mo pe Mose ko gba ogo isegun naa fun ara re tabi fun awon eniyan re bikose fun Olorun, o si lo oye ewi ti o ni lati sapejuwe Re. O soro nipa ola-nla Olorun lori Farao, bi o se je eleru-niyin ati awon ise-iyanu Re nipa pinpin Okun Pupa niya. Lotiito, eyi je apeere okan ninu awon ona ti awa Kristiani gbodo gba safihan isegun Olorun lori awon ota wa han. A le ko awon orin idupe ati ti iyin pelu oniruuru ohun elo orin lati jerisi isotiito Olorun si awon eniyan Re. Orin Mose yato gedengbe si awon orin aye ti a saba n gbo lode oni, eyi ti ko ni nnkan se pelu isegun. Pupo ninu won kun fun ibanuje ati ainireti, won si n so nipa igbe-aye ti ko ni ireti. A n gba awa Kristiani niyanju lati ko awon orin ireti, irapada ati ti isegun kuro lowo agbara ese ati iku nipase Kristi Jesu.

AKOKO IJIRORO:
1. Jiroro lori idi ti awon eniyan kan fi maa n se awawi lopo igba dipo ki won yin Olorun fun awon ise-iyanu Re.
2. So die ninu awon apeere orin aye ati ipa buburu ti won n ni lori igbe-aye awon eniyan paapaa julo, awon odo.

B. AWON ORIN IYIN MOSE:
[Eksodu 15:14-18]

Bi o se tesiwaju lati ko awon orin iyin si Olorun fun awon ise-iyanu Re, Mose kede pe awon orileede ti gbo nipa awon ise-iyanu Re, won si
wariri. Ni pataki, o tokasi awon orile-ede kan ati orisii iriri won pelu bi Olorun se fi agbara Re han. Gege bi apeere:

• lkaanu ba awon Filistini. • Enu ya awon baale Edomu.
• Iwariri mu awon alagbara Moabu.
• Gbogbo awon olugbe Kenaani so igboya won nu.

Eemelo ni awa Kristiani maa n ranti isotiito Olorun ki a le fiyin fun Un? Gege bii Mose, awa onigbagbo ninu Kristi gbodo maa moyi Olorun nigba gbogbo ki a si maa korin isegun lati moriri Re. Sugbon o, iha ti a ko si iyin ko gbodo je nitori a ti ri gba nikan, bikose ki a maa yin In fun ohun gbogbo ti O ti se. Itumo eyi ni pe, a ko gbodo gbagbe gbogbo Ise Re, ki a yin Olorun fun awon ibukun Re gege bi Mose ti se ninu ibi kika toni.

AKOKO IJIRORO:
1. Bawo ni awon orin ti a n ko se maa n safihan okan imoore?
2. Kin ni ohun ti Mose n gbiyanju lati so ni ese 17?

D.ORIN IYIN MIRIAMU:
[Eksodu 15:19-21]

Isegun ti lsreli ni lori Egipti ru Mose ati Miriamu arabinrin re soke lati korin ope fun isotiito Olorun. Ibi kika yii se agbekale aworan orin ti Miriamu ko lati sajoyo isegun ti Isreli ni lori awon ota re gege bi orin Mose to wa ni ese 1. O nii se pelu itan bi awon omo lsreli se rin ni ile gbigbe laarin Okun Pupa nigba ti awon ota won (awon ara Egipti ati keke ogun ati elesin won) si segbe. Latari eyi Wolii Miriamu ati awon obinrin naa ko awon orin iyin, won samulo awon ohun elo orin bii tamboriini, won si tun jo pelu. Ese 21 wi pe, Miriamu korin, o da awon obinrin yooku lohun pe. “E korin si OLUWA nitori t O po ni ogo; esin ati elesin ni o bi subu sinu okun” Orin yii ti di gbajugbaja laarin awa Kristiani, paapaa julo ni akoko isin isoji ati akanse adura lodisi ise awon ota.

Olorun ja fun Isreli. Farao ati keke ogun ati awon elesin re ni won ri sinu okun naa. O daju pe, ohun ti eniyan ba gbin ni yoo ka. Miriamu saaju awon obinrin ti won ko ara jo, won si tokasi i gege bi woli obinrin ti on lo ohun didun re ati tanborini, bee lo si fi aayo re han bi o se n jo si orin naa. Olorun ni agbara lati ja fun wa, paapaa julo nigba ti a ba gbekele E fun isegun. Ni ikorita iporuru okan, nigba ti awon omo lsreli dojuko isoro lila Okun Pupa koja ti won si ri awon ota to n bo leyin, eru ba won ki won ma baa mu won, sugbon Olorun dasi i, O si fun won ni isegun. Ni tooto, o je ise-iyanu ti o yanilenu gidigidi, eyi ti o ru Mose, Miriamu ati awon obinrin miiran lokan soke lati ko orin iyin Iati bu ola fun Olorun.

AKOKO IJIRORO:
1. Kin ni ohun ti orin Mose ati ti Miriamu n ko wa nipa Olorun ati agbara Re lati se awon ise iyanu?
2. Nje o ye ki awa Kristiani maa sajoyo iku awon ota wa gege bi o ti ri ninu eko toni?

Mimu lbakegbepo ati Ise Iranse Dagba:
• Se agbekale orin kan to n so die nipa awon amuye Olorun, Jesu Kristi ati Emi Mimo.
• Gba won niyanju lati fi akoko kan sile lati yin Olorun pelu gbogbo ohun elo orin to wa larowoto won.

Awon Eko Ti A Ri Dimu:
▪︎ Ohun rere ni lati korin iyin si Oluwa nigba gbogbo.
▪︎ Olorun si n gba awon eniyan Re ninu ewu.
▪︎ Olorun n gbe ninu iyin awon eniyan Re.
▪︎ A gbodo yago fun awon orin aye ti yoo mu ki okan wa dibaje.
▪︎ Maa murasile lojoojumo lati darapo mo awon ogun orun Iati yin Olorun nisinsin yii ati ni ayeraye.
▪︎ Nigba gbogbo ni Olorun setan lati gbe ija wa.

Leave a Reply