IJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ  Ẹ̀KỌ́ ILE ẸKỌ ỌJỌ ÌSINMI  (ẸBI ÌJỌBA ỌRUN) FUN MARCH 20 ATI 27, 2022 : ÀKÒRÍ – AGBÁRA IMỌ

By | March 20, 2022

IJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ  Ẹ̀KỌ́ ILE ẸKỌ ỌJỌ ÌSINMI  (ẸBI ÌJỌBA ỌRUN) FUN MARCH 20 ATI 27, 2022 : ÀKÒRÍ – AGBÁRA IMỌ


KA AWON EKO ATI EYINWA NI BI

IJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI NÍ ÀGBÁYÉ

Ẹ̀KỌ́ ILE ẸKỌ ỌJỌ ÌSINMI

(ẸBI ÌJỌBA ỌRUN)

ÀKÒRÍ GBÒÒRÒ: Ẹ MAA DÀGBÀ NÍNÚ OORE-Ọ̀FẸ́ ÀTI NÍNÚ IMỌ OLÚWA

OṢÙ KÍNNÍ – OṢÙ KẸFÀ, 2022

ÌSỌRI KEJI: IMỌ OLÚWA WA

MARCH 20 ÀTI 27, 2022

Ẹ̀KỌ́ KÀRÚN-UN

ÀKÒRÍ: AGBÁRA IMỌ

Bí agbára Rẹ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí ìṣe iye àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa imọ ẹni tí o pe wa nípa ògo àti ọláńlá Rẹ (2 Pet. 1:3).

“IMỌ JẸ AGBÁRA”

Nítorí, agbára ni imọ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú agbára sii/ju bẹẹ lọ imọ Kristi ń ro ènìyàn lagbara ni gbogbo ona.

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ

Notòótọ́, ko wúlò kí a máa gbé inú ayé, bí kò ṣe ìgbà tí a ba mọ ẹni tí ń darí rẹ. Ilé ayé a máa dùn julọ nígba tí a ba fún Jésù Kristi ni Oye Mo ti kú nínú ayé wa. Èyí túmọ̀ sí pé Òun ni yóò máa dárí ọkàn wa, Ifẹ̀ wa, ohun ìní wa, ohun gbogbo tí a ní pẹ̀lú àwọn ìbátan wa, gbogbo àwọn ẹni tí a mọ pẹ̀lú. O túmọ̀ si pe Oun o ń darí wa! Ibi yii ni ayé tí bẹ̀rẹ̀, nípa fífún Jésù nìkan ni àṣẹ. Rántí, nígbà tí Jésù bá ní àṣẹ, nígbà tí O ba n dari, a borí! Ṣùgbọ́n kin ni a nílò láti ṣe àṣeyọrí nínú ayé yii? Nígbà tí a ba ti gbé Jésù si ipo atukọ, a ti gba pe Oun ni o dárí. Kin ni a o wa ṣe rẹyìn tí a ba ti gbe igbesẹ yii? Ẹsẹ akọsori wa ni ìdáhùn sí èyí. Ẹsẹ kanṣoṣo yii n sọ fún wa pe Jésù Kristi ń fún wá ní ohun gbogbo tí a nílò nínú ayé. Nítorí náà, dípò kí a máa wo ojú àwọn ‘tí wọn ro pé àwọn gbọn’ tí wọn máa ń sọ fún wa nípa àwọn ohun tí a nílò, ẹ jẹ ki a maa wo Ẹni kan ṣoṣo tí kii kùnà nípasẹ̀ Ọrọ Ọlọ́run ti ko ni àbùkù tàbí àṣìṣe. Nínú rẹ ni a ti le ri agbára atokewa Rẹ, oun ni agbára tí o ju agbára miran lọ. Nígbà tí afẹ́fẹ́ àti igbi ń ṣíṣẹ ìbínú wọn lórí òkun Galili, Jésù ba wọn wí, ohun gbogbo si dakẹ jẹẹ. Ẹnu ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn si agbára ńlá Jésù, wọn si béèrè, “Ta ni eleyii? Kódà afẹ́fẹ́ àti igbi gbọ tiRẹ”. Agbára tí o le e fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún igbe ayé àti ìwà bí Ọlọ́run nìyẹn. Ṣùgbọ́n o gbọ́dọ̀ pinnu, lakaka kí o si poungbẹ fún agbára yii nípa ìgbàlà àti ìdàgbàsókè nínú imọ Kristi, nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ ti a ti kọ, Bíbélì. Báwo ni o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́/ṣaṣaro Ọ̀rọ̀ náà tó si?

ÀṢÀRÒ LÁTI ÌNU BÍBÉLÌ FÚN Ọ̀SẸ̀ KÍNNÍ

Mon. 14: Imọ Ń Ṣafihan oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run (O.D 77:1-3)

Tue.   15: Imọ A maa Fi Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Si Ìṣe (O.D 77:4-6)

Wed.  16: Imọ A Máa Tàn Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Kalẹ (O.D 77:7-10)

Thur.  17: Imọ Máa Ń Pa Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Mọ (O.D 77:11-13)

Fri.     18: Imọ Maa N Fìdí Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Mulẹ (O.D 77:14-15)

Sat.    19: Imọ Ń Ránni Lọwọ Láti Mọrírì Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run (O.D 77:16-20)

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN

1. Imọ Ọlọ́run ní agbára tí ń dojúkọ a ti o si n ṣẹ́gun ẹ̀kọ́ èké nínú ìjọ àti nínú ayé lapapọ.

2. A máa ń ní ìdánilójú èyí nípa kí a kọkọ ṣe ayẹwo ohun tí a gbọ, dídán án wò nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gẹgẹ bí àwọn ará Berea tí ṣe ni Makadonia (Ìṣe 17:11). A tún gbọ́dọ̀ di òtítọ́ ọrọ Ọlọ́run mú ṣinṣin (2 Tim. 2:15). Bí a bá ṣe ń ka ọrọ Ọlọ́run sì ti a si n ṣe àṣàrò nínú rẹ déédéé sí (Jọs. 1:8); bẹẹ ni a ń ṣe alábàápín rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn laarin Ìjọ àti nínú ayé lapapọ.

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA

ILEPA: Láti lè gba àwọn onigbagbọ níyànjú láti dàgbà nínú imọ òtítọ́ (irin àti ibaṣepọ) Olúwa Jésù Kristi.

ÀWỌN ERONGBA: Ní òpin ẹ̀kọ́ yii, akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ le e:

i. ti dabi àwọn Aposteli ni fífi ami ìṣetan láti dàgbà nínú ẹ̀mí, àti ki wọn si dàgbà de ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ imọ Rẹ pẹ̀lú ìwà bí Ọlọ́run hàn;

ii. Jíròrò lórí àwọn ewu ti o wa ninu kíkọ imọ òtítọ́ tí o wa ninu Olúwa wa Jésù Kristi nìkan;

iii. Jíròrò lórí ìbínú Ọlọ́run ti o bọ wa sórí àwọn ti wọn tẹsiwaju nínú aiwa bí Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀kọ́ èké; àti

iv. túbọ̀ ṣetan láti gbé ìgbé ayé tí yóò fi hàn agbaye, lai wo tí ìfiṣẹlẹya wọn, pé imọ Kristi nìkan ṣoṣo ni o n fúnni ní agbára tòótọ́ tí o si wa títí láé.

IFAARA

ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: HÓṢÉÀ 4:6; ROMU 10:1-4; HEBREW 8:11-12; 2 PÉTÉRÙ 1:2-4

Ògo ni fún Ọlọ́run Olódùmarè fún mímú wa la ẹ̀kọ́ kẹrin já, níbi tí a ti jíròrò nípa, OORE-Ọ̀FẸ́ ỌLỌ́RUN DI MÍMỌ́ NÍNÚ JÉSÙ yii ni kíkún, ẹ si ti bẹ̀rẹ̀ si gbádùn ọrọ àgbọn – ọn gbẹ tí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú Kristi Jésù.

Ẹ̀kọ́ tí lọọlọ yii ni a pe ni ‘AGBÁRA IMỌ.’ O yanilẹnu, ni bí Bíbélì ṣe mú imọ gẹ́gẹ́ bí ohun iyebíye! Gbogbo agbára tí o ń wa lati ọdọ Ọlọ́run láti máa gbé ìgbé ayé àti láti jẹ oníwà-bí-Ọlọ́run máa ń wa nípasẹ̀ imọ — imọ Rẹ. A ní láti mú ìlànà àti ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ ni Pataki nítorí nínú rẹ ni iye àti ìwà-bí-Ọlọ́run dájú. Imọ lè ma fi ìdánilójú ìwà-bí-Ọlọ́run hàn, ṣùgbọ́n bí o ti wu ki o mọ, o n tọni si ọna ti ìwà-bí-Ọlọ́run. Ní idakẹji, àìmọkan a máa fi ìdánilójú aìwà-bí-Ọlọ́run han, nítorí Ìwé Mímọ́ wí pé agbára àtọ̀runwá to ń tọni si ìwà-bí-Ọlọ́run ni a ń fúnni nípasẹ̀ imọ Ọlọ́run.

Kí kan ìṣe imọkimọ kan ṣáá ní yóò yọrisi níní ìrírí agbára Ọlọ́run; imọ ọrọ Ọlọ́run nìkan ni máa ń tọ ènìyàn si imọ tòótọ́ Rẹ, àti ní ayọrisi èyí, agbára Rẹ. Imọ tí ó da lori ọrọ Ọlọ́run nìkan ni yóò so èso níní ìrírí Ọlọ́run àti agbára Rẹ nitòótọ́. Eredi èyí ni pé, a fi agbára Ọlọ́run han, a si n ní ìrírí nínú ọ̀rọ̀ Rẹ. Nítorí náà, láti mọ Ọrọ Rẹ ni láti mọ àti láti ni ìrírí agbára Rẹ.

A gbàdúrà pé a o fún wa ní agbára nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ láti ni ìrírí Ọlọ́run lọtun, kí a si túbọ̀ ro wa lágbára síwájú sii, nípasẹ̀ imọ Ọlọ́run, ní orúkọ Jésù. Àmín.

Èyí jẹ ẹ̀kọ́ ọlọsẹ méjì pẹ̀lú àwọn ìpín pàtàkì méjì, I àti II. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni a tún pin si A àti B.

ÌPÍN KÍNNÍ:IMỌ ÒTÍTỌ́: MA ṢE KỌ Ọ SILẸ

Ìpin àkọ́kọ́ yii n sọ nípa àtúbọ̀tán tí kò dára tí aini imọ Ọlọ́run máa ń ní. Ẹni tí ko bá ní ìmọ̀ Ọlọ́run ń pa ara rẹ. Ní ọ̀nà miran, ẹni tí o ní ìtara tí ko si ni imọ ń ṣe ara rẹ ní ijamba ńlá. Bákan náà, imọ tí a ní ti ko wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni kii dúró pẹ; torí pé lọgan ni yóò pòórá bí afẹ́fẹ́. Ṣùgbọ́n nígba tí a ba ni imọ òtítọ́, a gbọ́dọ̀ dii mu ṣinṣin, pẹ̀lú ìtara àti ìpinnu kí a ma ṣe jẹ́ kí o bọ.

ÌPÍN KÍNNÍ: IMỌ ÒTÍTỌ́ JẸ AGBÁRA

Ipin yii bákan náà ń sọ nípa àwọn ohun méjì Pataki. Ekinni, Imọ Ọlọ́run a máa ní Agbára Atokewa, níbi tí a o ti ní ààyè si ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára Ọlọ́run ti o maa n wa nípasẹ̀ imọ Ọlọ́run. Èkejì ni pé, Ọlọ́run ṣe ìlérí imọ Rẹ fún wa. Èyí ni yóò di mímúṣẹ nínú wa nígbà tí a fi tọkàntọkàn ṣe afẹri Rẹ ni àwọn oríṣiríṣi ọna — Ẹ̀mí Mímọ́, Bíbélì àwọn olùkọ́ni tí a ti gbala tí a si ti sọ di mímọ, pẹ̀lú ibaṣe papọ pẹ̀lú àwọn ará.

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́

I. IMỌ TÒÓTỌ́: MAṢE KỌ Ọ SILẸ

A. ÀÌNÍ IMỌ ỌLỌ́RUN JẸ ÌṢEKÚPARA-ẸNI

B. ÌTARA LÁÌSÍ IMỌ LEWU

II. IMỌ TÒÓTỌ́ JẸ AGBÁRA

A. IMỌ ONÍWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN MÁA N BÍ AGBÁRA ATỌRUNWA

B. ỌLỌ́RUN ṢÈLÉRÍ IMỌ RẸ FÚN WA.

I. IMỌ TÒÓTỌ́: MAṢE KỌ Ọ SILẸ (Hóṣéà 4:6; Romu 10:1-4)

Bíbélì gba wa níyànjú láti ra òtítọ́ kí a ma si ṣe ta á. Imọ òtítọ́ ni imọ tí o máa ń ṣe àfihàn tí o si maa n jọ̀wọ́ gbogbo ohun rere àti àwọn ohun tí Ọlọ́run láti òkè wa (wo Jak. 1:17), nípa ti ara ati ni ẹmi. Torí náà, ẹnikẹ́ni tí o ba ṣoriire láti ni í gbọ́dọ̀ dáàbò bo o gidi nípa gbígbé nínú rẹ, àti fún un. Kikọ ọ silẹ lewu!

A. ÀÌNÍ IMỌ ỌLỌ́RUN JẸ ÌṢEKÚPARA ẸNI (Hos. 4:6)

A ke àwọn ènìyàn Mi kúrò nítorí àìní imọ tí kọ imọ silẹ, Emi o si kọ ọ, tí ìwọ kì yóò ṣe àlùfáà Mi mọ: níwọ̀n bí ìwọ ti gbàgbé òfin Ọlọ́run rẹ, Èmi pẹ̀lú o gbàgbé àwọn ọmọ rẹ (ẹsẹ 6)

i. Ẹsẹ 6a: Ẹsun to báni nínú jẹ ní fún àwọn ènìyàn Israẹli. Ọkàn Ọlọ́run bajẹ nígbà tí O ṣe aroye yii, tí o sọ pe, “A ké àwọn ènìyàn Mi kúrò nítorí àìní imọ…”

ii. Àwọn ọmọ Israẹli ni òfin, àwọn wolii, àwọn ìlérí Ọlọ́run, àti ìdánilójú tí wíwà Mèsáyà tí yóò wa gba wọn la kúrò nínú ẹṣẹ wọn. Kíkọ wọn láti gbọ́ràn si/kíyèsí àwọn ìtọ́ni àti ikilọ Ọlọ́run, a ke wọn kúrò a si tu wọn ka. Nítòótọ́ àìsí imọ Ọlọ́run jẹ́ ìṣekúpara ẹni.

iii. Àwọn adari orílẹ̀-ede náà, àti àwọn àlùfáà paapaa, ní a di ẹbi ọrọ náà ru fún ipò ipadasẹyin nípa ti ẹ̀mí èyí tí o báni nínú jẹ laarin awọn eniyan Ọlọ́run, àwọn ni wọn fọwọ́sowọpọ pẹ̀lú àwọn ọba àti ọlọrun àjèjì, dípò wiwo Yahweh fún iranlọwọ nígbà àìní. Nibo/tàbí ta ni ìwọ ń koju sì nígbà ìṣòro?

iv. Ẹsẹ 6b: Gẹ́gẹ́ bi àbájáde kíkọ àti gbigbagbe tí Ọlọ́run kọ Israẹli tí O si gbàgbé wọn, a o ke wọn kúrò (wo Deut. 28:15swj).

v. Nínú Isaiah 5:13, a kilọ fún ìjọba Gúsù tí Juda niti ofo/ìparun tí ìjẹniya yóò muwa. Egun tí a sọtẹ́lẹ̀ rẹ nípasẹ̀ wolii wa si ìmúṣẹ nínú ìgbèkùn Bábílónì ní 606-536. S.I.K. Imọ Ọlọ́run ń pè fún ìgbọràn, fún iduroore àti iseso.

vi. Níwọ̀n ìgbà tí òtítọ́ ńlá tí Májẹ̀mú Láéláé tó dúró fún ẹ̀kọ́/ìtọ́ni wa (Rom. 15:4), títẹsiwaju nínú àìmọkan imọ Ọlọ́run le mú àjálù ba àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n a le ri iranwọ nínú Ọlọ́run (Hos. 13:9).

vii. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbọ́ràn/kíyèsí ikilọ tí a fún Israẹli yii, nítorí ọpọ ni ó ti ṣáko lọ nípasẹ̀ ihinrere èké, tí àwọn olùkọ́ eke ṣe agbatẹru rẹ. Ọ̀pọ̀ ni a ń parun/ké kúrò àìní imọ, nítorí wọn tí kọ ihinrere tòótọ́ tí oore-ọ̀fẹ́ náà tí wọn si n gba àwọn ẹ̀kọ́ tí kò fìdí múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (wo Ìṣe 5:36-37).

viii.ṣíṣe bi àwọn ará Berea jẹ igbaniyanju ti àwọn onigbagbọ gbọ́dọ̀ fi etí si, láti ni ati lati pa imọ Ọlọ́run mọ (Ìṣe 17:11).

B. ITARA LÁÌSÍ IMỌ LÉWU (Rom. 10:1-4)

Nítorí Mo gbà ẹri wọn jẹ pe, wọn ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kí ìṣe gege bí imọ (ẹsẹ 2)

i. Ẹsẹ 2: Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o ni ìtara fún àwọn nǹkan tí ẹṣin, ṣùgbọ́n tí wọn ko mọ òdodo tí ń ti ọdọ Ọlọ́run wa, nípa èyí, wọn ń ṣàfẹ́rí/wọna àti ṣagbakalẹ tí ara wọn, ìyẹn ṣíṣẹ alakoso òye ara wọn àti ìṣiwèrè tí àṣà àwùjọ nínú èyí tí wọn n gbe. Èyí lewu.

ii. Ìtara láìsí imọ tí mú akaimoye òfo/ìparun wa ninu itan! Ronú nípa iye igbesẹ ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn tí a rí bi olùgbàlà tí wọn tí leri leka ohun tí ko ṣe e ṣe nígbà tí wọn sinmi le àìmọkan àwọn ará ìlú/mẹkunnu gẹ́gẹ́ bi sí erongba/ìpinnu wọn nítòótọ́.

iii. Pípa àìní òye pọ mọ ìtara ẹsin máa ń yọrisi ìṣofin àti iwa ipa tí ẹsin. Ní búburú jáì, àwọn tí wọn ba tẹsiwaju nínú irú ìtara àìmọkan bẹẹ a máa jẹ ẹni àjèjì si Kristi.

iv. Ọ̀pọ̀ àwọn Farisí ni wọn kún fún pípa àwọn òfin òtítọ́ mọ si ipalara ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, tí wọn ń da ara wọn lare níwájú àwọn ènìyàn, gẹgẹ bí wọn tí ń ṣafihan àwọn iṣẹ́ òdodo wọn (Mat. 23:23-26; Luk. 16:14-17; wo Fil. 3:4-7). Nínú ìtara wọn, wọn ń pàdánù òdodo Rẹ. Ní ayọrisi èyí, wọn ń kọsẹ lára Jésù (wo Rom. 10:3,4).

v. O ṣe é ṣe kí a bọ sínú èrò ọkàn pé a gbọ́dọ̀ fi nnkan kún ìṣẹ́ àṣeparí Kristi, láti jẹ ìtẹ́wọgbà tòótọ́ si Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni, gbigbọran sì àwọn òfin/àṣẹ Kristi kí ìṣe bí mo ba fẹ (Jhn. 14:15). Síbẹ̀, àwọn iṣẹ́ rere wa kí ìṣe ọna sì ìṣàgbekalẹ ibaṣepọ tí o tọ pẹ̀lú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni a ko le mú ara wa yẹ nípasẹ̀ ìgbọràn wa. Òdodo Kristi nìkanṣoṣo tí a gbìn sínú wa nípa ìgbàgbọ́, ní o máa ń ṣe èyí fún wa (wo Isa. 64:6).

vi. Israẹli kọ láti gba òdodo tí o wa nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ dípò bẹẹ, wọn rankankan mọ èyí tó wá nípasẹ̀ òfin, eredi nìyii tí wọn fi jẹ onítara àlaìmọkan (Rom. 10:1-3). Bákan náà ni Jẹfta pẹ̀lú ṣafihan ìtara to mewu lọ́wọ́ láìsí imọ. Ènìyàn le fọ́jú kí o si jẹ àlaìmọkan paraku (Jhn. 8:39-44; 9:13-41).

vii. Àwọn onítara fún Ọlọ́run wọnnì láìsí imọ, n dari sí/lọ ní ọna ti ó dàbí ẹni pé o tọ ṣùgbọ́n tí o ń yọrisi ìparun (wo Òwe 14:12).

viii Ìtara ni agbara ati ìtẹnumọ ohun kan, tàbí erongba kan. O ṣe é ṣe kí a ní ìtara tí o lòdì. Èyí ni o fẹ́rẹ̀ẹ́ pa Pọ́ọ̀lù rún kí o tó di ẹni ìgbàlà. Níni ìtara fún ohun tí o jẹ ti Ọlọ́run lai ni imọ nípa Rẹ ni ọna ìrírí àti ibaṣepọ pẹ̀lú Rẹ ní yóò yọrí sí ìtara si ọdọ èṣù, bí a ko ba ronupiwada.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1. Imọ yowu tí a ko ba gba ninu Ọlọ́run jẹ ẹdẹ àti òjìji ikú.

2. Ṣọ́ra láti máṣe jẹ onítara àlaìmọkan nínú àwọn ohun tí ẹsin, kí o si ma ba maa dojú ìjà kọ Ọlọ́run laimọ. Béèrè lọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù!

ÌṢẸ́ ṢÍṢẸ

Ṣàlàyé ìyàtọ̀ to wa laarin imọ àti imọ Ọlọ́run.

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÌṢẸ́ ṢÍṢE

* “Ìmọ̀” nihin in ń tọka sì imọ ènìyàn. O jẹ ìmọ̀lára lapapọ, tàbí níní ìròyìn, òtítọ́, erongba, òdodo, tàbí àwọn igbesẹ,

* Ìmọ̀ Ọlọ́run nii ṣe pẹ̀lú níní ìmọ̀lára tààrà, tàbí ìròyìn tí o jẹ ojúlówó nípa Ọlọ́run ti ó nii ṣe pẹ̀lú ibaṣepọ tàbí òye, tí a ní nípasẹ̀ ikẹ́kọ̀ọ́ nípa Rẹ, nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi, èyí si wa ninu ọrọ Rẹ.

* Nígbà tó ènìyàn ba fi òtítọ́ ṣe agbeyẹwo ìyàtọ̀ laarin imọ Ọlọ́run, kíá ni yóò mọ bí òun ti jẹ ope to nítòótọ́; torí pé imọ ènìyàn kéré púpọ̀ sí ìyanu ògo tí imọ Ẹlẹ́dàá.

Ẹ jẹ ki a wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa àwọn ìyàtọ̀ tí o wa laarin imọ ènìyàn àti imọ Ọlọ́run:

i. Imọ ènìyàn ni o ni gbedeke, nígbà tí imọ Ọlọ́run kò ní odiwọn. Imọ ènìyàn ni ko leè kọjá ìrírí rẹ nínú ayé. Àwọn ìrírí wọnyi lè wa lati oríṣiríṣi ọna, yálà láti ipasẹ àwọn ẹ̀yà ara márùn-ún tí a ń lo julọ, tàbí nípasẹ̀ imọ tí a ní láti inú ìwé, àti bẹẹ bẹẹ lọ. Nígbà tí ohun gbogbo tí ènìyàn ni ni imọ tìrẹ pẹ̀lú òye láti sinmi le, ìwòye rẹ nípa ilé ayé ni o ṣókùnkùn tí o si jẹ ti apakan.

Imọ Ọlọ́run ni idakeji, ní kó ni gbedeke lọ́nàkọ́nà, tàbí bí o ṣe rí. Ẹnikẹ́ni tí o ba gbagbọ pé èrò òun pẹ̀lú ti Olódùmarè gbọ́dọ̀ ṣe Ìdánwò tí Ọlọ́run ṣe fún Jobu ni Jobu 28-41. Ìdánwò yii jẹ Ìdánwò àṣekágba tí o ń sọ nípa ìyàtọ̀ laarin imọ tí o ní ìwọ̀n àti èyí tí ko ni ìwọ̀n. Kódà pẹ̀lú gbogbo àwọn ìyanu eto ṣàyẹnsi tí a ń rí lonii, a kàn le dáhùn díẹ̀ nínú àwọn ìbéèrè tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ Jobu ni. A ko tilẹ̀ le e ta putu, kí a máa sọ pé a oo ṣe àṣeyọrí nínú Ìdánwò náà.

Imọ Ọlọ́run ni ko ni odiwọn lọ́nà kọna. Ọlọ́run mọ ohun gbogbo nípa ènìyàn, nípa ti ara ati èrò inú, torí pé Òun ni Ó da a. Ọlọ́run mọ bí ohun gbogbo tí ń ṣíṣẹ papọ nínú ayé, torí pé Òun ni O fi wọn sì ààyè wọn. O tẹsiwaju sii. Síbẹ̀, imọ Ọlọ́run kii ṣakii bẹẹ ni kii dibajẹ.

ii. Imọ ènìyàn jẹ èyí tí a fi ojú rí, nígbà tí tí Ọlọ́run jẹ́ ti ẹmi. Nítorí pé láti ipasẹ ìrírí ni imọ ènìyàn tí ń wa, pẹ̀lú imọ àwọn ẹlòmíràn, imọ tí ènìyàn, nínú ìfẹ́ ọkàn rẹ, ko jọ papọ ni ó le e wúlò fún àwọn ohun tí a fi ojú tí nìkan. Nítorí náà, imọ ènìyàn pẹ̀lú òye rẹ nípa àwọn ètò ayé ni kí i si, bi ki i ba ṣe ọpẹlọpẹ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ rẹ. Ìṣòro tí ó ga julọ tó ènìyàn ń koju ni ifẹ láti ṣe àmúlò imọ tí ara Rẹ nìkan ni ṣíṣe ìpinnu kí o ma si wa ọgbọ́n Ọlọ́run láti inú Ọrọ Ọlọ́run. Ní idakeji, imọ Ọlọ́run jẹ́ láti inú ẹ̀mí wa. Àwọn ohun tí ayé yii ti a fi ojú rí ko le e di lọwọ, ṣùgbọ́n dípò bẹẹ o ga ju u lọ pẹ̀lú imọ Ẹni tí O kọjá àwọn ohun tí a fi ojú rí wọnyi (Isa. 55:8-9).

Imọ Ọlọ́run ju tiwa lọ, nítorí imọ Rẹ nípa àwọn ohun tí ẹmi. Lai si ìfihàn imọ náà láti inú Ìwé Mímọ́, òtítọ́ ni pé ènìyàn yóò sọnù sínú ilakaka rẹ láti wa imọ àti òye kiri. Ọlọ́run ti ṣe àfihàn àwọn òtítọ́ ńlá tí Ìwé Mímọ́ láti inú ibú imọ Rẹ. Síbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan wọnyi níwájú wa, a ko tilẹ̀ tii mọ ohunkóhun bí a ba n sọ nípa imọ Ọlọ́run. Nígbà tí a ba n ṣe agbeyẹwo afiwe imọ àti òye, Ẹlẹ́dàá a máa pa ohun tí a da layo, dáadáa ni.

iii. Ní akotan, imọ Ọlọ́run ní imọ tí a ní nípasẹ̀ ìgbàlà nínú Kristi Jésù nìkan. Òun ni imọ tí ń gbani tí o fìdí múlẹ̀ nínú ìpinnu Ọlọ́run nìkan láti fi ara Rẹ hàn fún àwọn ẹlẹṣẹ (Gen. 18:18-19; Eks. 33:17; Orin Daf. 139; Jer. 1:5; Amosi 3:2; Efe. 3:15). Èyí kí i rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú imọ tí ènìyàn.

Leave a Reply