ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ    Ọlọ́run nínú Ìṣàkóso Ènìyàn.    ÌSỌRI KÍNNÍ: NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ      Ẹ̀KỌ́ KẸTA /Apa Kejì.

By | February 23, 2020

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ    Ọlọ́run nínú Ìṣàkóso Ènìyàn.    ÌSỌRI KÍNNÍ: NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ      Ẹ̀KỌ́ KẸTA /Apa Kejì.

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ

Ọlọ́run nínú Ìṣàkóso Ènìyàn.

ÌSỌRI KÍNNÍ: NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ

Ẹ̀KỌ́ KẸTA /Apa Kejì.

February 23, 2020.

II.   ṢÁÁJÚ TẸMPILI SOLOMONI (I Sámúẹ́lì 22:11-23; 2 Sam. 15:24-35; I A. Ọba 1:8,26,32-40; 2:22-27, 34,35).

Ọlọ́run ṣe imuduro ìṣẹ́ àwọn àlùfáà O sì jẹ ki ó wa ṣáájú kíkọ tẹmpili Sólómọ́nì àti lẹhin rẹ, nítorí pé o jẹ ara eto/alakalẹ Rẹ.

A.   ÌṢẸ́ ÁBÍÁTÁRÌ (1 Sam. 22:22-23; 2 Sam. 15:24-35; I.A. Ọba 2:26,27 7).

O si ba Jóábù, ọmọ Seruiah, àti Ábíátárì, àlùfáà, gbèrò: wọn si n ran Ádóníjà lọwọ 1 A. Ọba 1:7).

i.    I Sam. 22:11-23: Ọlọ́run nínú ìpèsè Rẹ ran Ábíátárì lọwọ láti jẹ ẹnìkan ṣoṣo tí o moribọ nínú ogun ìpakúpa àwọn àlùfáà Rẹ ti ọba Sọ́ọ̀lù gbé dìde. Kín ni ìdí tí Ọlọ́run ṣe gba irú iṣẹlẹ tí o burú jáì bẹẹ láàyè láti deba àwọn ènìyàn tiRẹ?

ii.   Ọlọ́run ní Ọlọ́run títì lae. O wa ni ọrun, O si n ṣe ohun tí o wu U. “Ko si ohun ti o le ṣẹlẹ̀ láìsí imọtẹ́lẹ̀ Rẹ,” nitori O da ohun gbogbo fún ìfẹ́ inú Rẹ (Rom. 11:36; Ifih. 4:11).

iii.   2 Sam. 15:24-35: Ọlọ́run pa Ábíátárì mọ́ fún ìtẹ́siwaju ìṣẹ́ alufaa, kí i ṣe pé nítorí tí o jẹ ẹni mimọ tàbí dára ju. O tilẹ wa pada di olórí àlùfáà. Njẹ o ja fun un bi? Bẹẹ kọ. Ìpèsè Ọlọ́run ni.

iv.  Ọgbọ́n ni o jẹ láti mọ, kí a sì máa gbìyànjú láti sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run láti mú erongba ti O n tẹsiwaju láti mu dúró àti láti pa ọ mọ fún ṣẹ.

v.   I A. Ọba 2:26,27: Igbesẹ láti gbójú kúrò lára Ọlọ́run sáábà máa ń mú àjálù àti ijakulẹ tí kìí latunse lọ́wọ́. Pẹ̀lú gbogbo ìṣeun àti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, báwo wa ni Ábíátárì ṣe sọ àfojúsùn rẹ nípa Ọlọ́run nù láti ditẹ lòdì sí òfin Ọlọ́run? (1:7). A papa yọ ọ dànù kúrò ní ipo gíga náà, a si fẹ’lómìnira rọ́pò rẹ nígbẹhin, ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ (wo 1 Sam. 2:27-36).

vi.  Ọlọ́run fìyà jẹ adari to síwáhu náà fún sisoju erongba àti eto ayérayé Rẹ lọ́nà tí ko tọ. Ọlọ́run ti ko ṣe e bí lẹjọ, Ẹni tí o pe wa àti Ẹni ti O ran wa niṣe, le yọ èyíkéyìí nínú àwọn tí O yàn sípò tí wọn ba síwáhu dànù, gẹgẹ bi orílẹ̀-ede ṣe máa n yọ aṣojú tó ba soju rẹ lọ́nà tí ko bójú mú dànù.

B.   IPA TÍ SÁDÓKÙ KO (I.A. Ọba 1:8,26,32-40; 2:22-27,34,35).

Ṣùgbọ́n Sádókù àlùfáà, àti Bẹnáyà, ọmọ Jèhóádà, àti Nátánì wolii, àti Simei, àti Rei, àti àwọn ọkùnrin alágbára tí n bẹ lọdọ Dáfídì, ko wà pẹ̀lú Ádóníjà (I.A. Ọba 1:8).

i.    Ẹsẹ 8: ‘Ṣùgbọ́n’ n safihan ìyàtọ̀ tó hàn kedere láàrin Sádókù àti Ábíátárì. Tani Sádókù yìí? Ọmọ Léfì kan, àlùfáà, tí o sin pẹlu Ábíátárì lakoko isejọba Dáfídì (2 Sam. 15:24-35). Ṣé òun ni olórí àlùfáà bí? Bẹẹ kọ. Síbẹ̀, o ya ara rẹ sọtọ. Ọlọ́run a máa lo àwọn ènìyàn to ṣe olóòótọ́ bẹẹ.

ii.    Sádókù gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run láti ya ara rẹ sọtọ. Oun ati àwọn mìíràn kan kọ láti dára pọ mọ ìdítẹ Ádóníjà. Iha tani ìwọ wa, Ọlọ́run tàbí sátánì?.

iii.   Ẹsẹ 26,32-40: Nítorí tí o yàn láti tẹle Ọlọ́run, wọn mọ-ọn-mọ yọ ọ lẹgbẹ. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run, tí ki I dojú tí ẹni tiRẹ, sọ ọ di ẹni to wulo. Òun ni o wà níkalẹ láti fi ọba tuntun jẹ àti arọpo Dáfídì.

iv.   2:22-27: Koda, bí Sólómọ́nì ko tilẹ̀ ni ipa Ábíátárì fún àwọn ìdí pàtàkì kan, a ti mú ìṣẹ́ àlùfáà rẹ kúrò a si ti fi fún ẹlòmíràn, ẹni tí o túbọ̀ safihan òtítọ́ si Ọlọ́run.

v.    Ẹsẹ 34,35: Lai si idaduro, Sádókù gba ipò Ábíátárì, bí ọba tuntun ṣe n ṣe atunto igbimọ ọba ní ìbámu pẹlu eto Ọlọ́run. Nípa èyí, ìṣẹ́ Ọlọ́run kì yóò wọlẹ bo ti wu ko ri.

vi.   Ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run máa n ni olurọpo ní arọwọto fún ipo kan pàtó láti ríi dájú pe ko si àlàfo nínú ìṣẹ́ Rẹ, bí o bá ṣẹlẹ̀ pé ẹni to wa ni ipo náà lọwọlọwọ tasẹ agẹrẹ. Ọlọ́run yàn Sádókù láìní àbùkù láti gba ipo Ábíátárì to siwahu. Ìṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ tẹsiwaju lẹhin àṣìṣe Ábíátárì. Yàtọ̀ sí pé ẹnikẹ́ni ní láti wa lẹhin ifẹhinti rẹ, maa fọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ki ó má a ba a di ẹni ti a le jáde/dànù kúrò nínú Rẹ.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1.   Ko gbọdọ sì ìkòríta kankan nínú ayé wa ti a gbọdọ fi ọwọ gbẹfẹ́ mú eto Ọlọ́run tàbí sọ ọ di ohun tí ko ṣe pàtàkì.

2.   Nígbà tí a ba fojú yẹpẹrẹ wo Ọlọ́run, Oun naa yoo fojú yẹpẹrẹ wo wa, ṣùgbọ́n oore-ọ̀fẹ́ àti ọlá wa fún ẹnikẹ́ni tí ó ba n bọlá fún Ọlọ́run àti àwọn ohun ìní Rẹ.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1.   Kin ni iṣẹ́ àlùfáà àwọn onigbagbọ túmọ̀ si?

2.   Kín ni ìdí tí Ọlọ́run fi nílò àwọn àlùfáà?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ KÍNNÍ

i.   “Ìṣẹ́ àlùfáà àwọn onigbagbọ” túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn onigbagbọ nínú Kristi Jésù ni àlùfáà (ìránṣẹ́) si Ọlọ́run.

ii.    Nínú májẹ̀mú láéláé, a máa ń yan àwọn àlùfáà láti inú ẹ̀yà Léfì nìkan, àti ní Pàtàkì, nínú ìran Áárónì.

iii.   Ṣùgbọ́n nisinsin yìí (Májẹ̀mú Tuntun), èyí ko ri bẹẹ mọ. Nípasẹ̀ Jésù Kristi, gbogbo Kristẹni ni o jẹ àlùfáà Ọlọ́run fún ìṣẹ́ rere àti ìṣẹ́ ìsìn tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà (Efe. 2:10).

iv.   A n beere lọ́wọ́ gbogbo wa lati ṣíṣẹ kí a sì máa ṣíṣẹ ìránṣẹ́ fún Ọlọ́run. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa rúbọ ìyìn àti ọpẹ tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà (Rom. 12:1-3).

v.   Ọrẹ/ìrúbọ tí Ọlọ́run nílò nisinsin yìí, ní láti yọnda ara rẹ, ìyẹn ni, yíyọdá ara ẹni, kiise ẹranko mọ màlúù, ewurẹ, ọdọ àgùntàn, tàbí ẹyẹ abbl. Àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè fún nísinsìn yìí ni ẹbọ ààyè mimọ àti ìtẹ́wọ́gbà, kí ìṣe ẹbọ òkú.

vi.   Àwọn àlùfáà Májẹ̀mú Láéláé máa n ní láti pa ẹran kí wọn si fọn ẹ̀jẹ̀ rẹ fún ètùtù. Èyí tí yipada pẹ̀lú agbekalẹ tuntun. Ẹ̀jẹ̀ ẹran kò ní agbára mọ láti mú ẹṣẹ kúrò, nítorí Jésù ti fi ẹ̀jẹ̀ àti ara Rẹ ṣe ìrúbọ gẹ́gẹ́ bí ètùtù, lẹẹkan ṣoṣo àti fún gbogbo ẹda eniyan. Ohun tí agbekalẹ ìṣẹ́ àlùfáà tí Májẹ̀mú tuntun ń ṣe nísinsìn yìí, ní ki wọn maa fi ara wọn fún Ọlọ́run lojoojumọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ààyè. Wọn jẹ òkú sì ẹṣẹ ṣùgbọ́n alààyè sì Ọlọ́run.

vii.  Ìṣẹ́ àlùfáà àwọn onigbagbọ ń sọ nípa aṣọ ìbòjú/aṣọ ìlékè tí a mú kúrò náà, èyí tí o jẹ ìdiwọ̀ sì níní oore-ọ̀fẹ́ láti tọ Ọlọ́run wa fúnra ẹni (Eks. 26:31-33; Lk. 23:45; Heb. 9:3,8; 10:19-20). O n sọ nípa níní ibasepọ tààrà pẹ̀lú láìsí idasi ẹnikẹ́ni.

viii. Ìṣẹ́ àlùfáà tí àwọn onigbagbọ wa lati mú Iwe mímọ́, láti inú ẹ̀mí, o si n tọ́ka sí agbekalẹ Ìṣẹ́ Àlùfáà Tuntun gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe idasilẹ rẹ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù.

ix.   Àwọn kristẹni ko nílò alarena mọ láti tọ Ọlọ́run lọ: wọn jẹ ìjọba àlùfáà fún Ọlọ́run (Ifi. 1:6), wọn yóò sì máa jẹ àlùfáà Kristi, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò máa jọba pẹlu Rẹ ni ẹgbẹ̀rún ọdún (20:6). Nítorí náà, kí ìṣe ìròyìn mọ wí pé awa jẹ àlùfáà Ọlọ́run. Ẹ jẹ ki a maa rìn nínú iwa mimọ àti ìsọdi mimọ, kí a si fi ara wa fún Ọlọ́run ní ẹbọ tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà nígbà tí a ba n ṣíṣẹ ìfẹ́ àti idalare Ọlọ́run fún ayé.

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ KEJI

1.   Lọ sí ìpín I. ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ fún irú ẹni tí àwọn àlùfáà jẹ àti 2. ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN

ii.    Síwájú sii, ìṣẹ́ àlùfáà kí ìṣe fún awada, ko si ẹni to fipá mú Ọlọ́run tàbí gba Ọlọ́run ní ìmọ̀ràn láti ṣe idasilẹ ipò àwọn àlùfáà. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Olódùmarè, tí O máa ń ní erongba, O ṣe agbekalẹ ìṣẹ́ àlùfáà láti inú ìfẹ́ ọkàn ara Rẹ gẹ́gẹ́ bí Òun ko ti nílò ẹnikẹ́ni láti ba A sọ̀rọ̀ kí O to bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ isẹ̀dá.

iii.   Àwọn àlùfáà wa lati maa sójú Ọlọ́run.

iv.   Wọn ní láti máa ṣíṣẹ ìránṣẹ́ fún Ọlọ́run àti fún àwọn ènìyàn Rẹ.

v.    Wọn ní láti máa rúbọ sí Ọlọ́run.

vi.   A fun wọn ní ojúṣe láti máa fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

vii.  Wọn máa ń gbé ẹrù àwọn ènìyàn ru: Áárónì ní orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí Israẹli ni èjìká rẹ — efodu náà.

viii. Wọn ní láti máa fi Ọlọ́run hàn àwọn ènìyàn tàbí lọ síwájú Ọlọ́run ṣáájú àwọn ènìyàn.

Nipataki, Ọlọ́run ṣe idasilẹ ipò mimọ yìí kì a le maa ṣíṣẹ fún Un àti fún àwọn ènìyàn Rẹ. Njẹ a sì wa lójú ìlà bí? Rántí pé, Áárónì pàápàá sọ àfojúsùn rẹ nù ti ó sì pàdánù rẹ, tí o sì ṣe lòdì sí alakalẹ ipò rẹ. Ọlọ́run paarọ rẹ. Èyí ló ní jẹ ìpín wa ni orúkọ Jésù. Àmín.

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI :

Ọlọ́run lágbára láti soju araRẹ; Òun kò nílò ẹnikẹ́ni láti ṣe èyíni fún Un, ṣùgbọ́n niwọn ìgbà tí Òun ti yàn láti yan àwọn àlùfáà lati maa soju Rẹ larin àwọn ènìyàn Rẹ, àwọn àlùfáà tuntun tí a gbé kalẹ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ máa rí èyíni gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́/anfaani ọ̀tọ̀, kí wọn sì máa ṣe iṣẹ́ sisoju Ọlọ́run náà bo ti yẹ kó gbọ́dọ̀ sì idagẹ́gẹ́/mimẹhẹ. Lai jẹ bẹẹ, a o kan dabi aṣojú orílẹ̀-èdè kan pàtó tí a da padà lẹ́nu ìṣẹ́ ilẹ-òkèèrè nítorí pé òun kò le soju orílẹ̀-èdè rẹ bí o ti tọ. A o ni kùnà, ní orúkọ Jésù. Àmín.

IGUNLẸ:

Eyi ni opin ẹ̀kọ́ kẹta. A kò lè yàn láti soju Ọlọ́run lọ́nà aitọ ni iru àkókò tó ṣe Pàtàkì tí I ṣe ìgbà ikẹhin yìí. Ayé ni lati ri Ọlọ́run nípasẹ̀ wá nínú ìṣe àti nínú ọrọ. Àwa ní episteli tí ayé ń ka. Ayé ń fi ìkánjú béèrè lọwọ wa lati fi Baba náà hàn wọn, gẹgẹ bí àwọn òǹdè ọmọ Israẹli nínú aginjù ṣe beere lọ́wọ́ Áárónì láti fi Ọlọ́run ti O mú wọn jáde láti Egipti wa hàn wọn, o pari èyí nípa ṣíṣe agbekalẹ ère màlúù kan (òrìṣà). Ìwọ kò le fúnni ní ohun tí ìwọ kò ní. Kí ìwọ tó le fi Ọlọ́run hàn fún ayé, o gbọ́dọ̀ tí mọ Ọn dáadáa ki o si máa ṣojú Rẹ ni kíkún. Àdúrà àtinuwa wá ní pe iwọ ko ni ṣojú Ọlọ́run lọ́nà aitọ, ní orúkọ Jésù.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KEJI

Mon. 17: Ọlọ́run Nilo Ìṣẹ́-Àlùfáà Gíga àti Pípé (Héb. 7:7-11)

Tue.  18: Ìṣẹ́ Àlùfáà Pípé Ọlọ́run Láti Inú Ẹ̀yà Júdà (Héb. 7:12-14)

Wed. 19: Ọlọ́run Ṣe Jésù Ní Àlùfáà Tí Ń Fúnni Ní Iye (Héb. 7:15,16)

Thur. 20: Ọlọ́run Dá Májẹ̀mú Ìṣẹ́ Àlùfáà Jésù (Héb. 7:17-21)

Fri.    21: Ìṣẹ́ Àlùfáà Kristi Wà Titi Láé (Héb. 7:22-24)

Sat.   22: Ìṣẹ́ Àlùfáà Kristi Ń Gba Wa Là Ó Sì N Pawa Mọ (Héb. 7:25-28).

Leave a Reply