YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL FUN ỌJỌ́ KẸTÀLÉLÓGÚN, OSÙ KẸWÀÁ, ỌDÚN 2022: ÌJẸGÀBA TI ÒṢÈLÚ

By | October 23, 2022

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL FUN ỌJỌ́ KẸTÀLÉLÓGÚN, OSÙ KẸWÀÁ, ỌDÚN 2022: ÌJẸGÀBA TI ÒṢÈLÚ

KA AWON EKO ATI EYIN WA NIHIN YI

YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER’S MANUAL
Ẹ̀KỌ́ KẸJỌ : ÌJẸGÀBA TI ÒṢÈLÚ
ỌJỌ́ KẸTÀLÉLÓGÚN, OSÙ KẸWÀÁ, ỌDÚN 2022.

ÀDÚRÀ ÌBẸ̀RẸ̀: Baba, ràn mí lọ́wọ́ láti ní òye ìjẹgàba èyí tí ẹ fifún ènìyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.

ÌMỌ̀ ÀTẸ̀HÌNWÁ: Kí olùkọ́ ṣe àtúnsọ ẹ̀kọ́ ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá.

BÍBÉLÌ KÍKÀ: Gẹnẹsisi 1:26-28.
26. Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi irí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ. 27. Bẹ̃li Ọlọrun dá enia li aworan rẹ̀, li aworan Ọlọrun li o dá a; ati akọ ati abo li o dá wọn. Ọlọrun si súre fun wọn.
28. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si ma jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alãye gbogbo ti nrakò lori ilẹ.

ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: “Ìwọ sì ti ṣe wọ́n ní ọba àti àlúfa sí Ọlọ́run wa, wọ́n sì n jọba lórí ilẹ̀ ayé’ Ifihan 5:10.

ÀFIHÀN: Ọ̀rọ̀ tí a pè ní ìjẹgàba tùmọ̀ sí dídarí tàbí agbára lórí nǹkan, Ọlọ́run ní agbára tí ó ga jùlọ àwọn ohun tí ó da àti pẹ̀lú pín àsẹ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn láti ní àsẹ lórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ (Gẹn.1:26, Orin Daf.8:6). Síbẹ̀ àwọn Kristiẹni kò ní òye bẹ́ẹ̀ wọn kò sì ríi pé Ọlọ́run fẹ́ kí ìjọ gba àkóso àti jẹgàgba lórí ágbègbè wọn.Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n rí àṣẹ Ọlọ́run fún àwọn onígbàgbọ́ láti wàásù ìhìnrere nìkan gẹ́gẹ́ bi àsẹ lè ríi nínú ìwé (Mat.28:19-20). Tí wọ́n sìn dúró de Ọlọ́run láti ṣe àtúnṣe àwùjọ fúnra rẹ̀.

ÀKỌSÍLẸ̀ OLÙKỌ
ÌLÉPA Ẹ̀KỌ́: Láti tọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ sínú ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ti òmìnira.

ÈRÒǸGBÀ ÌKỌ́NÍ: Ní òpin ẹ̀kọ́ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní láti lè:
a. Ní ìmòye Ọlọ́run nípa ìjẹ̀gaba. b. Ní òye bí ìjẹ̀gaba tí òṣèlu tín ṣíṣe. d. Ní òye ojúṣe àwọn onígbàgbọ́ nínú lílò ìjẹgàba.

ÈTÒ ÌKỌ́NI: Láti ní ìmúsẹ àwọn kókó òkè wọ̀nyí, ki ́olùkọ́:
a. Fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láàyè láti ka ẹsẹ̀ àkọ́sórí, ka Bibeli kíkà, dásí ìfọ̀rọ̀wérọ̀, ṣe iṣẹ́ yàrá ìkàwé ṣíṣe àti iṣẹ́ àmúrelé. b. Fún igbákejì, olùkọ́ ní ánfààní láti ṣe àbójútó yàrá, ìkẹ́kọ̀ọ́ fi máàkì fún àwọn tí wọ́n wá àti iṣẹ́ àmúrelé. d. Kọ́ àwọn ìlànà ẹ̀kọ́, ṣe àkójọpọ̀, ìkáàdí, yànnàná ẹ̀kọ́ àti pẹ̀lú fún wọn ni iṣẹ́ àmúrelé.

ÀTÚNYẸ̀WÒ BÍBẸ́LÌ KÍKÀ: Gẹnẹsisi 1:26-28.
Ní àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run wípé, kí á dá ènìyàn ni àwòrán ara rẹ̀, kí ó sì máa jẹgàba lórí àwọn ohun náà tí ó dá, ẹsẹ 26.
Nítorí náà—————————————-ẹsẹ 27.
Ọlọ́run sì bùkún ——————————ẹsẹ 28.
ỌGBỌ́N ÌKỌ́NI:
Ọgbọ́n ìkọ́ni alálàyé.

LÍLÒ ÀKÓKÒ:.Kí olùkọ́ lo àkókò tí o wà fún ìlànà ẹ̀kọ́ méjèèjì.

ÀWỌN ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́
1..Ẹ̀KỌ́ ÈSÌN NÍPA ÌJÈGÀBA
2..ÌHÀ TÍ ÀWỌN KRÌSTÌẸ́NÌ KỌ SÍ ÌJẸGÀBA TI ÒṢÈLU

1..Ẹ̀KỌ́ ÈSÌN NÍPA ÌJÈGÀBA
A. Kí olùkọ ṣàlàyé ìtumọ̀ ìjẹgàba ìmọ̀ Ọlọ́run báyìí:
i. Ìjẹgàba ìmọ Ọlọ́run ń tọ́ka si ọ̀nà láti rónú pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí ipa ìjọ ní àwùjọ tí a wà yìí
ii. Ó jásí wípé àwọn Kristiẹni ní láti pàsẹ lórí gbogbo ipa ní àwùjọ, ara ẹni àti pẹ̀lú fọwọ́-sowọ́pọ̀ pẹ̀lú òfin Ọlọ́run.
iii. Ìgbàgbọ́ yìí dá lórí Genesisi 1:28, tí ó wí pé “ẹ máa bísi, kí e sì máa rẹ̀ si kí esì gbilè, kí ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀.”
iv. Gen 1:28 jẹ́ asẹ àtòkèwá láti jẹgàba lórí ilẹ̀ aye, ara, ẹ̀mí, ìṣúná, ọrọ ajé, Òsèlú abbl (Lk 19:13).
v. Òye ìmọ̀ Ọlọ́run nípa àwọn Kristiẹni láti jẹgàba lórí òṣèlú fi ẹsẹ̀ mulẹ̀ nínú:
a. Ọlọ̀run àti òtítọ́ rẹ̀.
b. Pàtàkì ìdájọ́ òdodo.
d. Pàtàkì òmìnira àti.
e. Òye ìjìnlẹ̀ ènìyàn gẹ́gẹ́ bí a ti dáa ní àwòrán Ọlọ́run (O.D 82:6, Jn 10:34).
ẹ. Fún wípé a sẹ̀dá àwọn Kristiẹni fún títàn (O.D. 92:12-13).
f. A pè wá sí àyànmọ́ ayérayé (Rom 8:30).
Ẹ̀kọ èsìn nípa ìjègàba tọ́ka sí ọ̀nà láti rónú pẹ̀lú ipa ìjọ ní àwùjọ tí a wà yìí. Ó jásí pé àwọn Kristiẹni ní láti pàsẹ lórí gbogbo ipa ní àwùjọ, ara ẹni àti pẹ̀lú fọwọ́-sowọ́pọ̀ pẹ̀lú òfin Ọlọ́run ìgbàgbọ́ yìí da lórí Genesisi 1:28, tí ó wí pé “ ẹ máa bísi, kí e sì máa rẹ̀ si kí esì gbilè, kí e sì jẹ̀gàba“ Ẹsẹ̀ Bibeli yìí jẹ́ àsẹ àtokèwá láti jẹgàba lórí ilẹ̀ ayé, ara, ẹ̀mí, ìṣúna ọrọ̀ ajẹ, òṣèlú abbl (Luk.19:13) Òye ìmọ̀ Ọlọ́run nípa àwọn Kristiẹni láti jẹ̀gàba lórí òṣèlú ni ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ti Ọlọ́run àti òtítọ́ rẹ̀; pàtàkì ìdájọ́ òdodo, pàtàkì ìjẹgàba àti òye tí ó jinlẹ̀ (O.Daf.92:12-13) àti pẹ̀lú sí àyànmọ́ ayéraye (Rom.8:30).

IṢẸ́ ṢíṢe Kíláàsì Kínní: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jíròrò pọ̀ lórí ìdí tí àwọn onígbàgbọ́ kan kìí ṣe fẹ́ láti máa darí.

2. ÌHÀ TÍ ÀWỌN KRÌSTÌẸ́NÌ KỌ SÍ ÌJẸGÀBA TI ÒṢÈLU
A. Kí olùkọ́ fi gbòǹgbò ìtàn òṣèlú mulẹ̀ nínú ìjọ:
i. Ìfẹ́ inú àwọn Kristiẹni ìjọ ìgbaanì jẹ́ ohun tí a lè tọ pinpin de àkókò tí Isreali pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-ede aláìgbàgbọ́ kan nbẹ lábẹ́ aṣẹ ìṣàkóso ti Romu tí a sì kọ́ àwọn láti máa tẹríba sí àwọn àṣẹ náà (Rom 13:1) ní pàtàkì jùlọ wọ́n ní láti gbàdúrà fún àwọn tí ń bẹ ní ipò aṣẹ tí wọn kò sì lè darapọ̀ nínú òṣèlú àkókò wọn (1Tim 2:1-2).
ii. Èyí sì lè jẹ́ okùnfà sí ìfàsẹ́hìn àwọn Kristiẹni láti máse darapọ̀ nínú òṣèlú àkókó yìí, sùgbọ́n Ọlọ́run náà tí a gbàgbọ́ tí a sì ń sìn ni inù dídùn nínú ọ̀nà tí à ń gbà ṣe àkóso ayé. (Gen 1:28).
iii. Sàtánì ti jí “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjẹgàba” nígbà ti ó tan Adamu àti Efa jẹ.
iv. nígbà tí Kristi fi kọ́kọ́rọ́ ìjọba náa fún Peteru nínú Matiu 16:19 Ójẹ́ àmì wípé, ìjẹgàba ti padà tọ ènìyàn wá.
v. Nísisìyí ojúṣe wa ni láti “gba padà” ohun náà tí ó jẹ́ẹ̀tọ́ rẹ.
vi. Ìjẹgàba tí òṣèlú jẹ́ dandan fún gbogbo Kristiẹni, bẹ́ẹ̀ sì ni kìí, yíyàn nítorí orílẹ̀ ayé jẹ́ àyè fún wa láti jẹgàba, kìí ṣe ọ̀run (O.Daf.115:16) ipa tí ó dára ní ipò àṣẹ.

B. Kí olùkọ́ ṣàlàyé ìhà tí àwọn onígbàgbọ́ kọ sí ìjẹgàba ti òṣèlú báyìí:
i.Òtítọ́ ni wípé àwa nbẹ ní ìhà tí ìjọba ọ̀run kìí si ṣe ti ayè yìí, a sì kà wá mọ́ àwọn ènìyàn inú ayé yìí tí a sì ń gbọ́ràn sí àwọn òfin àti ìlànà ìjọba rẹ̀.(Jn 17:15-16).
ii. Nítòótọ́, àwa ń ṣàférí ilé mìíràn (Heb.11:10, 14, 13:14) ṣùgbọ́n èyí kò gbọdọ̀ jẹ́ àwáwí láti jẹ́ aláìbìkítà nípa ibùgbé wa ti ayé kí á sì kọ̀ láti màa ṣe ojúṣe tí ó yẹ fún ṣíṣe ètò ìjọba re. O.D. 115:16.
iii. Òtítọ́ tún ni pé ayé ń rékọja lọ (1Kọr.7:31). Ṣùgbọ́n kí á máṣe gbàgbé wípé àwa yóò jíhìn gbogbo ohun tí a ṣe nínú rẹ̀ kí ó tọ́ rékọjá lọ (1Joh.2:17).

D. Fún ìdí èyí ó yẹ láti jẹ́ ẹ̀dùn ọ̀kàn fún àwọn Kristiẹni:
i. Láti darapọ̀ mọ́ ìgbésẹ̀, ìpinnu tí ó ga náà láti ríi dajú pé ìdájọ́ òdodo jẹ́ síṣe.
ii. Àwọn àgbekalẹ̀ ìlànà Bibeli jẹ́ olúborí tí ìgbàgbọ́ àwọn Kristiẹni sí jáwé olúborí àti pípamọ́ (O.D. 33:5, Mk 6:8).
iii. Gẹ́gẹ́ bí iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ayé nígbà ti a bá darapọ̀ nínú òṣèlú àti ṣíṣe ìjọba, kí a jẹ́ agbẹnusọ fùn àwọn wọnnì tí kò lè sọ̀rọ̀ jáde kí á sì máa jà fún ètọ́ àwọn òtòṣì àti aláìní (Owe 31:8-9).
Ìgbádùn òṣèlú àwọn Kristiẹni ti ìjọ àkọ́kọ́ ni a lè tọ pinpin rẹ̀ débi wípé Isreali àti àwọn orílẹ̀ èdè aláìgbàgbọ́ kan n bẹ lábẹ́ àṣẹ ìtẹ̀dó ìlú míràn ti Romu àti pé a kọ́ àwọn Kristiẹni láti jọ̀wọ́ ara wọn sí àwọn àṣẹ tí ó wà (Rom.13:1) tí ó dára jùlọ, Wọ́n ní láti gbàdúrà fún àwọn tí ó wà ní ipò agbára tí wọn kò sì le darapọ mọ òsèlú àkókò wọn (1 Tim.2:1-2) Èyí sì lè jẹ́ okùnfa sí ìfàsẹ́hìn àwọn Kristiẹni láti máse darapọ̀ nínú òṣèlú àkókó yìí, sùgbọ́n Ọlọ́run náà tí a gbàgbọ́ tí a sì ń sìn ni inùdídùn nínú ọ̀nà tí à n gbà ṣe àkóso ayé (Gẹn.1:28).
Satani ti jí “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjẹgàba” nígbàti ó tan Adamu àti Efa jẹ. Nígbà náà, nígbàtí Kristi fi kọ́kọ́rọ́ ìjọba náa fún Peteru nínú Matiu 16:19, Ójẹ́ àmì pé, ìjẹgàba ti padà tọ ènìyàn wá. Nísisìyí ojúṣe wa ni láti “gbàá padà” ohun náà tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ rẹ. Ìjẹgàba ti òsẹ̀lú jẹ́ dandan fún gbogbo Kristiẹni, bẹ́ẹ̀ sì ni kìí se yíyàn, nítorí orílẹ̀ ayé jẹ́ àyè fún wa láti jẹgàba, kìí ṣe ọ̀run (Orin Daf.115:16).awà ní ìhà ìjọba ti ọ̀run tí kìí si ṣe ti ayè yìí, a sì kà wá mọ́ àwọn ènìyàn inú ayé yìí tí a sì ń gbọ́ràn sí àwọn òfin àti ìlànà ìjọba rẹ̀ (Joh.17:15-16). Nítòótọ́ àwá ń ṣàfẹ́rí ilé mìíràn (Heb.11:10, 14, 13:14) ṣùgbọ́n èyí kò gbọdọ̀ jẹ́ àwáwí láti jẹ́ aláìbìkítà nípa ibùgbé wa ti ayé kí á sì kọ̀ láti màa ṣe ojúṣe tí ó yẹ fún ṣíṣe ètò ìjọba rẹ̀ (Orin Daf.115:16) Òtítọ́ tún ni pé ayé ń rékọja lọ (1 Kọr.7:31).
Ṣùgbọ́n kí á máṣe gbàgbé wípé àwa yóò jíhìn gbogbo ohun tí a ṣe nínú rẹ̀ kí ó tọ́ rékọjá lọ (1Joh.2:17).
Nítorínà, ó yẹ kí ó jẹ́ ìpinnu tí ó ga jùlọ ní síṣe fún Onígbàgbọ́ láti ríi dájú pé à ń ṣe ohun tí ó tọ́ nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run kí ìgbàgbọ́ àwọn Kristiẹni sì dúro ṣinṣin (Orin Daf.33:5, Mak.5:13-16) nígbà ti a bá darapọ̀ nínú òṣèlú àti ṣíṣe ìjọba, kí a jẹ́ agbẹnusọ fùn àwọn wọnnì tí kò lè sọ̀rọ̀ jáde kí á sì máa jà fún ètọ́ àwọn òtòṣì àti aláìní (Owe 31:8-9).

IṢẸ́ ṢíṢe Kíláàsì Kejì: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ àwọn ipa àyè tí wọn yóò ti ṣe àyípadà rere tí wọ́n bá ní àǹfààní láti wà ní ipò agbára.

ÀKOJỌPỌ̀: Níní òye ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa ìjẹgàba òṣèlú yóò mú àwọn onígbàgbọ́ láti gba ipò ẹtọ́ wọ́n nínú ìdarí káàkiri àgbáyé.

ÌPARÍ: Gbogbo Kristiẹni jẹ́ Olóṣèlú bóyá a mọ̀ tàbí, bẹ́ẹ̀ kọ́, tí a bá kọ̀ láti darapọ̀ nínú Òṣèlú, Ó túmọ̀ sí wípé a faramọ́ bí ohun gbogbo ṣe n lọ.

ÌBÉÈRÈ:
* Ṣàlàyé Ìjegàba nípa ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn.
*.Dárúkọ ìwà àwọn Kristiẹni mẹ́ta sí ìjẹgàba ti Òsèlú.

ÌYÀNNÀNÁ: Kí olùkọ́ pe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ nípa òye wọn lórí ìmọ̀ ìjẹgàgba.

ÀDÚRÀ ÌPARÍ: Baba, mo gba ore ọ̀fẹ́ láti máa jẹgàba ní ipa gbogbo.

ISẸ́ ÀMÚRELÉ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ èrèdí márùn-ún tí àwọn Kristiẹni kan se máa ń bẹ̀rù láti darapọ̀ níṅú òṣèlú (Máàkì Mẹ́wàá)

Leave a Reply