IJO APOSTELI KRISTI LAGBAYE  OMI IYE NAA  OJO: OJOBO (THURSDAY), MARCH 17, 2022 : AKORI: IRAPADA/IDANDE PATAPATA

By | March 17, 2022

IJO APOSTELI KRISTI LAGBAYE  OMI IYE NAA  OJO: OJOBO (THURSDAY), MARCH 17, 2022 : AKORI: IRAPADA/IDANDE PATAPATA

 

 

IJO APOSTELI KRISTI LAGBAYE

OMI IYE NAA

OJO: OJOBO (THURSDAY), MARCH 17, 2022

IRAPADA/IDANDE PATAPATA

KA: LUKU 21:25-28

AKOSORI: Sugbon nigba ti nnkan wonyii ba bere si ise, nje ki e wo oke, ki e si gbe  orin yin soke; nitori idande yin kusi dede (Luku 21: 28)

ITUPALE

Igbese irapada n pe fun, ni pataki julo, sisan owo itusile kan pato lati gba eni/ohun to se iyebiye si ni. Jesu Kristi Oluwa wa yii ti se asepe eyi leekansoso, fun onigbagbo ati ijo Re, nipa opo ina Re ati iku Re lori agbelebu ni Kalfari (O.D. 49:6; Jhn. 19:30). Abala miran ti o tun le mu ki eniyan wa ni ifojusona ki o si se itewogba si Olorun ni ise Emi Mimo to n lo lowolowo ninu onigbagbo  (Filipi 1:28-30;2:12,13). Alaye irapada to wulo ti o keyin, eyi ti ise aaye tabi igbese didi eni igbala kuro lowo agbara buburu, ni o fe bere bayii. Itokasi eyi ni ifarahan ti oniruuru awon ami to gba aye kan to n lo lowolowo ti won wa lati saaju ti yoo si se atona isele yii, gege bi a  ti safihan re ninu ibi kika wa ti oni (Lk. 21:28; i Pet. 1:6-12). Ipe yoo dun si gbogbo awon orile-ede lati gbaradi fun isele pataki ati ologo yii, eyi ti o wa  lati fi opin si gbogbo awuye nipa Tooto ti Olorun Alaaye.


 

Siwaju sii, ninu ise irapada patapata ti onigbagbo ninu Kristi, awon ibapade ati iriri kan pato ko se e yera fun. Eyi pe fun “gbigbe nnkan,” eyi ti ise ise ona tabi igbese gbigbe awon oro tabi aworan si ara igi, okuta, irin  abbl. Eniyan le finuro o daradara nipa ohun ti eyi ni tumosi. Ewe, eyi ti a ri ni je iriri awon kan ninu awon omo eyin Oluwa ni oju ona won si Emmanusi ninu  Luku 24:13-35.

Ese 31,32 (oju won si la…won si ba ara won so pe okan wa ko ha gbina ninu wa, nigba ti O n ba wa soro ni ona ati nigba ti o n tumo iwe-Mimo fun wa?)  n safihan igbese “gbigbona” yii ati gbigbin awon otito ati awon eko iwa rere sinu iwa nipase  eda inu tabi emi wa nipase Olorun Alaaye, gege bi a ti sasotele re nipase awon wolii Re igbanni (Sek. 3:8-10). Iye awon ti won ba ti to Kristi wa ti won si n dagba ninu Re nikan ni won le ni iriri irapada patapata yii. Iwo ha ti ni iriri eyi bi?.

AWON KOKO ADURA

1.  Iwo okan mi, gbo iro agogo irapada patapata ki Emi didabi Kristi ni gbogbo ona re soji ninu mi, ni oruko Jesu.

2. Wo mi pale ki o si tun mi mo si aworan ayeraye Re, Jesu Oluwa.

3. Gbadura fun Ijo Aposteli Kristi, ti Ekun Nla ti Akinyele, Baba wa ninu Oluwa, Alabojuto, ati awon osise re ni oniruuru ipele, gege bi Emi Olorun ba se dari.

AFIKUN IBI KIKA FUN ONI: JOSUA 23 – 24; Awon Onidajo 1

Leave a Reply