NBC ILE EKO OJO ISIMI FUN Sunday, October 23, 2022: ORI EKO –  ISRELI KO OLORUN SILE, WON FI ENIYAN JOBA

By | October 23, 2022

NBC ILE EKO OJO ISIMI FUN Sunday, October 23, 2022: ORI EKO –  ISRELI KO OLORUN SILE, WON FI ENIYAN JOBA

Read previous NBC Sunday School Mnauals

Sunday, October 23, 2022

Bibeli Kika fun Ipalemo Eko: Samueli kinni 8:4-7, 10:17-26

Bibeli Kika fun Eko: Samueli Kinni 8:1-9

ORI ORO: ISRELI KO OLORUN SILE, WON FI ENIYAN JOBA

Ese lati ranti: eyin si ko olorun yín lonii, eni tí oun tikara Re ti gbà yín kuro lowo gbogbo awon ota yín, ati gbogbo wahala yín; eyin si ti wi fun un pe, beeko, sugbon awa n fe ki o fi enikan joba lori wa. Nisisin yii, e duro niwaju Oluwa nipa eyà yín, ati nipa egbeegberun yín. Samueli Kinni 10:19

Ni opin eko yii, awon omo kilaasi gbodo le e:

1. So idi ti awon eniyan Isreli fi beere fun oba;

2. Daruko awon ona to dara ju ti awon adari Kristiani le e samu

3. So ifarajin won si olorun latimaa gbekele E fun itosona nigba gbogbodi otun.

Oro Isaaju
Ipinnu sise je okan lara awon ise ti o wopo laarin awon eniyan to wa lorile aye, yala eni naa je arugbo tabi omode.Nigba tiolorun seda eniyan, O fun wa ni ominira lati se ipinnu. Nitori naa, nigba gbogbo ni iran eniyan ni ominiral lati se ipinnu -lati
yan eni to n dari wa, ohun ti a feje, mu, wo, ibi ti a o gbe, ibi ti a felo, ati ohun ti a fese ni akoko kan pato.

Sugbon ni opo igba, awa eniyan n si anfaani ominira naa lo, a kii kiyesi awon atubotan to romo iru ipinnu
bee, yala o dunmo olorun tabi ko dun mo on. Awon
wolii ati awon onidajo ni won n dari eya Isreli mejeejila. sugbon ni akoko kan, won fe dabii awon orile-ede ti o yi won ka, ti won ni oba to n dari won.

Nitori naa, won so fun Samueli lati yan eni ti yoo
maa dari won fun won. Wolii Samueli ko faramo ipo
oba naa nitori pe nigba gbogbo niOluwa n dari awon
eniyan Re nipase awon wolii ati onidajo. Bakan naa, o se e se ki awon omo Isreli beere fun oba nitori ti awon omo Samueli mejeeji (Joeli ati Abijah) kii se alawokose bii baba won. Bi o tile je pe, ebe won ko dunmoolorun ninu, O pasefun Samueli latise ohun tiwon beere fun.Ohande pe, ebewon dabii ohun ti o dunmo gbogbo won ninu ayafi Samueli ati olorun.

Inu Samueli ko dun si ebe won fun oba, boya latari pe won fi ogbon ko awon omo rewon ko sife kiwon gba ipo re. Nitooto,inuolorun ko dun nitoriife okanwon lati dabii orile ede yooku (Samueli Kinni 8:20) lodi si ife re.

Idi ti awon eniyan Isreli fi beere fun oba tuntun ni o han kedere ninu oro won ni ibi kika naa. Yato si pe, won fe dabi awon orileede to yi won ka, awon omo Samueli mejeeji ko tele apeere rere baba won. Won jebi esun abetele, didori idajo kodo ati
bee bee lo. Nitori naa, Isreli pinnu lati gbe oro naa to
Samueli lo, ki won si beere fun oba tuntun latari iberu ki awon omo re ma ba a joba lori won. Boya, o ye ki won beere fun oba ti yoo joba lori won pelu isododo ati eyi ti yoo wulo. Bakan naa, awon
eniyan, orile-ede agbaye n ko ijoba Kristi lori won.

Abalajo, ile aye n ke rora labee iwa aiwa-biolorun. Ipinnu lati gba tabi ko Jesu Kristi gege bi Olugbala ati Oluwa maa n ni awon atubotan tire.
Eko ti oni da lori bi Isreli se ko isedari olorun sile lati fi eniyan joba.

ALAYE LORI EKO

A. Ebe Fun oba Kan Samueli Kinni 8:4-7
Samueli lo keyin, oun si ni o po julo ninu awon adari Isreli ti a mo si ‘Awon Onidajo. ‘Bakan naa, oun ni wolii ati eni ti o yan Soolu gege bi oba akoko fun Isreli, o si da a lejo nigba ti o saigboran si olorun nigbeyin. Nigba ti Samueli di ogbo, o fi awon omokunrin re mejeeji je onidajo ni Isreli, sugbon o seni laanu pe, won ko tele apeere rere baba won (ese 1-3). Eyi fun awon eniyan naa ni anfaani lati beere fun oba ti yoo dari won bii awon orile-ede yooku. Awon agbaagba ile Isreli to Samueli lo lati beere fun oba. Won wi pe, “Kiye si i, iwo di arugbo, awon omo re kò si rin ni ìwa re, nje fi enikan je oba fun wa, ki o le maa se idajo wa, bi ti gbogbo orile-ède.” Ohun to fa ebe won ni a le ri ninu oro enu won won fe dabii awon orile-ede yooku. ebe awon eniyan naa ko dunmo Samueli ninu, o si gbadura si Oluwa. Idahun olorun si adura Samueli ko gun rara. O wi fun un pe, “Gbo ohun awon eniyan naa ni gbogbo eyi ti won so fun o, nitori pé iwo ki won ko, sugbon Emi ni won ko lati je oba lori won.”Inu olorun ko dun si ebe won, sugbon O gba won laaye ki won se ife won. olorun ti fun wa ni eto lati yan. Awon ohun ti eniyan ba yan ninu aye ni yoo se aye won ni anfaani tabi ki o se e ni ibi. olorun ko ni fi ipa gbe ara Re le enikeni lori. Abalajo, kii ba wa ja nigba ti a ba yan lati se awon nnkan ni ona ti wa. ebe awon agbaagba naa fihan pe, won ko olorun fun idari ti eniyan. ebe won fun oba se ogboogba pelu fifi abuku kan Samueli ati olorun to n soju fun. Ipo aladari Kristiani je eyi ti o romo ojuse. A gbodo se e pelu isotiito ti o ga julo. O han gbangba pe Samueli fe ki awon omokunrin re mejeeji dari awon eniyan Isreli leyin ti o ti fi won se onidajo, sugbon won ko tele apeere rere baba won. Won je alaisooto, won si n yi idajo po. Bi o tile je peSamueli fi aidunnu re han, olorun je ki o di mimo fun un pe, kii se oun ni won ko sile, bikose Oun ti Oun yan an lati je olori won ni won ko sile. Niwon igba to je eto olorun lati fun awon eniyan ni oba naa 17:14-20), (Diutaronomi sugbon, won ko ni suuru to fun ife Re ti o pe. eko ni eyi je fun awa onigbagbo lati mase “saaju” olorun nipa ileri Re fun wa nitori pe, ni akoko ti o yan, yoo mu ileri Re se dandan. Siwaju sii, nigba yoowu ti a ba se afarawe awon eniyan inu aye, a n ko olorun ati ete Re fun aye wa sile lai mo gege bi o ti ri fun awon eniyan Isreli.

AKOKO IJIRORO
Ni ibamu pelu ibi kika yii, kin 1. ni o ro wi pe o je ese awon omo Isreli pe won beere fun oba?
2. Kin ni awon atubotan kiko ljoba Jesu Kristi sile ninu aye lonii?

B. O fi Soolu han Bi oba fun Isreli Samueli Kinni 10:17-24
A ti fidi ododo naa mule pe, awon eniyan Isreli fe oba gege bi awon orile-ede to yi won ka.Bi o tileje pe, inu olorun ko dun siebe naa, sibe O pase fun Samueli lati gbo ohun tiwon n so leyin ti o ti gbadura (Samueli Kinni
8:7). Nigbeyin, Samueli yan Soolu gege bi oba lori ilsreli (ese 10), o si pe awon eniyan naa jo niwaju Oluwa ni Mispa fun lati yan ati lati fi oba naa han ni gbangba ni ibamu pelu ibeere won. O wi fun won pe, “Báyìí ni Oluwa olorun Isreli wi, Emi mu Isreli goke ti Egipti wá, mo si gbà yín kuro lowo awon ara Egipti, ati kuro lowo gbogbo ijoba wonni ti o pon yín loju. eyin si koolorun yín lonii,eni tí oun tikaraReti gbà yín kuro lowo gbogbo awon ota yín, ati gbogbo wahala yín…”(ese 18-19). A yan eya Benjamini; a mu idile Matri eyi ti Soolu tii se omo Kisi soju. Samuelisi fi i han fun gbogbo eniyan, o si wi fun won pe, “eyin kò rieni tí Oluwa yan fun ara Re, pe, ko sieni tí o dabi re ninu gbogbo eniyan naa” (ese 24). Idahun awon eniyan naa yanilenu
pupo, won hoyeewipe,
“Kiobakiope!” Osidiolori awon eya Isreli (Samueli Kinni15:17).

O se pataki lati mo ni ibi kika yii pe, yiyan Soolu gege bi oba Isreli je ase olorun bi o tile je pe ilana naa ko han si eniyan, yala, boya won se gege ni tabi won gba ona miiran. Sibe-sibe, eya kookan farahan niwaju

Oluwa, Soolu ti o wa lati eya Benjamini si ni a yan. Ni oro miiran, ko si ojusaaju nitori a ko fi oju pa eya tabi idile kankan re. Awon eniyan naa ni idaniloju ninu pe Soolu dangajiya fun ipo oba naa, boya latari awon amuye ti a le foju ri; nitori naa, won pariwo ninu ayo nla pe, “Ki oba ki o pe!” eko nla kan gboogi fun awa onigbagbo ninu eko yii ni pe a nilo lati wa oju olorun nigba gbogbo ninu yiyan adari ni gbogbo ipele. A ko gbodo gba eran ara, irisi, eko, ipo ni awujo ati bee bee lo laaye nigba ti a ba n yan awon adari, paapaa julo ni awujo Kristiani. Bee ni a ko gbodo se bayo-bayo ninu ilana naa nitori ti imotara-eni.

AKOKO IJIRORO
1. Kin ni idi ti awon eniyan Isreli fi ni dandan, awon nilo oba ti yoo joba lori won bi o tile je pe inu olorun ko dun si ebe won?
2. Kin ni awon ohun kan ti awa Kristiani n se eyi ti o le farapee kiko olorun sile ati bi a se le yago fun iru nnkan bee?

Mimu Ibakegbepo ati Ise Iranse Dagba
Je ki o kere tan, awon omo kilaasi meji se alabaapin iriri won pelu oga ti o dara julo ti won tii ba sise ni soki, ki won si se apejuwe ipa ti awon amuye re ni lori won fun kilaasi.

Awon Eko Ti A Ri Dimu
Ko awon eko meta ti on mu lo sile ninu eko ti oni sile

Adura
1. Ran mi lowo Oluwa lati ni itelorun pelu eto ati ete Re fun aye mi.
2. Oluwa, je ki n gbe igbe-aye mi ni ibamu pelu ete ti O fi da mi saye.
3. Oluwa, ran mi lowo lati beere ni ibamu pelu ife Re.

ifarajin
Se ifarajin ti ara-eni lati gbe igbeaye ti o te olorun lorun, ti kii si se lati te awon eniyan lorun

Leave a Reply